Orí 9
Bá A Ṣe Lè Di Orúkọ Jésù Mú Ṣinṣin
PÁGÁMÙ
1. Ìjọ wo ni Jésù tún ránṣẹ́ sí, irú ìlú wo sì láwọn Kristẹni yẹn ń gbé?
LÁTI Símínà, téèyàn bá rin ìrìn kìlómítà méjìlélọ́gọ́rin [82] gba ọ̀nà etíkun lápá àríwá, lẹyìn náà téèyàn wá rin ìrìn kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] gba ọ̀gbun odò Caicus, èèyàn á dé Págámù, tá a mọ̀ sí Bẹ́gámà lóde òní. Tẹ́ńpìlì Súúsì tàbí ti Júpítà tó wà nínú ìlú náà ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n bí ẹni mowó. Láàárín ọdún 1800 sí 1899, àwọn awalẹ̀pìtàn gbé pẹpẹ tẹ́ńpìlì yẹn, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ ère àtàwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe fáwọn ọlọ́run èké lọ sí Jámánì, ìyẹn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó wà nílùú Berlin. Iṣẹ́ wo ni Jésù Olúwa rán sí ìjọ tó ń gbé láàárín àwọn abọ̀rìṣà yẹn?
2. Báwo ni Jésù ṣe fìdí ẹni tóun jẹ́ múlẹ̀, kí sì ni ìtumọ̀ níní tó ní ‘idà olójú méjì’?
2 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jésù fìdí ẹni tóun jẹ́ múlẹ̀, ó ní: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Págámù pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí, ẹni tí ó ní idà gígùn olójú méjì mímú.” (Ìṣípayá 2:12) Ṣe ni Jésù ń ṣàtúnsọ bí Ìṣípayá 1:16 ṣe ṣàpèjúwe irú ẹni tó jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ àti Amúdàájọ́ṣẹ, ó máa rí i pé òun rẹ́yìn àwọn tó ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Èyí mà tuni nínú o! Síbẹ̀, ní ti ìdájọ́, ìkìlọ̀ léyìí jẹ́ fáwọn tó wà nínú ìjọ pé Jèhófà, nípasẹ̀ “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà,” Jésù Kristi, máa “di ẹlẹ́rìí yíyára kánkán” lòdì sí gbogbo àwọn tó ń fi ẹ̀sìn Kristẹni bojú láti máa lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, irọ́ pípa, àti àbòsí tí wọ́n sì kọ̀ láti tọ́jú àwọn aláìní. (Málákì 3:1, 5; Hébérù 13:1-3) A gbọ́dọ̀ máa fi ìmọ̀ràn àti ìbáwí tí Ọlọ́run fi rán Jésù ṣèwà hù!
3. Ìjọsìn èké wo ló wáyé ní Págámù, ọ̀nà wo la sì lè gbà sọ pé “ìtẹ́ Sátánì” wà ńbẹ̀?
3 Jésù wá sọ fún ìjọ náà pé: “Mo mọ ibi tí ìwọ ń gbé, èyíinì ni, ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà.” (Ìṣípayá 2:13a) Lóòótọ́ ni, ìjọsìn Sátánì ló yí àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ká. Yàtọ̀ sí tẹ́ńpìlì Súúsì, ibẹ̀ náà ni ojúbọ Ẹsikulápíọ̀sì, ìyẹn ọlọ́run ìmúláradá wà. Págámù tún lókìkí torí ibẹ̀ làwọn lóókọ lóókọ nínú ìjọsìn olú ọba máa ń kora jọ sí. Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “Sátánì” túmọ̀ sí “Alátakò,” nígbà tí “ìtẹ́” rẹ̀ dúró fún fífún tí Ọlọ́run fún un láyè láti ṣàkóso lórí ayé fún sáà kan. (Jóòbù 1:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW) Ìbọ̀rìṣà tó pọ̀ nílùú Págámù fi hàn pé lóòótọ́ ni “ìtẹ́” Sátánì wà ńbẹ̀. Ẹ ò rí i pé inú á ti bí Sátánì sáwọn Kristẹni yẹn gan-an ni torí pé wọ́n ò forí balẹ̀ fún un nínú ìjọsìn orílẹ̀-èdè!
