Orí Kẹrìnlá
Jèhófà Tẹ́ Ìlú Agbéraga
1. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà ṣe wá rìn jìnnà tó?
Ọ̀RÚNDÚN kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Ásíríà ṣígun wá sí Ilẹ̀ Ìlérí, ni Aísáyà kọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àwọn orí ìwé Aísáyà tí a ti yẹ̀ wò kọjá, gbogbo ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yẹn rìn jìnnà kọjá àkókò tí Ásíríà fi wà lórí àlééfà. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn ènìyàn tó bá Jèhófà dá májẹ̀mú yóò ṣe padà bọ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn nígbèkùn lọ, títí kan Ṣínárì tó jẹ́ ibi tí Bábílónì wà. (Aísáyà 11:11) Ní Aísáyà orí kẹtàlá, a rí àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan, tó jẹ́ pé, ìmúṣẹ rẹ̀ ni yóò ṣí ọ̀nà fún irú ìpadàbọ̀ yẹn. Gbólóhùn tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Bábílónì, èyí tí Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì rí nínú ìran.”—Aísáyà 13:1.
‘Èmi Yóò Rẹ Ìrera Wálẹ̀’
2. (a) Báwo ni Hesekáyà ṣe dẹni tó bá Bábílónì ní àjọṣe? (b) Kí ni “àmì àfiyèsí” tí wọ́n máa gbé sókè?
2 Nígbà ayé Aísáyà, àjọṣe wà láàárín Júdà àti Bábílónì. Àìsàn burúkú kan ló ṣe Hesekáyà Ọba, ó sì wá sàn. Ni àwọn ikọ̀ bá ti Bábílónì wá láti kí i kú ewu, bóyá láti lè fọgbọ́n mú kí Hesekáyà bá wọn lẹ̀dí àpò pọ̀ nínú ogun tí wọ́n fẹ́ bá Ásíríà jà ni. Hesekáyà Ọba wá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, ó fi gbogbo ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n. Nítorí náà, Aísáyà sọ fún Hesekáyà pé, lẹ́yìn ikú rẹ̀, gbogbo dúkìá wọ̀nyẹn ni wọn yóò kó lọ sí Bábílónì. (Aísáyà 39:1-7) Ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, tí wọ́n sì kó orílẹ̀-èdè yẹn lọ sí ìgbèkùn. Ṣùgbọ́n o, àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn láàyò kò ní wà ní Bábílónì títí ayé. Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí òun yóò ṣe ṣí ọ̀nà fún wọn láti padà wálé. Ó gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ pé: “Ẹ gbé àmì àfiyèsí sókè lórí òkè ńlá àwọn àpáta dídán borokoto. Ẹ gbé ohùn sókè sí wọn, ẹ ju ọwọ́, kí wọ́n lè wá sí ẹnu ọ̀nà àwọn ọ̀tọ̀kùlú.” (Aísáyà 13:2) Agbára ayé tí yóò já Bábílónì bọ́ lórí ipò ọlá ńlá tó wà ni “àmì àfiyèsí” yẹn. Orí “òkè ńlá àwọn àpáta dídán borokoto,” ìyẹn ibi tó hàn kedere láti òkè réré ni wọ́n máa gbé e sí. Bí agbára ayé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú yẹn bá ti gbọ́ ìpè pé kó kọ lu Bábílónì, “ẹnu ọ̀nà àwọn ọ̀tọ̀kùlú,” ìyẹn ẹnubodè ìlú alágbára yẹn, ni yóò fi tipátipá gbà wọlé, yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.
3. (a) Àwọn wo ni Jèhófà “sọ di mímọ́” tó sì máa gbé dìde? (b) Ọ̀nà wo la fi “sọ” agbo ọmọ ogun àwọn abọ̀rìṣà “di mímọ́”?
3 Jèhófà wá sọ pé: “Èmi fúnra mi ti pa àṣẹ náà fún àwọn tí mo ti sọ di mímọ́. Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti pe àwọn ẹni alágbára ńlá mi fún fífi ìbínú mi hàn, àwọn onítèmi tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà títayọ. Fetí sílẹ̀! Ogunlọ́gọ̀ kan ń bẹ ní òkè ńlá, ohun kan tí ó dà bí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye! Fetí sílẹ̀! Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àwọn ìjọba, ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kóra jọpọ̀! Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń pe ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ.” (Aísáyà 13:3, 4) Àwọn wo ni àwọn tó ti “sọ di mímọ́” yìí, tó yàn pé kó wá tẹ́ Bábílónì? Àpapọ̀ agbo ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè ni, “àwọn orílẹ̀-èdè tó kóra jọpọ̀.” Láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá tí ń bẹ lọ́nà jíjìn réré ni wọ́n ti sọ̀ kalẹ̀ wá gbéjà ko Bábílónì. “Wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìnnàréré, láti ìkángun ọ̀run.” (Aísáyà 13:5) Ọ̀nà wo ló gbà sọ wọ́n di mímọ́? Ó dájú pé kì í ṣe lọ́nà ti pé wọ́n di ẹni mímọ́. Abọ̀rìṣà làwọn ọmọ ogun yẹn, wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn Jèhófà. Àmọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, láti “sọ di mímọ́” túmọ̀ sí láti “yà sọ́tọ̀ fún ìlò Ọlọ́run.” Jèhófà lè sọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́, kí ó sì lo ẹ̀mí ọ̀kánjúwà tí wọ́n ní fún ète fífi ìbínú rẹ̀ hàn. Ọ̀nà tó gbà lo Ásíríà nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lo Bábílónì. (Aísáyà 10:5; Jeremáyà 25:9) Yóò sì wá lo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti fìyà jẹ Bábílónì.
