Wíwo Ayé
A Ti Òmìnira Ìsìn Lẹ́yìn
Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri ti Tokyo sọ pé, ní March 8, 1996, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Japan dájọ́ pé ilé ẹ̀kọ́ Kobe Municipal Industrial Technical College rú òfin nípa lílé Kunihito Kobayashi, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, dànù, nítorí pé ó kọ̀ láti kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ eré ìgbèjà ara ẹni. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ilé ẹjọ́ gíga jù lọ Japan kọ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí kọ́lẹ́ẹ̀jì náà pè, ó sì gbé ìlànà kan kalẹ̀ fún àwọn ẹjọ́ ọjọ́ iwájú. (Jọ̀wọ́ wo ìtẹ̀jáde Jí!, October 8, 1995 fún ìsọfúnni síwájú sí i.) Ilé ẹjọ́ náà mọ̀ pé ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe kọ̀ láti kópa nínú eré ìgbèjà ara ẹni kendo “jẹ́ láti ọkàn wá, ó sì ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ tí ó jinlẹ̀” pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ilé ẹjọ́ náà pé Kobayashi ní “akẹ́kọ̀ọ́ títayọ kan,” ó sì sọ pé ilé ẹ̀kọ́ náà ì bá ti pèsè ẹ̀kọ́ ìmárale mìíràn fún un dípò eré kendo.
Àìgbọlọ́rungbọ́ Ń Tẹ̀ Síwájú
Kádínà Joachim Meisner rí i pé “ìtẹ̀sí alágbára síhà àìgbọlọ́rungbọ́” wà ní Germany. Meisner sọ pé ètò ìjọba Kọ́múníìsì lè ti pàdánù ní ti ètò ọrọ̀ ajé, àmọ́ ó jọ pé ó ti jèrè ní ti àkópọ̀ èrò inú. Ó wí pé: “Ó jọ pé ìtẹ̀sí yìí ti tàn kálẹ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè tuntun [Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ rí] dé àwọn orílẹ̀-èdè ògbólógbòó [ìhà ìwọ̀ oòrùn].” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Weser Kurier ṣe sọ, nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn mílíọ̀nù 16 olùgbé Ìlà Oòrùn Germany tẹ́lẹ̀ rí ni kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kankan. Ìròyìn náà ń tẹ̀ síwájú pé: “Bí ṣọ́ọ̀ṣì kò bá ní ìgboyà láti gbé ìgbésẹ̀ lílágbára ní kíkéde òtítọ́ tí a ṣí payá fún un, nígbà náà kò ní ìrètí.”
Jọ̀wọ́, Bá Mi Gbé Kòkòrò!
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé gbogbo ènìyàn kọ́ ni yóò rí ìfojúṣọ́na rírí ìwòsàn nípa jíjẹ kòkòrò gẹ́gẹ́ bí ohun tó bára dé, àmọ́ àwọn púpọ̀ yóò rí i bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Asiaweek sọ, èrò náà kì í ṣe tuntun. Ní Singapore, ilé àrójẹ Imperial Herbal Restaurant máa ń ta oúnjẹ tí ó ní èròjà bí èèrà àti àkekèé nínú, tí àwọn méjèèjì ní òkìkí fún níní ohun aṣaralóore àti awonisàn nínú. Obìnrin tí o ni ilé àrójẹ náà, Ìyáàfin Tee Eng Wang-Lee, sọ pé èèrà dára fún làkúègbé, ó sì sọ pé májèlé àkekèé máa ń dẹ iṣan, ó sì ń gbani lọ́wọ́ ẹ̀fọ́rí túúlu. Àwọn egbòogi tí a fi kòkòrò ṣe mìíràn ní nínú, múkúlù gbígbẹ láti gbani lọ́wọ́ ìrora; ìdin cicada láti gbógun ti ikùn tí atẹ́gùn kún tandi, ọgbẹ́ ẹnu, àti èéyi; àti ìtẹ́ agbọ́n gbìgbẹ láti pa àwọn kòkòrò àrùn. Báwo ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ṣe ń rí lẹ́nu ènìyàn? Àwọn kòkòrò máa ń ní ìtọ́wò mímú, tí ó dà bí ọtí kíkan, àwọn àkekèé sì máa ń rọ̀. Ìyáàfin Wang-Lee sọ pé: “Àwọn ènìyàn ní láti gbìyànju rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà kí ó tó lè mọ́ wọn lára.”