4. (a) Báwo wá ni Jésù ṣe gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó wà ní Págámù? (b) Kí ni aṣojú Róòmù náà Pliny kọ sí Olú Ọba Trajan nípa ọwọ́ tóun fi mú àwọn Kristẹni? (d) Láìka ewu sí, ìhà ta làwọn Kristẹni tó wà ní Págámù wà?
4 Bẹ́ẹ̀ ni, “ìtẹ́ Sátánì” wà ní Págámù. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Síbẹ̀ ìwọ ń bá a nìṣó ní dídi orúkọ mi mú ṣinṣin, ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi, àní ní àwọn ọjọ́ Áńtípà, ẹlẹ́rìí mi, olùṣòtítọ́, ẹni tí a pa ní ẹ̀gbẹ́ yín, níbi tí Sátánì ń gbé.” (Ìṣípayá 2:13b) Ìgbóríyìn yìí mà múni lọ́kàn yọ̀ o! Kò síyè méjì pé torí kíkọ̀ tí Áńtípà kọ̀ láti bá wọn lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò àti ìjọsìn olú ọba Róòmù ló jẹ́ kí wọ́n pa á. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jòhánù gba àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Pliny Kékeré tó jẹ́ aṣojú Olú Ọba Trajan ti Róòmù, kọ̀wé sí Trajan, ó sì ṣàlàyé ìlànà tóun máa ń lò láti ṣèdájọ́ ẹni tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ Kristẹni—olú ọba náà fọwọ́ sí ìlànà yìí. Gẹ́gẹ́ bí Pliny ti wí, a máa ń tú àwọn tí wọ́n bá sọ pé àwọn kì í ṣe Kristẹni sílẹ̀ lẹ́yìn tí, “wọ́n bá ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ọlọ́run tẹ̀ lé mi, tí wọ́n fi tùràrí àti wáìnì rúbọ sí ère rẹ [ìyẹn ère Trajan] . . . láfikún síyẹn, wọ́n ní láti fi Kristi ré.” Ẹnikẹ́ni yòówù tí wọ́n bá rí tó jẹ́ Kristẹni, pípa ni wọ́n á pa á. Kódà pẹ̀lú irú ewu tí wọ́n dojú kọ yẹn, àwọn Kristẹni tó wà ní Págámù ò sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Wọ́n ‘di orúkọ Jésù mú ṣinṣin’ ní ti pé wọ́n ń bá a lọ láti máa bọlá fún ipò gíga tó wà gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn àti Ẹni tó ń fi hàn pé Jèhófà nìkan ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí Ìjọba Ọlọ́run.
5. (a) Kí lohun tó dà bí ìjọsìn olú ọba lóde òní tó ń fa ìdánwò mímúná fáwọn Kristẹni lákòókò wa yìí? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ilé Ìṣọ́ ti pèsè fáwọn Kristẹni?
5 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti sọ pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé burúkú yìí, ṣùgbọ́n nítorí pé Jésù jẹ́ olùṣòtítọ́, Sátánì ò rí i gbé ṣe. (Mátíù 4:8-11; Jòhánù 14:30) Lákòókò tiwa yìí, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára, ní pàtàkì “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù,” ti sapá láti já ìṣàkóso ayé gbà mọ́ ara wọn lọ́wọ́. (Dáníẹ́lì 11:40) Ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá ti gbilẹ̀, ó dà bí ìjọsìn olú ọba ayé ọjọ́un, ó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ jákèjádò ayé. Àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ṣíṣàì dá sí ọ̀ràn òṣèlú nínú Ilé Ìṣọ́ Náà (Gẹ̀ẹ́sì) ti November 1, 1939, ti May 1, 1980, àti ti September 1, 1986, sọ ní kedere ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yìí, ó pèsè ìlànà táwọn Kristẹni tí wọ́n fẹ́ láti rìn lorúkọ Jèhófà tí wọ́n sì fẹ́ láti ṣẹ́gun ayé ní láti máa tẹ̀ lé, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe tìgboyàtìgboyà.—Míkà 4:1, 3, 5; Jòhánù 16:33; 17:4, 6, 26; 18:36, 37; Ìṣe 5:29.