4, 5. (a) Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì? (b) Ìdènà wo làwọn tó ń ṣígun bọ̀ wá bá Bábílónì yóò kọ́kọ́ kò?
4 Bábílónì ò tíì di agbára ayé tó gba iwájú. Síbẹ̀, nínú ìkéde tí Jèhófà gba ẹnu Aísáyà ṣe, ńṣe ni Jèhófà ti rí ìgbà tí yóò bọ́ sí ipò yẹn lọ́jọ́ iwájú, tó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣubú. Ó ní: “Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé! Yóò dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọwọ́ Olódùmarè.” (Aísáyà 13:6) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìbànújẹ́ ni Bábílónì yóò fi hu gbẹ̀yìn ẹnu tó ń fọ́n. Kí ló fà á? Nítorí “ọjọ́ Jèhófà” ni, ìyẹn ọjọ́ tí Jèhófà yóò dá a lẹ́jọ́.
5 Ṣùgbọ́n, báwo ló ṣe máa wá ṣeé ṣe láti fi Bábílónì ṣèjẹ? Bó bá tákòókò tí Jèhófà fẹ́ ṣe é, ńṣe ló máa dà bíi pé mìmì kan ò lè mi ìlú yẹn. Ìdènà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó ṣígun tọ̀ ọ́ wá yóò kọ́kọ́ kò ni Odò Yúfírétì tó jẹ́ ààbò fún ìlú yẹn, nítorí pé, ṣe ni odò yẹn ṣàn gba àárín ìlú náà, wọ́n sì darí apá kan lára rẹ̀ gba inú yàrà tí wọ́n wà yípo ìlú náà fún ààbò, ó sì tún jẹ́ omi tí àwọn ará ìlú ń mu. Lẹ́yìn náà, wọn yóò tún kan odi ràgàjì, odi méjì alákànpọ̀, tó yí Bábílónì ká, tó dà bí èyí tí mìmì kan ò lè mì. Ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni oúnjẹ máa kún ìlú yẹn bámúbámú. Ìwé Daily Bible Illustrations sọ pé ńṣe ni Nábónídọ́sì, ọba tó jẹ kẹ́yìn ní Bábílónì, “sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rọ́ ohun kòṣeémánìí kún ìlú yẹn dẹ́múdẹ́mú, àwọn kan tilẹ̀ sọ pé oúnjẹ tó wà nínú ìlú yẹn tó àwọn aráàlú jẹ fún odindi ogún ọdún.”
6. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lójijì nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé wọn yóò kọlu Bábílónì bá wá ṣẹ?
6 Àmọ́ ṣá, ìrísí lè tanni jẹ o. Aísáyà sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí gbogbo ọwọ́ pàápàá yóò fi rọ jọwọrọ, tí gbogbo ọkàn-àyà ẹni kíkú yóò sì fi domi. Ìyọlẹ́nu sì ti bá àwọn ènìyàn. Ìsúnkì iṣan àti ìrora ìbímọ ti gbáni mú; wọ́n ní ìrora ìrọbí gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ. Wọ́n ń wo ara wọn pẹ̀lú kàyéfì. Ojú wọn jẹ́ ojú tí a mú gbiná.” (Aísáyà 13:7, 8) Bí agbo ọmọ ogun ajagunṣẹ́gun yìí bá ṣe ń wọnú ìlú yẹn ni ìtura àwọn aráàlú máa yí padà di ìrora gógó lójijì bí ìgbà tí obìnrin bá bẹ̀rẹ̀ sí rọbí. Ńṣe ni ìbẹ̀rù máa sọ ọkàn wọn domi. Ìpáyà a sì mú kí ọwọ́ wọn rọ̀ jọwọrọ, wọn kò ní lè gba ara wọn sílẹ̀. Ojú wọn á wá di “ojú tí a mú gbiná” nítorí ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú kàyéfì, nítorí pé ó yà wọ́n lẹ́nu pé ìlú wọn alágbára yìí lè ṣubú.
7. “Ọjọ́ Jèhófà” wo ló ń bọ̀, kí ni yóò sì yọrí sí fún Bábílónì?
7 Àmọ́, yóò ṣubú dandan ni. Ọjọ́ ìjíhìn Bábílónì yóò dé, “ọjọ́ Jèhófà,” ọjọ́ burúkú gbáà ni yóò jẹ́ fún wọn. Onídàájọ́ gíga jù lọ yóò fìbínú rẹ̀ hàn, ẹ̀san á wá ké lórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ará Bábílónì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Wò ó! Àní ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, ó níkà pẹ̀lú ìbínú kíkan àti pẹ̀lú ìbínú jíjófòfò, láti lè sọ ilẹ̀ náà di ohun ìyàlẹ́nu, kí ó sì lè pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀.” (Aísáyà 13:9) Ìjàngbọ̀n ń bẹ níwájú fún Bábílónì. Àfi bíi pé oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀ ò ràn mọ́. “Nítorí pé àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti àwọn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì wọn pàápàá kì yóò mú kí ìmọ́lẹ̀ wọn kọ mànà; oòrùn yóò ṣókùnkùn nígbà ìjáde lọ rẹ̀ ní ti tòótọ́, òṣùpá pàápàá kì yóò sì mú kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn.”—Aísáyà 13:10.
8. Èé ṣe tí Jèhófà fi pàṣẹ pé kí Bábílónì ṣubú?
