Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Á Gba Aráyé Lọ́wọ́ Àìsàn?
ṢÉ ÌMỌ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní á gba aráyé lọ́wọ́ àìsàn? Ǹjẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó wà nínú ìwé Aísáyà àti Ìṣípayá sọ nípa àkókò kan táwọn ọmọ aráyé á fọwọ́ ara wọn mú àìsàn kúrò pátápátá? Látàrí ọ̀pọ̀ ohun kàǹkà-kàǹkà tí wọ́n ti gbé ṣe lórí ọ̀ràn ìlera, àwọn kan ronú pé ìyẹn ò kọjá ohun tí wọ́n lè ṣe.
Ìjọba àtàwọn ẹlẹ́yinjú àánú ti ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ báyìí pẹ̀lú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti máa gbógun ti àrùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀kan lára ìgbòkègbodò náà dá lórí fífún àwọn ọmọdé lábẹ́rẹ́ àjẹsára láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé ṣe sọ, báwọn orílẹ̀-èdè bá lé àwọn ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé là sílẹ̀ fún wọn bá, “bó bá fi máa di ọdún 2015, èyí tó ju àádọ́rin mílíọ̀nù lọ lára àwọn ọmọdé tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ lágbàáyé á máa rí abẹ́rẹ́ àjẹsára gbà lọ́dọọdún láti lè dènà àwọn àrùn wọ̀nyí, ìyẹn ikọ́ fée, gbọ̀fungbọ̀fun, ẹran ipá, ikọ́ àwúbì, yìkíyìkí, ibà pọ́njú, kòkòrò tó ń fa yínrùnyínrùn, àrùn mẹ́dọ̀wú, rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀, àrùn tó ń mú kọ́mọdé máa yàgbẹ́ gbuuru, àrùn tó ń fa otútù àyà tó légbá kan, àrùn tó ń mú kí eegun ògóóró ẹ̀yìn máa roni àti àrùn tó máa ń mú kí ọpọlọ wúlé.” Wọ́n tún ti ń sapá láti ṣe àwọn ohun tó máa mú kára dá ṣáṣá, bíi kéèyàn máa rómi tó mọ́ mu, kéèyàn máa jẹun tó ń ṣara lóore, wọ́n sì tún ń pèsè ẹ̀kọ́ nípa ìmọ́tótó.
Àmọ́ ṣá o, ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní lọ́kàn láti ṣe ju wíwulẹ̀ ṣẹ́pá àwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti ń mú kí ìyípadà wáyé lágbo ìmọ̀ ìṣègùn. Wọ́n ti sọ pé ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ-mẹ́jọ, ìmọ̀ ìṣègùn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní máa ń di ìlọ́po méjì. Àlàyé tó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan díẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé lágbo ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń fẹ́ láti ṣe kí wọ́n bàa lè gbógun tàrùn.
◼ Fífi fọ́tò yàwòrán inú ara Ó ti lé lọ́gbọ̀n ọdún báyìí táwọn dókítà àtàwọn ilé ìwòsàn ti ń lo ohun tá a mọ̀ sí ẹ̀rọ CT tó máa ń gbé àwòrán inú ara jáde lábala lábala sórí kọ̀ǹpútà. Àpèjá orúkọ ẹ̀rọ CT yìí ni ẹ̀rọ afi-kọ̀ǹpútà yàwòrán kọ́lọ́fín inú ara. Ẹ̀rọ CT yìí máa ń lo ẹ̀rọ tó ń ya fọ́tò inú ara láti fi gbé àwòrán jáde, àwòrán náà a sì fi abala ọ̀tún, òsì àti ti àárín inú ara hàn. Àwọn àwòrán yìí máa ń dùn-ún lò láti fi ṣàyẹ̀wò àrùn tó bá wà lára àti ibi tó bá ń dunni nínú kọ́lọ́fín ara.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ṣì ń ṣawuyewuye lórí ewu tó wà nínú bí ìtànṣán tí ẹ̀rọ yìí ń lò ṣe máa ń wọnú ara, àwọn ògbógi nínú ìmọ̀ ìṣègùn ò tiẹ̀ mikàn rárá nípa àǹfààní tó lè jẹ yọ látinú ìmọ̀ ẹ̀rọ tó túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú yìí. Michael Vannier, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú fífi ìtànṣán inú ẹ̀rọ ṣètọ́jú àìsàn ní ilé ìwé gíga University of Chicago Hospital sọ pé: “Láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí nìkan, ibi tá a tẹ̀ síwájú dé tó ohun téèyàn lè tìtorí ẹ̀ gbàlù.”
