Orí 37
Ọ̀fọ̀ àti Ayọ̀ Nígbà Ìparun Bábílónì
1. Báwo ni “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” yóò ṣe ṣe nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run lójijì?
ÌRÒYÌN AYỌ̀ ni ìparun Bábílónì máa jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà, ṣùgbọ́n báwo ló ṣe máa rí lára àwọn orílẹ̀-èdè? Jòhánù sọ fún wa pé: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé tí wọ́n bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú yóò sunkún, wọn yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn lórí rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá wo èéfín ìjóná rẹ̀, bí wọ́n ti dúró ní òkèèrè nítorí ìbẹ̀rù wọn fún ìjoró rẹ̀, tí wọ́n sì wí pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, ìwọ ìlú ńlá títóbi, Bábílónì ìwọ ìlú ńlá alágbára, nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’”—Ìṣípayá 18:9, 10.
2. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ tó wà lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ló pa Bábílónì Ńlá run, kí nìdí tí “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” fi banú jẹ́ pé ó pa run? (b) Kí nìdí tí àwọn ọba tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò fi dúró ní òkèèrè sí ìlú tó ń pa run lọ náà?
2 Ó jọ pé báwọn orílẹ̀-èdè ṣe máa ṣe yìí yani lẹ́nu nítorí pé ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ tó wà lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ló pa Bábílónì run. (Ìṣípayá 17:16) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Bábílónì bá ti pa run, ó dájú pé “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” yóò wá mọ̀ bó ṣe wúlò tó fún wọn nínú pípẹ̀tù sọ́kàn àwọn èèyàn àti mímú káwọn èèyàn wà nítẹríba. Àwùjọ àlùfáà ti polongo pé àwọn ogun jẹ́ mímọ́, wọ́n ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbanisíṣẹ́, wọ́n sì ti fi ìwàásù kó àwọn èwe lọ sí ojú ogun. Nítorí pé àwọn èèyàn ka ìsìn sí ohun mímọ́, òun làwọn alákòóso oníwà ìbàjẹ́ fi ń ṣe bojúbojú láti máa ni àwọn aláìní lára. (Fi wé Jeremáyà 5:30, 31; Mátíù 23:27, 28.) Àmọ́, kíyè sí i pé àwọn ọba tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò yìí dúró ní òkèèrè réré sí ìlú tó ń pa run lọ yìí. Wọn kò sún mọ́ ọn dépò tí wọ́n fi lè ràn án lọ́wọ́. Inú wọn bà jẹ́ pé ó ń lọ ṣùgbọ́n inú wọn kò bà jẹ́ dépò tí wọ́n á fi fẹ̀mí ara wọn wewu nítorí rẹ̀.
Àwọn Oníṣòwò Ń Sunkún Wọ́n sì Ń Ṣọ̀fọ̀
3. Ta ni ẹlòmíràn tó tún kẹ́dùn ìparun tó dé bá Bábílónì Ńlá, àwọn ohun wo sì ni Jòhánù sọ pé ó fà ìkẹ́dùn náà?
3 Kì í ṣe àwọn ọba ilẹ̀ ayé nìkan ni ìbànújẹ́ máa bá nítorí ìparun Bábílónì Ńlá. Jòhánù tún sọ fún wa pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn olówò arìnrìn-àjò ilẹ̀ ayé ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé kò sí ẹnì kankan láti ra ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹrù ọjà wọn mọ́, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹrù ọjà wúrà àti fàdákà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti aláwọ̀ àlùkò àti aṣọ ṣẹ́dà àti rírẹ̀dòdò; àti ohun gbogbo tí ó wá láti inú igi olóòórùn dídùn àti gbogbo onírúurú ohun tí a fi eyín erin ṣe àti gbogbo onírúurú ohun tí a fi igi tí ó ṣeyebíye jù lọ ṣe àti ti bàbà àti ti irin àti ti òkúta mábìlì; pẹ̀lúpẹ̀lù, igi sínámónì àti èròjà atasánsán ti Íńdíà àti tùràrí àti òróró onílọ́fínńdà àti oje igi tùràrí àti wáìnì àti òróró ólífì àti ìyẹ̀fun kíkúnná àti àlìkámà àti àwọn màlúù àti àgùntàn, àti àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àwọ́rìn àti ẹrú àti ọkàn ẹ̀dá ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni, èso àtàtà tí ọkàn rẹ fẹ́ ti lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ [ìyẹn Bábílónì Ńlá], àti gbogbo ohun ẹlẹ́wà oge àti àwọn ohun mèremère ti ṣègbé kúrò lọ́wọ́ rẹ, àwọn ènìyàn kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.”—Ìṣípayá 18:11-14.