8 Kí ló kó irú ìyà yìí jẹ ìlú agbéraga yìí? Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò mú ìwà búburú tirẹ̀ wọlé wá sórí ilẹ̀ eléso náà, àti ìṣìnà tiwọn wá sórí àwọn ẹni burúkú tìkára wọn. Ní ti tòótọ́, èmi yóò mú kí ìgbéraga àwọn oníkùgbù kásẹ̀ nílẹ̀, ìrera àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ sì ni èmi yóò rẹ̀ wálẹ̀.” (Aísáyà 13:11) Nítorí ìwà ìkà tí Bábílónì hù sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ni Jèhófà yóò ṣe mú kó rí ìbínú òun. Gbogbo ilẹ̀ náà ni ìwà ibi tí àwọn ará Bábílónì hù yóò sì kó ìyà jẹ. Láé, àwọn òṣìkà agbéraga yìí kò ní jẹ́ tàpá sí Jèhófà mọ́!
9. Kí ló ń bọ̀ wá sórí Bábílónì lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà?
9 Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò mú kí ẹni kíkú ṣọ̀wọ́n ju wúrà tí a yọ́ mọ́, èmi yóò sì mú kí ará ayé ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ófírì.” (Aísáyà 13:12) Bẹ́ẹ̀ ni, ahoro pátápátá ni ìlú yẹn yóò dà. Jèhófà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi kó ṣìbáṣìbo bá ọ̀run pàápàá, ilẹ̀ ayé yóò sì mì jìgìjìgì kúrò ní ipò rẹ̀ nínú ìbínú kíkan Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ jíjófòfò.” (Aísáyà 13:13) “Ọ̀run” Bábílónì, ìyẹn gbogbo òrìṣà rẹ̀, ni ṣìbáṣìbo yóò bá, wọn kò ní lè ṣèrànwọ́ kankan fún ìlú yẹn nígbà ìṣòro. “Ilẹ̀ ayé,” ìyẹn Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, ni wọn yóò sì mì jìgìjìgì kúrò ní ipò rẹ̀, ilẹ̀ ọba yẹn yóò sì dìtàn pátápátá. “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí àgbàlàǹgbó tí a lé lọ àti bí agbo ẹran tí kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kó wọn jọpọ̀, olúkúlùkù wọn yóò yí padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tirẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò sì sá lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀.” (Aísáyà 13:14) Ńṣe ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè tí ń ti Bábílónì lẹ́yìn máa sá fi í sílẹ̀ lọ, tí wọn yóò lọ máa wá ọ̀nà bí wọn yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ àjọṣe pẹ̀lú agbára ayé tó ṣẹ́gun rẹ̀. Níkẹyìn, ìrora tó ń bá ìlú tí wọ́n bá ṣẹ́gun yóò dé bá Bábílónì, irú ìrora tóun náà ti mú bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú nígbà tó ṣì wà lójú ọpọ́n, bẹ́ẹ̀ ni: “Olúkúlùkù ẹni tí a bá rí ni a óò gún ní àgúnyọ, olúkúlùkù ẹni tí a bá sì mú nínú gbígbálọ náà yóò tipa idà ṣubú; àwọn ọmọ wọn gan-an ni a ó sì fọ́ túútúú lójú wọn. Ilé wọn ni a óò kó ní ìkógun, aya wọn ni a ó sì fipá bá lò pọ̀.”—Aísáyà 13:15, 16.
Ohun Èlò Tí Ọlọ́run Yóò fi Ṣèparun
10. Ta ni Jèhófà yóò lò láti fi ṣẹ́gun Bábílónì?
10 Orílẹ̀-èdè wo ni Jèhófà yóò lò láti fi bi Bábílónì ṣubú? Nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀ ni Jèhófà ti sọ ìdáhùn rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, èmi yóò gbé àwọn ará Mídíà dìde sí wọn, àwọn tí kò ka fàdákà pàápàá sí nǹkan kan, àwọn tí ó sì jẹ́ pé, ní ti wúrà, wọn kò ní inú dídùn sí i. Ọrun wọn yóò sì fọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin túútúú. Wọn kì yóò sì ṣe ojú àánú sí èso ikùn; ojú wọn kì yóò káàánú àwọn ọmọ. Bábílónì, ìṣelóge àwọn ìjọba, ẹwà ìyangàn àwọn ará Kálídíà, yóò sì dà bí ìgbà tí Ọlọ́run bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú.” (Aísáyà 13:17-19) Bábílónì ọlọ́lá ńlá yóò ṣubú, ọ̀nà jíjìn réré sì ni ohun èlò tí Jèhófà yóò fi ṣe iṣẹ́ yìí yóò ti wá, ìyẹn ni, ẹgbẹ́ ọmọ ogun láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ní Mídíà.a Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Bábílónì yóò dahoro bíi Sódómù òun Gòmórà, àwọn ìlú oníwà ìbàjẹ́ tó burú jáì wọ̀nyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 13:13; 19:13, 24.
11, 12. (a) Báwo ni Mídíà ṣe di agbára ayé? (b) Ìwà tó ṣàjèjì wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ pé agbo ọmọ ogun Mídíà máa ní?
11 Nígbà ayé Aísáyà, abẹ́ àjàgà Ásíríà ni Mídíà àti Bábílónì wà. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, lọ́dún 632 ṣááju Sànmánì Tiwa, Mídíà àti Bábílónì pawọ́ pọ̀ gba Nínéfè, olú ìlú Ásíríà. Èyí lọ̀nà fi là fún Bábílónì láti di agbára ayé tó mókè. Kò mọ̀ pé Mídíà máa bá òun kanlẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà! Yàtọ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run, ta ló tó fọwọ́ sọ̀yà láti sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn?