Àwọn ẹ̀rọ CT ti ń yara ṣiṣẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ báyìí, àwòrán wọn ń ṣe kedere sí i, owó tí wọ́n ń náni sì ti dín kù sí i. Àǹfààní pàtàkì kan ni báwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń yàwòrán inú ara ní báyìí ṣe yára sì tún wá jẹ́. Pàápàá nígbà tí wọ́n bá ń yàwòrán ọkàn. Nítorí pé àyà máa ń lù kìkì láìdáwọ́ dúró, bí wọ́n bá fi ìtànṣán ẹ̀rọ yàwòrán rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ hàn dáadáa, ìyẹn sì máa ń mú kó ṣòro fún wọn láti mọ àlàyé tí wọ́n máa ṣe nípa bó ṣe ń ṣiṣẹ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe ṣàlàyé, “ìdámẹ́ta ìṣẹ́jú àáyá péré ló máa ń gba” àwọn ẹ̀rọ tó ń fi ìtànṣán yàwòrán kọ́lọ́fín ara tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, “láti lọ yíká inú ara, á sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán kí àyà tó lù kì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Èyí ń mú kí àwòrán tó bá yà túbọ̀ ṣe kedere.
Báwọn dókítà ṣe ń lo ẹ̀rọ tó ń yàwòrán kọ́lọ́fín inú ara tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde yìí, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti yàwòrán tó máa ń fi kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ẹ̀yà inú kọ́lọ́fín ara hàn. Àti pé yàtọ̀ síyẹn, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣàyẹ̀wò bí àwọn kẹ́míkà ṣe ń ṣiṣẹ́ sí láwọn ibì kan nínú ara. Irú àyẹ̀wò tó ti ṣeé ṣe yìí lè mú kó rọrùn láti dá àrùn jẹjẹrẹ mọ̀ nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nínú ara.
◼ Fífi ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì ṣiṣẹ́ abẹ Iṣẹ́ àwọn ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì tó ń ṣiṣẹ́ bí èèyàn kì í tún ṣe ìtàn àròsọ mọ́ lágbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, pàápàá lágbo ìmọ̀ ìṣègùn. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún iṣẹ́ abẹ ni wọ́n ti ń fi àwọn ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì ṣe. Wọ́n tiẹ̀ ń ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ kan nípa títẹ bọ́tìnnì láti ibi kan. Bọ́tìnnì tí wọ́n ń tẹ̀ yìí á máa mú kí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì náà lè máa lo ọwọ́ rẹ̀ láti ṣe onírúurú ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe. Wọ́n máa ń de ọ̀bẹ, sísọ́ọ̀sì, kámẹ́rà, ohun èlò oníná tí wọ́n fi ń la ara àtàwọn ohun èlò iṣẹ́ abẹ míì mọ́ ọwọ́ róbọ́ọ̀tì náà. Ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí máa ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn oníṣẹ́ abẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ tó díjú débi gẹ́ẹ́, tó sì jẹ́ pé ibi tí ìṣòro wà ní tààràtà ni wọ́n á lọ, láìyà sọ́tùn-ún sósì. Ìwé ìròyìn Newsweek ṣàlàyé pé: “Àwọn oníṣẹ́ abẹ tí wọn ń gba ọ̀nà yìí ṣiṣẹ́ abẹ ti rí i pé kì í jẹ́ káwọn aláìsàn pàdánù ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀, ó máa ń dín ìrora kù, àṣìṣe kì í fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, aláìsàn kì í pẹ́ nílé ìwòsàn, ara aláìsàn sì tètè máa ń yá ju àwọn tí wọn ò fi ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ abẹ fún lọ.”