6. Bí Áńtípà, báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dúró gbọn-in lóde òní?
6 A nílò irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ní kánjúkánjú. Pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni karí, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ àti olùkọ́ ni wọ́n lé kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ torí pé wọ́n kọ̀ láti kí àsíá orílẹ̀-èdè, bákan náà, wọ́n ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Jámánì lọ́nà rírorò torí pé wọ́n kọ̀ láti kí àsíá Násì. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mọ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Hitler tí wọ́n ń pè ní Násì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin torí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sírú ìjọsìn orílẹ̀-èdè ẹni bẹ́ẹ̀. Láàárín ọdún 1930 sí 1939, tí ìjọsìn olú ọba àwọn Ṣintó gbòde kan ní Japan, àwọn òjíṣẹ́ méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fúnrúgbìn Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ lágbègbè táwọn ara Taiwan tẹ̀ dó sí ní Japan. Àwọn alákòóso ológun jù wọ́n sẹ́wọ̀n, níbi tí ọ̀kan nínú wọn ti kú nítorí ṣíṣe tí wọ́n ṣe wọn níṣe ìkà. Nígbà tó yá, wọ́n ní kí èkejì máa lọ, wọ́n wá yìnbọn fún un látẹ̀yìn. A lè pè é ní Áńtípà òde òní. Títí dòní olónìí, àwọn ilẹ̀ kan wà tí wọ́n ṣì ń fi dandan lé e pé àfi káwọn èèyàn jọ́sìn àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè kí wọ́n sì fún Ìjọba Orílẹ̀-Èdè ní ìfọkànsìn tó tọ́ sí Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n, àwọn tí wọ́n pa ò sì kéré látàrí ìpinnu wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni láti má ṣe dá sí ọ̀ràn òṣèlú. Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tí irú àwọn ìṣòro yẹn sì wà níwájú rẹ, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ kó o bàa lè ní “ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè,” pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun lọ́kàn rẹ.—Hébérù 10:39-11:1; Mátíù 10:28-31.
7. Báwo làwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà ṣe dojú kọ ọ̀ràn ìjọsìn orílẹ̀-èdè, kí ló sì yọrí sí?
7 Àwọn ọ̀dọ́ nílé ẹ̀kọ́ ti dojú kọ irú àwọn ìṣòro kan náà. Lọ́dún 1985, ní ìpínlẹ̀ Kerala, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, àwọn ọ̀dọ́mọdé mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn tó dá lórí Bíbélì, wọ́n kọ̀ láti kọ orin ìyìn sí orílẹ̀-èdè. Wọ́n fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dúró nígbà táwọn yòókù ń kọrin, síbẹ̀ àfìgbà tí wọ́n lé wọn kúrò nílé ẹ̀kọ́. Baba wọn pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìgbésẹ̀ yìí sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti orílẹ̀-èdè Íńdíà, níbi táwọn adájọ́ méjèèjì ti dáre fáwọn ọmọ náà, ní sísọ tìgboyàtìgboyà pé: “Àṣà ilẹ̀ wa ń kọ́ni pé ká fàyè gba èrò àwọn ẹlòmíì; ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn wa ń kọ́ni pé ká fàyè gba èrò àwọn ẹlòmíì; òfin orílẹ̀-èdè wa ò ta ko fífàyè gba èrò àwọn ẹlòmíì; ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn.” Ṣe lojú ìwé ìròyìn kún fún ìròyìn rere nípa ìdájọ́ yìí, èyí tó jẹ́ kí gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámárùn-ún iye àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé nígbà yẹn mọ̀ pé àwọn Kristẹni kan wà lórílẹ̀-èdè yẹn tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà àti pé wọn kì í ṣe ohunkóhun tó bá yàtọ̀ sí ìlànà tó wà nínú Bíbélì.
Àwọn Ohun Tó Lè Sọ Èèyàn Dìdàkudà
8. Ìbáwí wo ni Jésù rí i pé ó pọn dandan láti fáwọn Kristẹni tó wà ní Págámù?
8 Dájúdájú, adúróṣinṣin làwọn Kristẹni tó wà ní Págámù tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ lòdì sí ọ.” Kí ni wọ́n ṣe tí wọ́n fi yẹ fún ìbáwí? Jésù sọ fún wa, ó ní: “Ìwọ ní níbẹ̀, àwọn tí wọ́n di ẹ̀kọ́ Báláámù mú ṣinṣin, ẹni tí ó lọ ń kọ́ Bálákì láti fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti jẹ àwọn ohun tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà àti láti ṣe àgbèrè.”—Ìṣípayá 2:14.
9. Ta ni Báláámù, báwo sì ni ìmọ̀ràn rẹ̀ ṣe fi ohun “ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì”?
9 Nígbà ayé Mósè, Bálákì Ọba Móábù bẹ Báláámù, ìyẹn wòlíì kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà, pé kó bá òun gégùn-ún fún Ísírẹ́lì. Jèhófà de Báláámù lọ́nà, ó sọ ọ́ di dandan fún un láti kéde ìbùkún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ègbé fáwọn ọ̀tá wọn. Báláámù pẹ̀tù sí inú tó ń bí Bálákì torí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó wá dábàá ọ̀nà kan tó rọrùn láti rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú: Jẹ́ káwọn ọmọbìnrin Móábù tan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sínú ìṣekúṣe tó burú jáì àti sínú ìjọsìn èké ọlọ́run tó ń jẹ́ Báálì ti Péórù! Ọgbọ́n àrékendá yìí ṣiṣẹ́. Ìbínú òdodo Jèhófà ru, ó sì rán ìyọnu ńlá kan tó pa egbèjìlá [24,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alágbèrè wọ̀nyẹn. Ìgbà tí Fíníhásì àlùfáà gbégbèésẹ̀ rere láti mú ìwà búburú kúrò ní Ísírẹ́lì ni ìyọnu náà tó dáwọ́ dúró.—Númérì 24:10, 11; 25:1-3, 6-9; 31:16.
10. Àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ wo ló ti yọ́ wọnú ìjọ tó wà ní Págámù, kí ló sì lè ti jẹ́ káwọn Kristẹni yẹn rò pé Ọlọ́run á máa gbójú fo ìrékọjá àwọn?
10 Ṣé irú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kan náà wà ní Págámù nígbà ayé Jòhánù? Wọ́n wà! Ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà ti yọ́ wọnú ìjọ. Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ò tíì gbà ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fúnni nípasẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́ríńtì 10:6-11) Torí pé wọ́n ti fara da inúnibíni, bóyá wọ́n ń rò pé Jèhófà á máa gbójú fo àwọn ìrékọjá àwọn ní ti ọ̀ràn ìṣekúṣe. Nítorí náà Jésù mú kó ṣe kedere pé ṣe ni wọ́n gbọ́dọ̀ kọ irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.
11. (a) Kí làwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí, irú ìrònú wo ni wọn ò sì gbọ́dọ̀ ní? (b) Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, àwọn mélòó la ti yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni, torí kí la sì ṣe yọ èyí tó pọ̀ jù lára wọn?
11 Bákan náà lónìí, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún “[sísọ] inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” (Júúdà 4) Ó di dandan fún wa láti kórìíra ohun tó burú ká sì ‘lu ara wa kíkankíkan’ ká bàa lè máa fi ìwà Kristẹni ṣèwà hù. (1 Kọ́ríńtì 9:27; Sáàmù 97:10; Róòmù 8:6) A ò gbọ́dọ̀ ronú láé pé ìtara tá a ní nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti ìwà títọ́ wa lákòókò inúnibíni á fún wa lómìnira láti lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún làwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni kárí ayé látàrí ìwà ìṣekúṣe. Àwọn ọdún kan tiẹ̀ wà tí iye àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ pọ̀ ju iye àwọn tó ṣubú ní Ísírẹ́lì ìgbàanì nítorí Báálì ti Péórù lọ. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wà lójúfò ká má bàa fìwà jọ wọn!—Róòmù 11:20; 1 Kọ́ríńtì 10:12.
12. Gẹ́gẹ́ bíi tàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbàanì, àwọn ìlànà wo ló yẹ káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé lónìí?
