Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ló Burú Nínú Títage?
“Kí ló dé ti a máa ń ronú nípa ìtage bí ìwà ẹ̀tàn tàbí ohun tí kò dára? kò rí bẹ́ẹ̀! eré amóríyá ni! tọ̀túntòsì ló sì ń jẹ, nítorí pé o ń mú inú ẹnì kejì dùn.”—Susan Rabin, olùdarí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìtage, New York City.
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ń wo ìtage bí ohun tí ó bójú mu, tí kò lè ṣèpalára, tí kò tilẹ̀ ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú fífìdí àjọṣe ẹ̀dá múlẹ̀, kí ó sì máa wà nìṣó. Ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn, àwọn ìwé, àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn, àti àwọn àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ń kọ́ni ní bí a óò ṣe máa ṣe, bí a óò ṣe máa rìn, bí a óò ṣe máa wo ènìyàn lọ́nà tí ó kan “ìṣe ìtage” túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìpẹ́ yìí.
Kí ni ìtage? Onírúurú ìtumọ̀ àti àpẹẹrẹ ló wà. Ìwé atúmọ̀ èdè kan pè é ní ìwà “fífi ìfẹ́ oníbàálòpọ̀ fa ojú ẹni mọ́ra.” Ìwé atúmọ̀ èdè mìíràn sọ pé ó jẹ́ ìwà “fífi ìfẹ́ oníbàálòpọ̀ hàn láìsí ète pàtàkì.” Nípa bẹ́ẹ̀, èrò náà pé ẹni tí ń bá ènìyàn tage ni ẹni tí ń fi àfiyèsí eléré ìfẹ́ hàn láìní ète ìgbéyàwó jọ èyí tí a tẹ́wọ́ gbà ní gbogbogbòò. Ó ha yẹ kí a wo ìtage bí ohun tí kò lè ṣèpalára? Kí ni ojú ìwòye Bíbélì nípa ìtage?a
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mẹ́nu kan ìtage ní pàtó nínú Ìwé Mímọ́, a lè pinnu ohun tí èrò Ọlọ́run jẹ́. Báwo? Nípa gbígbé àwọn ìlànà Bíbélì tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. A óò wá tipa bẹ́ẹ̀ lo ‘agbára ìwòye wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’ (Hébérù 5:14) Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a ronú nípa bóyá ìtage jẹ́ ìwà tí ó bójú mu fún àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó láti máa hù.
Bí Ẹnì Kan Bá Ti Ṣègbéyàwó
Ó bá ìwà ẹ̀dá mu kí àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa fi ìfẹ́ oníbàálòpọ̀ hàn sí ara wọn nínú kọ̀rọ̀ iyàrá wọn. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 26:8.) Àmọ́ dídarí irú àfiyèsí yẹn sí ẹni tí kì í ṣe ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó lòdì sí àwọn ìlànà Ọlọ́run. Jèhófà pète pé kí tọkọtaya tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́, tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Éfésù 5:21-33) Ó ń wo ìgbéyàwó bí ìsopọ̀ mímọ́, tí ó wà títí lọ. Málákì 2:16 sọ nípa Ọlọ́run pé: “Òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.”b
Ó ha bá èrò Ọlọ́run mu kí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó máa bá ẹlòmíràn tage bí? Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré nítorí pé ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó tí ó wá ń bá ẹlòmíràn tage kò fi ọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe. Bákan náà ni Éfésù 5:33 pàṣẹ fún Kristẹni tí ó jẹ́ ọkọ láti “nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀,” kí aya sì “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” Ǹjẹ́ bíbá ẹlòmíràn tage, tí ń ru ẹ̀mí owú sókè, ń fi hàn pé a ń fi ìfẹ́ tàbí ọ̀wọ̀ hàn fún ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó?
Èyí tó tún ń múni ronú sí i ni pé bíbá ẹlòmíràn tage lè súnni ṣe panṣágà, ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà dẹ́bi fún gbangbagbàǹgbà, tí ó sì pè ní àdàkàdekè. (Ẹ́kísódù 20:14; Léfítíkù 20:10; Málákì 2:14, 15; Máàkù 10:17-19) Ní gidi, Jèhófà kò ka ìwà panṣágà sí ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá, nítorí náà ló ṣe gba àwọn tí a ṣe àìṣòótọ́ sí nínú ìgbéyàwó láyè láti gba ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 5:32) Nígbà náà, a ha lè ronú pé Jèhófà yóò fọwọ́ sí irú ohun amóríyá tí ó léwu bí bíbá ẹlòmíràn tage bí? Ọlọ́run kò jẹ́ fọwọ́ sí i bí òbí onífẹ̀ẹ́ kan kò ṣe ní fọwọ́ sí kí ọmọ rẹ̀ tí ó kéré máa fi ọ̀bẹ mímú ṣeré.