◼ Iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n ń fàwọn ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ ṣe Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó dá lórí ṣíṣe àwọn ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ ni wọ́n ń lò nínú irú iṣẹ́ ìṣègùn yìí. Ẹ̀wẹ̀, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó dá lórí ṣíṣe àwọn ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ yìí ní í ṣe pẹ̀lú dídarí àwọn ẹ̀rọ yìí láti ṣiṣẹ́ tàbí ṣíṣe irú àwọn ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ tààrà. Nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí, bí wọ́n bá díwọ̀n ohun kan, èdè tí wọ́n fi máa ń pe ohun tí wọ́n díwọ̀n náà ni nànómità, èyí tó jẹ́ ìdá kan nínú bílíọ̀nù mítà.a
Ọ̀nà tó o lè gbà lóye bí ìdíwọ̀n yìí ṣe kéré tó rèé. Ṣó o rí ojú ìwé tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, nínípọn rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] nànómità. Nínípọn irun orí èèyàn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] nànómità. Fífẹ̀ sẹ́ẹ̀lì pupa tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] nànómità. Gígùn bakitéríà kan tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún nànómità, gígùn fáírọ́ọ̀sì kan jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún nànómità. Èròjà apilẹ̀ àbùdá tìẹ fúnra ẹ sí fẹ́ to nǹkan bíi nànómità méjì ààbọ̀.
Àwọn tó dábàá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ yìí gbà gbọ́ pé láìpẹ́ láìjìnnà, ó máa ṣeé ṣe fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣe àwọn ẹ̀rọ tín-tínní táá lè máa ṣètọ́jú àìsàn nínú ara èèyàn. Àwọn kọ̀ǹpútà tó kéré kọjá ohun tí ojú lè rí á máa wà nínú àwọn ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì tíntìntín tí wọ́n sábà máa ń kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ yìí, àwọn ohun tí kọ̀ǹpútà yìí á ṣe sì ti wà nínú ẹ̀. Ohun tó wá jẹ́ ìyàlẹ́nu jù lọ níbẹ̀ ni pé, ohun èlò tí wọ́n máa fi ṣe àwọn ẹ̀rọ tó díjú yìí ò ní tóbi ju ọgọ́rùn-ún nànómità lọ, ìyẹn dà bí ìgbà tá a bá dá nínípọn ojú ìwé yìí sí ọ̀nà ẹgbẹ̀rún kan. Ìyẹn sì fìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kéré sí fífẹ̀ sẹ́ẹ̀lì pupa!
Nítorí pé àwọn ẹ̀rọ yìí kéré gan-an, wọ́n nírètí pé ọjọ́ kan á jọ́kan táwọn ẹ̀rọ yìí á lè máa rìn gba inú àwọn òpójẹ̀ tó tín-ín-rín kọjá kí wọ́n bàa lè máa gbé afẹ́fẹ́ ọ́síjìn lọ sínú ẹran ara tí kò lẹ́jẹ̀ tó, kí wọ́n máa kó èérí tó bá dí ojúhò iṣan ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì máa ha ìdọ̀tí kúrò lára sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ, kódà kí wọ́n máa ṣàwárí àwọn fáírọ́ọ̀sì, bakitéríà àtàwọn kòkòrò mìíràn tó ń ranni kí wọ́n sì máa pa wọ́n. Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n máa lo àwọn ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ yìí láti máa gbé oògùn lọ sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì pàtó kan nínú ara.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé lílo ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ yìí á mú kó túbọ̀ rọrùn láti mọ̀ bí àrùn jẹjẹrẹ bá wà nínú. Dókítà Samuel Wickline, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìṣègùn, ẹ̀kọ́ físíìsì àti ìlò ìmọ̀ ẹ̀rọ fún yíyanjú ìṣòro ìlera, sọ pé: “Ó ti wá ṣeé ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà báyìí láti tètè ṣàwárí àrùn jẹjẹrẹ tó kéré gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ, láti fàwọn oògùn tó lágbára ṣètọ́jú apá ibi tó bá ti wúlé nìkan, ká sì tún dín ewu èyíkéyìí tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ kù.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè dún bí ìtàn àsọdùn nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan wà tí wọ́n lè fọwọ́ iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ ṣe yìí sọ̀yà. Àwọn òléwájú nínú ìwádìí tó jẹ mọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí nírètí pé láàárín ọdún mẹ́wàá sígbà tá a wà yìí, á ti di èyí tí wọ́n á máa lò láti tún sẹ́ẹ̀lì tó bá bà jẹ́ ṣe tàbí kí wọ́n máa lò ó láti ṣe àtúntò sẹ́ẹ̀lì. Ọ̀kan lára àwọn agbátẹrù ìmọ̀ ẹ̀rọ náà tiẹ̀ sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àrùn tó wọ́pọ̀ pátá tó ti ń ṣe aráyé láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ yìí ṣe á mú kúrò, á fẹ́rẹ̀ẹ́ fòpin sí gbogbo ìrora àti ìjìyà tí àìsàn ń mú wá, á sì jẹ́ kára àwa èèyàn túbọ̀ máa gbé kánkán sí i.” Ní báyìí pàápàá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ti lo iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ ṣe yìí láti tọ́jú àwọn ẹran láwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣèwádìí, wọ́n sì rí i pé ó ṣiṣẹ́ dáadáa bí wọ́n ṣe fẹ́.
◼ Ẹ̀kọ́ nípa apilẹ̀ àbùdá Ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ nípa bí apilẹ̀ àbùdá ṣe rí àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Gbogbo sẹ́ẹ̀lì inú ara ló ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe kókó fún gbígbé ìwàláàyè ró nínú. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan ṣíṣe kókó ọ̀hún ló ń jẹ́ apilẹ̀ àbùdá. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní apilẹ̀ àbùdá tó tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [35,000]. Àwọn apilẹ̀ àbùdá yìí ló sì ń darí irú àwọ̀ tí irun wa máa ní àti bó ṣe máa rí lọ́wọ́, bí àwọ̀ ara àti ojú wa ṣe máa rí, bá a ṣe máa ga tó àtàwọn àbùdá míì nípa ìrísí ara wa. Àwọn apilẹ̀ àbùdá wa tún máa ń kó ipa pàtàkì nínú dídarí bí àwọn ẹ̀yà inú ara wa lọ́hùn-ún á ṣe máa ṣiṣẹ́ dáadáa sí.
Bí àwọn apilẹ̀ àbùdá bá bà jẹ́, wọ́n máa ń nípa lórí ìlera wa. Kódà, àwọn olùṣèwádìí kan gbà gbọ́ pé gbogbo àìsàn tó wà ló jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ ló ń fà á. Àwọn apilẹ̀ àbùdá kan wà tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa, tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa. Àwọn ohun tó wà láyìíká wa ló sì ń ba àwọn míì jẹ́.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nírètí pé ó máa tó ṣeé ṣe fáwọn láti dá àwọn apilẹ̀ àbùdá pàtó kan tí wọ́n máa ń jẹ́ ká kó àrùn mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, èyí lè jẹ́ káwọn dókítà kan lóye ìdí tí àrùn jẹjẹrẹ fi máa ń ṣe àwọn kan ju àwọn míì lọ tàbí ìdí tí irú àrùn jẹjẹrẹ kan fi máa ń lágbára lára àwọn kan ju àwọn míì lọ. Ẹ̀kọ́ nípa apilẹ̀ àbùdá tún lè jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí oògùn kan fi máa ń ṣiṣẹ́ lára àwọn aláìsàn kan tí kì í sì í ṣiṣẹ́ lára àwọn aláìsàn míì.
Irú ìsọfúnni pàtó yìí nípa apilẹ̀ àbùdá lè yọrí sí ohun tí wọ́n ń pè ní iṣẹ́ ìṣègùn tó bá ohun tó ń ṣe oníkálùkù mu. Báwo ni ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní? Ohun tí iṣẹ́ ìṣègùn yìí dá lé lórí ni pé wọ́n á lè lò ó láti fi tọ́jú oníkálùkù lọ́nà tó bá apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ mu. Bí àpẹẹrẹ, bí ìwádìí bá fi hàn pé àwọn apilẹ̀ àbùdá rẹ lè mú kí irú àrùn kan ràn ẹ́, àwọn dókítà á ti rí irú àrùn bẹ́ẹ̀ kó tiẹ̀ tó di pé àwọn àmì àrùn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Àwọn tó ń ṣagbátẹrù irú ìtọ́jú yìí sọ pé bó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé àrùn náà ò tíì wáyé rárá, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kòòré ẹ̀ pátápátá nípa fífúnni ní ìtọ́jú àti oúnjẹ tó yẹ, títí kan yíyí ìwà ẹni padà.