12 Jésù tún bá àwọn Kristẹni tó wà ní Págámù wí fún ‘jíjẹ àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.’ Kí lèyí túmọ̀ sí? Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì, ó dà bíi pé àwọn kan lára wọn ń ṣi òmìnira Kristẹni wọn lò, tí wọ́n sì dìídì ń ṣẹ̀ sí ẹ̀rí-ọkàn àwọn ẹlòmíràn. Àfàìmọ̀ ni wọ́n ò ní máa lọ́wọ́ lọ́nà kan ṣáá nínú àwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà. (1 Kọ́ríńtì 8:4-13; 10:25-30) Àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ lónìí gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn nínú lílo òmìnira Kristẹni wọn, kí wọ́n ṣọ́ra láti má ṣe mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. Dájúdájú, wọ́n ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí oríṣiríṣi ọ̀nà ìbọ̀rìṣà òde òní, irú bíi jíjọ́sìn àwọn gbajúgbajà òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn eré sinimá, àti eré ìdárayá, tàbí sísọ owó di ọlọ́run, tàbí sísọ ikùn tiwọn fúnra wọn di ọlọ́run!—Mátíù 6:24; Fílípì 1:9, 10; 3:17-19.
Ṣọ́ra fún Ẹ̀ya Ìsìn!
13. Ìbáwí wo ni Jésù fún àwọn Kristẹni ní Págámù tẹ̀ lé e, kí sì nìdí tí ìjọ náà fi nílò ìbáwí yẹn?
13 Jésù tún fáwọn Kristẹni tó wà ní Págámù ní ìbáwí sí i, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ, pẹ̀lú, ní àwọn tí ó di ẹ̀kọ́ ẹ̀ya ìsìn Níkoláọ́sì mú ṣinṣin bákan náà.” (Ìṣípayá 2:15) Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ gbóríyìn fáwọn ará Éfésù ni torí pé wọ́n kórìíra àwọn iṣẹ́ ẹ̀ya ìsìn yìí. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni ní Págámù nílò ìmọ̀ràn láti lè mọ bí wọ́n á ṣe máa pa ìjọ mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ya ìsìn. Wọ́n ní láti túbọ̀ mọ bí wọ́n ò ṣe ní máa fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àwọn ìlànà Kristẹni kí ìṣọ̀kan tí Jésù gbàdúrà fún nínú Jòhánù 17:20-23 lè wà nínú ìjọ. Ó pọn dandan láti “gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera àti láti fi ìbáwí tọ́ àwọn tí ń ṣàtakò sọ́nà.”—Títù 1:9.
14. (a) Látìbẹ̀rẹ̀, àwọn wo ló pọn dandan pé kí ìjọ Kristẹni bá wọ̀jà, báwo sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe wọn? (b) Ọ̀rọ̀ Jésù wo lẹnikẹ́ni tó bá ti ń wù láti tẹ̀ lé àwùjọ tó yapa ní láti fiyè sí?
14 Látìbẹ̀rẹ̀ ni ìjọ Kristẹni ti ní láti wọ̀jà pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà agbéraga, àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in fa ‘ìpínyà àti ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀, èyí tó lòdì sí ẹ̀kọ́’ táwọn tí Jèhófà ń lò fi ń kọ́ni. (Róòmù 16:17, 18) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ló ti kìlọ̀ nípa irú ewu yìí.a Lóde òní, lẹ́yìn tí Jésù ti fọ ìjọ tòótọ́ mọ́ tó sì ti dá ìṣọ̀kan tó jẹ́ ti Kristẹni padà sínú rẹ̀, ewu ẹ̀ya ìsìn ṣì wà síbẹ̀. Fún ìdí yìí, ẹnikẹ́ni tó bá ti ń wù bíi pé kó tẹ̀ lé àwùjọ tó yapa, tó sì ti fẹ́ dá ẹ̀ya ìsìn sílẹ̀ ní láti fiyè sí ọ̀rọ̀ Jésù yìí pé: “Nítorí náà, ronú pìwà dà. Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, mo ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ ní kíákíá, ṣe ni èmi yóò fi idà gígùn ẹnu mi bá wọn jagun.”—Ìṣípayá 2:16.