Ní ti ìwà panṣágà, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná? Tàbí kẹ̀, ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyín iná, kí ẹsẹ̀ rẹ̀ pàápàá má sì jó? Bákan náà ni pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀, kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí kò ní yẹ fún ìyà.” (Òwe 6:27-29) Bí ó ti wù kí ó rí, bí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó tí ó wá ń bá ẹlòmíràn tage kò bá tilẹ̀ ṣe panṣágà, ó ń tọrùn bọ ewu mìíràn—lílọ́wọ́ nínú ohun tí a ń pè ní “àjọṣe onígbòónára.”
Àjọṣe Onígbòónára
Àwọn ènìyàn kan ti wọnú àjọṣe, nínú èyí tí wọ́n ti ń ní ìmọ̀lára eléré ìfẹ́ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ẹnì tí wọ́n bá ṣègbéyàwó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní ìbálòpọ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jésù kìlọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Èé ṣe tí Jésù fi lòdì sí ìfẹ́ onígbòónára tí kò kọjá ọkàn-àyà?
Ìdí kan ni pé, “láti inú ọkàn-àyà ni . . . panṣágà ti ń wá.” (Mátíù 15:19) Síbẹ̀síbẹ̀, irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ lè pani lára, kódà bí wọn kò bá tíì bá a dé bèbè panṣágà. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ìwé kan tí ń sọ nípa kókó ọ̀rọ̀ yìí ṣàlàyé pé: “Àjọṣe tàbí ipò ìbátan èyíkéyìí tó bá ń gba àkókò àti agbára púpọ̀ jù lára èyí tí ó yẹ kí o lò pẹ̀lú ẹni tí o bá ṣègbéyàwó lọ́wọ́ rẹ jẹ́ àìṣòtítọ́.” Òtítọ́ ni, àjọṣe onígbòónára máa ń fi àkókò, àfiyèsí, àti ìfẹ́ni du ẹni tí o bá ṣègbéyàwó. Ní ojú ìwòye àṣẹ Jésù pé, ohun tí a bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí wa ni kí a máa ṣe sí wọn, yóò dára kí ẹni tí ń bá ẹlòmíràn tage bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Báwo ni yóò ṣe rí lára mi tí ẹnì kejì mi bá ń ṣe irú ohun tí mo ń ṣe yìí pẹ̀lú ẹlòmíràn?’—Òwe 5:15-23; Mátíù 7:12.
Bí ẹnì kan bá ti wọnú irú ìdè ìmọ̀lára tí kò tọ́ bí èyí, kí ni ó yẹ kí ó ṣe? Ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó tí ó ń ní àjọṣe onífẹ̀ẹ́ tí kò tọ́ dà bí awakọ̀ kan tí ń sùn nídìí ọkọ̀ wíwà. Ó gbọ́dọ̀ ta kìjí sí ipò rẹ̀, kí ó sì gbé ìgbésẹ̀ tí ó ṣe gúnmọ́, láìjáfara, kí ìgbéyàwó rẹ̀ àti ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run tó fọ́ yángá. Jésù ṣàpèjúwe ìdí tí a fi nílò ìgbésẹ̀ kánmọ́ nígbà tí ó sọ pé, kí a yọ ohun tí ó ṣeyebíye síni gan-an bí ojú jáde tàbí kí a ké ọwọ́ kúrò, bí yóò bá ba ìdúró rere wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.—Mátíù 5:29, 30.
Nítorí náà, yóò bọ́gbọ́n mu láti pààlà ibi tí a ti ń rí onítọ̀hún àti bí a ṣe ń rí i tó. Dájúdájú, yẹra fún dídá wà níbì kan pẹ̀lú onítọ̀hún, bí ó bá sì jẹ́ ní ibi iṣẹ́ ni, pààlà sí irú ìjíròrò tí ẹ jọ ń ṣe. Ó tilẹ̀ lè pọndandan láti fòpin sí rírí onítọ̀hún pátápátá. Lẹ́yìn náà, o gbọ́dọ̀ fi àìgbagbẹ̀rẹ́ kó ojú, èrò, ìmọ̀lára, àti ìhùwà rẹ níjàánu. (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12; Sáàmù 19:14; Òwe 4:23; 1 Tẹsalóníkà 4:4-6) Jóòbù, tí ó ti gbéyàwó, fi àpẹẹrẹ dídára gan-an lélẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?”—Jóòbù 31:1.
