Kilima—Njaro Ibi Gíga Jù Lọ ní Áfíríkà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
NÍ 150 ọdún péré sẹ́yìn, apá àárín ilẹ̀ Áfíríkà kò sí lórí àwòrán ilẹ̀ kankan. Àwọn tí kì í ṣe ará ibẹ̀ rí kọ́ńtínẹ́ǹtì ńlá yìí bí ohun tí a kò ṣàwárí rẹ̀, tí ó sì kún fún àdììtú. Lára ọ̀pọ̀ ohun tí a gbọ́ láti Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ó jọ pé ọ̀kan ṣàjèjì pátápátá sí àwọn ará Europe. Ìyẹn ni ìròyìn tí àwọn míṣọ́nnárì ọmọ ilẹ̀ Germany tí ń jẹ́ Johannes Rebmann àti Johann L. Krapf, ṣe, pé ní 1848, àwọn rí òkè ńlá kan nítòsí ìlà agbedeméjì ayé, tí ó ga tó bẹ́ẹ̀ tí òjò dídì mú kí orí rẹ̀ funfun.
Àwọn ènìyàn ṣiyè méjì nípa ìròyìn pé òkè ńlá tí òjò dídì bo orí rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Áfíríkà olóoru, wọ́n sì fi ṣẹ̀sín. Síbẹ̀, ìròyìn nípa òkè ńlá kíkàmàmà kan ru ìfẹ́ ìtọpinpin àti ìdàníyàn àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀ àti àwọn olùṣàwárí sókè, wọ́n sì fìdí ìròyìn tí àwọn míṣọ́nnárì náà ṣe múlẹ̀ níkẹyìn. Ní gidi, òkè ńlá ayọnáyèéfín kan, tí òjò dídì bo orí rẹ̀, tí a ń pè ní Kilimanjaro, wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Àwọn ènìyàn kan lóye pé ìyẹn túmọ̀ sí “Òkè Ńlá Kíkàmàmà.”
“Ibi Gíga Jù Lọ” ní Áfíríkà
Lónìí, Kilimanjaro kíkàmàmà náà lókìkí nítorí ẹwà rẹ̀ tí ó hàn kedere àti gíga rẹ̀ tí ó kàmàmà. Àwọn ìran mélòó kan dára lójú, wọ́n sì wà fún ìrántí bíi ti agbo àwọn erin tí ń jẹko bí wọ́n ti ń la àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbẹ, eléruku ti ilẹ̀ Áfíríkà kọjá, tí “Kili” tí òjò dídì bo orí rẹ̀ náà sì ní ìrísí ọlọ́lá ńlá lẹ́yìn wọn lọ́hùn-ún.
Kilimanjaro ni òkè ńlá tó ga jù lọ ní kọ́ńtínẹ́ǹtì Áfíríkà, a sì kà á mọ́ àwọn òkè ayọnáyèéfín títóbi jù lọ tí kò tí ì bú lágbàáyé. Ó wà ní Tanzania, gẹ́rẹ́ níhà gúúsù agbedeméjì ilẹ̀ ayé ní ẹ̀bá ẹnu ibodè ilẹ̀ Kẹ́ńyà. Níhìn-ín, ilẹ̀ ayé ti ru àwọn ohun ayọnáyèéfín tí ó lé ní bílíọ̀nù mẹ́rin mítà ní ìwọ̀n gígùn, òró àti ìbú sókè, tí wọ́n wá di òkè ńlá yìí tí ṣóńṣó rẹ̀ ga dé inú kùrukùru.
Bí òkè ńlá náà ṣe tóbi lọ́nà kíkàmàmà tó túbọ̀ fara hàn nípa bí ó ṣe dá dó. Ó dá wà ní ìtakété, ó yọrí láti inú aginjù Masai gbígbẹ koránkorán, tí ó ga ju ìtẹ́jú òkun lọ ní nǹkan bí 900 mítà, ó sì ga tó ìwọ̀n yíyanilẹ́nu ti 5,895 mítà! Kò yani lẹ́nu pé a máa ń ṣàpèjúwe Kilimanjaro nígbà míràn gẹ́gẹ́ bí ibi gíga jù lọ ní ilẹ̀ Áfíríkà.
A tún ń pe Kilimanjaro ní “Òkè Ńlá Àwọn Arìnrìn-Àjò Nínú Aṣálẹ̀,” nítorí pé àwọn yìnyín orí rẹ̀ àti àwọn ìṣàn òkìtì yìnyín rẹ̀ ṣeé rí láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà níhà èyíkéyìí bí iná ìsàmì funfun tí ó mọ́lẹ̀ rekete. Láàárín àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, orí rẹ̀ tó ní òjò dídì ti ń ṣamọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀ tí ń rin ìrìn àjò gba àárín Áfíríkà tí kò lọ́làjú kọjá, pẹ̀lú àwọn ẹrù eyín erin, wúrà, àti ẹrú wọn.