Dáwọ́ Ìsúni Dúró!
Oríṣiríṣi másùnmáwo ń pọ̀ sí i, nígbà tí Ellen McGrath, tí ó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn United States náà, Health, ó pèsè àwọn ọgbọ́n ìwéwèé díẹ̀ tí kò níí jẹ́ kí másùnmáwo ṣamọ̀nà sí ìsúni nínú ìgbésí ayé rẹ.
◼ Máa sinmi lóòrèkóòrè, ìsinmi lọ́nàkọnà: Rìn kiri fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá tàbí kí o mí kanlẹ̀ pẹ̀lú ìsinmẹ̀dọ̀ fún ìṣẹ́jú márùn-ún. Ya ìṣẹ́jú 15 sọ́tọ̀ láti kàwé tàbí láti ronú ní ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
◼ Darí ara rẹ: Fi àwọn ohun tí ó lè mú ọ rẹ́rìn-ín yí ara rẹ ká—fọ́tò, òdòdó, tàbí ohun ìránnilétí. Gbé ìgbésẹ̀ láti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ, kí o sì ṣètò fún àkókò tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní másùnmáwo nínú láti ṣe àwọn ohun pípọn dandan.
◼ Jẹ oúnjẹ tí ń ṣara lóore: Má ṣe máa ṣiṣẹ́ títí di ìgbà tí ebi bá ń pa ọ́ gan-an tàbí kí o jẹ ìpápánu pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti dẹ̀rọ̀ ebi tí ń pa ọ́—bí ọwọ́ rẹ bá tilẹ̀ dí gan-an. Jíjẹ oúnjẹ tí ó ní èso àti ewébẹ̀ nínú déédéé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àárẹ̀.
◼ Máa tẹ̀ síwájú: Ṣíṣe eré ìmárale gbígbagbára máa ń dín másùnmáwo kù, ó sì máa ń mú kí ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn àti èro wíwà déédéé pọ̀ sí i. Mú kí ó jẹ́ ohun amóríyá!
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọmọdé Gbé Májèlé Jẹ
Ìwé ìròyìn Àjọ FDA Consumer sọ pé àwọn ọmọdé wà nínú ewu jíjẹ májèlé nínú ilé àwọn tìkára wọn nípa mími ìwọ̀nba hóró egbòogi kékeré kan tí kì í ṣe fún wọn. Mími egbòogi, kẹ́míkà ìtúnléṣe, àti ohun ọlọ́tí líle lè fa àìsàn àti ikú pàápàá fún ọmọ kékeré kan. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ tọ́jú àwọn nǹkan wọ̀nyí síbi tí ọwọ́ àti ojú wọn kò ní í tó. Àlòjù èròjà afúnni ní iron, títí kan àwọn fítámì ọmọdé, ń mú kí a máa ṣàníyàn gidi. Dókítà George Rodgers ti Ibùdó Àbójútó Ìjẹmájèlé ní Ẹkùn Kentucky, U.S.A., sọ pé: “Nítorí pé a ṣe [fítámì fún títọ́jú ọmọdé] bíi dáyá tàbí àwọn ẹ̀dá inú àwòrán ẹ̀fẹ̀, ó máa ń dà bíi dáyá, kò sì jọ egbòogi.” Àwọn ògbógi dámọ̀ràn pé, bí ọmọ kan bá yọwọ́ àmì àrùn ṣíṣàjèjì kan, bíi yíyí ojú lọ́nà tí kò bára dé tàbí oorun àsùnjù, tàbí bí ẹ bá rí ìgò egbòogi kan ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ ké sí dókítà kan tàbí ibùdó kan fún àbójútó ọ̀ràn májèlé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀ lé ìtọ́ni wọn gẹ́lẹ́.