Àwọn apilẹ̀ àbùdá ẹ tún lè ta àwọn dókítà lólobó pé ó ṣeé ṣe káwọn oògùn kan gbòdì lára ẹ. Ìsọfúnni yìí lè mú kó ṣeé ṣe fáwọn dókítà láti júwe oògùn pàtó tó yẹ kó o lò sí ohun tó ń ṣe ẹ́ àti ìwọ̀n tó yẹ kó o lò. Ìwé ìròyìn The Boston Globe ròyìn pé: “Bó bá fi máa di ọdún 2020, ipa tí [iṣẹ́ ìṣègùn tó bá ohun tó ń ṣe oníkálùkù mu] á ní á ti pọ̀ fíìfíì kọjá ohun tí ẹnikẹ́ni nínú wa lè fọkàn yàwòrán ẹ̀ lóde òní. Àwọn oògùn tuntun tó dá lórí apilẹ̀ àbùdá tí wọ́n ṣe lọ́nà táá fi bá ohun tó ń ṣe oníkálùkù mu á ti wà fáwọn àìsàn bí àtọ̀gbẹ, àrùn ọkàn, àrùn Alzheimer tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ dáadáa, àrùn ọpọlọ dídàrú, àtàwọn àìlera míì tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn láwùjọ wa.”
Àpẹẹrẹ lásán làwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tá a ṣàlàyé nípa wọn yìí wulẹ̀ jẹ́ lára ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣèlérí pé àwọn á ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ńṣe ni ìmọ̀ nípa ìṣègùn ń pọ̀ sí i níwọ̀n tá a ò rírú ẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò retí pé àwọn máa tó mú àìsàn kúrò pátápátá láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí o. Ọ̀pọ̀ ìdíwọ́ ló ṣì wà tó dà bí èyí tí wọn ò lè mú kúrò.
Àwọn Ìdíwọ́ Tó Dà bí Èyí Tí Kò Ṣeé Borí
Ìwà táwọn èèyàn ń hù lè mú kí bí fífòpin sí àrùn ì bá ṣe yára tó di èyí tó falẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà gbọ́ pé báwọn èèyàn ṣe ń ba àwọn àyíká kan àtàwọn ohun alààyè tó ń gbé níbẹ̀ jẹ́ ti yọrí sí àwọn àrùn tuntun, tó sì léwu. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí ìwé ìròyìn Newsweek gbé jáde, Mary Pearl, ààrẹ ẹgbẹ́ kan tó ń jẹ́ Wildlife Trust, ṣàlàyé pé: “Láti ọdún 1975 wá, àrùn tuntun tó ju ọgbọ̀n lọ ti wáyé, lára wọn ni éèdì, àrùn Ebola, àrùn Lyme àti àrùn tó jẹ mọ́ èémí. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ẹranko ló kó wọn ran àwọn èèyàn.”
Láfikún sí ìyẹn, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ jẹ èso àti ẹ̀fọ́ mọ́, àmọ́ ṣúgà, iyọ̀ àti ọ̀rá tí wọ́n ń jẹ ń pọ̀ sí i. Èyí àti ṣíṣe táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe eré ìdárayá àtàwọn àṣà míì tí kì í jẹ́ kí ara dá ṣáṣá ti mú kí àrùn òpójẹ̀ máa pọ̀ sí i. Sìgá mímu náà tún ń pọ̀ sí i, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ilẹ̀ ayé lèyí ń fa ìṣòro ìlera tó pọ̀ fún tàbí kó tiẹ̀ ṣekú pa wọ́n. Lọ́dọọdún, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ [20,000,000] èèyàn ló ń ṣèṣe tàbí kí wọ́n kú sínú ìjàǹbá ọkọ̀. Àìmọye àwọn míì sì wà tí ogun àti oríṣi àwọn ìwà ipá míì ń pa tàbí kó sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti di aláìlera nítorí ọtí líle tàbí lílo oògùn olóró.