Òtéńté Orí Rẹ̀ Kíkàmàmà
Kilimanjaro ní òtéńté ayọnáyèéfín méjì. Kibo ni òtéńté ayọnáyèéfín gan-an; ìrísí òkòtó rẹ̀ tí ó rẹwà tí ó sì dọ́gba délẹ̀ ni omi dídì àti òjò dídì tí ó wà títí bò pátápátá. Ní ìhà ìlà oòrùn ni òtéńté kejì, tí ń jẹ́ Mawenzi, ó ga tó 5,354 mítà, ó sì wà ní ipò kejì láàárín àwọn òkè ńlá gíga jù lọ ní Áfíríkà, lẹ́yìn Kibo. Láìdàbí Kibo tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ tí ó dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀ wálẹ̀ ń dán, Mawenzi jẹ́ òkè alára págunpàgun tí a gbẹ́ lọ́nà rírẹwà, tí ó ní àwọn àpáta tí ara wọn kò dán ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbòòrò kan, tí àwọn àfọ́kù àpáta fọ́n ká sínú rẹ̀, tí ó sì dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀, ló so òtéńté Kibo àti Mawenzi pọ̀ ní 4,600 mítà. Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Kibo ni Shira wà, tí ó jẹ́ àwókù òkè ayọnáyèéfín ìgbàanì kan, tí afẹ́fẹ́ àti omi ti ṣàn lọ, tí ń kóra jọ di òkè títẹ́jú pẹrẹsẹ, ti ilẹ̀ tí kò lẹ́tù lójú, tí ó ga ní ìwọ̀n 4,000 mítà lókè ìtẹ́jú òkun nísinsìnyí.
Àgbàyanu Àjọṣepọ̀ Àwọn Ohun Alààyè àti Àyíká Wọn
Onírúurú ẹkùn ilẹ̀ tí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan ṣe ga tó, bí òjò ṣe ń rọ̀ púpọ̀ tó, àti bí ewéko ṣe pọ̀ níbẹ̀ tó pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú àyíká àwọn ohun alààyè tó wà ní àyíká Kilimanjaro. Igbó ilẹ̀ olóoru tí a kò fọwọ́ kàn rí, tí àwọn erin àti ẹfọ̀n ń wọ́ kiri nínú rẹ̀, ló wà ní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ìsàlẹ̀. Irú ọ̀wọ́ àwọn ọ̀bọ mélòó kan ń gbé orí àwọn tigitìtàkùn tó ṣíji bo igbó náà, àlejò kan sì lè kófìrí àwọn ẹtu àti gìdìgìdì, tí ó rọrùn fún láti fara pa mọ́ sínú àwọn ìgbẹ́ tí kì í ga.
Ẹkùn ilẹ̀ òdòdó ẹ̀bá òkè ló wà lókè igbó náà. Àwọn fọ́nrán okùn àlọ́mọ́ tí ó jọ irùngbọ̀n funfun àwọn arúgbó bo àwọn ògbólógbòó igi oníkókó, tí afẹ́fẹ́ àti ọjọ́ orí wọn ti mú kí wọ́n lọ́. Níhìn-ín, ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè náà lanu, àwọn òdòdó ẹ̀bá òkè tí ó tóbi gan-an sì gbilẹ̀. Àwọn koríko tí ó dí pẹ̀lú àwọn ìdì òdòdó aláwọ̀ títàn tí ó hù gá-gà-gá láàárín wọn mú kí ìran àgbègbè àrọko náà jojú ní gbèsè.
Lókè ibi tí àwọn igi igbó náà ga dé, àwọn ilẹ̀ tí kò lẹ́tù lójú tún fara hàn. Dípò àwọn igi, àwọn ewéko tí ìrísí wọn ṣàjèjì, tí a ń pè ní Senecio ńlá, tí ó máa ń ga tó mítà mẹ́rin, àti àwọn igi lobelia, tí ó máa ń rí bí ẹ̀fọ́ cabbage ńlá tàbí ẹ̀fọ́ artichoke ló ń hù níbẹ̀. Òdòdó àìnípẹ̀kun, tí ó dà bíi pòpórò, tí ó sì gbẹ wọnú, máa ń hù yí ká àwọn àfọ́kù àpáta àti àwọn ibi àpáta tí ó ní ilẹ̀ díẹ̀ lójú, ó sì ń fún ojú ilẹ̀ tí ó ní àwọ̀ eérú títànyanran nìkan ní àfikún àwọ̀.
Lókè díẹ̀ sí i, ẹkùn ilẹ̀ olókè gbàyè lọ́wọ́ ilẹ̀ tí kò lẹ́tù lójú náà. Ilẹ̀ náà ní àwọ̀ tí kì í tàn ti àwọ̀ ilẹ̀ bìnìjọ̀ àti eérú. Àwọn ewéko mélòó kan péré ló lè hù ní àyíká gbígbẹ, tí kò ní ewéko rẹpẹtẹ yìí. Ní ibí yìí ni aṣálẹ̀ gíga kan, tí ó gbẹ koránkorán, tí ó sì ní àpáta, ti so àwọn òkè ńlá méjèèjì náà, Kibo àti Mawenzi, pọ̀. Ibí yìí máa ń gbóná kọjá ààlà, ó ń dé ìwọ̀n 38 lórí òṣùwọ̀n Celsius lọ́sàn-án, ó sì ń lọ sílẹ̀ gan-an kọjá ìwọ̀n tí ń mú nǹkan dì lóru.
