Ori 9
Majẹmu Ọlọrun Pẹlu “Ọ̀rẹ́” Rẹ̀ Ti Ṣanfaani fun Araadọta Ọkẹ Nisinsinyi
1, 2. (a) Ibaṣepọ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ wo ni ó ti bẹrẹsii ṣaṣeyọri si anfaani araadọta ọkẹ eniyan? (b) Eeṣe ti ó fi ṣeeṣe fun Abrahamu lati di ọ̀rẹ́ Ọlọrun?
NÍ EYI ti ó ju 1,950 ọdun sẹhin ọ̀rẹ́ tootọ fun gbogbo araye kan sọ pe: “Kò si ẹnikan ti ó ní ifẹ ti ó tobi ju eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmi rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Johannu 15:13) Asọrọ naa, Jesu, jẹ́ atọmọdọmọ ọkunrin kan ti a pe ní ọ̀rẹ́ Ẹni titayọ julọ ní gbogbo agbaye, Jehofa Ọlọrun. Ibaṣepọ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ yii, bi o ti wu ki o dabi eyi ti ó pọ̀n sẹgbẹkan tó, ti bẹrẹsii ṣaṣeyọri si anfaani araadọta ọkẹ bayii.
2 Ta ni ọkunrin igbaani yẹn ti ó jere ohun pupọ fun wa nitori ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹlu Ọlọrun? Abrahamu ni, atọmọdọmọ ọkunrin naa Ṣemu, ti ó jẹ́ ọkan ninu awọn olula Ikun-omi kárí-ayé ọjọ Noa já. Abrahamu kówọnú ibatan kan pẹlu Ọlọrun, ní fifi awọn animọ ọ̀rẹ́ tootọ kan hàn. Nipasẹ isunniṣe ifẹ ati igbagbọ, Abrahamu gbe igbesẹ ní ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun, ati nitori idi eyi onkọwe Bibeli naa Jakọbu wi pe: “Iwe mímọ́ si ṣẹ ti ó wi pe, Abrahamu gba Ọlọrun gbọ, a sì kà á si ododo fun un: a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun.”—Jakọbu 2:23.
3, 4. (a) Ki ni ó ṣakawe idiwọn giga ti Jehofa gbekari igbagbọ ati igbẹkẹle ti Abrahamu ní ninu rẹ̀? (b) Pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wo ni Jehofa fi mu itolẹsẹẹsẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Isaiah 41:8 wá sí otente giga nla?
3 Ọkunrin onigbagbọ ati agbegbeesẹ yẹn wá lati ilu Uri ti awọn ará Kaldea, oun si ni ẹni ti a kọkọ pè ní Heberu. (Genesisi 14:13) Idanimọ yii ni a wá lò fun awọn atọmọdọmọ rẹ̀ ti orilẹ-ede Israeli. (Filippi 3:5) Ní oju iwoye sisọ Abrahamu di ọ̀rẹ́ rẹ̀, Jehofa Ọlọrun tun mú un wọ inu diẹ ninu awọn ọran aṣiri Rẹ̀. Eyi ni ohun ti a kọ sinu Genesisi 18:17-19 sì fihan.
4 Eyi ṣakawe idiwọn giga ti Jehofa Ọlọrun gbe karí igbagbọ ati igbẹkẹle ti Abrahamu ní ninu rẹ̀, ti eyi si yọrisi igbọran aibojuwẹhin ní iha ọdọ Abrahamu. Nitori naa laisi ikotijubani tabi itọrọ aforiji, Jehofa mu ọ̀rọ̀ rẹ̀ si orilẹ-ede Israeli dé otente nipa sisọ pe: “Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakọbu ẹni tí mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ mi.”—Isaiah 41:8.
Majẹmu Abrahamu Bẹrẹsii Ṣiṣẹ
5, 6. (a) Majẹmu wo ni Jehofa dá pẹlu ọ̀rẹ́ rẹ̀ Abrahamu? (b) Loju ipo ti ó yatọ patapata wo ni Ọlọrun ṣe ileri kan fun ọ̀rẹ́ rẹ̀ niti “iru-ọmọ” kan?
