Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tó FI Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
KÁ SỌ pé ìwọ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì kan jọ wà ní ibi tẹ́ ẹ ti ń jẹun níléèwé yín. Ọ̀kan nínú wọn wá tẹjú mọ́ ọmọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé.
Èyí àkọ́kọ́ sọ fún ẹ pé: “Ṣó o mọ̀ pé bọ̀bọ́ yẹn gba tìẹ gan-an. Bó ṣe wò ẹ́ ni mo ti mọ̀. Ńṣe ló ń fojú bá ẹ sọ̀rọ̀.”
Èkejì ẹ̀ wá sọ sí ẹ létí pé: “Wò ó, jẹ́ n sọ fún ẹ, bọ̀bọ́ yẹn ò tíì lẹ́ni tó ń fẹ́.”
Èyí àkọ́kọ́ tún sọ pé: “Ó mà dùn mí pé mo ti ní bọ̀bọ́ tèmi o, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò lè gbà mí níṣẹ̀ẹ́jú kan kí n tó wọlé sí i lára!”
Ọmọbìnrin àkọ́kọ́ yẹn wá bi ẹ́ ní ìbéèrè tó máa ń múnú bí ẹ.
“Kí ló dé tíwọ ò tiẹ̀ fi ní bọ̀bọ́ kankan?”
O ti mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ ń lọ náà nìyẹn. Ká sòótọ́, ó wù ẹ́ kí ìwọ náà ní ọmọkùnrin kan tí wàá máa fẹ́. Àmọ́, wọ́n ti kọ́ ẹ pé ṣe ló yẹ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣe tán láti ṣègbéyàwó kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ọkùnrin. Ká ní ò síyẹn ni . . .
Ọmọbìnrin kejì wá béèrè pè, “Ẹ kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìjọ yín, àbí?”
O wá rò ó lọ́kàn ara ẹ pé, ‘Àbó mọ nǹkan tó wà lọ́kàn mi ni?’
Ọmọbìnrin àkọ́kọ́ yẹn wá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ó sọ pé, “Ìwọ ò tiẹ̀ mọ̀ ju Bíbélì lọ láyé ẹ. Ṣé ìwọ ò tiẹ̀ lè máa jayé orí ẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni?”
Ṣé wọ́n ti fi ìwọ náà ṣe yẹ̀yẹ́ rí nítorí pé ò ń fẹ́ máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù? Kí lo wá ṣe?
◼ O fọkàn balẹ̀ ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́.
◼ Ojú tì ẹ́, àmọ́ o ṣì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ débi tó yé ẹ mọ.
◼ O rò pé, òótọ́ lọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé ẹ yìí, ó yẹ kíwọ náà máa jayé díẹ̀díẹ̀!
Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé, ‘Àǹfààní wo ló tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù?’ Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah pàápàá ti rò bẹ́ẹ̀ rí.a Ó sọ pé: “Ohun tó bá wu àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ni wọ́n máa ń ṣe. Ńṣe ló dà bíi pé kò sí ẹni tó máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Ṣe ló dà bíi pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń káni lọ́wọ́ kò. Ó ń ṣe mí bíi kémi náà máa ṣe ohun tó wù mí bíi tàwọn ọ̀rẹ́ mi ní ilé ìwé.”
Ṣó Burú Láti Ṣiyè Méjì Nípa Àwọn Ìlànà Bíbélì?
Nígbà kan, Ásáfù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì ń ṣiyè méjì bóyá àǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú ṣíṣe ohun tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ó kọ̀wé pé: “Èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” Kódà ó sọ pé: “Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.”—Sáàmù 73:3, 13.
Ó ṣe kedere báyìí pé, Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwa èèyàn ṣiyè méjì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lórí bóyá àǹfààní wà nínú fífi àwọn ìlànà rẹ̀ ṣèwà hù. Ó ṣe tán, ó rí sí i pé wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ásáfù sọ yẹn sínú Bíbélì. Nígbà tó yá, Ásáfù wá rí i pé ṣíṣe àwọn ohun tó wà nínú òfin Ọlọ́run ló dáa jù fóun. (Sáàmù 73:28) Kí ló mú kó rò báyẹn? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, Ásáfù gbọ́n. Kò dúró dìgbà tójú ẹ̀ rí màbo kó tó ṣohun tó tọ́, ṣe ló kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe àwọn ẹlòmíì. (Sáàmù 73:16-19) Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ṣàyẹ̀wò Ara Ẹ!