Ohun tó wà nídìí ọ̀ràn náà ni pé láìka ohun yòówù kó fà á sí, àti bó ti wù kí ìtẹ̀síwájú bá lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ìṣègùn tó, àwọn àìsàn kan á ṣì máa bá a lọ láti fa ìrora ńláǹlà. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, ‘kò sígbà tá a kà iye àwọn tó ń ṣàárẹ̀ ọkàn, tí iye wọn kì í jú àádọ́jọ mílíọ̀nù èèyàn lọ, bẹ́ẹ̀ náà sì làwọn tó lárùn ọpọlọ, wọ́n máa ń tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, àwọn tó lárùn ẹ̀tẹ̀ sì máa ń tó mílíọ̀nù méjìdínlógójì.’ Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni àrùn éèdì, àrùn tó ń fa ìgbẹ́ gbuuru, ibà, yìkíyìkí, otútù àyà àti ikọ́ fée ti ràn, ó sì ti pa àìmọye ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́.
Àwọn ìdíwọ́ míì tún wà tó dà bí èyí tí kò ṣeé borí tó ń mú kó ṣòro láti mú àìsàn kúrò pátápátá. Méjì tó le jù lára irú àwọn ohun ìdíwọ́ bẹ́ẹ̀ ni ipò òṣì àti ìjọba tó ń fayé ni aráàlú. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ nínú ìròyìn kan láìpẹ́ yìí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn táwọn àrùn àjàkálẹ̀ ń pa ni wọn ò bá rí ìtọ́jú gbà bí kì í bá ṣe ti ìjọba tó kùnà àti àìsí owó àkànlò.
Ṣé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìtẹ̀síwájú pípabanbarì tó ti bá lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ìṣègùn wá lè fòpin sáwọn ìdíwọ́ yìí bí? Ṣé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a ó máa gbé nínú ayé kan tí ò ti ní sí àìsàn mọ́? Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ tá a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ò fún wa ní ìdáhùn tó ṣe kedere sí ìbéèrè yìí. Àmọ́, Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú nígbà tí kò ní sí àìsàn mọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Nánò” tó bẹ̀rẹ̀ nànómità, wá látinú èdè Gíríìkì tó túmọ̀ sí aràrá, ó sì túmọ̀ sí “ìdá kan nínú bílíọ̀nù.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Fífi fọ́tò yàwòrán inú ara
Àwọn àwòrán tó túbọ̀ ṣe kedere, tó sì fi bí inú ara ṣe rí hàn ketekete lè mú kó ṣeé ṣe láti ṣàwárí àìsàn kó tó di pé ó fẹjú
[Àwọn Credit Line]
© Philips
Siemens AG
Fífi ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì ṣiṣẹ́ abẹ
Àwọn róbọ́ọ̀tì tí wọ́n de onírúurú ohun èlò iṣẹ́ abẹ mọ́ lára máa ń ran àwọn dókítà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ tó díjú débi gẹ́ẹ́, tó sì jẹ́ pé ibi tí ìṣòro wà ní tààràtà ni wọ́n á lọ, láìyà sọ́tùn-ún sósì
[Credit Line]
© 2006 Intuitive Surgical, Inc.
