Orí 62
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n kan Nipa Ìrẹ̀lẹ̀
LẸHIN mímú ọmọdekunrin ti o ni ẹmi-eṣu naa láradá ní ẹkùn-ilẹ̀ tí ó wà nítòsí Kesaria ti Filipi, Jesu fẹ́ lati pada wá sile ni Kapanaomu. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fẹ́ lati wà ní oun nikan pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ninu ìrìn àjò naa kí ó ba lè múra wọn sílẹ̀ siwaju sii fun ikú rẹ̀ ati awọn ẹrù-iṣẹ́ wọn lẹhin ìgbà naa. “A o fi Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] eniyan lé awọn eniyan lọwọ,” ni oun ṣàlàyé fun wọn, “wọn yoo sì pa á, ní ọjọ́ kẹta yoo sì jinde.”
Ani bí ó tilẹ jẹ́ pe Jesu ti sọ̀rọ̀ ṣaaju ìgbà naa nipa eyi, tí awọn apọsiteli mẹta niti tootọ sì rí ìparadà naa láàárín ìgbà tí wọn jíròrò “ìjádelọ” rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò lóye ọ̀ràn naa sibẹ. Bí ó tilẹ jẹ́ pe kò sí ẹnikan ninu wọn tí ó gbìyànjú lati sẹ́ pe a o pa á, bi Peteru ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀, wọn bẹ̀rù lati bi í ní ibeere siwaju sí i nipa rẹ̀.
Nígbẹ̀hin gbẹ́hin wọn dé sí Kapanaomu, ibi tí ó ti jẹ́ irú ibujokoo kan nigba iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu. Ó tún jẹ́ ìlú Peteru ati ti melookan ninu awọn apọsiteli. Nibẹ, awọn ọkunrin tí ńgba owó-orí tẹmpili wá sọ́dọ̀ Peteru. Boya wọn ńgbìyànjú lati fẹsunkan Jesu pe kò fiyèsí àṣà kan tí a tẹ́wọ́gbà, wọn beere pe: “Olùkọ́ yin kò ha ńsan owó-orí dirakima meji [ti tẹmpili] bí?”
“Bẹẹni,” ni Peteru dáhùnpadà.
Jesu, ẹni tí ó ti lè dé ilé kété lẹhin naa, mọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Nitori naa kódà ṣaaju kí Peteru tó pe àfiyèsí sí ọ̀ràn naa, Jesu beere pe: “Ki ni iwọ rò, Simoni? Lọwọ ta ni awọn ọba ilẹ̀-ayé ti ńgba owó-bodè tabi owó-orí? Ọwọ́ awọn ọmọ [“ọmọkunrin,” NW] tabi ọwọ́ awọn àjèjì?”
“Ọwọ́ awọn àjèjì,” ni Peteru dahun.
“Nitootọ, nigba naa awọn ọmọ [“ọmọkunrin,” NW] bọ́ ninu sísan owó-orí,” ni Jesu ṣàlàyé. Niwọn bi Baba Jesu ti jẹ́ Ọba àgbáyé, Ẹni tí a ńjọ́sìn ní tẹmpili, kii ṣe ohun abèèré fun tí ó bófinmu nitootọ fun Ọmọkunrin Ọlọrun lati san owó-orí ni tẹmpili naa. “Ṣugbọn kí a ma baa mú wọn kọsẹ̀,” ni Jesu wí, “iwọ lọ sí òkun, ju ìwọ̀-apẹja kan sínú òkun, kí o sì mú ẹja ekinni tí ó gòke, nigba ti o bá sì ya ẹnu rẹ̀, iwọ yoo rí ẹyọ-owo sitata kan [owó dirakima mẹrin]. Mú eyiini kí o sì fifún wọn temi ati tìrẹ.”
Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin péjọ pọ̀ lẹhin ipadabọ wọn sí Kapanaomu, boya ní ilé Peteru, wọn beere pe: “Nitootọ ta ni ó tóbi jùlọ ninu ijọba awọn ọrun?” Jesu mọ ohun naa tí ó ru ibeere wọn sókè, ní mimọ ohun tí ó ńlọ láàárín wọn bí wọn ti ntẹle e lẹhin nigba ti wọn npada bọ lati Kesaria ti Filipi. Nitori naa ó beere pe: “Ki ni ohun tí ẹyin ńbá araayin jiyàn sí ní ọ̀nà?” Bí ìtìjú ti bá wọn, awọn ọmọ-ẹhin naa dákẹ́, nitori wọn ti jiyàn láàárín araawọn lórí ẹni tí ó tóbi jùlọ.