4. Kí nìdí tí “àwọn olówò arìnrìn-àjò” fi sunkún tí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ìparun Bábílónì Ńlá?
4 Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àti oníbàárà gidi ni Bábílónì Ńlá jẹ́ fún àwọn olówò tó rí já jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ilé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣàkójọ ọ̀pọ̀ jaburata wúrà, fàdákà, àtàwọn òkúta iyebíye, àwọn pákó oníyebíye, àtàwọn oríṣi ohun èlò olówó gọbọi mìíràn láwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá sẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, ìsìn máa ń gbàdúrà sórí ọjà táwọn èèyàn máa ń rà yàlàyàlà àti ìmukúmu ọtí tó máa ń wáyé nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì tí ń tàbùkù sí Kristi àtàwọn ayẹyẹ mìíràn tí wọ́n ń pè ní ọjọ́ mímọ́. Àwọn míṣọ́nárì ṣọ́ọ̀ṣì ti lọ sí àwọn ilẹ̀ jíjìnnà réré, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí káràkátà ṣeé ṣe fún “àwọn olówò arìnrìn-àjò” ayé yìí. Ìsìn Kátólíìkì táwọn oníṣòwò mú wá sílẹ̀ Japan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún lọ́wọ́ sí ogun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ń ròyìn ìjà àjàmọ̀gá kan tí wọ́n jà níbi ògiri àwọn ilé olódi ìlú Osaka ní Japan, ó ní: “Àwọn ọ̀tá táwọn ọmọ ogun Tokugawa ń bá jà gbé àwọn àsíá dání, àwọn ohun tó sì wà lára àwọn àsíá náà ni àwòrán àgbélébùú, àwòrán ère Olùgbàlà àti ti Jákọ́bù Mímọ́ tó jẹ́ baba ìsàlẹ̀ ilẹ̀ Sípéènì.” Àwọn ọmọ ogun Tokugawa tó ṣẹ́gun nínú ìjà náà ṣenúnibíni sáwọn Kátólíìkì wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ìsìn Kátólíìkì dàwátì ní Japan. Lóde òní pẹ̀lú, ṣọ́ọ̀ṣì kò ní rí àǹfààní kankan nínú kíkópa tó ń kópa nínú àwọn ọ̀ràn ayé.
5. (a) Báwo ni ohùn tó dún láti ọ̀run ṣe ṣàpèjúwe síwájú sí i nípa bí “àwọn olówò arìnrìn-àjò” yóò ṣe ṣọ̀fọ̀? (b) Kí nìdí táwọn olówò pẹ̀lú fi “dúró ní òkèèrè”?
5 Ohùn tó dún láti ọ̀run sọ síwájú sí i pé: “Àwọn olówò arìnrìn-àjò nǹkan wọ̀nyí, tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ láti ara rẹ̀, yóò dúró ní òkèèrè nítorí ìbẹ̀rù wọn fún ìjoró rẹ̀, wọn yóò sì sunkún, wọn yóò sì ṣọ̀fọ̀, ní sísọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o—ìlú ńlá títóbi náà, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò, tí a sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti péálì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì, nítorí pé ní wákàtí kan irúfẹ́ ọrọ̀ ńláǹlà bẹ́ẹ̀ ni a ti pa run di ahoro!’” (Ìṣípayá 18:15-17a) Nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, “àwọn olówò” á ṣọ̀fọ̀ nítorí pé wọ́n ti pàdánù alájọṣòwò wọn. Lóòótọ́, “ó mà ṣe o, ó mà ṣe o” fún wọn. Àmọ́, ṣàkíyèsí pé èrè ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀, àti pé bíi ti àwọn ọba, àwọn náà “dúró ní òkèèrè.” Wọn kò sún mọ́ tòsí rárá débi tí wọ́n á fi lè ṣèrànwọ́ èyíkéyìí fún Bábílónì Ńlá.
6. Báwo ni ohùn tó wá láti ọ̀run ṣe ṣàpèjúwe bí àwọn ọ̀gákọ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun ṣe máa ṣọ̀fọ̀, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń sunkún?
6 Ohùn tó dún láti ọ̀run náà ń bá a lọ láti sọ pé: “Àti olúkúlùkù ọ̀gákọ̀ àti olúkúlùkù ènìyàn tí ń rìnrìn àjò lójú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ àti gbogbo àwọn tí ń rí oúnjẹ òòjọ́ wọn nípasẹ̀ òkun, dúró ní òkèèrè, wọ́n sì ké jáde bí wọ́n ti wo èéfín láti inú ìjóná rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Ìlú ńlá wo ni ó dà bí ìlú ńlá títóbi náà?’ Wọ́n sì da ekuru sí orí ara wọn, wọ́n sì ké jáde, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o—ìlú ńlá títóbi náà, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó ní ọkọ̀ ojú omi lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nítorí ìgbówólórí rẹ̀, nítorí pé ní wákàtí kan, a ti pa á run di ahoro!’” (Ìṣípayá 18:17b-19) Bábílónì ìgbàanì jẹ́ ìlú olówò ńlá ó sì ní ọ̀pọ̀ ọkọ̀ òkun. Lọ́nà kan náà, Bábílónì Ńlá ń ṣòwò púpọ̀ nípasẹ̀ “omi púpọ̀,” ìyẹn àwọn èèyàn rẹ̀. Èyí pèsè iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ìsìn rẹ̀. Ẹ wo irú àjálù tí ìparun Bábílónì Ńlá yóò mú bá ètò ìṣòwò àwọn èèyàn yẹn! Láéláé, wọn ò ní rí ibòmíràn tí á máa mú owó ìgbọ́bùkátà wọlé wá fún wọn bíi ti Bábílónì Ńlá.
Yíyọ̀ Lórí Ìparun Rẹ̀
7, 8. Báwo ni ohùn tó wá láti ọ̀run ṣe parí ìkéde rẹ̀ nípa Bábílónì Ńlá, àwọn wo sì ni inú wọn á dùn gẹ́gẹ́ bí ohùn náà ti rọ̀ wọ́n?
7 Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà táwọn ará Mídíà àti Páṣíà bá bi Bábílónì ìgbàanì ṣubú, “dájúdájú, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde lórí Bábílónì.” (Jeremáyà 51:48) Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá pa Bábílónì Ńlá run, ohùn tó wá láti ọ̀run náà yóò parí ìkéde rẹ̀, yóò sọ nípa Bábílónì Ńlá pé: “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run, pẹ̀lúpẹ̀lù ẹ̀yin ẹni mímọ́ àti ẹ̀yin àpọ́sítélì àti ẹ̀yin wòlíì, nítorí pé Ọlọ́run ti fi ìyà jẹ ẹ́ fún yín lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ mu!” (Ìṣípayá 18:20) Inú Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ yóò dùn láti rí ìparun ọ̀tá rẹ̀ àtọjọ́mọ́jọ́. Àwọn tí inú wọn tún má dùn ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn wòlíì tí wọ́n wà lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ti jí dìde báyìí kálukú wọn sì ti wà ní ipò tirẹ̀ nínú ìṣètò alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà.—Fi wé Sáàmù 97:8-12.