Ẹ̀kọ́ nípa apilẹ̀ àbùdá
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nírètí pé nípa fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa apilẹ̀ àbùdá ẹnì kọ̀ọ̀kan, á ṣeé ṣe fáwọn láti wá ohun tó lè fa àìsàn rí káwọn sì tọ́jú ẹ̀ kó tiẹ̀ tó di pé àmì èyíkéyìí fi hàn pé àìsàn náà wà lára
[Àwọn Credit Line]
Ayàwòrán: Vik Olliver (vik@diamondage.co.nz)/ Ẹni tó ṣe é: Robert Freitas
Iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n ń fàwọn ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ ṣe
Àwọn ẹ̀rọ tíntìntín táwọn èèyàn ṣe lè mú kó ṣeé ṣe fáwọn dókítà láti tọ́jú àìsàn kó tiẹ̀ tó yọjú. Fọ́tò tí ayàwòrán kan yà rèé láti fi ṣàpèjúwe bí ẹ̀rọ tó kéré ju orí abẹ́rẹ́ lọ táá máa ṣiṣẹ́ bíi sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ á ṣe rí
[Credit Line]
Àwọn èròjà apilẹ̀ àbùdá: © Phanie/Photo Researchers, Inc.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ọ̀tá Mẹ́fà Tápá Ò Ká
Ìmọ̀ ìṣègùn àtàwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ míì tó tan mọ́ ọn ń tẹ̀ síwájú àti síwájú lọ́nà tí a kò rí irú rẹ̀ rí. Síbẹ̀, ìyọnu tí àrùn tó ń tàn kálẹ̀ ń fà ṣì ń fogun ja aráyé. Apá ò tíì ká àwọn àrùn tó ń ṣekú pani tá a tò sísàlẹ̀ yìí títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.
ÀRÙN ÉÈDÌ ÀTI KÒKÒRÒ TÓ Ń FÀ Á
Ó ti tó ọgọ́ta mílíọ̀nù èèyàn báyìí tó ti ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì, nǹkan bí ogún mílíọ̀nù ni àrùn éèdì sì ti pa. Lọ́dún 2005, èèyàn mílíọ̀nù márùn-ún míì ni kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì yìí ràn, ó sì lé ní mílíọ̀nù mẹ́tà èèyàn tí ikú tó pa wọ́n ò ṣẹ̀yìn àrùn éèdì. Àwọn ọmọdé tí àrùn yìí gbẹ̀mí wọn ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] lọ. Èyí tó sì pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì ni ò sí níbi tí wọ́n ti lè rí ìtọ́jú tó dáa gbà.
Ìgbẹ́ gbuuru
Látàrí nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn ti ìgbẹ́ gbuuru ń pa lọ́dọọdún, wọ́n sọ pé ó wà lára àrùn tó máa ń pa àwọn òtòṣì jù lọ. Ọkàn-ò-jọ̀kan àrùn tó ń tàn kálẹ̀ ló máa ń fà á. Ohun tó sì lè tan irú àwọn àrùn bẹ́ẹ̀ kálẹ̀ ni omi tó dọ̀tí tàbí oúnjẹ eléèérí tàbí ìwà ọ̀bùn. Ríràn tó ń ràn káàkiri yìí máa ń fa ikú àwọn èèyàn tó ju mílíọ̀nù méjì lọ lọ́dọọdún.
Ibà
Lọ́dọọdún, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] mílíọ̀nù èèyàn ló máa ń lárùn ibà. Àwọn alárùn ibà bíi mílíọ̀nù kan ni wọ́n máa ń kú lọ́dọọdún, ọmọdé ló sì pọ̀ jù lára wọn. Ní Áfíríkà, ibà máa ń pa ọmọ kékeré méjì láàárín ìṣẹ́jú kan. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, “kò tíì sí oògùn ajẹ́bíidán kankan táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè júwe pé káwọn èèyàn máa lò sí ibà, àwọn kan ò sì lérò pé irú oògùn èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ lè wà.”
Yìkíyìkí
Lọ́dún 2003, àwọn èèyàn tí yìkíyìkí pa lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000]. Àrùn tó máa ń yára tàn kálẹ̀ ni àrùn yìí, ó sì wà lára àrùn tó ń pa àwọn ọmọdé jù lọ. Lọ́dọọdún, nǹkan bí ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn ni àrùn yìí máa ń mú. Ibi ọ̀rọ̀ náà sì wá ṣeni ní kàyéfì sí ni pé abẹ́rẹ́ àjẹsára ti wà fún un láti ogójì ọdún sẹ́yìn, abẹ́rẹ́ àjẹsára náà kì í bà á tì, kò sì gbówó lórí.
Otútù àyà
Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé àwọn ọmọdé tí otútù àyà ń pa pọ̀ ju àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn èyíkéyìí mìíràn ń pa lọ. Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì lára àwọn tí ò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún ni otútù àyà ń pa lọ́dọọdún. Ilẹ̀ Áfíríkà àti Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà lèyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó kú yìí wà. Lápá ibi tó pọ̀ jù lọ láyé, àìsí ìtọ́jú tó tó ni kì í jẹ́ káwọn tó bá ní otútù àyà rí ìtọ́jú ìṣègùn tó lè dóòlà ẹ̀mí wọn gbà.
