Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Àìsàn Ò Ní Sí Mọ́!
Ọ̀PỌ̀ èèyàn rò pé ìgbà táwọn bá lọ sọ́rùn làwọn máa tó bọ́ lọ́wọ́ ìrora àti àìsàn. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ ni pé gbogbo aráyé ló ní àǹfààní láti máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:11; 115:16) Lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé a máa gbádùn ní ọjọ́ ọ̀la yìí ni ìlera pípé, ayọ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun.
Kí ló fà á tá a fi ń ṣàìsàn tá a sì ń kú? Báwo sì ni ayé á ṣe dayé tí àìsàn ò ti ní í sí mọ́? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn.
◼ Ohun tó ń fa àìsàn gan-an Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà ní pípé, ara wọn sì dá ṣáṣá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Diutarónómì 32:4) Ọlọ́run dá wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa wà láàyè títí láé. Ìgbà tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ di ọlọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ni àrùn bẹ̀rẹ̀ sí í wọlé sí wọn lára. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ mú kí wọ́n di apẹ̀yìndà sí Ẹlẹ́dàá, Ẹni tó dá wọn ní pípé. Wọ́n dẹni tó lálèébù. Ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi dẹni tó ń ṣàìsàn tó sì ń kú, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 5:5.
Lẹ́yìn ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà, kò sóhun táwọn ọmọ wọn rí jogún lára wọn ju àìpé lọ. (Róòmù 5:12) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní gbà pé àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ kan wà tó ń pa kún àìsàn àti ikú, tó sì jẹ́ pé ṣe la jogún wọn. Lẹ́yìn ìwádìí tó rìn jìnnà, ibi táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fẹnu ọ̀rọ̀ jóná sí lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni pé: “Òtítọ́ kan tí ò ṣeé já ní koro nípa ẹ̀dá ni pé gbàrà tí ìwàláàyè bá ti bẹ̀rẹ̀ báyìí, ńṣe ni ohun tó máa pa ara fúnra rẹ̀ run á bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ara.”
◼ Ó kọjá agbára ẹ̀dá Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà lórí ọ̀ràn gbígbógun ti àìsàn. Àmọ́ ohun tó ń fa àìsàn ti díjú kọjá ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè wá ojútùú pátápátá sí. Èyí ò lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lóye gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.”—Sáàmù 146:3.
Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:27) Jèhófà Ọlọ́run lè mú ohun tó ń fa àìsàn kúrò. Ó máa mú gbogbo àìsàn tó ń ṣe wá kúrò. (Sáàmù 103:3) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
◼ Ohun tó yẹ kó o ṣe Jésù Kristi ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè gbádùn ayé tí ò ti ní sí àìsàn mọ́, èyí tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Ìmọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀kọ́ tí Ọmọ rẹ̀, Jésù fi kọ́ni, wà nínú Bíbélì. O lè rí ìmọ̀ràn tí ń ṣeni lóore, èyí tó lè mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i nísinsìnyí gbà nínú irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀. Kò wá mọ síbẹ̀ yẹn nìkan o, Ọlọ́run tún ṣèlérí pé ayé ń bọ̀ wá di ibi tí kò ti ní sí ìrora mọ́ fáwọn onígbọràn èèyàn tó ń sìn ín. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fẹ́ kí ìwọ náà máa gbé nínú ayé kan níbi tí kò ti ní sí “olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí’”!—Aísáyà 33:24.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Ìlera
Ohun tí Bíbélì tẹnu mọ́ ni pé ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ìwàláàyè. Irú ọwọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ sì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú un, ìyẹn ni wọ́n kì í fi í fọ̀ràn ìlera wọn ṣeré. Wọ́n kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó lè fa ìpalára, bíi lílo oògùn olóró àti fífín tábà tàbí mímu sìgá. Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn tó ń sin òun ki àṣejù bọ jíjẹ àti mímu. (Òwe 23:20; Títù 2:2, 3) Báwọn èèyàn bá ń ṣe àwọn ohun tó lè ṣara lóore wọ̀nyí, tí wọ́n ń fára nísinmi, tí wọ́n sì ń ṣeré ìdárayá tó bó ṣe yẹ, àìsàn ò ní tètè ṣe wọ́n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kòòré ẹ̀ pátápátá. Àwọn tó ń ṣàìsàn lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀jáfáfá oníṣègùn tó ṣeé gbára lé.
Bíbélì fẹ́ ká máa fojú tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì wo nǹkan ká sì ní “ìyèkooro èrò inú.” (Títù 2:12; Fílípì 4:5) Ọ̀pọ̀ èèyàn lóde tòní ni ò mọ béèyàn ṣeé wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tí kò sì sí ibi tí wọn ò lè wá ìtọ́jú gbà, kódà bí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ bá máa ba àárín àwọn àti Ọlọ́run jẹ́. Kódà, àwọn kan ò kọ ìtọ́jú tó ń kọni lóminú tó sì lè pani lára. Àwọn míì máa ń náwó nínàákúnàá sórí ìtọ́jú àti oògùn tí ò bá ohun tó ń ṣe wọ́n mu tàbí tó tiẹ̀ léwu pàápàá.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò tíì ṣeé ṣe báyìí láti gbádùn ìlera pípé. Bó o ti ń dúró de ọjọ́ iwájú náà nínú èyí tí kò ti ní í sí àìsàn mọ́, ọgbọ́n àti òye tó wà nínú Bíbélì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ìlera bó o ti ń wọ̀nà fún gbígbádùn ìlera tó jíire.