8 Ní tòótọ́, gbogbo “ẹni mímọ́,” yálà àwọn tá a ti jí dìde sí ọ̀run tàbí àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé yóò yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn tó ń bá wọn kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú yóò yọ̀ ṣẹ̀sẹ̀. Nígbà tó bá yá, gbogbo àwọn olóòótọ́ èèyàn ìgbà àtijọ́ la óò jí dìde sínú ètò àwọn nǹkan tuntun, àwọn pẹ̀lú yóò sì dara pọ̀ nínú ayọ̀ náà. Àwọn èèyàn Ọlọ́run kò gbìyànjú láti gbẹ̀san lára àwọn onísìn èké tó ń ṣenúnibíni sí wọn. Wọ́n rántí ọ̀rọ̀ Jèhófà pé: “Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.” (Róòmù 12:19; Diutarónómì 32:35, 41-43) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà máa gbẹ̀san. Á gbẹ̀san gbogbo ẹ̀jẹ̀ tí Bábílónì Ńlá ti ta sílẹ̀.
Ó Fi Ọlọ Ńlá Kan Sọ̀kò
9, 10. (a) Kí ni áńgẹ́lì alágbára kan ṣe tó sì sọ? (b) Nígbà ayé Jeremáyà, ohun wo ló wáyé tó jọ èyí tí áńgẹ́lì alágbára náà ṣe nínú Ìṣípayá 18:21, kí sì ni èyí mú dáni lójú? (d) Áńgẹ́lì alágbára tí Jòhánù rí ṣe nǹkan kan, kí ni nǹkan tó ṣe náà mú dáni lójú?
9 Ohun tí Jòhánù rí tẹ̀ lé e mú un dáni lójú pé ìdájọ́ Jèhófà lórí Bábílónì Ńlá jẹ́ àṣekágbá, ó ní: “Áńgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dà bí ọlọ ńlá sókè, ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun, ó wí pé: ‘Lọ́nà kan náà, pẹ̀lú ìgbésọnù yíyára ni a ó fi Bábílónì ìlú ńlá títóbi náà sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.’” (Ìṣípayá 18:21) Nígbà ayé Jeremáyà, ohun kan tó jọ èyí ṣẹlẹ̀, ohun náà sì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ lágbára. Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti kọ “gbogbo ìyọnu àjálù tí yóò já lu Bábílónì” sínú ìwé kan. Lẹ́yìn náà, Jeremáyà fi ìwé náà fún Seráyà ó sì sọ fún un pé kó rìnrìn àjò lọ sí Bábílónì. Seráyà tẹ̀ lé ohun tí Jeremáyà sọ fún un, ó ka ìkéde tó wà nínú ìwé náà lòdì sí ìlú Bábílónì pé: “Jèhófà, ìwọ fúnra rẹ ti sọ̀rọ̀ lòdì sí ibí yìí, láti ké e kúrò tí kò fi ní sí olùgbé kankan nínú rẹ̀, yálà èèyàn tàbí ẹran agbéléjẹ̀ pàápàá, ṣùgbọ́n kí ó lè di ahoro lásánlàsàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lẹ́yìn náà, Seráyà so òkúta kan mọ́ ìwé náà ó sì jù ú sínú odò Yúfírétì, ó wí pé: “Báyìí ni Bábílónì yóò ṣe rì wọlẹ̀, tí kì yóò sì dìde mọ́ nítorí ìyọnu àjálù tí èmi yóò mú wá sórí rẹ̀.”—Jeremáyà 51:59-64.
10 Jíju ìwé náà pẹ̀lú òkúta tá a so mọ́ ọn sínú odò jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Bábílónì yóò di ìgbàgbé, tí kì yóò padà bọ̀ sípò mọ́ láé. Rírí tí àpọ́sítélì Jòhánù rí áńgẹ́lì alágbára kan tó ṣe ohun kan náà yìí jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún Bábílónì Ńlá yóò ní ìmúṣẹ. Ipò ìparun pátápátá tí Bábílónì ìgbàanì wà lónìí jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé ohun kan náà máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké láìpẹ́.
11, 12. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni áńgẹ́lì alágbára náà sọ sí Bábílónì Ńlá? (b) Kí ni Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà, àpẹẹrẹ wo ló sì jẹ́ fún àkókò wa yìí?
