Àwọn Adití Ń yin Jèhófà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ
FÚN ọ̀pọ̀ ọdún, ó ṣòro fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà láti kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí jẹ́ nítorí àìtó Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n mọ èdè àwọn adití. Ṣùgbọ́n ìyẹn ti ń yí pa dà. Àwọn Ẹlẹ́rìí púpọ̀ sí i ti kọ́ èdè àwọn adití, wọ́n sì ń wàásù fún àwọn adití. Lájorí ìgbésẹ̀ kan nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun yìí ni àpéjọpọ̀ àgbègbè kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Nàìjíríà ní ohun tí ó lé ní ọdún kan sẹ́yìn.
Ẹnì kan tí ó jẹ́ àyànṣaṣojú sí àpéjọpọ̀ yẹn, ní Ọ̀tà, Nàìjíríà, sọ pé: “O lè nímọ̀lára ìrunisókè tí ó gbalẹ̀ kan.” Ẹlòmíràn sọ pé: “Ìmọ̀lára tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, ìmọ̀lára ìyanu wà níbẹ̀.” Kí ló fa irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ wá? Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, gbogbo ohun tí wọ́n sọ ni a ṣe ògbufọ̀ rẹ̀ sí èdè àwọn adití. Ní àpéjọpọ̀ yí nìkan ṣoṣo ni a ti ṣe èyí lára àpéjọpọ̀ 96 tí wọ́n ṣe ní ọdún náà jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.
Àwọn adití 43, tí wọ́n jókòó sí apá òsì pèpéle, ní àyè ìjókòó iwájú, ni wọ́n wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n wá síbẹ̀. Wọ́n so pátákó ńlá funfun kan kọ́ iwájú wọn, tí wọ́n fi ọ̀dà pupa kọ “Èdè Àwọn Adití” sí. Inú àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n jẹ́ adití náà dùn gidigidi láti wà níbẹ̀. Ọ̀kan lára wọn kọ̀wé pé: “Tomijétomijé òun ayọ̀ kíkàmàmà ni mo ń kọ̀wé yìí. ‘Láìpẹ́ sí àsìkò yí,’ a ń gé ìka jẹ nígbà tí a gbọ́ nípa ìpèsè tẹ̀mí tí a ṣe fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ adití ní àwọn ilẹ̀ míràn. A kò mọ̀ pé irú àwọn ìbùkún kan náà yóò dé ọ̀dọ̀ wa níhìn-ín.”
Àwọn Wo Ni Wọ́n Wá?
Àwọn adití wá láti apá ibi gbogbo ní Nàìjíríà. Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ adití kó mẹ́ta lára àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adití wá. Àwùjọ àwọn adití mìíràn, tí wọ́n rìnrìn àjò 700 kìlómítà ní àlọ nìkan, ti ń tọ́jú owó mọ́tò fún oṣù méje. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí ó tó àkókò láti gbéra ìrìn àjò, wọn kò lè háyà mọ́tò kan láti ilé iṣẹ́ ọlọ́kọ̀ ìrìnnà ti ìpínlẹ̀ nítorí ó jẹ́ àkókò ìsinmi. Nígbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ gbọ́ nípa ìṣòro tí wọ́n ní, ó fún wọn ní 13,000 náírà (dọ́là 152 ti U.S.) láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún gbígba mọ́tò míràn!
Àwọn ìdílé tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ adití rìnrìn àjò láti lọ sí àpéjọpọ̀ àrà ọ̀tọ̀ yí. Obìnrin kan tí ó wá láti àgbègbè àrọko kan gbọ́ nípa àpéjọpọ̀ náà, ó sì mú ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó jẹ́ adití wá. Yálà òun tàbí ọmọ rẹ̀ kò mọ púpọ̀ nípa èdè adití. Bí ohun tí wọ́n rí ti sún wọn láti sunkún, wọ́n pinnu láti kọ́ èdè adití.
Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n wá síbẹ̀, àwọn kan wá láti ibi tí ó jìnnà tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kìkì láti wo bí àwọn adití yóò ṣe “gbọ́” ohun tí a ń sọ. Iye àwọn tí wọ́n wá ní ọjọ́ Sunday jẹ́ 13,936—iye tí ó pọ̀ jù lọ lára gbogbo àpéjọpọ̀ àgbègbè 96 tí a ṣe ní Nàìjíríà. Àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n jẹ́ adití náà láyọ̀ láti jẹ́ apá kan àwọn èrò yẹn.