5 Ibi ti ẹ̀jẹ́ ẹni pẹlu ọ̀rẹ́ onifẹẹ kan lè sinni dé ni a ṣe apẹẹrẹ rẹ̀ pẹlu otitọ naa pe Jehofa, Ọba-Alaṣẹ agbaye, dá majẹmu kan pẹlu eniyan lasan yii, Abrahamu. Ninu Genesisi 15:18 a ka pe: “Ní ọjọ naa gan-an ni OLUWA bá Abramu [Abrahamu] dá majẹmu pe, iru-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yii fun, lati odò Egipti wá, titi o fi dé odò nla nì, odò Euferate.”
6 Euferate ni odò ti Abrahamu ati idile rẹ̀ là kọja lati bọ́ sinu Ilẹ Ileri naa. Nigba ti ó ń la odò naa kọja, Abrahamu wà lailọmọ, bi o tilẹ jẹ pe o ti di ẹni ọdun 75 nigba naa, ti aya rẹ̀ si ti kọja igba ọmọ bibi. (Genesisi 12:1-5) Sibẹ, loju ipo ti ó yatọ patapata bẹẹ, Ọlọrun wi fun Abrahamu onigbọran pe: “Gbojuwo oke ọ̀run nisinsinyi, ki o si ka irawọ bi iwọ ba lè ka wọn: . . . Bẹẹ ni iru-ọmọ rẹ yoo ri.”—Genesisi 15:2-5.
7. (a) Ki ni a ń pe majẹmu yii? (b) Ní ọdun wo ni ó bẹrẹsii ṣiṣẹ ati pẹlu iṣẹlẹ wo ninu igbesi-aye Abrahamu? (c) O tó ọdun mélòó ki a tó wá dá majẹmu Ofin pẹlu orilẹ-ede Israeli?
7 Majẹmu naa ti Jehofa dá pẹlu “ọ̀rẹ́” rẹ̀ ni a pè ní majẹmu Abrahamu. Majẹmu naa bẹrẹsii ṣiṣẹ ní 1943 B.C.E. nigba ti Abrahamu ṣegbọran si awọn ohun ti majẹmu Ọlọrun beere fun ti ó re odò Euferate kọja nigba ti ó ń lọ si Ilẹ Ileri naa. Ní ọdun yẹn Jehofa Ọlọrun wá sabẹ iṣẹ aigbọdọmaṣe lati bukun Abrahamu alailọmọ pẹlu “iru-ọmọ.” Ofin ti ó jẹ́ ti majẹmu naa ti a ṣe pẹlu orilẹ-ede Israeli ní Oke Sinai wá di eyi ti ó wà ní 430 ọdun lẹhin naa, ní 1513 B.C.E.—Genesisi 12:1-7; Eksodu 24:3-8.
A Fi Majẹmu Ofin Kun Majẹmu Abrahamu
8. (a) Ki ni ète majẹmu Ofin naa? (b) Majẹmu Ofin naa ha sọ majẹmu Abrahamu di alaiṣiṣẹ mọ́ bi?
8 Ní igba naa, awọn atọmọdọmọ Abrahamu nipasẹ ọmọkunrin rẹ̀ Isaaki ti di awọn eniyan olominira. A ti gba orilẹ-ede Israeli kuro lọwọ Egipti a sì ti ṣamọna wọn lọ si Oke Sinai ní Arabia. Nibẹ nipasẹ Mose bi alarina, ni a ti mu wọn wọnu majẹmu Ofin naa pẹlu Jehofa Ọlọrun. Niwọn bi awọn ọmọ Israeli wọnni ti jẹ́ atọmọdọmọ abinibi tẹlẹtẹlẹ fun Abrahamu, “ọ̀rẹ́” Jehofa, ki ni niti gidi ni ète iru majẹmu Ofin bẹẹ? Yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bi aabo fun awọn eniyan ayanfẹ ti Jehofa. Majẹmu Ofin naa kò pa majẹmu Abrahamu rẹ́, bi o tilẹ jẹ pe ó fi orilẹ-ede Israeli hàn bi ẹni ti ó jẹbi awọn irelanakọja ní oju iwoye ofin pipe ti Ọlọrun.—Galatia 3:19-23.