11 Wàyí o, áńgẹ́lì alágbára sọ̀rọ̀ sí Bábílónì Ńlá, ó ní: “Àti ìró àwọn akọrin tí ń lo háàpù sí orin wọn àti ti àwọn olórin àti ti àwọn onífèrè àti ti àwọn afunkàkàkí ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé, àti oníṣẹ́ ọnà iṣẹ́ ọwọ́ èyíkéyìí ni a kì yóò tún rí nínú rẹ mọ́ láé, àti ìró ọlọ kankan ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé, àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà kankan kì yóò tún tàn nínú rẹ mọ́ láé, àti ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé; nítorí pé àwọn ọkùnrin onípò gíga jù lọ ilẹ̀ ayé ni àwọn olówò arìnrìn-àjò rẹ, nítorí pé a ti ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìbẹ́mìílò rẹ.”—Ìṣípayá 18:22, 23.
12 Àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ èyí tá a kà lókè yìí ni Jeremáyà fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà, ó ní: “Ìró ayọ̀ ńláǹlà àti ìró ayọ̀ yíyọ̀, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ìró ọlọ ọlọ́wọ́ àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà sì ni èmi yóò pa run kúrò nínú wọn. Gbogbo ilẹ̀ yìí yóò sì di ibi ìparundahoro, ohun ìyàlẹ́nu.” (Jeremáyà 25:10, 11) Ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá pàtàkì nínú Bábílónì Ńlá yóò di ahoro láìsí olùjọsìn, bí ipò ahoro tí Jerúsálẹ́mù wà lẹ́yìn ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó ti ń fi ìgbà kan rí yọ̀ tí ariwo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn sì ń gba ibẹ̀ kan lójoojúmọ́ yóò wá di èyí tá a ṣẹ́gun tá a sì pa tì.
13. Ìyípadà wo ni yóò dé bá Bábílónì Ńlá lójijì, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde èyí fún “àwọn olówò arìnrìn-àjò” rẹ̀?
13 Dájúdájú, bí áńgẹ́lì náà ti sọ fún Jòhánù, àyípadà yóò bá Bábílónì Ńlá látòkèdélẹ̀. Láti ipò tó wà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ọba alágbára tó wà jákèjádò ayé, yóò di ahoro bí aṣálẹ̀. “Àwọn olówò arìnrìn-àjò” rẹ̀, títí kan àwọn olówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti lo ìsìn Bábílónì Ńlá fún àǹfààní ara wọn tàbí kí wọ́n fi ṣe bojúbojú, àwọn àlùfáà sì tìtorí èrè wọ àjọṣe pẹ̀lú àwọn wọ̀nyí láti di olókìkí bíi tiwọn. Ṣùgbọ́n Bábílónì Ńlá kò ní ran àwọn olówò wọ̀nyẹn lọ́wọ́ mọ́ nínú iṣẹ́ ibi wọn. Kò ní ṣeé ṣe fún Bábílónì Ńlá mọ́ láti máa fi àwọn àṣà awo tó wà nínú ìsìn rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ.
Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ Tó Búburú Jáì
14. Kí ni áńgẹ́lì alágbára náà sọ pé ó fà á tí ìdájọ́ Jèhófà fi le tó bẹ́ẹ̀, kí sì ni ohun tí Jésù sọ tó jọ ọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé?
14 Ní ìparí, áńgẹ́lì alágbára náà sọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe ìdájọ́ Bábílónì Ńlá lọ́nà tó le koko bẹ́ẹ̀. Áńgẹ́lì náà wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn ní Jerúsálẹ́mù pé wọn yóò jíhìn fún “gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí a ti ta sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé . . . [bẹ̀rẹ̀] láti ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì olódodo” lọ. Bó ṣe sọ, ìran èèyàn oníwà wíwọ́ yẹn pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. (Mátíù 23:35-38) Lónìí, ìran èèyàn mìíràn, ìyẹn àwọn onísìn, jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
15. Báwo ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nígbà ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lọ́nà méjì?