Ìwé Kíkà—“Ó Ha Ń Ṣamọ̀nà sí Kíkú Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ Bí”?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe ní Ítálì fún Àjọ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Òǹṣèwé Kéékèèké ṣe sọ, ní ọdún tó kọjá, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará Ítálì “ni kò ṣí ìwé rí, tàbí bí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ rí, wọn kò tilẹ̀ rántí orúkọ ìwé tàbí orúkọ òǹkọ̀wé náà pàápàá.” Ìwé agbéròyìnjáde Róòmù náà, La Repubblica, ṣàkíyèsí pé gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn àwòrán, tí ó ní tẹlifíṣọ̀n nínú, sábà máa ń ní ipa púpọ̀ lórí ìwà, ìṣesí, àti ìgbésí ayé àwọn ará Ítálì ju àwọn ohun kíkà lọ. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Àwọn ará Ítálì, kì í kàwé, wọn kò sì mọ̀ pé àwọ́n ń pàdánù ohun pàtàkì kankan.” Ìwádìí náà tún fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Ítálì so ìwé kíkà mọ́ “àìlèfìdi ìbáṣepọ̀ ‘ọlọ́yàyà’ pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn múlẹ̀” àti “àìní ìfẹ́ni ọlọ́yàyà.” Àwọn tí kì í kàwé “gbà pé ìwé kíkà wulẹ̀ jẹ́ fífi àkókò ṣòfò,” ìyẹ́n jẹ́ ‘iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà,’ tàbí pàápàá pé ó “ń fa ‘kíkú wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.’”
Ìpè fún Ìrànlọ́wọ́
Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail sọ, ìpèsè ìkésíni orí tẹlifóònù lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn èwe tí wàhálà bá ní Kánádà ń rí 4,000 ìkésíni gbà lóòjọ́, ó gbé “ìwọ̀n àìnírètí jíjinlẹ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ” jáde. Christine Simmons-Physick, olùdarí ẹ̀ka ìgbani nímọ̀ràn fún ìṣètò náà, sọ pé: “Ìyípadà [ètò ọrọ̀ ajé] tí ń lọ lágbàáyé ń dá àìnídàánilójú sílẹ̀ fún àwọn àgbàlagbà, èyí sì ń nípa lórí àwọn ọmọdé.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdajì lára àwọn ìkésíni náà ló jẹ́ nípa ìbáṣẹpọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, ìpín 78 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọ́n sì jẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin, tí ó rọrùn fún gan-an láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ju àwọn ọmọkùnrin lọ. Simmons-Physick ṣàkíyèsí pé àwọn ọ̀dọ́ ń ṣe ìkésíni nítorí pé ó ń fún wọn ní àǹfààní láti rí i pé àgbàlagbà kan fi ọwọ́ gidi mú àwọn ìṣòro wọn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, àwọn òbí àti àwọn àgbàlagbà míràn lọ́pọ̀ ìgbà “máa ń ní ìtẹ̀sí láti fọwọ́ rọ́ ìṣòro àwọn ọmọdé sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà fún ìgbà díẹ̀—wọ́n máa ń wí pé bí wọ́n ṣe ń dàgbà ni ìṣòro wọn yóò máa pòórá,” ó fi kún un pé: “Bí o bá jẹ́ kí wọ́n ní irú ẹ̀mí ìrònú yẹn, jẹ́ kí ó yé ọ pé wọn kò níí wá bá ọ fún ìrànlọ́wọ́ mọ́.”