Dáfídì Ọba ò ṣe bíi ti Ásáfù, ó jìyà kó tó wá yé e pé ojú ẹni tí kò bá ṣe ohun tí Ọlọ́run wí máa ń rí màbo. Dáfídì bá ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣèṣekúṣe, ó sì tún gbìyànjú láti bo àṣìṣe rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ìyẹn mú kó ba àwọn ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́, ọkàn òun pàápàá ò sì balẹ̀, kódà ọ̀rọ̀ náà dun Ọlọ́run. (2 Sámúẹ́lì 11:1-12:23) Lẹ́yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà, Jèhófà mí sí i láti kọrin lórí bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ̀, àkọsílẹ̀ orin yìí sì wà nínú Bíbélì fún àǹfààní wa. (Sáàmù 51:1-19; Róòmù 15:4) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì tún bá Ìwé Mímọ́ mu pé ká máa fọ̀rọ̀ ẹlòmíì kọ́gbọ́n.
A fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra. Àwọn ọ̀dọ́ yìí ti fìgbà kan rí kọ àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ wọn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bíi ti Ásáfù, kó o má bàa ṣe irú àṣìṣe tí Dáfídì ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé, wọ́n ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó. Àmọ́, wọ́n ti ronú pìwà dà gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ṣe, àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sì ti dán mọ́rán sí i. (Aísáyà 1:18; 55:7) Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.
Jí!: Àwọn nǹkan wo ló máa ń mú kó o ronú bó o ṣe ń ronú tó sì ń mú kó o hu irú ìwà tó ò ń hù?
Deborah: “Mo máa ń rí i pé gbogbo àwọn ọmọ ilé ìwé wa ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́, ó sì dà bíi pé, ìyẹn ń múnú wọn dùn. Tí n bá wà láàárín wọn, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe ń so mọ́ra wọn tí wọ́n sì ń fẹnu kora wọn lẹ́nu, ńṣe ló máa ń dà bíi pé èmi nìkan ni ò dákan mọ̀. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ronú nípa ọmọkùnrin kan tí mo fẹ́ràn. Ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí láti wà lọ́dọ̀ ẹ̀, mo sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tẹ́ra mi lọ́rùn.”
Mike: “Mo máa ń kàwé tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, mo sì máa ń wo àwọn eré orí tẹlifísọ̀n tó máa ń jẹ́ kó wu èèyàn. Sísọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ mi túbọ̀ máa ń jẹ́ kó wù mí láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Témi àtọmọge bá dá wà, mo máa ń rò pé mo kàn lè fara rò ó lára láìbá a sùn, àti pé mo mọbi tó ti yẹ kí n dúró.”
Andrew: “Mo máa ń wo àwòrán oníhòòhò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí lámujù. Mo sì máa ń lọ sóde àríyá pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà.”
Tracy: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, gbogbo ohun tí mo fẹ́ ò ju pé kí n ṣáà ti wà lọ́dọ̀ olólùfẹ́ mi. Mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé kò yẹ kí n ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, àmọ́ mi ò kórìíra ẹ̀. Kò wù mí pé kí n ṣe é, àmọ́ bọ́ràn náà ṣe rí lára mi ò jẹ́ kí n lè ronú jinlẹ̀. Ó wá di pé ẹ̀rí ọkàn mi ò dá mi lẹ́bi mọ́.”
Jí!: Ṣé inú rẹ dùn sóhun tó o ṣe yẹn?
Deborah: “Inú mi kọ́kọ́ dùn pé mo lómìnira láti ṣe ohun tó wù mí, àti pé èmi náà ti wá bẹ́gbẹ́ mu wàyí. Àmọ́ ayọ̀ yẹn ò tọ́jọ́. Ara mi ò mọ́ mọ́, mi ò wá lè fọwọ́ sọ̀yà pé mi ò tíì níbàálòpọ̀ rí, mo wá rí i pé mo ti bayé ara mi jẹ́. Mo wá kábàámọ̀ pé mo ti jẹ́ kẹ́nì kan já ìbálé mi, ìyẹn sì ti lọ nìyẹn. Látìgbà yẹn, mo sábà máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé mo tiẹ̀ rò pé mo gbọ́n lójú ara mi ni?’ Àti pé, ‘Kí ló bá mi débi tí mi ò fi ka àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí pàápàá?’”
Mike: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé nǹkan kan ti bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Mo gbìyànjú láti gbójú fo ẹ̀dùn ọkàn tí mò ń kó bá àwọn ẹlòmíì, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Ó máa ń ká mi lára pé mò ń ba àwọn ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́ bí mo ṣe ń gbádùn ara mi. Mi ò lè sùn dáadáa. Nígbà tó yá, mi ò gbádùn ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe yẹn mọ́, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í tì mí, ọkàn mi sì ń bà jẹ́.”
Andrew: “Ńṣe ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti máa hùwà àìtọ́. Síbẹ̀, mò ń dára mi lẹ́bi, ohun tí mò ń ṣe sì ń bà mí lọ́kàn jẹ́.”
