Wọ́n Di Ọlọ́rọ̀ Ní Èbúté Péálì
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ
APÁ àríwá ìwọ̀ oòrùn Ọsirélíà ni ìlú Broome wà. Òbítíbitì yanrìn àti agbami òkun tó lọ salalu ló yí i ká. Aṣálẹ̀ Ńlá Oníyanrìn wà ní apá gúúsù ìlà oòrùn, ó sì ṣe kọ́lọkọ̀lọ la àárín gbùngbùn Ọsirélíà kọjá. Òkun Íńdíà wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ó sì ṣàn gba etídò Áfíríkà. Ìjì líle sábàá máa ń jà ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ayé yìí.
Láyé ìgbà kan, nísàlẹ̀ ìgbì omi ìlú Broome, àwọn òkòtó òkun tí péálì wà nínú wọn pọ̀ gan-an débi pé Èbúté Péálì ni wọ́n ń pe ìlú Broome. Àwọn tó ń jalè lójú òkun, àwọn ẹrú àtàwọn tó ń ṣòwò péálì wà lára àwọn tí ìtàn ìlú Broome sọ̀rọ̀ nípa wọn.
Àwárí Tí Olè Ojú Òkun Kan Ṣe
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ilẹ̀ Netherlands náà Dirck Hartog, lọ káàkiri ilẹ̀ Ọsirélíà ní 1616, ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọ etíkun tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ yìí títí di 1688. Ọdún yẹn ni ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà William Dampier, tó jẹ́ òǹkọ̀wé, òṣèré, tó tún ń ṣàfọwọ́rá lójú òkun ṣàdédé kan etídò yìí ku nígbà tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń pè ní Cygnet. Nígbà tí Dampier padà délé, ó tẹ gbogbo nǹkan tó rí jáde nínú ìwé. Àwọn ohun tó kọ àtàwọn àwòrán tó yà wú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ lórí gan-an. Ni Àwọn Ọmọ Ogun Ojú Omi Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bá gbé ọkọ̀ ojú omi kan fún un pé kó fi rìnrìn àjò lójú òkun lọ sí New Holland, bí wọ́n ṣe ń pe Ọsirélíà nígbà yẹn.
Ìrìn àjò tí Dampier fi ọkọ̀ ojú omi tó ń jẹ́ Roebuck tí wọ́n gbé fún un rìn kò fọre o. Ó rìn-rìn-rìn láìrí agbègbè tuntun èyíkéyìí, kódà, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ rì, ibẹ̀ sì ni ìrìn àjò rẹ̀ parí sí. Àmọ́ Dampier rù ú là o, ìkarawun tó ní péálì nínú sì wà lára àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ṣàwárí nínú ìrìn àjò rẹ̀.
Ẹ̀mí Èèyàn àti Bọ́tìnnì Ṣíṣe Sọ Àwọn Kan Di Ọlọ́rọ̀
Ó tó ọgọ́jọ [160] ọdún lẹ́yìn náà kí ẹnikẹ́ni tó mọyì ohun tí Dampier ṣàwárí rẹ̀. Ní 1854, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kó òkòtó òkun ní àgbègbè tí Dampier ti pè ní Shark Bay tẹ́lẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà kò fi bẹ́ẹ̀ yọrí. Àmọ́ ṣá, wọ́n rí àwọn òkòtó òkun ńláńlá tí wọ́n ń pè ní Pinctada maxima, nínú àwọn omi tí kò jìnnà sí Nichol Bay. Inú ìkarawun àwọn òkòtó òkun tó fẹ̀ tó abọ́ ìjẹun yìí ni wọ́n ti ń rí péálì tó dára jù lọ lágbàáyé, àwọn èèyàn sì ń wá a lójú méjèèjì láti fi ṣe bọ́tìnnì.
Nígbà tó fi máa di àwọn ọdún 1890, péálì oníyebíye tí wọ́n ń kó wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dọọdún láti ìlú Broome ti tó ọ̀kẹ́ méje [140,000] owó ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n máa ń rí ọ̀pọ̀ péálì lára ìkarawun, àfikún èrè sì lèyí jẹ́. Àmọ́ ìkarawun yìí gangan ló sọ ọ̀pọ̀ àwọn tó bẹ̀rẹ̀ òwò péálì di ọlọ́rọ̀. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀mí èèyàn ń ṣòfò sórí ọrọ̀ wọn yìí lọ́pọ̀ ìgbà.
Tẹ́lẹ̀, ńṣe làwọn oníṣòwò péálì máa ń lo wàyó fún àwọn tó kọ́kọ́ tẹ̀dó sí ìlú Broome tàbí kí wọ́n fagbára mú wọn láti lọ máa kó òkòtó òkun lábẹ́ omi, kíá làwọn wọ̀nyí náà sì ti mọ iṣẹ́ náà dáadáa. Àmọ́ iṣẹ́ tó léwu púpọ̀ ni kí èèyàn máa lọ kó òkòtó òkun lábẹ́ omi, lára àwọn tó ń ṣe é kú sínú omi, ẹja ekurá sì pa àwọn mìíràn jẹ. Bákan náà, àìsí ààbò àti àbójútó tó péye látọ̀dọ̀ àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ mú kí ẹ̀mí àwọn mìíràn ṣòfò. Wọ́n tún lọ kó àwọn wẹdòwẹdò wá láti Malaysia àti Java káwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà bàa lè pọ̀ sí i. Ìgbà tí wọ́n kó gbogbo òkòtó òkun tó wà nínú omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jinlẹ̀ tán, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo akoto ìwẹmi tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti lè lọ sísàlẹ̀ omi tó túbọ̀ jìn gan-an.