Níkẹyìn, a dé ẹkùn ilẹ̀ òtéńté náà. Afẹ́fẹ́ ibí yìí tutù, ó sì mọ́ gaara. Bí òfuurufú ṣe ní àwọ̀ búlúù, àwọn ìṣàn òkìtì yìnyín ńláńlá àti omi dídì ní àwọ̀ funfun, ó sì mọ́ rekete, ó wá ń gbé ẹwà àfiwéra yọ sí ilẹ̀ òkè ńlá náà tí ó ṣókùnkùn. Afẹ́fẹ́ náà lọ́rinrin ju bó ti yẹ lọ, ó sì ní nǹkan bí ìdajì ìwọ̀n afẹ́fẹ́ oxygen tí ó ń wà ní ìpele ìtẹ́jú òkun. Lókè òtéńté títẹ́jú ti Kibo ni ihò ayọnáyèéfín náà wà, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ rí róbótó tán, tí ìwọ̀n ìdábùú òbírí rẹ̀ sì jẹ́ kìlómítà 2.5. Nínú ihò náà, ní àárín òkè ńlá náà ni ihò eérú ńlá kan tí ó wọn 300 mítà ní ìdábùú, tí ó sì jìn ní 120 mítà sínú ọ̀fun òkè ayọnáyèéfín náà wà. Àwọn gáàsì imí ọjọ́ gbígbóná rọra ń ru sókè láti inú àwọn ihò èéfín kéékèèké sí inú afẹ́fẹ́ tútù nini náà, tí ó jẹ́ ẹ̀rí sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún, nínú òkè ayọnáyèéfín tí kò tí ì bú náà.
Bí òkè ńlá Kilimanjaro ṣe tóbi tí ó sì gbòòrò tó mú kí ó lè ṣẹ̀dá ipò ojú ọjọ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀. Afẹ́fẹ́ ọlọ́rinrin, tí ń fẹ́ wá láti Òkun Íńdíà la àwọn ilẹ̀ títẹ́jú tí òjò kì í ti í dunlẹ̀ kọjá, máa ń fẹ́ lu òkè ńlá náà, ó sì máa ń darí lọ sókè níbi tí ó ti ń dì, tí ó sì ń rọ̀jò. Èyí ń mú kí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìsàlẹ̀ lọ́ràá fún ṣíṣe ọ̀gbìn kọfí àti àwọn irè tí ń di oúnjẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé àyíká ẹsẹ̀ òkè ńlá náà.
Gígun Orí “Kili”
Àwọn ènìyàn tí ń gbé nítòsí òkè ńlá Kilimanjaro ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán pé àwọn ẹ̀mí búburú, tí yóò ṣe ìjàǹbá fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú láti gun òkè náà dé àwọn ibi olómi dídì òkè rẹ̀, ń gbé àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Èyí ti ṣèdènà fún àwọn ènìyàn àdúgbò náà tí wọn kò fi lè gun òkè náà dé òtéńté rẹ̀. Ọdún 1889 ni àwọn olùṣàwárí méjì, tí wọ́n jẹ́ ará Germany, gun òkè náà, tí wọ́n sì dúró ní ibi gíga jù lọ ní Áfíríkà. Òtéńté kejì, Mawenzi, tí ó túbọ̀ gba ọgbọ́n àti òye kí ẹnì kan tó lè gùn ún, ni ẹnikẹ́ni kò gùn dókè títí di ọdún 1912.
Lónìí, ẹnikẹ́ni tí ara rẹ̀ bá dá ṣáṣá lè gun òkè ńlá Kilimanjaro, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sì wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí ń ṣèbẹ̀wò sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Tanzania tí ń bójú tó ọgbà ìtura náà ní ìṣètò dáradára fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ láti gun òkè ńlá náà. A lè rí aṣọ àti àwọn ohun èlò yá. Àwọn abójútérò àti afinimọ̀nà tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ọ̀pọ̀ hòtẹ́ẹ̀lì ìgbafẹ́ sì ń pèsè ìbùwọ̀ títura láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí ìrìn àjò ìpọ́nkè kan. Àwọn ahéré tí a kọ́ dáradára wà lọ ní ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí òkè náà, tí ń pèsè ibùsùn àti ibi ìsinmi fún àwọn tí ń pọ́nkè.
Rírí òkè ńlá Kilimanjaro fúnra ẹni ń wúni lórí gan-an, ó sì ń tanná ran ìmọ̀lára pé Ọlọ́run wà. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ nípa Ọlọ́run pé: “Nípa agbára rẹ̀, ẹni tí ó fi ìdí òkè ńlá múlẹ̀ ṣinṣin.” (Orin Dáfídì 65:6) Dájúdájú, òkè ńlá Kilimanjaro ga, kò lẹ́gbẹ́ ní Áfíríkà, ó sì jẹ́ ẹ̀rí títóbi nípa agbára Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá náà.
[Àwòrán ilxẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÁFÍRÍKÀ
Kẹ́ńyà
KILIMANJARO
Tanzania