15 Nínú ìwé ọ̀gbẹ́ni Guenter Lewy tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Catholic Church and Nazi Germany, ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò ní Bavaria ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù April ọdún [1933], Ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́ àti Ìsìn gbé fún un, pé kó máa sọ tó bá rí ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀ya ìsìn náà tó ṣì ń ṣe ìsìn tí wọ́n kà léèwọ̀ náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì pẹ̀lú jẹ̀bi títi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́; ọrùn rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pa wà. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, irú bí Wilhelm Kusserow, fi hàn pé ẹ̀rù ò ba àwọn láti kú ikú ìbọn látọwọ́ àwọn àgbájọ ọmọ ogun, Hitler pinnu pé fífi ẹ̀yìn àwọn tó kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tóun fẹ́ tàgbá kò burú tó; nítorí náà, wọ́n fi ẹ̀rọ bẹ́ Wolfgang àbúrò Wilhelm lórí lọ́mọ ogún ọdún. Lákòókò yẹn kan náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń fún àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Jámánì tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì níṣìírí láti kú nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ baba wọn. Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó wà lọ́rùn ṣọ́ọ̀ṣì mà hàn kedere sí gbogbo ayé o!
16, 17. (a) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wo ni Jèhófà yóò kà sí Bábílónì Ńlá lọ́rùn, báwo sì ni àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn Júù tí wọ́n kú nínú ìpakúpa rẹpẹtẹ látọwọ́ ìjọba Násì? (b) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ìsìn èké gbà jẹ̀bi ikú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun tó jà lóde òní nìkan?
16 Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ọrùn Bábílónì Ńlá ni Jèhófà yóò ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí [wọ́n] ti pa lórí ilẹ̀ ayé” sí. Dájúdájú, ìyẹn ti já sí òótọ́ lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ètò ìmùlẹ̀ Kátólíìkì ran Hitler lọ́wọ́ láti dé orí àlééfà ìjọba ilẹ̀ Jámánì, a jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì náà nípìn-ín nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ odindi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù tí àwọn Násì pa nípakúpa. Síwájú sí i, lóde òní nìkan, ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ tí wọ́n ti pa nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun. Ṣé ìsìn èké la máa dá lẹ́bi èyí? Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà méjì.
17 Ọ̀nà kan ni pé ọ̀pọ̀ ogun tó wáyé jẹ́ nítorí àwọn aáwọ̀ ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, ìsìn ló dá ìjà sílẹ̀ nílẹ̀ Íńdíà láàárín àwọn Mùsùlùmí àti Híńdù lọ́dún 1946 sí 1948. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí ló ṣòfò. Aáwọ̀ ẹ̀ya ìsìn ló sì fa ìforígbárí láàárín orílẹ̀-èdè Iraq àti Iran ní àwọn ọdún 1980, tí wọ́n sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Ìjà tó wáyé láàárín àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ní Northern Ireland ti gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Nígbà tí wọ́n ṣèwádìí káàkiri nípa ọ̀rọ̀ yìí, akọ̀ròyìn C. L. Sulzberger sọ ní 1976 pé: “Ó jẹ́ ohun tó bani nínú jẹ́, pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdajì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ogun tí wọ́n ń jà nísinsìnyí káàkiri ayé ló jẹ́ ogun ìsìn tàbí kó jẹ mọ́ aáwọ̀ àwọn ìsìn.” Bí Bábílónì Ńlá oníwàhálà sì ṣe ń ṣe látìgbà tó ti wà nìyẹn.
18. Ọ̀nà kejì wo ni àwọn ìsìn ayé gbà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?