Tracy: “Kò pẹ́ rárá tójú mi fi dá wáí. Mo ti fi ìṣekúṣe bayé ara mi jẹ́. Ńṣe ni mo rò pé èmi àti bọ̀bọ́ tí mò ń fẹ́ yẹn máa gbádùn ara wa dọ́ba, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ìrora ọkàn, wàhálà àti ìbànújẹ́ la kàn kó ara wa sí. Òròòru ni mo máa ń wa ẹkún mu lórí bẹ́ẹ̀dì mi, mo máa ń kábàámọ̀ pé, ǹ bá sì ti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ o.”
Jí!: Ìmọ̀ràn wo lo ní fáwọn ọ̀dọ́ tó bá ń ṣiyè méjì nípa bóyá àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà ń káni lọ́wọ́ kò?
Deborah: “Kì í ṣe pé nńkan á dùn fún ẹ sí i tó o bá kọ àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára Jèhófà tó o bá fetí sí ìmọ̀ràn rẹ̀. Kó o sì tún ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí ibi tó máa yọrí sí fún ẹ tó o bá kọ ìmọ̀ràn rẹ̀ sílẹ̀. Má gbàgbé pé ìwọ nìkan kọ́ lọ̀rọ̀ náà kàn o. Ohun tó o bá ṣe kan àwọn ẹlòmíì pẹ̀lú. Tó o bá sì kọ̀ láti fetí símọ̀ràn Ọlọ́run, ìwọ lo máa jìyà tó pọ̀ jù.”
Mike: “Lóòótọ́, àwọn nǹkan táwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣe lè dà bí ìgbádùn o. Àmọ́, kó o tó hùwà, máa ronú ohun tó máa tẹ̀yìn rẹ̀ wá. Jèhófà dá ọ̀wọ̀ ara ẹni mọ́ wa, kò sì fẹ́ ká máa ṣèṣekúṣe. Ẹ̀bùn pàtàkì ló sì ka àwọn nǹkan wọ̀nyí sí. Ńṣe lo máa tara ẹ lọ́pọ̀, tó o bá sọ àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí nù torí pé o ò kóra ẹ níjàánu. Fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí rẹ àtàwọn àgbàlagbà míì. Tó o bá ti ṣàṣìṣe, má bò ó mọ́ra, tètè sọ fún wọn, kó o sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Tó o bá ń ṣe àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn tòótọ́.”
Andrew: “Tó ò bá tíì gbọ́n, ṣe lo máa rò pé àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń jayé orí wọn ni. Nìwọ náà á bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tiwọn. Nítorí náà, lo ọgbọ́n tó o bá fẹ́ yan àwọn tó o fẹ́ fi ṣọ̀rẹ́. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o má bàa kábàámọ̀.”
Tracy: “Má ṣe rò láé pé ‘Kò lè ṣelẹ̀ sí mi.’ Màmá mi pè mí jókòó, ó sì sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n fún mi pé, àwọn nǹkan tí mò ń ṣe yẹn máa kó bá mi. Mo gbaná jẹ! Ńṣe ni mo rò pé mo gbọ́n lójú ara mi. Àṣé mi ò mọ nǹkan kan! Má fàwọn ìlànà Jèhófà ṣeré, àwọn tó ń tẹ̀ lé e ni kó o sì máa bá rìn. Ìyẹn ló lè fún ẹ láyọ̀.”
Ṣé Ìlànà Bíbélì Ń Káni Lọ́wọ́ Kò Ni àbí Ó Ń Dáàbò Boni?
Táwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ò ń gbìyànjú láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí wọn kì í fi í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà? Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ ti ka Bíbélì fúnra wọn láti ráwọn àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́? Ṣé wọ́n ti ronú jinlẹ̀ lórí ibi tó máa yọrí sí fún wọn, bí wọ́n bá kọ ìlànà Ọlọ́run sílẹ̀? Àbí ńṣe ni wọ́n kàn ń yí síbi táyé ń yí sí?’
Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tí wọ́n “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀” nígbà kan rí. (Ẹ́kísódù 23:2) Ó dájú pé ìwọ ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n wo lo máa dá sí i? Àfi kó o fetí símọ̀ràn Bíbélì pé kó o “ṣàwárí fúnra [rẹ] ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kíwọ náà láyọ̀. (1 Tímótì 1:11; Oníwàásù 11:9) Àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì máa ṣe ẹ́ láǹfààní. O lè máa ronú pé àwọn ìlànà wọ̀nyí ń ká ẹ lọ́wọ́ kò o. Àmọ́, ká sòótọ́, àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà wulẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ ni.
Ó dájú pé o lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì. Tó o bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, wàá múnú Jèhófà dùn, wàá sì ṣe ara rẹ láǹfààní.—Aísáyà 48:17.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí lo rò pé ó máa jẹ́ kó ṣòro fún ẹ láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù?
◼ Kí nìdí tó fi yẹ kó o mú un dá ara ẹ lójú pé fífi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù ló dáa jù lọ?