12 Nígbà tí Jèhófà ń sọ ohun èlò ìparun tó yàn láti lò, ó sọ pé agbo ọmọ ogun Mídíà “kò ka fàdákà pàápàá sí nǹkan kan . . . ní ti wúrà, wọn kò ní inú dídùn sí i.” Èyí mà ṣàjèjì o lójú ìwà táwọn ògbójú ológun máa ń hù! Albert Barnes tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lórí Bíbélì sọ pé: “Àwọn agbo ọmọ ogun tí yóò lọ gbógun ja ibì kan láìṣe pé wọ́n ń retí àtirí ohun ìfiṣèjẹ níbẹ̀ kò wọ́pọ̀.” Ǹjẹ́ agbo ọmọ ogun Mídíà ṣe bí Jèhófà ṣe sọ lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Wo àlàyé yìí, tó wà nínú ìwé The Bible-Work, látọwọ́ J. Glentworth Butler, ó sọ pé: “Àwọn ará Mídíà, pàápàá àwọn Páṣíà, kò dà bí ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè yòókù tó ti jagun rí, wọn ka ìṣẹ́gun àti ògo sí pàtàkì ju wúrà lọ.”b Ìyẹn ni kò fi yani lẹ́nu pé Kírúsì alákòóso Páṣíà kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun èlò wúrà àti fàdákà, tí Nebukadinésárì jí kó nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, padà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó dá nídè kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì.—Ẹ́sírà 1:7-11.
13, 14. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jagunjagun Mídíà àti Páṣíà kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ohun ìfiṣèjẹ, kí ni wọ́n ń lépa? (b) Báwo ni Kírúsì ṣe borí àwọn ohun ààbò tí Bábílónì fi ń yangàn?
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jagunjagun ará Mídíà àti Páṣíà kò fi bẹ́ẹ̀ máa lépa ohun ìfiṣèjẹ, wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n sáà máa lépa ohun tí wọn yóò fi gbògo. Wọn kò fẹ́ kí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí gba iwájú wọn lágbàáyé rárá ni. Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà tún ti fi ẹ̀mí “ìfiṣèjẹ” sínú ọkàn-àyà wọn. (Aísáyà 13:6) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n pinnu láti ṣẹ́gun Bábílónì, wọn yóò lo ọrun irin wọn, ìyẹn ọrun tó jẹ́ pé yàtọ̀ sí pé kí wọ́n fi tafà, wọ́n tún lè jàn án mọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá, ọmọ àwọn obìnrin Bábílónì, láti fi fọ́ wọn túútúú.
14 Àwọn ohun tó jẹ́ ààbò fún Bábílónì kò dá Kírúsì, olórí agbo ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà dúró rárá ni. Lóru October 5 sí 6, ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó pàṣẹ pé kí wọ́n darí omi Odò Yúfírétì gba ibòmíràn. Bí omi odò yẹn ṣe ń fà, àwọn ọmọ ogun yẹn bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ́dò kọjá sínú ìlú. Wọ́n yọ sáwọn ará Bábílónì lójijì, bí Bábílónì ṣe ṣubú nìyẹn. (Dáníẹ́lì 5:30) Ṣé Jèhófà Ọlọ́run ló kúkú mí sí Aísáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ìyẹn ni kò fi sí àní-àní pé Òun ló ń darí ọ̀ràn náà.
15. Kí ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì?
15 Báwo ni ìparun Bábílónì ṣe máa burú tó? Gbọ́ ìkéde Jèhófà, ó ní: “A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran. Àwọn ará Arébíà kì yóò sì pàgọ́ sí ibẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì yóò sì jẹ́ kí agbo ẹran wọn dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀. Ibẹ̀ sì ni àwọn olùgbé àwọn ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò dùbúlẹ̀ sí dájúdájú, ilé wọn yóò sì kún fún àwọn òwìwí idì. Ibẹ̀ sì ni àwọn ògòǹgò yóò máa gbé, àwọn ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́ pàápàá yóò sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri níbẹ̀. Àwọn akátá yóò sì máa hu nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀, ejò ńlá yóò sì wà nínú àwọn ààfin inú dídùn kíkọyọyọ. Àsìkò rẹ̀ sì ti sún mọ́lé, a kì yóò sì sún àwọn ọjọ́ rẹ̀ pàápàá síwájú.” (Aísáyà 13:20-22) Ìparun yán-ányán-án ni yóò bá ìlú yẹn.
16. Ìdánilójú wo ni ipò tí Bábílónì wà báyìí fún wa?
16 Èyí kò ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀, ó ṣe kedere lóde òní pé gbogbo ohun tí Aísáyà sọ nípa Bábílónì ló ti ṣẹ. Ẹnì kan tó jẹ́ alálàyé lórí Bíbélì sọ nípa Bábílónì pé, “ní báyìí, ahoro àti òkìtì àlàpà tó lọ súà ni, ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá.” Ó tún wá fi kún un pé: “Èèyàn ò lè máa wo gbogbo èyí kó máà rántí bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà àti ti Jeremáyà ṣe ní ìmúṣẹ tó ṣe rẹ́gí gan-an.” Ó dájú pé, nígbà ayé Aísáyà, kò sẹ́ni tó jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bábílónì yóò ṣubú, pé yóò sì wá dahoro níkẹyìn. Àní sẹ́, igba ọdún lẹ́yìn tí Aísáyà kọ̀wé rẹ̀ ni Bábílónì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn Mídíà àti Páṣíà! Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ló sì tó dahoro. Ǹjẹ́ èyí kò fún ìgbàgbọ́ wa lókun ní ti pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí? (2 Tímótì 3:16) Ẹ̀wẹ̀, níwọ̀n bí Jèhófà ti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti sọ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn ṣẹ, ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kò tíì ṣẹ ṣì ń bọ̀ wá ṣẹ bó bá tákòókò lójú Ọlọ́run.
‘Sinmi Kúrò Nínú Ìrora Rẹ’
17, 18. Àwọn ìbùkún wo ni ṣíṣẹ́gun tí wọ́n bá ṣẹ́gun Bábílónì yóò mú bá Ísírẹ́lì?