Dájúdájú, ó léwu, kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu kí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó máa bá ẹlòmíràn tage. Àmọ́, kí ni ojú ìwòye Bíbélì nípa ti àwọn àpọ́n tí ń tage? A ha lè kà á sí ohun tí ó bójú mu, tí kò lè ṣèpalára, tàbí tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú fífìdí ipò ìbátan pẹ̀lú ẹ̀yà kejì múlẹ̀ bí? Ìpalára gidi kan ha lè tìdí rẹ̀ yọ bí?
Àwọn Àpọ́n Ńkọ́?
Kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn àpọ́n méjì fi ọkàn-ìfẹ́ eléré ìfẹ́ hàn nínú ara wọn, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ní in lọ́kàn láti bá ara wọn ṣègbéyàwó, tí wọn kò sì hùwà àìmọ́. (Gálátíà 5:19-21) Irú ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lè fara hàn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra sọ́nà, tí ọ̀rọ̀ bíbá ara wọn ṣègbéyàwó lè máà tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀. Èyí kò fi dandan jẹ́ ohun tí kò tọ́ bí ó bá ní èrò rere nínú. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìwà ìtage.
Bí àwọn àpọ́n bá ń sejú síra wọn kìkì fún ìmóríyá ńkọ́? Ó lè jọ pé kò lè pa wọ́n lára, nítorí pé àpọ́n ni wọ́n. Àmọ́, ronú nípa ìpalára ní ti ìmọ̀lára tí yóò kẹ́yìn rẹ̀. Bí a bá fi ọwọ́ pàtàkì mú ìṣesí ẹni tí ń bá ẹ̀yà òdìkejì tage náà ju bí ó ṣe rò lọ, ó lè yọrí sí ìrora gógó àti ìbànújẹ́. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 13:12 ṣe jẹ́ òtítọ́ tó pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn, ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé”! Kódà, bí ẹni méjì bá ní àwọn mọ̀ pé àwọn kò ní ìfẹ́-ọkàn gidi nínú ara àwọn—èyíkéyìí lára wọn ha lè mọ ohun tí èkejì ń rò tàbí tí ó jẹ́ ìmọ̀lára rẹ̀ ní gidi bí? Bíbélì dáhùn pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?”—Jeremáyà 17:9; fi wé Fílípì 2:4.
Tún ronú nípa ewu ti ṣíṣe àgbèrè, pẹ̀lú àwọn àrùn tí a lè tibẹ̀ kó tàbí ti lílóyún láìyẹ. Ìwé Mímọ́ dẹ́bi fún ìwà àgbèrè, àwọn tí wọ́n sì ń fínnúfíndọ̀ ṣe é ń pàdánù ojú rere Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ọgbọ́n kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé, láti lè dènà àdánwò, wọ́n gbọ́dọ̀ “sọ àwọn ẹ̀yà ara” wọn “di òkú ní ti àgbèrè,” kí wọ́n sì yẹra fún “ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo,” tí ń sinni sí àgbèrè. (Kólósè 3:5; 1 Tẹsalóníkà 4:3-5) Nínú Éfésù 5:3, ó gbà wá nímọ̀ràn pé “kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan” àgbèrè, ìyẹn ni pé, ní ọ̀nà tí yóò fi ru ìfẹ́-ọkàn tí kò dára sókè. Títage kì í ṣe ìgbọràn sí ìmọ̀ràn yìí. Ọlọ́run tilẹ̀ ṣòfin lòdì sí ìjíròrò tí kò bójú mu nípa ìbálòpọ̀.
Àwọn ìlànà Bíbélì fi hàn pé títage lè jẹ́ ìwà òǹrorò sí ọmọnìkejì ẹni àti àìbọ̀wọ̀ fún Jèhófà, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó. Ojú ìwòye Bíbélì nípa àṣà àìtọ́ ti títage jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ó sì bọ́gbọ́n mu ní tòótọ́, nítorí pé ó ń yọ àwọn ènìyàn nínú ìpalára. Àwọn olùfẹ́ Ọlọ́run yóò tipa bẹ́ẹ̀ fà sẹ́yìn kúrò nínú àṣà àìtọ́ ti títage, wọ́n óò sì máa bá ẹ̀yà kejì lò pẹ̀lú ìwà mímọ́ àti ọ̀wọ̀.—1 Tímótì 2:9, 10; 5:1, 2.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A kò gbọ́dọ̀ ṣi ìtage gbé fún jíjẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ tàbí kíkó ènìyàn mọ́ra, tí kò ní èrò ìbálòpọ̀ kankan nínú.
b Wo àpilẹ̀kọ “Irú Ìkọ̀sílẹ̀ Wo Ni Ọlọrun Kórìíra?” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde February 8, 1994.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
© The Curtis Publishing Company