15. Báwo ni ẹ̀ya ìsìn ṣe ń bẹ̀rẹ̀?
15 Báwo ni ẹ̀ya ìsìn ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀? Àpẹẹrẹ kan rèé: Ẹnì kan tó pe ara rẹ̀ ní olùkọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbin iyè méjì sọ́kàn àwọn èèyàn, nípa títako àwọn òtítọ́ Bíbélì (irú bíi bó ṣe jẹ́ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà), èyí tó lè mú káwọn kan yapa kí wọ́n sì tẹ̀ lé e. (2 Tímótì 3:1; 2 Pétérù 3:3, 4) Ẹnì kan sì lè máa ṣàríwísí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń mú kí iṣẹ́ rẹ̀ di ṣíṣe kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú káwọn ará máa ṣe ìmẹ́lẹ́ nípa sísọ pé kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ sì ni kò pọn dandan láti máa mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tọ àwọn èèyàn lọ láti ilé dé ilé. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ì bá lè rẹ ara wọn sílẹ̀ ká ní wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù bíi ti Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni, àmọ́ dípò ìyẹn, ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n pínyà kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, bóyá kí wọ́n kàn máa ka Bíbélì lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kékeré kan. (Mátíù 10:7, 11-13; Ìṣe 5:42; 20:20, 21) Àwọn tá à ń sọ yìí gbé èrò ara wọn kalẹ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n gbé èrò ara wọn kalẹ̀ nípa àṣẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé ká má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀, nípa ṣíṣe àwọn àjọ̀dún, àti nípa ìlò tábà. Síwájú sí i, wọ́n bu ẹ̀tẹ́ lu orúkọ Jèhófà; kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi padà sínú ìwà àìfẹ́kan-án-ṣe bíi ti Bábílónì Ńlá. Èyí tó tiẹ̀ tún burú jù ni pé Sátánì sún àwọn kan nínú wọn láti kọjú ìjà sáwọn ‘ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn’ tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn tẹ́lẹ̀, wọ́n sì tún lù wọ́n.—Mátíù 24:49; Ìṣe 15:29; Ìṣípayá 17:5.
16. (a) Kí nìdí táwọn tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìwà apẹ̀yìndà fi ní láti ronú pìwà dà láìjáfara? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí wọ́n kọ̀ láti ronú pìwà dà?
16 Ẹnikẹ́ni tó bá ti ń rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìwà àwọn apẹ̀yìndà ní láti tètè fiyè sí ìkìlọ̀ Jésù láti ronú pìwà dà! A gbọ́dọ̀ kọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ táwọn apẹ̀yìndà ń sọ bí ìgbà téèyàn bá kọ májèlé! Ìlara àti ìkórìíra ló fà á, èyí tó yàtọ̀ sí òtítọ́ tó jẹ́ òdodo, tó mọ́ níwà, tó sì fani mọ́ra, tí Jésù fi ń bọ́ ìjọ rẹ̀. (Lúùkù 12:42; Fílípì 1:15, 16; 4:8, 9) Ní tàwọn tí wọ́n kọ̀ láti ronú pìwà dà, kò sí ni kí Jésù Olúwa má “fi idà gígùn ẹnu [rẹ̀] bá wọn jagun.” Ó ń sẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ kí ìṣọ̀kan tó gbàdúrà fún lálẹ́ tó lò kẹyìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé má bàa yingin. (Jòhánù 17:20-23, 26) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ṣe làwọn apẹ̀yìndà kọ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ àti ìrànlọ́wọ́ táwọn ìràwọ̀ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi fúnni, Jésù máa ṣèdájọ́ wọn, ó sì máa fìyà “mímúná jù lọ” jẹ wọ́n ní jíjù wọ́n sínú “òkùnkùn lóde.” Ṣe la yọ wọ́n dà nù kúrò nínú ìjọ kí wọ́n má bàa dà bí ìwúkàrà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Mátíù 24:48-51; 25:30; 1 Kọ́ríńtì 5:6, 9, 13; Ìṣípayá 1:16.
‘Mánà Tó Wà Nípamọ́ àti Òkúta Róbótó Funfun Kan’
17. Èrè wo ló ń dúró de àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n bá “ṣẹ́gun,” kí sì ló pọn dandan fáwọn Kristẹni ní Págámù láti ṣẹ́pá rẹ̀?