9, 10. (a) Ki ni ó jẹ́ imọlara awọn atọmọdọmọ Abrahamu ní gbogbogboo nipa “iru-ọmọ” naa nipasẹ eyi ti gbogbo orilẹ-ede yoo gbà bukun araawọn? (b) Ironu wọn ha ti jẹ́ eyi ti ó yekooro bi?
9 Ní sisọrọ lọna apẹẹrẹ, awọn ọmọ Israeli di “awọn ọmọkunrin” majẹmu Ofin yẹn. Wọn nimọlara pe nititori pe wọn ti jẹ́ atọmọdọmọ abinibi Abrahamu, ní taarata wọn ti di “iru-ọmọ” naa nipasẹ eyi ti gbogbo orilẹ-ede yoo bukun araawọn. Iyẹn ha ni bi ọran naa ti ri bi? Rara! Lonii, ní nǹkan bii 3,500 ọdun lẹhin naa, a ri Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli olominira ati alaijẹ ti isin, ṣugbọn ṣe ni o ń jà fun iwalaaye rẹ̀ laaarin ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede agboguntini.
10 Nitori naa pe ẹnikan di alawọṣe Ju lonii pẹlu ero didi apakan “iru-ọmọ” Abrahamu fun bibukun iyoku araye kii ṣe ọna Jehofa Ọlọrun. Ki ni, nigba naa, ni ó ti ṣẹlẹ?
11. Bawo ni aposteli Paulu ṣe ṣalaye ohun ti ó ṣẹlẹ si awọn atọmọdọmọ Abrahamu abinibi?
11 Aposteli Paulu ṣalaye ọ̀rọ̀ naa fun wa, ní wiwi pe: “A ti kọ ọ pe, Abrahamu ní ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹrubinrin [Hagari], ati ọkan lati ọdọ ominira obinrin [Sara]. Ṣugbọn a bi eyi tii ṣe ẹrubinrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti ominira obinrin ni a bí nipasẹ ileri. Nǹkan wọnyi jẹ́ apẹẹrẹ: nitori pe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeeji; ọkan lati ori oke Sinai wa, ti a bi ní oko ẹru, tii ṣe Hagari. Nitori Hagari yii ni oke Sinai Arabia, ti ó si duro fun Jerusalemu ti ó wà nisinsinyi, ti ó si wà ní oko ẹru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ́ ominira, eyi tii ṣe ìyá wa.”—Galatia 4:22-26.
12. Ta ni ẹrubinrin naa Hagari bá ṣe rẹ́gí?
12 Jerusalemu eyi ti ẹrubinrin naa Hagari ṣe rẹ́gí pẹlu rẹ̀ jẹ́ ti ilẹ̀-ayé, nitori pe awọn Ju nipa ti ara ní ń gbe ibẹ̀. Ní awọn ọjọ Jesu Kristi, oun ni olu-ilu orilẹ-ede Israeli, ó sì wà labẹ majẹmu Ofin. (Matteu 23:37, 38) Nigba ti majẹmu Ofin ti Mose ṣe alarina rẹ̀ wa lẹnu iṣẹ, Israeli abinibi ni apa ti a lè fojuri ti ètò-àjọ Jehofa. Nitori naa a lè fi obinrin kan ṣapejuwe rẹ̀, Hagari, ẹrubinrin Sara.
Awọn Ọmọkunrin Tootọ ti Majẹmu Abrahamu
13. (a) Ki ni ó ṣe rẹ́gí pẹlu Sara, aya Abrahamu? (b) Eeṣe ti a fi lè pe “Jerusalemu ti oke” ní “ominira”?