17 Ńṣe ni ara máa tu Ísírẹ́lì pẹ̀sẹ̀ tí Bábílónì bá ti ṣubú. Á jẹ́ pé wọ́n bọ́ nígbèkùn nìyẹn, pé ọ̀nà ti wá là fún wọn láti padà sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ìyẹn ni Aísáyà fi wá sọ pé: “Jèhófà yóò fi àánú hàn sí Jékọ́bù, ó sì dájú pé òun yóò ṣì yan Ísírẹ́lì; yóò sì fún wọn ní ìsinmi lórí ilẹ̀ wọn ní ti tòótọ́, àtìpó yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì so ara wọn mọ́ ilé Jékọ́bù. Àwọn ènìyàn yóò sì mú wọn ní ti tòótọ́, wọn yóò sì mú wọn wá sí ipò wọn, ilé Ísírẹ́lì yóò sì gbà wọ́n mọ́ra bí ohun ìní lórí ilẹ̀ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin; wọn yóò sì di amúnilóǹdè àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè, wọn yóò sì máa jọba lórí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí.” (Aísáyà 14:1, 2) Gbogbo Ísírẹ́lì, ìyẹn ẹ̀yà méjèèjìlá, ni “Jékọ́bù” tí ibí yìí ń tọ́ka sí. Jèhófà yóò ṣàánú “Jékọ́bù” nípa jíjẹ́ kí orílẹ̀-èdè yẹn padà wálé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ló máa bá wọn bọ̀ wálé, tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí yóò sì máa ṣiṣẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Àní àwọn kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò tilẹ̀ máa pàṣẹ fún àwọn tó ti kó wọn lẹ́rú tẹ́lẹ̀ rí.c
18 Gbogbo làásìgbò wíwà nígbèkùn yóò ti dìgbàgbé pátápátá. Dípò ìyẹn, Jèhófà yóò fáwọn èèyàn rẹ̀ ní “ìsinmi kúrò nínú ìrora [wọn] àti kúrò nínú ṣìbáṣìbo [wọn] àti kúrò nínú ìsìnrú nínira nínú èyí tí a ti sọ [wọ́n] di ẹrú.” (Aísáyà 14:3) Bí Ísírẹ́lì ṣe rí ìdáǹdè gbà kúrò lábẹ́ àjàgà ìsìnrú, bẹ́ẹ̀ ló bọ́ lọ́wọ́ ìrora àti ṣìbáṣìbo gbígbé láàárín àwọn abọ̀rìṣà. (Ẹ́sírà 3:1; Aísáyà 32:18) Nígbà tí ìwé Lands and Peoples of the Bible ń ṣàlàyé lórí èyí, ó ní: “Lójú ará Bábílónì, kò sí ohun tí òun àti ọlọ́run rẹ̀ fi yàtọ̀ síra, títí kan àwọn ìwà rẹ̀ tó burú jù lọ. Ojo, ọ̀mùtí àti òpònú ni wọ́n.” Áà, ìtura gbáà ló jẹ́ fún wọn láti lè bọ́ nínú àyíká tí wọn ti ń ṣe irú ìjọsìn burúkú bẹ́ẹ̀!
19. Kí ló ń béèrè kí Ísírẹ́lì tó lè rí ojú rere Jèhófà, kí la sì rí kọ́ látinú èyí?
19 Àmọ́ ṣá, àwọn ipò kan ni yóò mú kí Jèhófà ṣàánú wọn o. Àwọn èèyàn rẹ̀ ní láti kẹ́dùn nítorí ìwà búburú wọn, èyí tó mú kí Ọlọ́run jẹ wọ́n níyà gidigidi. (Jeremáyà 3:25) Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn látọkànwá, láìfi nǹkan kan bò, Jèhófà yóò dárí jì wọ́n. (Wo Nehemáyà 9:6-37; Dáníẹ́lì 9:5.) Ìlànà kan náà yìí ṣì wà dòní olónìí. Níwọ̀n bí kò ti “sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀,” gbogbo wa la nílò àánú Jèhófà. (2 Kíróníkà 6:36) Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí wa pé ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fóun, ká ronú pìwà dà, ká sì ṣíwọ́ àìtọ́ yòówù ká máa ṣe, kí a bàa lè rí ìwòsàn. (Diutarónómì 4:31; Aísáyà 1:18; Jákọ́bù 5:16) Yàtọ̀ sí pé èyí yóò jẹ́ ká tún padà rójú rere rẹ̀, ó tún ń jẹ́ kí ara tù wá.—Sáàmù 51:1; Òwe 28:13; 2 Kọ́ríńtì 2:7.
“Ọ̀rọ̀ Òwe” sí Bábílónì
20, 21. Báwo ni àwọn tó wà lágbègbè Bábílónì ṣe yọ̀ nígbà tó ṣubú?
20 Ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún kí Bábílónì tó di agbára ayé tó mókè ni Aísáyà ti sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tí aráyé yóò ṣe nígbà tó bá ṣubú. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti rí ìdáǹdè gbà kúrò nínú ìgbèkùn rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò sọ ọ̀rọ̀ òwe yìí lòdì sí ọba Bábílónì, pé: ‘Ẹ wo bí ẹni tí ń kó àwọn mìíràn ṣiṣẹ́ ṣe wá sí òpin, ìninilára ti wá sí òpin! Jèhófà ti ṣẹ́ ọ̀pá àwọn ẹni burúkú, ọ̀gọ àwọn tí ń ṣàkóso, ẹni tí ń fi ẹgba na àwọn ènìyàn láìdabọ̀ nínú ìbínú kíkan, ẹni tí ń tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba nínú kìkì ìbínú pẹ̀lú inúnibíni tí a kò dá dúró.’” (Aísáyà 14:4-6) Òkìkí Bábílónì ti kàn gidigidi pé ó jẹ́ ajagunṣẹ́gun, aninilára tí ń sọ àwọn èèyàn tó lómìnira dẹrú. Ẹ wo bó ṣe bá a mu tó pé wọ́n fi “ọ̀rọ̀ òwe” yìí yọ ayọ̀ ìṣubú ìlú yẹn, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ sí ìlà àwọn ọba Bábílónì ní tààràtà, ìyẹn bẹ̀rẹ̀ látorí Nebukadinésárì títí dórí Nábónídọ́sì àti Bẹliṣásárì—àwọn tó jọba nígbà tí ìlú yẹn ṣì lókìkí!
