Apa 4
Ọlọrun Sọ Fun Wa Nipa Awọn Ete Rẹ̀
1, 2. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Ọlọrun pese awọn idahun fun awọn ti wọn fi otitọ ọkan beere?
ỌLỌRUN onifẹẹ kan niti tootọ ṣi awọn ete rẹ̀ paya fun awọn olotiitọ ọkan ti ń wa a kiri. Oun pese awọn idahun si awọn ibeere iru bii idi ti oun ti fi fayegba ijiya, fun awọn eniyan ti ń ṣe iwadii.
2 Bibeli ṣalaye pe: “Bi iwọ ba ṣafẹri [Ọlọrun], iwọ o ri i.” “Ọlọrun kan ń bẹ ni ọrun ti ń fi aṣiri han.” “Oluwa Ọba-alaṣẹ Jehofa ki yoo ṣe kiní kankan ayafi bi oun bá ti ṣi awọn ọran aṣiri rẹ̀ paya fun awọn iranṣẹ rẹ̀ wolii.”—1 Kronika 28:9; Danieli 2:28; Amosi 3:7, NW.
Nibo Ni Awọn Idahun naa Wà?
3. Nibo ni a ti lè ṣawari idi ti Ọlọrun fi fayegba ijiya?
3 Awọn idahun si awọn ibeere iru bii idi ti Ọlọrun fi fayegba ijiya ati ohun ti oun yoo ṣe nipa rẹ̀ ni a ri ninu akọsilẹ ti oun misi fun anfaani tiwa. Akọsilẹ yẹn ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli Mimọ. “Gbogbo iwe-mimọ ti o ni imisi Ọlọrun ni o si ni èrè fun ẹ̀kọ́, fun iba-ni-wi, fun ìtọ́ni, fun ìkọ́ni ti o wà ninu ododo, ki eniyan Ọlọrun ki o lè pé, ti a ti murasilẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timoteu 3:16, 17.
4, 5. Ki ni mu ki Bibeli jẹ iwe àrà-ọ̀tọ̀ kan?
4 Bibeli jẹ iwe àrà-ọ̀tọ̀ kan nitootọ. O ni itan ti o peye julọ nipa eniyan ninu o sì tun lọ jinna rekọja iṣẹda awọn eniyan. O tun ba akoko mu pẹlu, nitori pe awọn asọtẹlẹ rẹ̀ niiṣe pẹlu awọn iṣẹlẹ ìgbà tiwa ati ti ọjọ iwaju ti kò jinna pẹlu.
5 Kò tun si iwe miiran ti o ni awọn ẹ̀rí itootun fun itan pipeye bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, kiki iwọnba iwe àdàkọ alafọwọkọ melookan ti awọn akọsilẹ awọn onkọwe olokiki ti ìgbà atijọ ni o wà. Sụgbọn awọn iwe àdàkọ alafọwọkọ ti Bibeli, òmíràn jẹ́ apakan ti awọn miiran si jẹ odindi, ni wọn wà: nǹkan bii 6,000 ti awọn Iwe Mimọ lede Heberu (awọn iwe 39 ti “Majẹmu Laelae”) ati nǹkan bii 13,000 ti awọn Iwe Mimọ Kristian lede Griki (awọn iwe 27 ti “Majẹmu Titun”).
6. Eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe Bibeli ti oni jẹ ọkan-naa ni pataki gẹgẹ bi ti ìgbà ti Ọlọrun mi si i?
6 Ọlọrun Olodumare, ti o misi Bibeli, ti ri si i pe iwatitọ awọn ọ̀rọ̀ inu rẹ̀ ni a pamọ laiyingin ninu awọn ẹ̀dà iwe àdàkọ alafọwọkọ wọnni. Nitori naa awọn Bibeli wa lonii jẹ ọkannaa nipataki pẹlu ti awọn akọsilẹ onimisi ti ipilẹsẹ. Koko miiran ti o ṣeranwọ fun wa lati mọriri eyi ni pe awọn ẹ̀dà awọn Iwe Mimọ Kristian lede Griki kan rìn jinna sẹhin to ohun ti kò ju ọgọrun-un ọdun kan si akoko ti awọn akọsilẹ ipilẹṣẹ. Iwọnba awọn àdàkọ alafọwọkọ ti awọn onkọwe olokiki ti atijọ ti o ṣi wà kii saba rin jinna sẹhin to ani ọpọ ọrundun melookan si ti awọn onkọwe ipilẹsẹ.
Ẹbun Ọlọrun
7. Bawo ni ipinkiri Bibeli ti gbooro to?
7 Bibeli jẹ iwe ti a tíì pinkiri julọ ninu itan. Nǹkan bii aadọta ọkẹ lọna aadọta ọkẹ lọna mẹta ni a ti tẹjade. Kò si iwe miiran ti o sunmọ iye yẹn. Bibeli tabi apakan rẹ̀ sì ni a ti tumọ si nǹkan bi 2,000 ede. Nipa bayi, a diwọn rẹ̀ pe Bibeli wà larọọwọto ipin 98 ninu ọgọrun-un iye awọn olugbe planẹti wa.
8-10. Ki ni awọn idi diẹ ti Bibeli fi yẹ fun ayẹwo wa?
8 Dajudaju iwe kan ti o sọ pe oun wá lati ọdọ Ọlọrun ti o sì ni awọn ẹri ijotitọ ninu ati lode yẹ fun ayẹwo wa.a O ṣalaye ete iwalaaye, itumọ awọn ipo ayé, ati ohun ti ọjọ iwaju ni nipamọ. Kò si iwe miiran ti o lè ṣe iyẹn.
9 Bẹẹni, Bibeli jẹ ibanisọrọpọ lati ọdọ Ọlọrun si idile eniyan. Oun dari kikọ akọsilẹ rẹ̀ nipasẹ agbara agbekankan ṣiṣẹ, tabi ẹmi mimọ rẹ̀, pẹlu nǹkan bi 40 eniyan ti ń ṣe kikọ rẹ̀. Nipa bayii Ọlọrun ń bá wa sọrọ nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli Mimọ. Aposteli Paulu kọwe pe: “Nigba ti ẹyin gba ọ̀rọ̀ ti ẹyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ẹyin kò gba a bi ẹni pe ọ̀rọ̀ eniyan, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitootọ, bi ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”—1 Tessalonika 2:13.
10 Abraham Lincoln, aarẹ 16 ti orilẹ-ede United States, pe Bibeli ni “ẹbun didara julọ ti Ọlọrun tíì fi fun eniyan rí . . . Laikò si i a kìbá tí mọ rere yatọ si buburu.” Nisinsinyi nigba naa, ki ni ẹbun titayọ julọ yii sọ fun wa nipa bi ijiya ṣe bẹrẹ, idi ti Ọlọrun fi fayegba a, ati ohun ti oun yoo ṣe nipa rẹ̀?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun iṣọfunni ni kikun nipa ijotitọ Bibeli, wo iwe naa The Bible—God’s Word or Man’s?, ti a tẹjade ni 1989 lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bibeli, ti o ni imisi Ọlọrun, jẹ ibanisọrọpọ rẹ̀ si idile eniyan