13 Ní odikeji ẹ̀wẹ̀, “Jerusalemu ti oke” ni ètò-àjọ Jehofa ti a ko le fojuri ti ọ̀run. Ní ibamu rẹ́gí, a lè fi obinrin kan ṣapejuwe rẹ̀, iyẹn ni Sara, aya tootọ ti Abrahamu. A kò dá majẹmu Ofin naa pẹlu ètò-àjọ yii, nitori naa “Jerusalemu ti oke” lominira, bii ti Sara igbaani. Eyi ni ètò-àjọ naa ti ó pese “iru-ọmọ” ileri naa, idi si niyii ti aposteli Paulu fi lè pè é ní “ìyá wa.”
14. A ha lè lo majẹmu Abrahamu fun “Jerusalemu ti oke” bi, ki si ni a lè pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi ti a fi ẹmi bi nigba naa?
14 Niti gidi, nigba naa, majẹmu Abrahamu naa ni a lè lò fun un gẹgẹ bi iyawo iṣapẹẹrẹ fun Abrahamu Gigaju, bẹẹni, ètò-àjọ agbaye ti Jehofa nibẹ loke ọ̀run. O baamu nigba naa pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi ti a fi ẹmi bi, gẹgẹ bii ti aposteli Paulu, jẹ awọn ọmọkunrin, tabi awọn ọmọ, majẹmu Abrahamu. Paulu ń baa lọ lati ṣalaye lọna bẹẹ, ní wiwi pe:
15. Ki ni aposteli Paulu sọ ninu Galatia 4:27-31 niti “awọn ọmọ” majẹmu Abrahamu?
15 “Nitori a ti kọ ọ pe: Maa yọ̀, iwọ àgàn ti kò bimọ: bu si ayọ̀ ki o sì kigbe soke, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ ju ti abilekọ lọ. Njẹ ará, ọmọ ileri ni awa gẹgẹ bii Isaaki. Ṣugbọn bi eyi ti a bi nipa ti ara ti ṣe inunibini nigba naa si eyi ti a bi nipa ti ẹmi, bẹẹ si ni nisinsinyi. Ṣugbọn iwe mímọ́ ha ti wi? Lé ẹrubinrin naa jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrubinrin ki yoo bá ọmọ ominira obinrin jogun pọ̀. Nitori naa, ará, awa kii ṣe ọmọ ẹrubinrin, bikoṣe ti ominira obinrin.”—Galatia 4:27-31; Isaiah 54:1.
16. Ki ni ohun ti aṣefihan iṣapẹẹrẹ ti igbaani sọ tẹ́lẹ̀ niti majẹmu Ofin, eyi si fi ki ni silẹ lati wà?
16 Nipa bayii aṣefihan iṣapẹẹrẹ ti igbaani naa sọ tẹ́lẹ̀ pe Jehofa Ọlọrun, Abrahamu Gigaju, yoo pa majẹmu Ofin ti a dá pẹlu Israeli ní Oke Sinai tì sapakan. Ní ọna yii afikun naa (majẹmu Ofin) sí majẹmu Abrahamu ni a ò yọ, tabi mú kuro, ní fifi kiki majẹmu Abrahamu silẹ pẹlu ileri rẹ̀ ti “iru-ọmọ” kan nipasẹ ẹni ti gbogbo idile ayé yoo fi bukun araawọn.
17. (a) Yoo ti pẹ tó ti majẹmu Ofin naa yoo fi maa wà? (b) Eeṣe ti Jesu Kristi fi jẹ́ olori atọmọdọmọ Abrahamu? (c) Fun Jesu lati di Olori Aṣoju Ọlọrun fun bibukun gbogbo idile ayé sinmi lori ki ni?