21 Ẹ wo àyípadà ńláǹlà tí ìṣubú rẹ̀ máa mú wá! “Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú. Àní àwọn igi júnípà pẹ̀lú ń yọ̀ ọ́, àwọn kédárì Lẹ́bánónì, wí pé, ‘Láti ìgbà tí o ti dùbúlẹ̀, kò sí agégi tí ó dìde sí wa.’” (Aísáyà 14:7, 8) Ńṣe ni àwọn alákòóso Bábílónì ń wo ọba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká bí igi tí wọ́n kàn lè gé láti fi ṣe ohun tó bá wù wọ́n. Àmọ́ o, gbogbo ìyẹn ti wá dópin báyìí. Àgémọ ẹ̀ ni ará Bábílónì tó ń gégi ti gé yẹn!
22. Kí ni a fi ewì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù nígbà tí ìlà àwọn ọba Bábílónì ṣubú?
22 Ìṣubú Bábílónì jẹ́ kàyéfì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ibojì alára fi mì tìtì, bẹ́ẹ̀ ni: “Kódà, Ṣìọ́ọ̀lù nísàlẹ̀ ni ṣìbáṣìbo ti bá nítorí rẹ, láti lè pàdé rẹ bí o ti ń wọlé bọ̀. Nítorí rẹ, ó ti jí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú, gbogbo àwọn aṣáájú ilẹ̀ ayé tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-ewúrẹ́. Ó ti mú kí gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. Gbogbo wọn sọ̀rọ̀ sókè, wọ́n sì wí fún ọ pé, ‘Ṣé a ti sọ ìwọ náà di aláìlera bí tiwa ni? Ṣé a ti sọ ọ́ di ẹni tí ó ṣeé fi wé wa ni? A ti mú ìyangàn rẹ sọ̀ kalẹ̀ wá sí Ṣìọ́ọ̀lù, ariwo adún-lọ-rére ti àwọn ohun èlò ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín. Lábẹ́ rẹ, ìdin tẹ́ rẹrẹ bí àga ìrọ̀gbọ̀kú; kòkòrò mùkúlú sì ni ìbora rẹ.’” (Aísáyà 14:9-11) Àkàwé inú ewì yìí mà kúkú ga o! Àfi bíi pé ibojì aráyé jí gbogbo ọba tó ti kú ṣáájú ìlà àwọn ọba Bábílónì kalẹ̀, kí wọ́n lè wá kí i káàbọ̀. Wọ́n ń gan ìlà àkóso Bábílónì, tí kò lè ta pútú mọ́, tó nà gbalaja sórí ìdin dípò ibùsùn olówó iyebíye, tí kòkòrò mùkúlú bò ó wẹ̀lẹ̀mù dípò aṣọ ọ̀gbọ̀ olówó iyebíye.
“Bí Òkú Tí A Tẹ̀ Mọ́lẹ̀”
23, 24. Ìwà ìgbéraga tó bùáyà wo làwọn ọba Bábílónì hù?
23 Aísáyà wá ń bá òwe rẹ̀ lọ pé: “Wo bí o ti já bọ́ láti ọ̀run, ìwọ ẹni tí ń tàn, ọmọ ọ̀yẹ̀! Wo bí a ti ké ọ lulẹ̀, ìwọ tí ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè di aláìlágbára!” (Aísáyà 14:12) Ìgbéraga àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló sún àwọn ọba Bábílónì tí wọ́n fi gbé ara wọn lékè àwọn tó wà yí wọn ká. Bí ìràwọ̀ àfẹ̀mọ́jú tó ń tàn yanran lófuurufú, ni agbára àti àṣẹ pípa ṣe ń gùn wọ́n. Ọ̀kan nínú ohun tó fa ìgbéraga yẹn ní pàtàkì ni ṣíṣẹ́gun tí Nebukadinésárì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, tó jẹ́ ohun táwọn Ásíríà ṣe tì. Ọ̀rọ̀ òwe yìí fi hàn pé ìlà àwọn tó jọba Bábílónì sọ pé: “Ọ̀run ni èmi yóò gòkè lọ. Òkè àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run ni èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sí, èmi yóò sì jókòó sórí òkè ńlá ìpàdé, ní àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá. Èmi yóò gòkè lọ sí àwọn ibi gíga àwọsánmà; èmi yóò mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Aísáyà 14:13, 14) Ìwà àṣejù wo ló tún lè ju èyí lọ?
24 Nínú Bíbélì, wọ́n fi àwọn tó jọba láti ìlà ìdílé Dáfídì wé ìràwọ̀. (Númérì 24:17) Orí Òkè Síónì làwọn “ìràwọ̀” wọ̀nyẹn máa ń jókòó sí ṣàkóso, bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Dáfídì. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ti kọ́ tẹ́ńpìlì sí Jerúsálẹ́mù, Síónì wá dorúkọ tó wà fún gbogbo ìlú yẹn. Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló gbọ́dọ̀ lọ sí Síónì lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. Bí ibẹ̀ ṣe di “òkè ńlá ìpàdé” nìyẹn. Bí Nebukadinésárì sì ṣe pinnu láti tẹ àwọn ọba Jùdíà lórí ba, kó sì wá kó wọn kúrò lórí òkè yẹn, ńṣe ló ń gbé ara rẹ̀ lékè “àwọn ìràwọ̀” wọ̀nyẹn. Kò gbé ògo ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí wọn fún Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká kúkú sọ pé ó fi ìgbéraga gbé ara rẹ̀ sí ipò Jèhófà ni.