Ó Wú Àwọn Òǹwòran Lórí
Ọ̀pọ̀ lára àwọn adití náà “ń gbọ́” ìhìn rere ní èdè àwọn adití fún ìgbà àkọ́kọ́. Àwọn tí wọ́n sì lè gbọ́rọ̀ ń rí bí èdè àwọn adití ṣe rí fún ìgbà àkọ́kọ́. Àyànṣaṣojú kan sọ pé, òun ṣe kàyéfì láti rí i pé gbogbo ohun tí a ń sọ ni wọ́n ṣe ògbufọ̀ rẹ̀ sí èdè àwọn adití—àwọn orin, àdúrà, ìfilọ̀, àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ pàápàá! Ẹlòmíràn sọ pé: “Ó kọyọyọ.”
Ìdùnnú àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n jẹ́ adití yọ nínú ìṣọwọ́kọrin wọn. Tọ̀yàyàtọ̀yàyà, wọ́n ń fi ọwọ́ wọn yin Jèhófà. Ní ti àwọn tí wọ́n ń gbọ́rọ̀, wíwo àwọn adití tí ń “kọrin” jẹ́ ìrírí amúni-káàánú gan-an fún wọn. Ó mú omijé wá sójú ọ̀pọ̀ ènìyàn. A gbọ́ tí àyànṣaṣojú kan fi ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí ó kún fún ìmọrírì kígbe sókè pé, “Jèhófà!” Nígbà kan, nígbà tí orin kan parí, àwọn tí wọ́n jókòó nítòsí àyè ìjókòó àwọn elédè adití bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ láìròtẹ́lẹ̀.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi, bí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣèrìbọmi ti dìde, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó wà ní àyè ìjókòó àwọn adití pẹ̀lú dìde. Ọ̀rọ̀ ìmọrírì ń lọ wúyẹ́wúyẹ́ láàárín àwùjọ nígbà tí ó fi ọwọ́ sọ pé, “bẹ́ẹ̀ ni,” ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè méjì tí olùbánisọ̀rọ̀ béèrè.
Ẹ wo bí ìdùnnú àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n jẹ́ adití ti pọ̀ tó láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí láti àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà! Àwọn apá àti ìka ń lọ, wọ́n ń bọ̀, lọ́nà tí ń rùmọ̀lára sókè bí àwọn adití náà ṣe ń di ojúlùmọ̀ ara wọn. Bíbọ ọwọ́ àti ṣíṣe pàṣípààrọ̀ àdírẹ́sì ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
Àwọn mẹ́sàn-án tí wọ́n jẹ́ ògbufọ̀ èdè àwọn adití (àwọn tí ń fi ọwọ́ sọ̀rọ̀) wá láti apá ibi gbogbo ní orílẹ̀-èdè náà. Ó gbádùn mọ́ni láti wòran bí àwọn ọwọ́ àti apá wọn ṣe ń fi àmì sọ gbogbo àwíyé, tí wọ́n sì ń kọrin. Àwọn ènìyàn dì mọ́ wọn, wọ́n bọ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì gbóríyìn fún wọn fún àwọn ìsapá wọn. Ìbéèrè tún ń ya lù wọ́n lóríṣiríṣi pé: Báwo lẹ ṣe kọ́ ọ? Báwo ni mo ṣe lè kọ́ ọ? Àwọn ìwé ha wà tí ń kọ́ni ní èdè àwọn adití bí?
Pápá Tuntun Kan Ṣí Sílẹ̀
Ní ti àwọn adití, kókó pàtàkì nínú àpéjọpọ̀ náà ni fídíò ẹ̀dà ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ní èdè àwọn adití. A rọ ènìyàn púpọ̀ sí i láti kọ́ èdè àwọn adití àti, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àrànṣe fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, láti wàásù fún àwọn adití jákèjádò Nàìjíríà. Àpéjọpọ̀ náà mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
Arábìnrin kan sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ rí, tí a bá pàdé adití nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, a óò wulẹ̀ lọ sí ilé tí ó tẹ̀ lé e ni. Nísinsìnyí, a ti mọ ohun tí a ní láti ṣe.” Pẹ̀lú àwọn adití tí a fojú díwọ̀n pé wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù márùn-ún ní Nàìjíríà, dájúdájú, a ní ìfojúsọ́nà púpọ̀. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìbẹ̀rẹ̀ nìyí. Nísinsìnyí, a ní láti kọ́ nípa ìlà iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tuntun yìí.”
Ní àwọn oṣù tí ó tẹ̀ lé e láti ìgbà tí a ti ṣe àpéjọpọ̀ náà, ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. A ti pawọ́ pọ̀ sapá takuntakun láti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn adití ní Nàìjíríà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhìn rere ayé tuntun tí ń bọ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, nítorí pé, ìwòsàn lọ́nà ìyanu yóò ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ àti pé, “etí àwọn adití yóò sì ṣí.”—Aísáyà 35:5.