17 Èrè tí ò láfiwé ló ń dúró de gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni nípasẹ̀ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Fetí sílẹ̀! “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ: Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fún ní díẹ̀ nínú mánà tí a fi pa mọ́, èmi yóò sì fún un ní òkúta róbótó funfun kan, àti lára òkúta róbótó náà orúkọ tuntun tí a kọ, èyí tí ẹnì kankan kò mọ̀ àyàfi ẹni tí ó rí i gbà.” (Ìṣípayá 2:17) Nípa báyìí, ó gbà àwọn Kristẹni tó wà ní Págámù níyànjú láti “ṣẹ́gun” bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Símínà. Báwọn tó wà ní Págámù, níbi tí ìtẹ́ Sátánì wà bá máa kẹ́sẹ járí, wọ́n gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣẹ́pá ìṣekúṣe, ẹ̀ya ìsìn, àti ìpẹ̀yìndà tó jọra pẹ̀lú ti Bálákì, Báláámù, àti ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn á rí ìkésíni gbà láti jẹ nínú “mánà tí a fi pa mọ́” náà. Kí lèyí túmọ̀ sí?
18, 19. (a) Kí ni mánà tí Jèhófà pèsè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Mánà wo ló wà nípamọ́? (d) Kí ni jíjẹ mánà tó wà nípamọ́ náà ṣàpẹẹrẹ?
18 Nígbà ayé Mósè, Jèhófà pèsè mánà láti gbé ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ró lákòókò ìrìn àjò wọn nínú aginjù. Mánà yẹn ò fara sin, nítorí láràárọ̀—àfi ọjọ́ Sábáàtì nìkan—ṣe ló máa ń fara hàn lọ́nà ìyanu, bí ìrì dídì wínníwínní tó bo ilẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run pèsè kí ebi má bàa pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kú ni. Gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí, Jèhófà pàṣẹ fún Mósè láti tọ́jú díẹ̀ nínú “oúnjẹ” yìí sínú ìṣà wúrà tí ń bẹ nínú àpótí ọlọ́wọ̀ ti májẹ̀mú “jálẹ̀ ìran-ìran [ọmọ Ísírẹ́lì].”—Ẹ́kísódù 16:14, 15, 23, 26, 33; Hébérù 9:3, 4.
19 Àpẹẹrẹ náà mà bá a mu rẹ́gí o! Ọlọ́run tọ́jú mánà yìí sínú iyàrá ìkélé Mímọ́ Jù Lọ ti àgọ́ ìsìn, níbi tí iná ìyanu tó rà bàbà lórí ìdérí Àpótí ti ṣàpẹẹrẹ wíwà tí Jèhófà wà ńbẹ̀. (Ẹ́kísódù 26:34) Kò sí ẹnì kankan tó lè wọnú ibi ọlọ́wọ̀ yẹn láti jẹ mánà tó fara sin náà. Bó ti wù kó rí, Jésù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn òun tí wọ́n ṣẹ́gun yóò jẹ “mánà tí a fi pa mọ́” náà. Bí Kristi ti ṣe ṣáájú wọn, ó ṣeé ṣe fún wọn láti wọlé, “[kì í ṣe] sí ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe, tí ó jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́, bí kò ṣe sí ọ̀run.” (Hébérù 9:12, 24) Bí wọ́n bá ṣe ń jí dìde, wọ́n ń gbé àìdibàjẹ́ àti àìleèkú wọ̀—ìpèsè aláìláfiwé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, tó ṣàpẹẹrẹ fífún tí wọ́n fún wọn ní “mánà tí a fi pa mọ́” èyí tí ò lè bà jẹ́. Àǹfààní tí àwùjọ kékeré tó ṣẹ́gun yìí ní mà ga o!—1 Kọ́ríńtì 15:53-57.
20, 21. (a) Kí ni fífún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní òkúta róbótó funfun ṣàpẹẹrẹ? (b) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kìkì ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì òkúta róbótó funfun ló wà, ìrètí wo ló wà fáwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá?
20 Àwọn èèyàn yìí tún gba “òkúta róbótó funfun.” Láwọn ilé ẹjọ́ Róòmù, wọ́n máa ń lo òkúta róbótó láti fi ṣèdájọ́.b Òkúta róbótó funfun túmọ̀ sí ìdásílẹ̀, nígbà tí òkúta róbótó dúdú túmọ̀ sí ìdálẹ́bi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ikú lọ́pọ̀ ìgbà. Fífún tí Jésù fáwọn Kristẹni ní Págámù ní “òkúta róbótó funfun” fi hàn pé ó kà wọ́n sí aláìmọwọ́mẹsẹ̀, aláìlábààwọ́n tó mọ́ tónítóní. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ Jésù lè ní ìtumọ̀ míì. Láyé ìgbà tí Róòmù ṣì ń jẹ́ Róòmù, wọ́n máa ń lo òkúta róbótó bíi tíkẹ́ẹ̀tì láti lè wọlé sáwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Nítorí náà, òkúta róbótó funfun náà lè tọ́ka sí ohun kan tó jẹ́ àkànṣe gan-an fún Kristẹni ẹni àmì òróró náà tó ṣẹ́gun, ìyẹn gbígbà tí wọ́n gbà á wọlé síbi ọlọ́lá ní ọ̀run níbi ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Gbogbo irú òkúta róbótó bẹ́ẹ̀ tó wà ò ju ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] lọ.—Ìṣípayá 14:1; 19:7-9.