Ikọ́ fée
Lọ́dún 2003, ikọ́ fée pa èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ márùndínláàádọ́rùn-ún [1,700,000]. Èyí tó tiẹ̀ wá jẹ́ kàyéfì jù lọ fáwọn òṣìṣẹ́ ìlera ni tàwọn kòkòrò tó ń fa ikọ́ fée tí oògùn ò ràn mọ́. Irú àwọn kòkòrò yìí kan ti wà báyìí tó jẹ́ pé gbogbo oògùn pàtàkì pàtàkì tí wọ́n sábà máa ń lò sí ikọ́ fée ò ràn wọ́n mọ́ báyìí. Àwọn oníkọ́ fée tí wọn ò bá rí ìtọ́jú tó dáa gbà tàbí tí wọn ò rí ìtọ́jú gbà dé ìwọ̀n tó yẹ ni wọ́n sábà máa ń ní kòkòrò ikọ́ fée tí kò gbóògùn yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìtọ́jú Àìsàn Lónírúurú Ọ̀nà Ń Pọ̀ Sí I
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀nà ló wà táwọn èèyàn ń gbà tọ́jú àìsàn táwọn oníṣègùn òyìnbó ò fara mọ́. Irú àwọn ìtọ́jú yìí lọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ìṣègùn ìbílẹ̀ tàbí gbígba ìtọ́jú àfirọ́pò. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà egbòogi ìbílẹ̀ lọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ibẹ̀ gbára lé fún ìtọ́jú ìlera. Níbi táwọn òtòṣì pọ̀ sí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ṣeé ṣe fún láti gbàtọ́jú ìṣègùn òyìnbó, àwọn èèyàn míì sì wà tó jẹ́ pé lílo egbòogi ìbílẹ̀ làwọn fẹ́ ní tiwọn.
Àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò tún ti ń gbilẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀. Àwọn tó wọ́pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò yìí ni acupuncture, ìyẹn fífi àwọn abẹ́rẹ́ tín-tìn-tín gún àwọn ibi pàtó kan nínú ara, fífọwọ́ wọ́ àwọn ibì kan nínú ara, fífi egbòogi tó máa dá àìsàn sára ẹni tó léra wo aláìlera, fífi àwọn nǹkan bí afẹ́fẹ́ àti omi wo àrùn àti lílo tewé tegbò. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti wádìí àwọn kan lára irú ìtọ́jú yìí, wọ́n sì rí i pé wọ́n dára fún irú àwọn àìsàn kan. Àmọ́, kò tíì ṣeé ṣe láti fọwọ́ sọ̀yà nípa bí irú àwọn ìtọ́jú pàtó kan ṣe dáa tó. Báyé ṣe ń gba ti ìtọ́jú àfirọ́pò ti mú kó di ohun tó ń kọni lóminú nítorí pé ó léwu. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọn ò ní ìlànà kan gúnmọ́ fún lílo irú oògùn bẹ́ẹ̀. Èyí wá mú kí àṣà lílo oògùn láìdé ọ̀dọ̀ dókítà, lílo ayédèrú egbòogi àti fífi dúdú pe funfun fáwọn èèyàn máa pọ̀ sí i. Tẹbí tọ̀rẹ́ á wá dẹni ń júwe oògùn láìjẹ́ pé wọ́n gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi ṣìkà. Gbogbo èyí ti wá ń mú kí oògùn máa gbòdì lára aláìsàn, ó sì ti fa àwọn ewu mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìlera.
Láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tí òfin ti wà lórí lílo oògùn, àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò ti ríbi wọlé sáàárín àwọn oníṣègùn òyìnbó, àmọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó yìí ló ń lò wọ́n láti fi ṣètọ́jú. Síbẹ̀, kò dà bí ẹni pé ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà pé irú ìtọ́jú wọ̀nyí á sọ ayé di ibi tí kò ti ní sí àìsàn mọ́.