17 Nitori naa majẹmu Ofin naa ti a fi kun un ni yoo maa baa lọ titi “iru-ọmọ” ti a ṣeleri naa yoo fi de, eyi sì wá jẹ́ Jesu Kristi. Nipasẹ iṣẹ iyanu atọrunwa, o di atọmọdọmọ Abrahamu nipa ti ara. O di olori atọmọdọmọ fun babanla naa. Kii ṣe pe o jẹ́ atọmọdọmọ Abrahamu nipa ti ara nikan ni ṣugbọn o tun jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun, ati nitori naa eniyan pipe kan, ẹnikan ti ó wá duro ní “mímọ́, ailẹgan, aileeri, ti a yà sọtọ kuro ninu ẹlẹṣẹ.” (Heberu 7:26) Bi o ti wu ki o ri, fun un lati di Olori Aṣoju Ọlọrun fun bibukun gbogbo idile ayé sinmi lori fifi iwalaaye eniyan pipe rẹ̀ rubọ ati lilo ìtóye eyi lati ṣoju fun gbogbo araye. Nipasẹ iru ifi ara-ẹni rubọ bẹẹ, oun yoo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi Olori Alufaa nla ti Jehofa, ní riru ẹbọ kan ti ó bá gbogbo ohun ti a beere fun lati ọ̀run wá mu.
A Kan Majẹmu Ofin Mọ́ Igi Oró Jesu
18. (a) Awọn wo ni a o kọkọ gbe anfaani ẹbọ irapada naa kalẹ fun, eesitiṣe? (b) Ki ni Jesu wá dà?
18 Awọn anfaani ẹbọ irapada yii ni a o gbekalẹ lakọọkọ fun anfaani orilẹ-ede Ju, ti Jesu wa jẹ́ mẹmba kan ninu rẹ̀ nipasẹ bibi ti a bi i lọna iyanu nipasẹ Maria wundia. Eyi yẹ ní pataki, nitori ti awọn Ju wà labẹ idalẹbi iku ni ìlọ́po meji. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? Lakọọkọ ná, wọn jẹ́ iru-ọmọ Adamu ẹlẹṣẹ, ati lẹẹkeji, nitori aipe wọn, wọn ti di ẹni ifibu nitori kikuna lati dé oju ìlà majẹmu Ofin pẹlu Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, Jesu di ẹni ifibu fun wọn. Nipa didi ẹni ti a kàn mọ́ igi oró titi ti ó fi ku, o ṣeeṣe fun un lati gbé ègún naa kuro fun “awọn agutan ile Israeli ti ó nù.” Ní 33 C.E., majẹmu Ofin ni a kàn mọ́ igi oró Jesu, ọgba agutan awọn Ju labẹ majẹmu Ofin onigba kukuru yẹn ni a tì pa, ní mimu un kuro.—Matteu 15:24; Galatia 3:10-13; Kolosse 2:14.
19. (a) Ọgba agutan titun wo ni a nilati ṣi, ki ni yoo sì ní ninu? (b) Awọn wọnni ti a mu wọnu ọgba agutan titun naa nigba naa wa di ki ni?
19 Nitori naa ọgba agutan titun kan ni a nilati ṣí lati lè fi àyè gba awọn agutan tẹmi ti Oluṣọ-Agutan Rere naa, Jesu Kristi, ti a ti ji dide. Oluṣọ-Agutan Rere naa ti ó fi araarẹ̀ rubọ ni ó sì tun jẹ́ ẹnu ọna iṣapẹẹrẹ fun ọgba agutan titun yii. (Johannu 10:7) Awọn wọnni ti a mu wọnu ọgba agutan titun yii labẹ Oluṣọ-Agutan Rere naa di awọn ọmọkunrin ti a fi ẹmi bí ti Abrahamu Gigaju naa ti wọn sì tipa bẹẹ di apakan “iru-ọmọ” Rẹ̀. (Romu 2:28, 29) Ní ibamu pẹlu otitọ yii, ní ìgbà awọn akoko ikẹhin wọnyi àṣẹ́kù “iru-ọmọ” tẹmi yii ti ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ibukun fun awọn araadọta ọkẹ eniyan ti ń bisii ninu eyi ti ó ju 200 ilẹ lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 80, 81]
Majẹmu Ofin Mose ti a dá ni Oke Sinai wá si opin nigba ti a kàn án mọ́ igi oró pẹlu Jesu