21 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò kà ọ́ sí bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń jọ́sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Bó ò tiẹ̀ sí lára àwọn tó máa gba òkúta róbótó funfun tó o lè fi wọlé sí ọ̀run, wà á la ìpọ́njú ńlá já, wà á sì kópa nínú iṣẹ́ aláyọ̀ ti mímú Párádísè orí ilẹ̀ ayé padà bọ̀ sípò, ìyẹn bó o bá fara dà á. Àwọn tó tún máa bá ọ nípìn-ín nínú èyí làwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n gbé ayé kí ìsìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n á jí dìde àtàwọn tí wọ́n jẹ́ àgùntàn mìíràn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, gbogbo àwọn òkú yòókù tá a tún rà padà ló máa rí àjíǹde sí ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 45:16; Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9, 14.
22, 23. Kí ni ìjẹ́pàtàkì orúkọ tó wà lára òkúta róbótó náà fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ìṣírí wo ló sì yẹ kéyìí fún wa?
22 Kí lórúkọ tuntun tó wà lára òkúta róbótó náà? Orúkọ jẹ́ ọ̀nà kan láti dá ẹnì kan mọ̀ láti lè fìyàtọ̀ sáàárín ẹni náà àtàwọn mìíràn. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí gba òkúta róbótó náà lẹ́yìn tí wọ́n ti parí iṣẹ́ wọn ti orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun. Lọ́nà tó ṣe kedere, nígbà náà, orúkọ tó wà lára òkúta róbótó náà ní í ṣe pẹ̀lú àǹfààní wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù lọ́run—ipò tó máa jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Jésù jù lọ bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn pẹ̀lú ìmọrírì gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé, èyí tó wà fún kìkì àwọn tí wọ́n jogún Ìjọba ọ̀run. Fún ìdí yìí, ó jẹ́ orúkọ kan, tàbí ipò, “èyí tí ẹnì kankan kò mọ̀ àyàfi ẹni tí ó rí i gbà.”—Fi wé Ìṣípayá 3:12.
23 Ìṣírí gbáà lèyí jẹ́ fún ẹgbẹ́ Jòhánù láti “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ” kí wọn sì fi ṣèwà hù! Ìyànjú kékeré kọ́ lèyí máa jẹ́ fáwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ogunlọ́gọ̀ ńlá, bí wọ́n ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sìn pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n ṣì wà pẹ̀lú wọn níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé láti mú kí Ìjọba Jèhófà di mímọ̀!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tún wo 1 Kọ́ríńtì 3:3, 4, 18, 19; 2 Kọ́ríńtì 11:13; Gálátíà 4:9; Éfésù 4:14, 15; Fílípì 3:18, 19; Kólósè 2:8; 1 Tẹsalóníkà 3:5; 2 Tẹsalóníkà 2:1-3; 1 Tímótì 6:3-5; 2 Tímótì 2:17; 4:3, 4; Títù 1:13, 14; 3:10; Hébérù 10:26, 27.
b Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Ìṣe 26:10, NW.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 43]
Àwọn ohun wọ̀nyí tó fi hàn pé ìjọsìn òrìṣà gbilẹ̀ wà ní Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Pergamon tó wà ní Berlin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 45]
Wọ́n fi mánà díẹ̀ pa mọ́ sínú àpótí májẹ̀mú. Fífún tí Jésù fún ẹni àmì òróró tó ṣẹ́gun ní mánà ìṣàpẹẹrẹ tó wà nípamọ́ túmọ̀ sí pé ẹni náà rí àìleèkú gbà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 45]
Àwọn tó bá máa wọlé síbi ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ni òkúta róbótó funfun náà wà fún