Lẹhin eyi tí ó fẹrẹẹ tó ọdun mẹta ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jesu, ó ha jẹ́ ohun tí kò ṣeé gbàgbọ́ pe awọn ọmọ-ẹhin naa yoo tún ní irúfẹ́ ìjiyàn kan bẹẹ? Ó dára, ó ṣípayá agbára ìdarí lílágbára ti àìpé ẹ̀dá-ènìyàn, ati pẹlu ìpìlẹ̀ ti ìsìn. Ìsìn awọn Juu ninu eyi tí a ti tọ́ awọn ọmọ-ẹhin naa dàgbà tẹnumọ́ ipò ati ipò ọ̀gá ninu gbogbo awọn ìbálò. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, boya Peteru nímọ̀lára ìlọ́lájù kan nitori ìlérí Jesu lati fun un ni “awọn kọ́kọ́rọ́” pàtàkì kan ti Ijọba naa. Jakọbu ati Johanu, pẹlu lè ti ní awọn èrò-ọkàn tí ó farajọra nitori pe a ti ṣojúrere sí wọn pẹlu ìṣẹ̀lẹ̀ ìparadà Jesu tí ó ṣojú wọn.
Ohun yoowu kí ọ̀ràn naa jẹ́, Jesu gbé àṣefihànni kan tí ńru ìmọ̀lára sókè kalẹ̀ ninu ìsapá lati ṣàtúnṣe ẹ̀mí-ìrònú wọn. Ó pe ọmọ kan, ó mú un dúró láàárín wọn, ó fi apá rẹ̀ kọ́ ọ mọ́ra, ó sì wipe: “Àyàfi bí ẹyin bá ṣẹ́rí padà kí ẹ sì dabi awọn ọmọ kéékèèké ẹyin kì yoo lè wọnú ijọba awọn ọ̀run lọnakọna. Nitori naa ẹni yoowu tí ó bá rẹ araarẹ̀ silẹ gẹgẹ bi ọmọ kekere yii ni ẹni naa tí ó tóbi jùlọ ninu ijọba awọn ọ̀run; ẹni yoowu tí ó bá sì gba irúfẹ́ ọmọ kekere bẹẹ lórí ìpìlẹ̀ orukọ mi gbà mí pẹlu.”
Ẹ wo ọ̀nà yíyanilẹ́nu lati fi tọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ́nà! Jesu kò bínú sí wọn kí ó sì pè wọn ní onírera, oníwọra, tabi olùlépa àṣeyọrí. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó ṣàpèjúwe ìkọ́ni rẹ̀ atọ́nisọ́nà nipa lílò awọn ọmọ kéékèèké, tí wọn jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà niti ànímọ́ wọn, tí wọn bọ́ lọwọ ìlépa àṣeyọrí, ati ní gbogbogboo tí wọn kò ní ìrònú nipa ipò ọ̀gá láàárín araawọn. Nipa bayii Jesu fihàn pe ó jẹ́ ọ̀ranyàn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati mú awọn ìwà kan naa yii dàgbà tí ó jẹ́ ànímọ́ awọn ọmọdé. Gẹgẹ bi Jesu ti pari ọrọ rẹ̀: “Ẹni tí ó bá hùwàdarí araarẹ̀ gẹgẹ bi ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yin ni ẹni naa tí ó tóbi.” Matiu 17:22-27; 18:1-5, NW; Maaku 9:30-37; Luuku 9:43-48, NW.
▪ Nigba tí wọn padà de Kapanaomu, ẹ̀kọ́ wo ni Jesu tún ṣe àsọtúnsọ rẹ̀, bawo ni a sì ṣe gbà á?
▪ Eeṣe tí kò fi jẹ́ ọranyan fun Jesu lati san owó-orí ni tẹmpili, ṣugbọn ki ni ìdí tí ó fi san án?
▪ Ki ni ó ṣeeṣe kí ó dákún ìjiyàn awọn ọmọ-ẹhin naa, bawo sì ni Jesu ṣe tọ́ wọn sọ́nà?