25, 26. Báwo ni ìlà àwọn tó ń jọba Bábílónì ṣe dópin lọ́nà ẹ̀tẹ́?
25 Áà, àyípadà sí búburú ń bẹ níwájú fún Bábílónì agbéraga! Bábílónì kò tiẹ̀ sún mọ́ dídi ẹni tó lékè àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run rárá ni. Dípò ìyẹn, Jèhófà sọ pé: “Ṣìọ́ọ̀lù ni a óò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá, sí àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ nínú kòtò. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjú mọ́ ọ; wọn yóò ṣe àyẹ̀wò rẹ fínnífínní, wọn yóò wí pé, ‘Ṣé ọkùnrin yìí ni ó ń kó ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ ayé, tí ó ń mú kí àwọn ìjọba mì jìgìjìgì, tí ó mú kí ilẹ̀ eléso dà bí aginjù, tí ó sì bi ìlú ńlá rẹ̀ pàápàá ṣubú, tí kò ṣí ọ̀nà àtilọ sí ilé sílẹ̀ àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀?’” (Aísáyà 14:15-17) Ńṣe ni ìlà àwọn ọba tó ń lépa ògo ṣáá yìí máa dèrò Hédíìsì (Ṣìọ́ọ̀lù) nísàlẹ̀, bí aráyé.
26 Nígbà náà, ibo ni ìlà àwọn ọba tó ṣẹ́gun àwọn ìjọba, tó sọ ilẹ̀ eléso dìbàjẹ́, tó sì bi ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìlú wó yìí máa wá wà? Ibo ni agbára ayé tó kó àwọn òǹdè, tí kò sì jẹ́ kí wọ́n padà sílé yìí yóò wá wà? Àní, kò tilẹ̀ ní sí ìsìnkú ẹ̀yẹ fún ìlà àwọn ọba Bábílónì rárá! Jèhófà sọ pé: “Gbogbo àwọn ọba yòókù ti àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo wọn, ti dùbúlẹ̀ nínú ògo, olúkúlùkù nínú ilé tirẹ̀. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, a ti gbé ọ sọnù láìsí ibi ìsìnkú fún ọ, gẹ́gẹ́ bí èéhù tí a ṣe họ́ọ̀ sí, tí a fi àwọn ènìyàn tí a pa bò bí aṣọ, àwọn tí a fi idà gún, tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn òkúta inú kòtò, bí òkú tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀. Ìwọ kì yóò wà ní ìsopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn nínú sàréè, nítorí pé ìwọ run ilẹ̀ tìrẹ, ìwọ pa àwọn ènìyàn tìrẹ. Fún àkókò tí ó lọ kánrin, a kì yóò dárúkọ ọmọ àwọn aṣebi.” (Aísáyà 14:18-20) Láyé àtijọ́, ohun àbùkù ni wọ́n kà á sí bí wọn ò bá sìnkú àwọn ọba lọ́nà ẹ̀yẹ. Ti ìlà àwọn tí ń jọba ní Bábílónì wá ńkọ́? Òótọ́ ni pé wọ́n sìnkú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọba yẹn lọ́nà ẹ̀yẹ, àmọ́, bí “èéhù tí a ṣe họ́ọ̀ sí” ni wọ́n ṣe gbé àwọn ọba tó ti ìlà ìdílé Nebukadinésárì wá, sọnù. Àfi bíi pé wọ́n ju ìlà àwọn ọba yẹn sínú ibojì tí kò ní àmì kankan—bíi tàwọn sójà tó kú sójú ogun. Wọ́n mà kúkú tẹ́ o!
27. Ọ̀nà wo ni ìran àwọn ọmọ Bábílónì tó ń bọ̀ yóò gbà jìyà nítorí ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn?
27 Ọ̀rọ̀ òwe yìí parí nípa pípa àṣẹ ìkẹyìn yìí fáwọn ará Mídíà àti Páṣíà aṣẹ́gun, ó ní: “Ẹ pèsè búlọ́ọ̀kù ìpẹran sílẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n má bàa dìde, kí wọ́n sì gba ilẹ̀ ayé ní ti tòótọ́, kí wọ́n sì fi àwọn ìlú ńlá kún ojú ilẹ̀ eléso.” (Aísáyà 14:21) Títí gbére ni ìṣubú Bábílónì máa jẹ́. Ńṣe ni wọ́n máa fa ìlà ìdílé àwọn ọba Bábílónì tu. Kò sì ní gbérí mọ́ láéláé. Ìran àwọn ọmọ Bábílónì tó ń bọ̀ yóò jìyà nítorí “ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn.”
28. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Bábílónì, kí la sì rí kọ́ látinú èyí?