18 Kí ni ọ̀nà kejì tí ìsìn gbà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀? Lójú Jèhófà, àwọn ìsìn ayé jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí pé wọn kò fi ohun náà gan-an tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́nà tó fi máa dá wọn lójú. Wọn kò kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà táwọn èèyàn fi máa gbà gbọ́ pé àwọn tí ń jọ́sìn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Míkà 4:3, 5; Jòhánù 13:34, 35; Ìṣe 10:34, 35; 1 Jòhánù 3:10-12) Nítorí pé àwọn ìsìn tí wọ́n para pọ̀ di Bábílónì Ńlá kò kọ́ni ní nǹkan wọ̀nyí, àwọn ọmọ ìjọ wọn kó sínú hílàhílo ogun làwọn orílẹ̀-èdè ayé. Ẹ wo bí èyí ti hàn gbangba tó nínú ogun àgbáyé méjèèjì tó wáyé ní ọ̀rúndún ogún, tí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí ìsìn Kristẹni ti gbilẹ̀ tó sì yọrí sí pípa tí àwọn onísìn kan náà ń pa ara wọn! Ì bá jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn ti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì ni, ogun wọ̀nyẹn kì bá ti wáyé rárá.
19. Ẹrù ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù wo ni Bábílónì Ńlá rù?
19 Jèhófà ka ẹ̀bi gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ yìí sọ́rùn Bábílónì Ńlá. Ká ní àwọn aṣáájú ìsìn, pàápàá jù lọ àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì, bá ti kọ́ àwọn èèyàn wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì ni, irú ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ kì bá tí wáyé. Nítorí náà, lọ́nà tó ṣe tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, Bábílónì Ńlá tí í ṣe aṣẹ́wó ńlá àti ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé gbọ́dọ̀ jíhìn fún Jèhófà, kì í ṣe nítorí “ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́” tó ti ṣe inúnibíni sí tó sì ti pa nìkan ni, àmọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí [wọ́n] ti pa lórí ilẹ̀ ayé.” Dájúdájú, Bábílónì Ńlá ti ru ẹrù ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù. À-kú-tún-kú ẹ̀ nígbà tí ìparun ẹ̀ ìkẹyìn bá dé!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 270]
Aburú Tí Ìgbagbẹ̀rẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Fà
Guenter Lewy kọ ìwé kan tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Catholic Church and Nazi Germany, ó sì sọ nínú ìwé rẹ̀ náà pé: “Ká ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ilẹ̀ Jámánì ti ta ko ìjọba Násì látìbẹ̀rẹ̀ ni, bóyá ohun tó ṣẹlẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀. Bí àtakò wọn ò tiẹ̀ borí Hitler tí kò sì dènà òbítíbitì ìwà ìkà tó hù, ì bá ti buyì kún Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gan-an. Ká sòótọ́, ẹ̀mí tí ì bá lọ sí irú àtakò bẹ́ẹ̀ ì bá pọ̀ gan-an, àmọ́ ìyẹn ì bá jẹ́ nítorí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ká ní Hitler rí i pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè òun ò ní ti òun lẹ́yìn ni, ó ṣeé ṣe kó má gbójúgbóyà láti lọ sógun, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó kú ì bá má sì kú. . . . Nígbà tí wọ́n dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n ta kò ìjọba Násì lóró títí tí wọ́n fi kú ní àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Hitler, nígbà tí wọ́n pa àwọn ọ̀mọ̀ràn ilẹ̀ Poland nípakúpa, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kú látàrí ṣíṣe tí wọ́n ṣe wọ́n ṣúkaṣùka nítorí pé wọ́n kà wọ́n sí Slavic Untermenschen, [ìyẹn ààbọ̀ èèyàn], nígbà tí wọ́n pa mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] èèyàn nítorí pé wọn ‘kì í ṣe ẹ̀yà Aryan,’ ńṣe làwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ní Jámánì ń ṣètìlẹyìn fún ìjọba Násì tó hu ìwà ìkà wọ̀nyí. Póòpù tó wà ní Róòmù náà ò sọ nǹkan kan nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ òun ni olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ẹni tó ga jù lọ lára àwọn tó ń kọ́ àwọn Kátólíìkì níwà rere.”—Ojú ìwé 320, 341.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 268]
“Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o,” ni àwọn alákòóso ń wí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 268]
“Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o,” ni àwọn olówò ń wí