Ohun 3—Má Ṣe Máa Jókòó Gẹlẹtẹ Sójú Kan
“Bó bá jẹ́ pé oògùn ni eré ìmárale, òun láwọn dókítà ì bá máa júwe fáwọn èèyàn jù lọ.” (Emory University School of Medicine) Ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn lè ṣe láti mú kí ìlera rẹ̀ sunwọ̀n sí i, àmọ́ díẹ̀ lára wọn ló ṣàǹfààní ju ṣíṣe eré ìmárale lọ.
◯ Máa ṣe eré ìmárale. Téèyàn kì í bá jókòó gẹlẹtẹ sójú kan, ó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀, kí ìrònú èèyàn já geere, kí ara èèyàn le dáadáa, kí èèyàn sì gbé nǹkan gidi ṣe. Téèyàn bá tún wá ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, kò ní jẹ́ kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Kò dìgbà tí eré ìmárale bá roni lára tàbí tó kọjá ààlà kó tó lè ṣèèyàn láǹfààní. Téèyàn bá ń ṣe eré ìmárale déédéé ní ìgbà mélòó kan lọ́sẹ̀, ó máa ṣeni láǹfààní.
Sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, rírìn kánmọ́kánmọ́, gígun kẹ̀kẹ́ àti ṣíṣe àwọn eré ìmárale míì tó máa gba pé kéèyàn lo ara rẹ̀ dáadáa máa ń jẹ́ kí ọkàn èèyàn túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, táá sì tún jẹ́ kéèyàn làágùn, èyí máa ń jẹ́ kára èèyàn túbọ̀ le, ó sì tún máa ń dènà àrùn ọkàn àti rọpárọsẹ̀. Téèyàn bá ń ṣe irú eré ìmárale tó ń jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú gbígbé ohun tó bá wúwo níwọ̀nba àti eré ìmárale tí kò le púpọ̀, ó máa ń jẹ́ kí eegun, iṣan ara àti àwọn ẹ̀yà ará míì lágbára. Àwọn nǹkan yìí máa ń mú kéèyàn lè máa ta kébékébé, èyí kò sì ní jẹ́ kéèyàn sanra jù.
◯ Máa fi ẹsẹ̀ rìn. Gbogbo èèyàn ni eré ìmárale ṣàǹfààní fún yálà ọmọdé tàbí àgbàlagbà, kò sì pọn dandan pé kéèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ ní ibi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìmárale. O lè máa fi ẹsẹ̀ rìn dípò tí wàá fi wọ mọ́tò tàbí tí wàá fi lo ẹ̀rọ agbéniròkè. Kò sídìí tí wàá fi máa dúró de ẹni tó máa gbé ẹ nígbà tó jẹ́ pé o lè fẹsẹ̀ rìn débi tó ò ń lọ, kódà ìyẹn lè jẹ́ kó o tètè débẹ̀. Ẹ̀yin òbí, ẹ máa fún àwọn ọmọ yín ní ìṣírí láti máa ṣeré ìdárayá tó máa jẹ́ kí wọ́n lo okun wọn. Irú àwọn eré ìdárayá bẹ́ẹ̀ máa fún ara wọn lókun, ó sì máa jẹ́ kí wọ́n lè lo gbogbo ara wọn dáadáa, èyí tó jẹ́ pé wọn ò ní lè ṣe tó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n jókòó tẹtẹrẹ tí wọ́n ń gbá géèmù fídíò.
Láìka bó o ṣe dàgbà tó kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìmárale, wàá jàǹfààní tó o bá ń ṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n. Tó o bá ti dàgbà tàbí tó o ní àìlera kan, tí o kò sì ń ṣe eré ìmárale tẹ́lẹ̀, ó máa dáa kó o béèrè lọ́wọ́ dókítà nípa bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, o ní láti bẹ̀rẹ̀! Eré ìmárale téèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe díẹ̀díẹ̀ tí kò sì ré kọjá ààlà lè ran àwọn àgbàlagbà pàápàá lọ́wọ́ láti mú kí iṣan ara wọn àti eegun wọn le. Kò sì tún ní jẹ́ kí àwọn àgbàlagbà máa ṣubú.
Eré ìmárale ló ṣèrànwọ́ fún Rustam tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ nínú ọwọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Lọ́dún méje sẹ́yìn, òun àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ ní ìdájí ní ìgbà márùn-ún lọ́sẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀ a máa ń ṣàwáwí ká má bàa lọ, àmọ́ bá a ṣe pé méjì ń fún wa ní ìṣírí gan-an. Ní báyìí a ti wá ń gbádùn ẹ̀ gan-an, ó sì ti mọ́ wa lára.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣíṣe eré ìmárale máa ń gbádùn mọ́ni