Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ka Ìgbéyàwó Sí Ohun Mímọ́?
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lónìí ló máa sọ pé àwọn gbà gbọ́ nínú ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó. Nígbà náà, kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó fi ń tú ká? Lójú àwọn kan, wíwulẹ̀ báni ṣàdéhùn àtimáa jadùn ìfẹ́ tàbí bíbáni ṣàdéhùn lábẹ́ òfin ni ìgbéyàwó jẹ́. Àdéhùn a sì máa yẹ̀. Àwọn tó ń wo ìgbéyàwó lọ́nà yìí rí i pé ó rọrùn jẹ̀lẹ̀jẹlẹ láti fòpin sí ìgbéyàwó bí nǹkan ò bá rí bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀.
Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ètò ìgbéyàwó? Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé Hébérù 13:4: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ní ọlá” túmọ̀ sí ohun kan tó ṣeyebíye tá a sì ń gbé gẹ̀gẹ̀. Bá a bá ka ohun kan sí èyí tó ṣeyebíye, ńṣe la ó máa ṣìkẹ́ rẹ̀, a ò sì ní fẹ́ pàdánù rẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí. Ọwọ́ tó yẹ ká fi mú ìgbéyàwó náà nìyẹn. Ó yẹ káwọn Kristẹni máa wò ó bí ohun tó lọ́lá, ohun iyebíye kan tí wọ́n á máa ṣìkẹ́ rẹ̀.
Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà Ọlọ́run fètò ìgbéyàwó lélẹ̀ g̣ẹ́gẹ́ bí ètò mímọ́ láàárín ọkọ àti aya. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè fi hàn pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó la fi ń wò ó?
Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀
Bíbọlá fún ètò ìgbéyàwó béèrè pé kí tọkọtaya máa bọlá fún ara wọn. (Róòmù 12:10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
Òótọ́ ni pé nígbà míì, ọkọ tàbí aya kan lè má máa fi ìfẹ́ tàbí ọ̀wọ̀ hàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fi irú ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ bára wọn lò. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.
Àkókò àti Àfiyèsí
Àwọn tọkọtaya tí wọ́n bá wo ìdè ìgbéyàwó wọn bí ohun mímọ́, máa ń wá bí wọ́n á ṣe pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara àti bí wọ́n á ṣe máa wá nǹkan ṣe sí ohun tó bá ń dùn wọ́n lọ́kàn. Èyí ò sì yọ ọ̀ràn nípa ìbálòpọ̀ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:3.
Àmọ́ ṣá o, àwọn tọkọtaya kan ti rí i pé ó pọn dandan fún ọkọ láti wáṣẹ́ lọ síbòmíràn fúngbà díẹ̀, kówó tó ń wọlé fún wọn lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Nígbà míì, àkókò tí wọn ò fi wà pa pọ̀ yìí máa ń gùn ju bí wọ́n ti rò lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, irú ìpínyà bẹ́ẹ̀ ti kó ìgbéyàwó sí ìṣòro, ó tiẹ̀ máa ń yọrí sí panṣágà àti ìkọ̀sílẹ̀ nígbà mìíràn. (1 Kọ́ríńtì 7:2, 5) Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ tọkọtaya ti pinnu láti má ṣe lépa ọrọ̀ nípa tara kí wọ́n má bàa wu ìgbéyàwó tí wọ́n kà sí mímọ́ léwu.
Nígbà tí Ìṣòro Bá Yọjú
Nígbà tí ìṣòro bá yọjú, àwọn Kristẹni tí wọ́n bọlá fún ìgbéyàwó wọn kì í tètè pínyà tàbí kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀. (Málákì 2:16; 1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Jésù wí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe ní tìtorí àgbèrè, sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu panṣágà, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 5:32) Bí tọkọtaya kan bá yàn láti kọra wọn sílẹ̀ tàbí láti pínyà láìsí ìdí èyíkéyìí tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe ni wọ́n tàbùkù sí ètò ìgbéyàwó.
Ìmọ̀ràn tá a bá ń fáwọn tó ń fojú winá ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn tún ń sọ nípa ojú tá a fi ń wo ìgbéyàwó. Ṣé ara máa ń yá wa láti dábàá pé kí tọkọtaya pínyà tàbí kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀? Lóòótọ́, ìdí tó lẹ́ṣẹ̀ nílẹ̀ lè wà fáwọn kan láti pínyà o, irú bí ìgbà tí tọkọtaya bá ń lu ara wọn ní àlùpamọ́kùú, tàbí tí wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fúnra wọn.a Bákan náà, bá a ṣe mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ yìí, Bíbélì jẹ́ kó yéni pé nígbà tí ọkọ tàbí aya ẹni bá ṣe àgbèrè nìkan la lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Síbẹ̀, kò yẹ káwọn Kristẹni máa ṣàdéédéé báwọn ẹlòmíràn pinnu ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ó ṣe tán, ẹni tó ń fojú winá ìṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ̀ lá máa bá àbájáde àwọn ìpinnu tóun fúnra rẹ̀ ṣe yí, kì í ṣe ẹni tó gbà á nímọ̀ràn.—Gálátíà 6:5, 7.
Má Ṣe Fojú Ṣákálá Wo Ìgbéyàwó
Láwọn àgbègbè kan ìgbéyàwó làwọn kan sábà máa ń fi bojú kí wọ́n lè rí ìwé àṣẹ gbà láti máa gbé lórílẹ̀-èdè mìíràn. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ẹnì kan á bá ẹni tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè yẹn ṣàdéhùn pé òun á sanwó fún un bó bá lè gbà káwọn jọ fẹ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì gbéra wọn níyàwó, wọn ò ní jọ gbé pọ̀, wọ́n tiẹ̀ lè máà ní àjọṣe kankan dà bí alárà. Gbàrà tọ́wọ́ èyí tó ń wá ìwé àṣẹ tó fi lè máa gbé lórílẹ̀-èdè náà nínú àwọn méjèèjì bá ti tẹ ohun tó ń wá, ńṣe ni wọ́n á kọra wọn sílẹ̀. Òwò ṣíṣe ni wọ́n ka ìgbéyàwó wọn sí.
Bíbélì ò lọ́wọ́ sí fífi irú ojú ṣákálá bẹ́ẹ̀ wo ìgbéyàwó. Ohun yòówù táwọn tó gbéra wọn níyàwó ì báà sì ní lọ́kàn, wọ́n ti sọ ara wọn di apá kan ètò mímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kó wà títí gbére. Àwọn tó bá gbéra wọn níyàwó ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ti di tọkọtaya, òfin kan ṣoṣo tó bá Bíbélì mu fún ìkọ̀sílẹ̀ kéèyàn sì fẹ́ ẹlòmíràn, de àwọn náà.—Mátíù 19:5, 6, 9.
Bó ṣe máa ń rí nínú gbogbo ohun téèyàn bá dáwọ́ lé, ìgbéyàwó tó bá máa yọrí sí rere ń béèrè ìsapá àti ìforítì. Àwọn tí ò mọrírì ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó ni wọ́n tètè máa ń juwọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì lè máa fagídí yí i mọ́ ọn nínú ìgbéyàwó tí ò fún wọn láyọ̀. Ẹ̀wẹ̀, àwọn tó mọrírì ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn jọ wà pọ̀ ni. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Wọ́n tún mọ̀ pé báwọn bá jẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn wà ní ìṣọ̀kan, àwọn ń bọlá fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Níní ojú ìwòye yìí ni ò mú kí wọ́n dẹ́kun àtimáa sapá kí ìgbéyàwó wọn lè yọrí sí rere.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1988, ojú ìwé 22 sí 23.