“Sódómù àti Gòmórà” Wọko Gbèsè
Iṣẹ́ péálì wíwá ní Broome gbèrú gan-an, ó lé ní irínwó [400] ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ náà. Ìṣe àti àṣà àwọn ará Éṣíà, àwọn ará Yúróòpù àti tàwọn tó tẹ Broome dó, tí wọ́n kóra jọ pọ̀ kò dára rárá, ìwàkiwà ni wọ́n sábàá máa ń hù. Ọkùnrin kan tó bá wọn wá péálì sọ ohun tó gbòde nígbà náà pé: “Broome [jẹ́] àgbègbè tó lọ́rọ̀, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ kúnnú rẹ̀, kóńkó jabele lọ̀rọ̀ ibẹ̀ ohun tó sì wu kálukú ló ń ṣe. Wọ́n ka fífi tí àwọn Àlùfáà ń fi ìwà wọn wé Sódómù àti Gòmórà sí ọ̀rọ̀ ìyìn nípa ìtẹ̀síwájú táwọn èèyàn ń ní, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ìkìlọ̀ àjálù tí Ọlọ́run á mú wá lọ́jọ́ iwájú ni.”
Àmọ́ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀, òwò péálì oníyebíye dẹnu kọlẹ̀, ìlú Broome sì wọko gbèsè lójijì. Láàárín ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí sígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, okòwò náà gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀, àmọ́ àjálù mìíràn tún já lu ìlú Broome lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ike, kò sì pẹ́ tí bọ́tìnnì oníke fi gbayì táwọn èèyàn ò sì ra péálì mọ́.
Ṣíṣe ‘Péálì Tó Ṣeyebíye’
Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, aṣojú ilẹ̀ Ọsirélíà kan ṣèbẹ̀wò sáwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe péálì nílùú Ago, ní Japan. Níbẹ̀, Kokichi Mikimoto ti sọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe péálì dòun. Bó ṣe ṣe é ni pé ó fi òkúta kékeré kan sínú ìkarawun òkòtó òkun. Ìwé Port of Pearls sọ pé, Mikimoto sọ fún àwọn ará Ọsirélíà pé “wọ́n lè ṣe é kí àwọn péálì tó ṣeyebíye máa hù nínú àwọn ìkarawun [òkòtó òkun] ńláńlá tó wà nínú omi Ọsirélíà tó máa ń lọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́.” Wọ́n kúkú ka ìmọ̀ràn rẹ̀ sí, nígbà tó sì fi máa di àwọn ọdún 1970, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn péálì tó tóbi jù lọ tó tún níyì jù lọ lágbàáyé lára àwọn òkòtó òkun tó wà ní Ọsirélíà.
Àwọn péálì tí wọ́n ń ṣe ní ọ̀pọ̀ àgbègbè lágbàáyé kì í fẹ̀ ju mìlímítà mọ́kànlá lọ, àmọ́ èyí tí wọ́n ń rí lára àwọn òkòtó òkun tó wà ní Òkun Gúúsù máa ń fẹ̀ tó mìlímítà méjìdínlógún. Tí wọ́n bá sín àwọn péálì ńlá yìí sára okùn tán, owó rẹ̀ lè lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] owó Ọsirélíà. Abájọ téèyàn ò fi ṣì sọ tó bá pe ohun iyebíye tó rí róbótó yìí ní dáyámọ́ńdì tí wọ́n ń rí lábẹ́ òkun!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
William Dampier
Wẹdòwẹdò kan tó ń ṣa ìkarawun òkòtó òkun ní etíkun tó wà ní àríwá ìlú Broome
Akọ́ṣẹ́mọsẹ́ kan ń yọ péálì nínú ìkarawun
Ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ ojú omi ayé ọjọ́un tí wọ́n tún ṣe kí wọ́n tún lè rí i lò lójú òkun
Oríṣiríṣi àwọ̀ ni péálì máa ń ní (wọ́n yà á gàdàgbà)
[Àwọn Credit Line]
William Dampier: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda National Library of Australia - Rex Nan Kivell Collection, NK550; wẹdòwẹdò: © C. Bryce - Lochman Transparencies; ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti ògbógi: Ọlá Àṣẹ Department of Fisheries WA, J. Lochman; ọkọ̀ ojú omi: Ọlá Àṣẹ Department of Fisheries WA, C. Young; péálì tá a yà gàdàgbà: Ọlá Àṣẹ Department of Fisheries WA, R. Rose