Àwọn Labalábá Afòkunṣọ̀nà
Ní oṣù March, lọ́dọọdún, àwọn labalábá monarch máa ń fò gba ojú gbalasa òkun tí ó fẹ̀ ní 800 kìlómítà, bí wọ́n ti ń ṣí láti Mexico lọ sí agbègbè kékeré kan ní ìhà etíkun Louisiana, U.S.A. Àwọn labalábá monarch náà yóò wáá kọrí sí ìhà àríwá, àwọn kan ń lọ jìnnà tó Kánádà. Ní oṣù October tí ó tẹ̀ lé e, àwọn ìrandíran wọn karùn-ún yóò gba ọ̀nà kan náà padà sí Mexico. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe máa ń mọ ibi tí wọ́n ń lọ pẹ̀lú ọpọlọ wọn kóńkó, tí ó jẹ́ kìkì ìwọ̀n orí abẹ́rẹ́? Èyí ṣì jẹ́ ohun àràmàǹdà. Ìwé agbéròyìnjáde Enterprise-Record ti Chico, California, ròyìn pé aṣèwádìí nípa labalábá, Ọ̀mọ̀wé Gary Noel Ross, gbà gbọ́ pé ó lè jẹ́ agbára òòfà ilẹ̀ ló ń darí àwọn kòkòrò náà. Ìbéèrè tí ń rúni lójú nípa rẹ̀ ni pé, Báwo ni ìwéwèé ìfòpadà sí Mexico ṣe la ìran márùn-ún kọjá? Ọ̀mọ̀wé Ross sọ pé: “Bí gbogbo èyí ṣe díjú pọ̀ tó kò ṣeé finú wòye.”
Ìkìlọ̀ Nípa Aṣọ Tuntun
Ìwé ìròyìn Asiaweek ti kéde ìkìlọ̀ nípa ewu tí ó wà nínú àwọn kẹ́míkà tí a fi ń ṣe aṣọ ní ilẹ̀ Faransé, England, àti Thailand. A máa ń rí gáàsì formaldehyde, èròjà amúǹkantọ́ tí ó lágbára tí a ń fi ṣe aró, nínú ọ̀pọ̀ aṣọ, wọ́n sì ní ó máa ń fa ìṣòro fún awọ ara, ojú, àti mímí. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ aṣọ lè wà nínú ewu, àyàfi bí àwọn ibi iṣẹ́ wọn bá ní ọ̀nà ìgbàjáde afẹ́fẹ́ tí wọ́n ṣe dáradára, tí kò sì sí ọ̀rinrin, àwọn òǹrajà sì gbọ́dọ̀ fọ aṣọ tuntun tí wọ́n bá rà, kí wọ́n tó wọ̀ ọ́, láti dènà ìpalára tí ó lè ṣẹlẹ̀.
Ìwà Ọ̀daràn àti Àwọn Ọ̀dọ́langba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà
Ìwé agbéròyìnjáde The St. Petersburg Press sọ pé, ní St. Petersburg, Rọ́ṣíà, “ìwà ọ̀daràn àwọn màjèṣí túbọ̀ ń burú jáì, tí ó sì ń jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe lọ́nà púpọ̀ sí i.” Fún àpẹẹrẹ, ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìlú ńlá kan ní 1995, wọ́n so ọmọkùnrin ọlọ́dún 13 kan mọ́ òkè, wọ́n sì lù ú pa ní gbàrà tí ó parí ìdánwò ìparí ọdún rẹ̀. Àníyàn tí àwọn òbí àti àwọn olùkọ́ ní nípa ìwà ọ̀daràn ní ilé ẹ̀kọ́ ṣokùnfà ẹ̀ka ẹ̀kọ́ pàtàkì kan fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lórí “Ìlànà Ìpìlẹ̀ fún Lílà Á Já,” àti “Ìlànà Ìpìlẹ̀ Ìṣègùn” fún àwọn ọmọbìnrin. Populi, ìwé ìròyìn Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Iye Ènìyàn, sọ pé níbi àpérò kan fún àwọn olùkọ́ ẹ̀ka ẹ̀kọ́ náà, a ṣí i payá fún wọn pé ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọbìnrin ilé ẹ̀kọ́ girama ní ìlú ńlá náà lérò pé iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹ́ apá pàtàkì ìgbésí ayé ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Síwájú sí i, iye ìṣẹ́yún tí ń wáyé láàárín àwọn ọmọbìnrin ọlọ́dún 17 àti àwọn tí wọ́n kéré sí wọn ni a gbà gbọ́ pé ó ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá.