Ìwé Yìí Ha Fohùn Ṣọ̀kan Pẹ̀lú Sáyẹ́ǹsì Bí?
Ìsìn kò tí ì f ìgbà gbogbo ka sáyẹ́ǹsì sí ọ̀rẹ́ òun. Nínú àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ta ko àwọn àwárí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu nígbà tí wọ́n rò pé ìwọ̀nyí fi àlàyé tí àwọn ṣe nípa Bíbélì sínú ewu. Ṣùgbọ́n, ṣé ọ̀tá Bíbélì ni sáyẹ́ǹsì jẹ́ ní tòótọ́?
KÁ NÍ àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ti fọwọ́ sí ojú ìwòye tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu, tí ó gbilẹ̀ nígbà ayé wọn ni, ìwé kan tí ó kún fọ́fọ́ fún àwọn àṣìṣe tí kò bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu ni ì bá ti jẹ́ àbájáde rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn òǹkọ̀wé náà kò gbé irú àwọn àṣìlóye tí kò bá ìlànà ṣáyẹ́ǹsì mu bẹ́ẹ̀ lárugẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn gbólóhùn tí kì í wulẹ̀ ṣe pé ó péye lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì nìkan ni, ṣùgbọ́n tí ó tún ta ko àwọn èròǹgbà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà nígbà náà lọ́hùn-ún pátápátá.
Kí Ni Ìrísí Ayé?
Ìbéèrè yẹn ti ru ẹ̀dá ènìyàn lọ́kàn sókè fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ojú ìwòye tí ó gbilẹ̀ ní ìgbàanì ni pé ilẹ̀ ayé tẹ́ pẹrẹsẹ. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé àgbáyé jẹ́ àpótí tàbí yàrá kan, tí ilẹ̀ ayé sì jẹ́ ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ rẹ̀. Àwọn àlùfáà ìsìn Híńdù àtijọ́ ní Íńdíà finú wòye pé ilẹ̀ ayé tẹ́ pẹrẹsẹ, àti pé, kìkì ìhà kan rẹ̀ ni a ń gbé. Ẹ̀yà àtijọ́ kan ní ilẹ̀ Éṣíà yàwòrán ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àtẹ kan tí a ń gbé tí ì sí.
Nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Tiwa, onímọ̀ èrò orí ará ilẹ̀ Gírí ìkì náà, Pythagoras, dá àbá èrò orí náà pé níwọ̀n bí òṣùpá àti oòrùn ti jẹ́ òbírí, ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ní láti jẹ́ òbírí. Aristotle (ti ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Tiwa) fara mọ́ èyí lẹ́yìn náà, ní ṣíṣàlàyé pé ẹ̀rí jíjẹ́ tí ilẹ̀ ayé jẹ́ òbírí máa ń hàn nígbà tí ilẹ̀ ayé bá ṣíji bo òṣùpá. Òjìji ilẹ̀ ayé lára òṣùpá jẹ́ èyí tí ó tẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, èrò nípa pé títẹ́ pẹrẹsẹ ni ilẹ̀ ayé wà (tí ó jẹ́ pé kìkì apá òkè rẹ̀ ni a ń gbé) kò pòórá tán. Àwọn kan kò lè fara mọ́ ìtumọ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu tí gbígbà pé róbótó ni ilẹ̀ ayé jẹ́ yóò ní—èròǹgbà ti antipodes.a Lactantius, tí ó jẹ́ agbèjà ìgbàgbọ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, fi èrò yí gan-an ṣẹ̀sín. Ó ṣàlàyé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ó kúrí tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gbà gbọ́ pé àwọn ènìyàn kan wà tí ipa ẹsẹ̀ wọ́n ga ju orí wọn lọ bí? . . . pé àwọn irúgbìn àti àwọn igi ń hù ní ìdoríkodò? pé òjò, àti òjò dídì, àti yìnyín ń já bọ́ láti ilẹ̀ lọ sókè?”2
Èròǹgbà antipodes fa ìṣòro fún àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn mélòó kan. Àwọn àbá èrò orí kan sọ pé bí àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìpẹ̀kun ìhà kejì ilẹ̀ ayé bá wà, wọn kò ní lè ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí a mọ̀ ì báà jẹ́ tìtorí pé òkun tí fẹ̀ jù láti lè tukọ̀ kọjá rẹ̀ tàbí tìtorí àgbègbè ilẹ̀ olóoru tí kò ṣeé gbà kọjá tí ó yí agbedeméjì ayé po. Nítorí náà, ibo ni àwọn ènìyàn tí ń gbé ìpẹ̀kun ìhà kejì ilẹ̀ ayé ì bá ti wá? Bí èyí tí pin wọ́n lẹ́mìí, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn mélòó kan yàn láti gbà gbọ́ pé kò lè sí àwọn tí ń gbé ní ìhà kejì ilẹ̀ ayé, tàbí kẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìjiyàn Lactantius, kò tilẹ̀ lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé òbírí ni ilẹ̀ ayé!
Síbẹ̀síbẹ̀, èròǹgbà ti pé òbírí ni ilẹ̀ ayé borí, níkẹyìn ó sì wá di èyí tí a tẹ́wọ́ gbà lọ́nà gbígbòòrò. Ṣùgbọ́n, kìkì ìgbà tí ayé di ayé lílọ sí gbalasa òfuurufú ní ọ̀rúndún ogún ni ó wá ṣeé ṣe fún ènìyàn láti rìnrìn àjò jìnnà lọ sí gbalasa òfuurufú tó bí ó ti yẹ láti lè wádìí ìjótìítọ́ èyí nípa rírí i ní tààràtà pé òbíríkítí ni ilẹ̀ ayé jẹ́.b
Ìhà wo sì ni Bíbélì wà nínú ọ̀ràn yí? Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Tiwa, nígbà tí ojú ìwòye tí ó gbòde jẹ́ ti pé pẹrẹsẹ ni ilẹ̀ ayé jẹ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí àwọn onímọ̀ èrò orí ti ilẹ̀ Gírí ìkì tó dá àbá pé ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ayé jẹ́ òbírí, àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí ẹ̀dá ènìyàn tó rí ilẹ̀ ayé ní òbíríkítí láti gbalasa òfuurufú, Aísáyà, wòlí ì Hébérù náà, sọ ọ́ lọ́nà tí ó rọrùn gidigidi pé: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 40:22) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà chugh, tí a túmọ̀ sí “òbìrìkìtì” níhìn-ín, ni a tún lè pè ní “òbírí.”3 Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míràn kà pé, “òbíríkítí ilẹ̀ ayé” (Douay Version) àti “ilẹ̀ ayé róbótó.”—Moffatt.c
Aísáyà, òǹkọ̀wé Bíbélì náà, yẹra fún ìtàn àròsọ tí ó wọ́pọ̀ nípa ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ gbólóhùn kan sílẹ̀ tí ìtẹ̀síwájú nínú àwárí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu kò ṣe ní ohunkóhun.
Kí Ní So Ilẹ̀ Ayé Rọ̀?
Ní ìgbà àtijọ́, àwọn ìbéèrè míràn nípa àgbáálá ayé pin ẹ̀dá ènìyàn lẹ́mìí, bíi: Orí kí ni ayé dúró lé? Kí ní so oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ rọ̀? Wọn kò ní ìmọ̀ nípa òfin òòfà àgbáyé, tí Isaac Newton gbé jáde tí a sì tẹ̀ jáde ní 1687. Wọn kò mọ̀ nípa èrò náà pé àwọn ìṣẹ̀dá ọ̀run so rọ̀ sójú òfuurufú láìtòrò mọ́ ohunkóhun. Nípa báyìí, àlàyé wọn sábà máa ń dábàá ti pé àwọn ohun àfojúrí tàbí àwọn nǹkan gidi kan ni ó so ilẹ̀ ayé àti àwọn ìṣẹ̀dá ọ̀run yòó kù rọ̀ sókè.
Fún àpẹẹrẹ, àbá èrò orí ìgbàanì kan, bóyá tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ní erékùṣù kan, ni pé omi ni ó yí ilẹ̀ ayé po àti pé ṣe ni ó léfòó lórí omi wọ̀nyí. Àwọn Híńdù ní in lọ́kàn pé ilẹ̀ ayé ní onírúurú ìpìlẹ̀, tí ọ̀kan wà lórí èkejì. Ó sinmi lé orí àwọn erin mẹ́rin, àwọn erin náà dúró lórí ìjàpá fàkìàfakia kan, ìjàpá náà dúró lórí ejò ràbàtà kan, ejò tí ó kájọ náà sì léfòó lórí omi àgbáyé. Alábàá-èrò-orí ará Gírí ìkì ti ọ̀rúndún karùn ún ṣáájú Sànmánì Tiwa náà, Empedocles, gbà gbọ́ pé ilẹ̀ ayé sinmi lé orí ìjì kan àti pé ìjì yí ni ó fa yíyí tí àwọn ìṣẹ̀dá ọ̀run ń yí.
Ojú ìwòye Aristotle wà lára àwọn èyí tí ó nípa lórí àwọn ènìyàn jù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá àbá èrò orí náà pé òbírí ni ilẹ̀ ayé jẹ́, kò jẹ́ gbà pé ó lè so rọ̀ sójú gbalasa òfuurufú tí ó ṣófo láé. Nínú ọ̀rọ̀ ìwé àkọyé rẹ̀, On the Heavens, nígbà tí ó ń já èròǹgbà náà pé ilẹ̀ ayé sinmi lé ojú omi ní koro, ó sọ pé: “Bí omi ṣe rí kò lè jẹ́ kí ó dá dúró láàárín afẹ́fẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ilẹ̀ ayé pẹ̀lú: ó ní láti ní ohun tí yóò dúró lé.”4 Nítorí náà, kí wá ni ilẹ̀ ayé “dúró lé”? Aristotle kọ́ni pé ṣe ni a de oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ mọ́ ojú àwọn àgbá tí ó fi òdì kejì hàn rekete. Àwọn àgbá náà ni a sì kì bọ inú ara wọn, tí ilẹ̀ ayé sì wà—lójú kan ṣoṣo—ní àárín gbùngbùn rẹ̀. Bí àwọn àgbá náà ṣe ń yípo nínú ìkíní-kejì, àwọn ohun tí ó wà lára wọn—oòrùn, òṣùpá, àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì—ń yí kọjá ní ojú òfuurufú.
Àlàyé Aristotle dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu ní ìgbà yẹn. Ká ní kì í ṣe pé a de àwọn ẹ̀dá ọ̀run pinpin mọ kiní kan ni, ọ̀nà wo tún ni wọ́n fi lè wà ní sísorọ̀? Ojú ìwòye wọ̀nyí tí Aristotle, tí a bọ̀wọ̀ fún, ní ni a tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí òkodoro òtítọ́ fún nǹkan bí 2,000 ọdún. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, ṣe sọ, ní àwọn ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ikẹtàdínlógún, lójú ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ “ga dé ipò ẹ̀kọ́ tí ìsìn fàṣẹ sí.”5
Nígbà tí a wá hùmọ̀ awò awọ̀nàjíjìn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìbéèrè dìde sí àbá èrò orí ti Aristotle. Síbẹ̀ náà, wọ́n wá ojútùú tì títí tí Alàgbà Isaac Newton fi ṣàlàyé pé ṣe ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì so rọ̀ sójú gbalasa òfuurufú tí ó ṣófo, tí agbára tí a kò lè fojú rí kan—agbára òòfà—sì so wọ́n rọ̀ sí òpó ìrìnnà wọn. Ó dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́, ó sì ṣòro láti gbà gbọ́ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ Newton pé gbalasa òfuurufú lè ṣófo, kí èyí tí ó pọ̀ jù nínú rẹ̀ wà lófo láìní ohunkóhun nínú.d6
Kí ni Bíbélì ní láti sọ lórí ìbéèrè yí? Ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 3,500 ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tí ó yéni lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ pé ilẹ̀ ayé so “rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Nínú èdè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tí a lò fún “òfo” (beli-mahʹ) ní ṣangiliti túmọ̀ sí “láìsí ohunkóhun.”7 Bíbélì Contemporary English Version lo gbólóhùn náà, “sórí gbalasa òfuurufú tí ó ṣófo.”
Àwòrán tí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ ní àwọn ọjọ́ náà lọ́hùn-ún ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé kì í ṣe ti wí pé ó jẹ́ pílánẹ́ẹ̀tì kan tí ó so rọ̀ “sórí gbalasa òfuurufú tí ó ṣófo” rárá. Síbẹ̀, òǹkọ̀wé Bíbélì náà ṣàkọsílẹ̀ gbólóhùn yíyè kooro ní ti bíbá ìlànà ṣáyẹ́ǹsì mu, tí ó lọ jìnnàjìnnà ré kọjá àkókò tirẹ̀.
Bíbélì àti Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ìṣègùn —Wọ́n Ha Fohùn Ṣọ̀kan Bí?
Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn lóde òní ti kọ́ wa ní ohun púpọ̀ nípa ìtànkálẹ̀ àrùn àti bí a ṣe ń ṣèdíwọ́ fún èyí. Ìtẹ̀síwájú nínú ìṣègùn ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣamọ̀nà sí àṣà ìṣègùn ti lílo ohun agbógunti kòkòrò àrùn—wíwà ní mímọ́ tónítóní láti dín àkóràn àrùn kù. Àbájáde rẹ̀ kàmàmà. Iye àkóràn àrùn àti ikú ní rèwerèwe dín kù gan-an ni.
Àmọ́ o, àwọn oníṣègùn ìgbàanì kò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye nípa bí àrùn ṣe ń gbèèràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ìjẹ́pàtàkì tí ìmọ́tótó ní lórí ṣíṣèdíwọ́ fún àìsàn. Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ nínú ìlànà ìṣègùn wọn ni yóò dà bí ìwà àìlajú lójú ìdiwọ̀n ti òde òní.
Ọ̀kan nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìṣègùn tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni Ebers Papyrus, àkójọ ìmọ̀ ìṣègùn àwọn ará Íjíbítì, tí a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 1550 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àkájọ ìwé yìí ní 700 oògùn nínú fún onírúurú àmódi “bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbunijẹ ọ̀nì dórí kí orí èékánná máa dunni.”8 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopaedia, sọ pé: “Ìmọ̀ ìṣègùn àwọn oníṣègùn wọ̀nyí jẹ́ ti àfòyegbé pátápátá, èyí tí ó pọ̀ jù jẹ́ nípasẹ̀ àlúpàyídà kò sì bá ìlànà ṣáyẹ́ǹsì mu rárá.”9 Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú oògùn wọn wulẹ̀ jẹ́ aláìgbéṣẹ́, ṣùgbọ́n mélòó kan nínú wọn léwu ré kọjá ààlà. Láti tọ́jú ọgbẹ́, ọ̀kan lára ìtọ́jú tí wọ́n dábàá ni pé kí a bu àpòpọ̀ kan tí a fi ìgbọ̀nsẹ̀ ènìyàn àti àwọn ohun mìíràn ṣe lẹ̀ ẹ́.10
Ìwé àkọsílẹ̀ nípa oògùn àwọn ará Íjíbítì yí ni a kọ ní nǹkan bí àkókò kan náà tí a kọ àwọn ìwé àkọ́kọ́ Bíbélì, lára èyí tí Òfin Mósè wà. Íjíbítì ni Mósè, ẹni tí a bí ní ọdún 1593 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ti dàgbà. (Ẹ́kísódù 2:1-10) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára mẹ́ńbà agbo ilé Fáráò, a fún un “ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ó mọ “àwọn oníṣègùn” Íjíbítì dáadáa. (Jẹ́nẹ́sísì 50:1-3) Ìlànà ìṣègùn wọn tí kò gbéṣẹ́ tàbí tí ó jẹ́ eléwu ha nípa lórí àwọn ìwé tí ó kọ bí?
Rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Òfin Mósè ní ìlànà ìmọ́tótó tí ó lọ jìnnàjìnnà ré kọjá ìgbà tiwọn nínú. Fún àpẹẹrẹ, òfin kan nípa ìpabùdó àwọn ológun sọ pé kí wọ́n bo ìgbọ̀nsẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ ní ibi tí ó jìnnà sí ibùdó. (Diutarónómì 23:13) Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ adáàbòboni tí ó lọ jìnnàjìnnà ré kọjá ìgbà tiwọn ní ti ìjìnlẹ̀ òye. Ó ṣèrànwọ́ láti mú kí omi bọ́ lọ́wọ́ ìsọdẹ̀gbin, ó sì pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ àrùn ìgbẹ́ gbuuru shigellosis tí a ń kó láti ara eṣinṣin àti àwọn àìsàn míràn tí ó jẹ mọ́ àrunṣu tí ó ṣì ń ṣekú pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́dọọdún ní àwọn ilẹ̀ tí ipò ìmọ́tótó ti jó rẹ̀yìn gidigidi.
Òfin Mósè ní àwọn ìlànà ìmọ́tótó mìíràn nínú, tí ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn àkóràn míràn. Ẹnì kan tí ó bá ní àìsàn tí ó lè gbèèràn tàbí tí a fura sí pé ó ní in ni a máa ń sé mọ́. (Léfítíkù 13:1-5) Àwọn ẹ̀wù tàbí ohun èlò tí ó bá kan ẹranko kan tí ó fúnra rẹ̀ kú (bóyá láti ọwọ́ àìsàn) ni a ó fọ̀ kí a tó tún lò ó tàbí kí a run ún. (Léfítíkù 11:27, 28, 32, 33) Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú ni a máa ń kà sí aláìmọ́ tí ó sì ní láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwẹ̀nùmọ́ tí ó ní nínú fífọ àwọn ẹ̀wù rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Nínú sáà àìmọ́ ọlọ́jọ́ méje náà, ó ní láti yẹra fún níní ìfarakanra pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Númérì 19:1-13.
Àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ lórí ìmọ́tótó yìí ṣàfihàn ọgbọ́n tí àwọn oníṣègùn àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wọ́n ká nígbà náà kò ní. Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn tó mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí àìsàn ń gbà tàn kálẹ̀, Bíbélì ti tọ́ka àwọn ìgbésẹ̀ adáàbòboni tí ó bọ́gbọ́n mu láti dáàbò boni lọ́wọ́ àìsàn. Abájọ tí Mósè fi lè sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbogbòò ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ń gbé tó 70 tàbí 80 ọdún láyé.e—Sáàmù 90:10.
O lè gbà pé àwọn gbólóhùn Bíbélì tí a mẹ́nu kàn sẹ́yìn wọ̀nyí péye ní ti bíbá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu. Ṣùgbọ́n àwọn gbólóhùn míràn wà nínú Bíbélì tí a kò lè fẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu. Ìyẹn ha fi dandan fi Bíbélì síhà tí ó ta ko sáyẹ́ǹsì bí?
Títẹ́wọ́gba Ohun Tí A Kò Lè Fẹ̀rí Rẹ̀ Múlẹ̀
Pé a kò lè fẹ̀rí gbólóhùn kan múlẹ̀ kò fi dandan sọ ọ́ di aláìjóòótọ́. Ẹ̀rí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu ni àìtó agbára ènìyàn láti ṣàwárí ẹ̀rí tí ó kún tó àti láti sọ ìtumọ̀ àwọn ìsọfúnni oníṣirò lọ́nà tí ó tọ́ máa ń fi ààlà sí. Ṣùgbọ́n a kò lè fẹ̀rí àwọn òtítọ́ kan múlẹ̀ nítorí pé kò sí ẹ̀rí tí a fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ẹ̀rí náà fara sin tàbí pé a kò tí ì ṣàwárí rẹ̀, tàbí pé agbára ìṣe àti òye iṣẹ́ sáyẹ́ǹsì kò tó láti dórí òpin èrò tí a kò lè jàníyàn. Èyí ha lè jẹ́ bí ọ̀ràn ti rí ní ti àwọn gbólóhùn Bíbélì kan tí ẹ̀rí tí a lè fojú rí, tí ó dá fó, kò sí fún un bí?
Fún àpẹẹrẹ, ìtọ́ka tí Bíbélì ṣe sí àgbègbè kan tí a kò lè fójú rí, tí àwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé, ni a kò lè fẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀—tàbí kí a já a ní koro—lọ́nà tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mú. Ohun kan náà ni a lè sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníṣẹ́ ìyanu tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì. Kò sí ẹ̀rí lọ́nà ti ìmọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ tí ó yéni yékéyéké tó lárọ̀ọ́wọ́tó nípa Ìkún Omi kárí ayé lọ́jọ́ Nóà láti tẹ́ àwọn ènìyàn kan lọ́rùn. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 7) Ṣé kí a dórí èrò náà pé kò ṣẹlẹ̀ ni? Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn ni àkókò àti ìyípadà lè mú kí ó fara sin. Nítorí náà, ṣé kò lè jẹ́ pé àwọn ìgbòkègbodò lórí ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ ni ó ti pa èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ẹ̀rí nípa Ìkún Omi rẹ́?
Lóòótọ́, Bíbélì ní àwọn gbólóhùn kan nínú tí a kò lè fẹ̀rí wọn múlẹ̀ tàbí kí a já wọn ní koro nípa ẹ̀rí àfojúrí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ṣùgbọ́n ó ha yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu bí? Bíbélì kì í ṣe ìwé àkànlò lórí sáyẹ́ǹsì. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ìwé òtítọ́. A ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí alágbára tẹ́lẹ̀ pé àwọn òǹkọ̀wé rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn oníwà títọ́ àti aláìlábòsí. Nígbà tí wọ́n bá sì mẹ́nu kan ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, àwọn ọ̀rọ̀ wọn péye, ó sì bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn àbá èrò orí “tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu” nígbàanì èyí tí ó wá hàn pé ó jẹ́ àwọn ìtàn àròsọ lásán. Nípa báyìí, sáyẹ́ǹsì kì í ṣe ọ̀tá Bíbélì. Ìdí tí ó ṣe gúnmọ́ wà láti fi ọ̀kan tí ó dára gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò.
[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Antipodes . . . jẹ́ ibi méjì tí ó wà ní òdì kejì gẹ́lẹ́ sí ara wọn lórí ilẹ̀ ayé. Bí a bá fa ìlà títọ́ kan láti ìpẹ̀kun ìkíní sí ìkejì, ìlà náà yóò gba àárín gbùngbùn ilẹ̀ ayé kọjá. Ọ̀rọ̀ náà antipodes túmọ̀ sí láti ẹsẹ̀ dé ẹsẹ̀ ní èdè Gírí ìkì. Bí ẹni méjì bá dúró ní antipodes sí ara wọn, àtẹ́lẹsẹ̀ ni ibi tí wọn yóò fi sún mọ́ ara wọn jù lọ.”1—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia.
b Ká sọ̀rọ̀ ní èdè ìjìnlẹ̀, kẹrẹbutu ni ayé rí; ṣe ni ó rọra tẹ́ pẹrẹsẹ ní òkè àti ní ìsàlẹ̀.
c Ní àfikún sí i, kìkì nǹkan tí ó bá jẹ́ òbírí ni ó máa ń ṣe bìrìkìtì ní gbogbo ìhà tí a bá ti wò ó. Ìrísí ẹyin ni ohun palaba tí ó tẹ́jú kan sábà máa ń ní, kì í ṣe ti òbìrìkìtì.
d Ojú ìwòye tí ó gba iwájú jù lọ ní ọjọ́ Newton ni pé ohun olómi ni ó kún àgbáálá ayé—“ọbẹ̀” àgbáálá ayé—àti pé pípòyì tí ohun olómi yìí ń pòyì kíkankíkan ní ń mú kí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì máa lọ yí po ní òpó wọn.
e Ní 1900, ìfojúdíwọ̀n iye ọdún tí a retí pé kí ẹnì kan gbé láyé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ní ilẹ̀ Europe àti ní United States kò tó 50. Láti ìgbà náà wá, ó ti lọ sókè gidi gan-an ni, kì í ṣe kìkì nítorí ìtẹ̀síwájú ìṣègùn nínú mímú kí àrùn lọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n, tìtorí ìmúsunwọ̀n sí i nínú ipò ìmọ́tótó àti àwọn ọ̀nà ìgbégbèésí ayé pẹ̀lú.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 1]
Pé a kò lè fẹ̀rí gbólóhùn kan múlẹ̀ kò fi dandan sọ ọ́ di aláìjóòótọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó rí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí òbíríkítí láti gbalasa òfuurufú, Bíbélì tọ́ka sí “òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Alàgbà Isaac Newton ṣàlàyé pé agbára òòfà ni ó so àwọn pílánẹ́ẹ̀tì mọ́ òpó ìrìnnà wọn