28 Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni ìdájọ́ tí wọ́n ṣe fún ìlà àwọn tó ń jọba Bábílónì kọ́ wa. Ohun tó fa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Bábílónì ni ẹ̀mí fífi ọ̀kánjúwà lépa agbára. (Dáníẹ́lì 5:23) Ìfẹ́ agbára ló gbà wọ́n lọ́kàn. Kí wọ́n sáà máa jẹ gàba lórí àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n ń wá. (Aísáyà 47:5, 6) Wọ́n sì tún ń fẹ́ káwọn èèyàn máa fògo fún wọn, ògo tó tọ́ sí Ọlọ́run. (Ìṣípayá 4:11) Èyí jẹ́ ìkìlọ̀ fẹ́nikẹ́ni tó bá wà nípò àṣẹ—àní nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. Ẹ̀mí fífi ọ̀kánjúwà lépa agbára, ẹ̀mí ìgbéraga àti ìmọtara-ẹni-nìkan jẹ́ àwọn ìwà tí Jèhófà kò fara mọ́, yálà látọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
29. Ẹ̀mí ìgbéraga àti fífi ọ̀kánjúwà lépa agbára táwọn ọba Bábílónì ní jẹ́ àfihàn ẹ̀mí ta ni?
29 Ẹ̀mí ìgbéraga táwọn ọba Bábílónì ní jẹ́ àfihàn ẹ̀mí Sátánì Èṣù tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Òun náà fi ọ̀kánjúwà lépa agbára, ó sì fẹ́ láti gbé ara rẹ̀ lékè Jèhófà Ọlọ́run. Ńṣe ni fífi tí Sátánì ń fi ọ̀kánjúwà lépa agbára kó òṣì àti ìjìyà bá gbogbo aráyé gẹ́lẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ọba Bábílónì àtàwọn tó tẹ̀ lórí ba.
30. Bábílónì mìíràn wo ni Bíbélì tún mẹ́nu kàn, irú ẹ̀mí wo ló sì ti ń lò?
30 Ẹ̀wẹ̀, nínú ìwé Ìṣípayá, a kà nípa Bábílónì mìíràn, ìyẹn ni, “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣípayá 18:2) Ètò àjọ yìí, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ń lo ẹ̀mí ìgbéraga, ìtẹnilóríba, àti ìwà ìkà bákan náà. Nítorí náà, “ọjọ́ Jèhófà” yóò dé bá òun pẹ̀lú, yóò sì pa run bó bá ti tákòókò lójú Ọlọ́run. (Aísáyà 13:6) Látọdún 1919 ni ìsọfúnni ti ń lọ káàkiri ayé pé: “Bábílónì Ńlá ti ṣubú!” (Ìṣípayá 14:8) Látìgbà tí kò ti lè de àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́lẹ̀ nígbèkùn mọ́ ló ti ṣubú. Láìpẹ́, yóò pa run pátápátá. Àṣẹ tí Jèhófà pa nípa Bábílónì àtijọ́ ni pé: “Ẹ san án padà fún un gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i. Nítorí pé ó ti fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí Jèhófà, lòdì sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” ((Jeremáyà 50:29; Jákọ́bù 2:13) Irú ìdájọ́ kan náà ní ń bọ̀ wá sórí Bábílónì Ńlá.
31. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá láìpẹ́?
31 Nípa bẹ́ẹ̀, Bábílónì àtijọ́ nìkan kọ́ ni gbólóhùn ìkẹyìn tí Jèhófà sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà yìí kàn, ó kan Bábílónì Ńlá pẹ̀lú, ó sọ pé: “Èmi yóò . . . dìde sí wọn dájúdájú . . . Èmi yóò sì ké orúkọ àti àṣẹ́kù àti àtọmọdọ́mọ àti ìran àtẹ̀lé kúrò ní Bábílónì . . . Dájúdájú, èmi yóò sọ ọ́ di ohun ìní àwọn òòrẹ̀ àti àwọn adágún omi tí ó kún fún esùsú, èmi yóò sì fi ìgbálẹ̀ ìparẹ́ráúráú gbá a.” (Aísáyà 14:22, 23) Àwọn òkìtì àlàpà Bábílónì àtijọ́ ń fi ohun tí Jèhófà yóò ṣe sí Bábílónì Ńlá láìpẹ́ hàn. Ìtùnú gbáà lèyí jẹ́ fáwọn olùfẹ́ ìjọsìn tòótọ́! Ó mà sì fúnni níṣìírí gan-an o, pé ká sapá láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga, ìjọra-ẹni-lójú, tàbí ìwà ìkà tó jẹ́ ẹ̀mí Sátánì wà nínú wa láé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ àwọn ará Mídíà nìkan ni Aísáyà mẹ́nu kàn, àmọ́ orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ni yóò para pọ̀ gbógun ti Bábílónì, àwọn ni, Mídíà, Páṣíà, Élámù, àti àwọn orílẹ̀-èdè kéékèèké mìíràn. (Jeremáyà 50:9; 51:24, 27, 28) Àwọn ará Mídíà pa pọ̀ mọ́ Páṣíà làwọn orílẹ̀-èdè àgbègbè ibẹ̀ máa ń pè ní “ará Mídíà.” Àti pé, nígbà ayé Aísáyà, Mídíà lorílẹ̀-èdè tó gba iwájú. Ìgbà tí Kírúsì di olórí ni Páṣíà ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iwájú.
b Àmọ́, ó jọ pé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà padà wá di aláfẹ́ gan-an nígbà tó yá.—Ẹ́sítérì 1:1-7.
c Bí àpẹẹrẹ, lábẹ́ ìjọba Mídíà àti Páṣíà, wọ́n fi Dáníẹ́lì jẹ onípò àṣẹ gíga ní Bábílónì. Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, Ẹ́sítérì tún di ayaba fún Ahasuwérúsì ọba Páṣíà, Módékáì sì di igbákejì nínú gbogbo Ilẹ̀ Ọba Páṣíà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 178]
Bábílónì tó ti ṣubú yóò di ibi táwọn ẹran tí ń gbé aṣálẹ̀ yóò ti máa jẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 186]
Bábílónì Ńlá yóò di òkìtì àlàpà bíi Bábílónì tàtijọ́