Ojú Ìwòye Bíbélì
O Ṣeyebíye Lójú Ọlọ́run!
KRISTẸNI OBÌNRIN KAN KỌ̀WÉ PÉ: “ÈYÍ TÓ PỌ̀ JÙ LỌ NÍNÚ ÌGBÉSÍ AYÉ MI NI MO FI Ń NÍMỌ̀LÁRA ÀÌJÁMỌ́-NǸKANKAN. KÒ SÍ BÍ MO ṢE LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ TÓ TÀBÍ BÍ MO ṢE LÈ FI GBOGBO IPÁ MI SÌN ÍN TÓ TÍ N KÒ NÍ NÍMỌ̀LÁRA PÉ Ó KÙ DÍẸ̀ KÁÀTÓ.”
ǸJẸ́ o mọ ẹnì kan tó ń bá ìmọ̀lára àìtóótun tàbí àìjámọ́-nǹkankan jìjàkadì? Àbí ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ kò ṣọ̀wọ́n, kódà láàárín àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run pàápàá. Kò sí ẹni tó bọ́ lọ́wọ́ ipa tí gbígbé ní “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” yìí ń ní. A gbójú fo ọ̀pọ̀ ènìyàn dá, a sì ti fìyà jẹ wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere”—àwọn ìwà tó gbòdekan ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Irú ìrírí aronilára bẹ́ẹ̀ lè bani lọ́kàn jẹ́ gan-an, kó sì mú kéèyàn máa nímọ̀lára àìjámọ́-nǹkankan lọ́nà tó lé kenkà.
Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, ó lè yọrí sí èrò òdì fáwọn èèyàn tí ń gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga kalẹ̀ fúnra wọn. Àìlèkúnjú ìwọ̀n ọ̀pá ìdíwọ̀n yìí yóò túbọ̀ jẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn kò lè tóótun láé. Ohunkóhun tí ọ̀ràn náà lè jẹ́, ó lè ṣòro fáwọn tí ń bá ìmọ̀lára àìjámọ́-nǹkankan jà láti rídìí tí Ọlọ́run—tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn pàápàá—fi nífẹ̀ẹ́ àwọn. Láìsí àní-àní, wọ́n tilẹ̀ lè rò pé àwọn wulẹ̀ jẹ́ ẹni tí kò ṣeé fẹ́ràn.
Àmọ́, báyẹn kọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń ronú o! Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jèhófà kìlọ̀ fún wa láti ṣọ́ra fún “àwọn ọgbọ́n ìtannijẹ” Elénìní rẹ̀, Sátánì Èṣù. (Éfésù 6:11, Jewish New Testament) Sátánì ń gbìyànjú láti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ mú wa jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run wa. Láti ṣe èyí, Sátánì ń mú kí a ronú pé a kò já mọ́ nǹkankan, pé Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ wa láé. Ṣùgbọ́n “òpùrọ́” ni Sátánì—ní tòótọ́, “baba irọ́” ni. (Jòhánù 8:44) Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó fi àwọn ọgbọ́n ìtànjẹ rẹ̀ mú wa! Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ nínú Bíbélì, ó sì mú un dá wa lójú pé a ṣeyebíye lójú òun.
Ojú Ìwòye Tó Wà Déédéé Nípa Bí A Ṣe Ṣeyebíye Tó
Bíbélì ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa ipa búburú tí ìrẹ̀wẹ̀sì lè ní lórí wa. Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Èrò òdì tó pẹ́ lọ́kàn wa lè sọ wá di aláìlókun, kó sì sọ wá di aláàárẹ̀ àti ẹni tó rọrùn láti pa lára. Jẹ́ kí ó yé ọ pé Sátánì mọ èyí dáradára. Ó máa ń ṣòro gan-an bí èrò àìjámọ́-nǹkankan bá ń dààmú ọkàn wa. Bó ti wù kó rí, ipò náà túbọ̀ máa ń nira sí i nígbà tí Sátánì bá ń gbìyànjú láti lo irú ìrònú òdì bẹ́ẹ̀.
Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a ní ojú ìwòye tó jọjú tó sì wà déédéé nípa bí a ṣe ṣeyebíye tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.” (Róòmù 12:3) Àwọn ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ mìíràn lo nìyí: “N óò sọ fún olúkúlùkù yín kó má ṣe díye lé ara rẹ̀ ju ibi tí iye rẹ̀ gan-an mọ, àmọ́ kí ó díwọ̀n ara rẹ̀ níwọ̀ntúnwọ̀nsì.” (Charles B. Williams) Nítorí náà Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti ní ojú ìwòye tó wà déédéé nípa ara wa. Ní ọ̀nà kan, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú; ní ọ̀nà kejì, a kò tún ní láti ṣàṣejù, nítorí pé Pọ́ọ̀lù fi hàn pé láti ní èrò inú yíyèkooro, ó pọndandan láti ro nǹkan kan nípa ara wa. Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù fi hàn lábẹ́ agbára ìmísí àtọ̀runwá pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ṣeyebíye lójú Jèhófà.
Níní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa bí a ṣe ṣeyebíye tó tún hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù, nígbà tó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Ọ̀rọ̀ náà “gẹ́gẹ́ bí ara rẹ” fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ní àwọn èrò kan nípa bí a ṣe ṣeyebíye tó, tàbí iyì tí a ní. Lóòótọ́, a máa ń ní àwọn ẹ̀bi a sì máa ń ṣe àwọn àṣìṣe. Àmọ́, nígbà tí a bá ń tiraka láti wu Ọlọ́run, tí a kábàámọ̀ nípa àwọn àṣìṣe wa, tí a sì tọrọ ìdáríjì, a ṣì lè ṣeyebíye síbẹ̀. Ọkàn-àyà wa tó máa ń ṣe lámèyítọ́ gan-an le máa rin kinkin mọ nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n rántí pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ.” (1 Jòhánù 3:20) Lọ́rọ̀ mìíràn, ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà wò wá lè yàtọ̀ pátápátá sí bí a ṣe ń wo ara wa.
Ọkàn-Àyà Oníròbìnújẹ́, Ẹ̀mí Tí A Wó Palẹ̀
Onísáàmù náà, Dáfídì kọ̀wé pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Ìwé Matthew Henry’s Commentary on the Whole Bible sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Ó jẹ́ ìwà àwọn olódodo . . . pé kí wọ́n ní ìròbìnújẹ́ ọkàn àti ẹ̀mí ìkáàánú, ìyẹn ni rírẹ ara wọn sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, àti ṣíṣàìka ara wọn sí; wọ́n rẹlẹ̀ lójú ara wọn, wọn kò sì ní ìdánilójú kankan nínú àṣeyọrí tiwọn fúnra wọn.”
Àwọn tó jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” tàbí “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀” lè rò pé Jèhófà jìnnà àti pé àwọn kò já mọ́ nǹkankan rárá tí Jèhófà yóò fi bìkítà nípa àwọn. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì mú un dá wa lójú pé Jèhófà kì í fi àwọn tí wọ́n “rẹlẹ̀ ní ojú ara wọn” sílẹ̀. Ọlọ́run wa oníyọ̀ọ́nú mọ̀ pé a nílò òun ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ jú ìgbà mìíràn lọ, ó sì wà nítòsí.
Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìyá kan sáré gbé ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì, tí akọ èfù ń ṣe, lọ sílé ìwòsàn. Lẹ́yìn tí dókítà yẹ ọmọ náà wò, ó sọ fún ìyá náà pé àwọn yóò dá ọmọ náà dúró sílé ìwòsàn di ọjọ́ kejì. Níbo ni ìyá náà sùn mọ́jú? Orí àga kan tó wà ní yàrá ilé ìwòsàn náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì ọmọ rẹ̀ ni. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ìkókó ń ṣàìsàn, obìnrin náà sì ní láti dúró tì í. Dájúdájú, a lè retí pé kí Bàbá wa ọ̀run, ẹni táa dá wa ní àwòrán rẹ̀, ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ! (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Aísáyà 49:15) Àwọn ọ̀rọ̀ amúnilọ́kànyọ̀ tó wà nínú Sáàmù 34:18 mú un dá wa lójú pé nígbà tí a bá jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ọkàn,” Jèhófà “wà nítòsí” gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́—ó wà lójúfò, ó ń tẹ́tí sílẹ̀, ó sì ṣe tán láti ṣèrànwọ́.—Sáàmù 147:1, 3.
“Ẹ Níye Lórí Púpọ̀ Ju Ọ̀pọ̀ Ológoṣẹ́ Lọ”
Ní àkókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó fi púpọ̀ hàn nípa èrò àti ìmọ̀lára Jèhófà, títí kan èrò Jèhófà nípa àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ó ju ìgbà kan lọ tí Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé wọ́n ṣeyebíye lójú Jèhófà.—Mátíù 6:26; 12:12.
Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń ṣàpèjúwe bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ṣeyebíye tó, ó sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ronú nípa ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yóò túmọ̀ sí fún àwọn olùgbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ní ọ̀rúndún kìíní.
Ó hàn gbangba pé ológoṣẹ́ wà lára àwọn ẹyẹ tó dínwó jù nínú àwọn ẹyẹ tí a máa ń jẹ. A sábà máa ń tu ìyẹ́ àwọn ẹyẹ tín-tìn-tín wọ̀nyí, a óò wá kì í bọ ọ̀pá onígi, a óò sì yan-án bíi súyà. Kò sí àní-àní pé Jésù yóò ti máa rí àwọn tálákà obìnrin ní ọjà tí wọ́n ń ka owó ẹyọ wọn láti mọ iye ológoṣẹ́ tí wọn yóò rà. Àwọn ẹyẹ náà kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí púpọ̀ débi pé ẹnì kan lè fi ẹyọ owó kékeré kan (ìyẹn assarion kan, tí kò tó sẹ́ǹtì márùn-ún owó Amẹ́ríkà), ra ológoṣẹ́ méjì.
Jésù tún àpèjúwe yìí sọ lẹ́yìn náà—àmọ́ pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú Lúùkù 12:6, Jésù sọ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ronú nípa rẹ̀ ná. Pẹ̀lú ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, ẹnì kan lè ra ológoṣẹ́ méjì. Síbẹ̀, bó bá ṣe tán láti ná ẹyọ owó méjì, kò ni ra ológoṣẹ́ mẹ́rin bíkòṣe márùn-ún. Wọ́n fi ẹyẹ kan yòókù ṣe èènì ìdúnàádúrà náà bí ẹni pé kò níye lórí rara. “Síbẹ̀,” Jésù sọ pé, “kò sí ọ̀kan nínú wọn [títí kan èyí tí a fi ṣe èènì] tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” Ní lílo àpèjúwe yìí, Jésù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:7) Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yóò ṣe fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ níṣìírí tó!
Ǹjẹ́ o lóye kókó tó wà nínú àpèjúwe amọ́kànyọ̀ tí Jésù ṣe? Bí Jèhófà bá ka àwọn ẹyẹ kéékèèké pàápàá sí, mélòómélòó ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé yóò ti jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí i tó! Lójú Jèhófà, kò sí ọ̀kan nínú wa tí kò ní láárí. Olúkúlùkù wa ṣeyebíye gan-an sí Jèhófà débi pé ó ń kíyè sí ohun tó kéré jù lọ lára wa pàápàá—gbogbo irun orí wa ló níye.
Dájúdájú, Sátánì yóò máa tẹ̀ síwájú láti lo “ọgbọ́n ìtannijẹ” rẹ̀—bíi lílo èrò pé a kò já mọ́ nǹkankan—láti mú wa jáwọ́ nínú sísin Jèhófà. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí Sátánì borí! Rántí obìnrin Kristẹni tí a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó kìlọ̀ nípa ìsapá Sátánì láti lo ìmọ̀lára wa ló ràn án lọ́wọ́.a Ó sọ pé: “N kò mọ̀ rárá pé Sátánì ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀lára mi kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Bí mo ṣe mọ èyí fún mi ní ìsúnniṣe láti bá ìmọ̀lára yìí jà. Báyìí, mo lè kojú àtakò Sátánì yìí pẹ̀lú ìdánilójú.”
Jèhófà “mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) Dájúdájú, ó mọ ohun tí a ń fara dà nísinsìnyí. Ó sì mọ ìrírí táa ti ní sẹ́yìn tó ti lè wó iyì ara ẹni wa palẹ̀. Rántí, ojú ìwòye Jèhófà nípa wa ló ṣe pàtàkì jù! Bó ti wù kí a ka ara wa sí ẹni tí kò ṣeé fẹ́ràn tàbí tí kò já mọ́ nǹkankan tó, Jèhófà mú un dá wa lójú gbangba pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ òun ṣe iyebíye lójú òun. A lè gba ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́, nítorí pé, láìdàbí Elénìní rẹ̀, Ọlọ́run “kò lè purọ́.”—Títù 1:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìsọ́nà ti April 1, 1995, ojú ìwé 10 sí 15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
Gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́, Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ìròbìnújẹ́ ọkàn-àyà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Bí Jèhófà kò bá gbàgbé ológoṣẹ́, báwo ni yóò ṣe gbàgbé rẹ?
[Àwọn Credit Line]
Lydekker
Illustrated Natural History