Orí Ogún
Jèhófà Jọba
1, 2. (a) Àwọn wo ló máa rí ìbínú Jèhófà? (b) Ṣé àṣegbé ni ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tí Júdà hù, báwo la ṣe mọ̀?
BÁBÍLÓNÌ ni o, Filísíà ni o, Móábù ni o, Síríà ni o, Etiópíà ni o, Íjíbítì ni o, Édómù ni o, Tírè ni o, Ásíríà ni o, gbogbo wọn pátá ló máa rí ìbínú Jèhófà. Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àjálù tó máa já lu àwọn orílẹ̀-èdè àti ìlú ọ̀tá wọ̀nyí. Júdà wá ńkọ́? Ṣé àṣegbé ni gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn ará Júdà ń hù ni? Ohun tí ìtàn sọ fi hàn pé wọn ò lè mú un jẹ rárá ni!
2 Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Samáríà, olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ní Ísírẹ́lì. Orílẹ̀-èdè yẹn da májẹ̀mú tó bá Ọlọ́run dá. Kò yàgò fún ìwàkiwà àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ará Samáríà “ń ṣe ohun búburú ṣáá láti mú Jèhófà bínú . . . Nítorí náà, ìbínú Jèhófà ru gidigidi sí Ísírẹ́lì, tí ó fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀.” Wọ́n lé Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀, ìyẹn ló sì fi “lọ kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ sí ìgbèkùn ní Ásíríà títí di òní yìí.” (2 Àwọn Ọba 17:9-12, 16-18, 23; Hóséà 4:12-14) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì jẹ́ àmì pé ibi ń bọ̀ wá bá ìjọba Júdà tó ṣìkejì rẹ̀.
Aísáyà Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsọdahoro Júdà
3. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ ìjọba Júdà tó jẹ́ ẹ̀yà méjì sílẹ̀? (b) Kí ni Jèhófà pinnu láti ṣe?
3 Àwọn kan nínú àwọn ọba Júdà jẹ́ olóòótọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ ló jẹ́ aláìṣòótọ́. Kódà, lábẹ́ ìṣàkóso àwọn olóòótọ́ ọba bíi Jótámù, àwọn èèyàn yẹn kò fi gbogbo ara yọwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. (2 Àwọn Ọba 15:32-35) Ìwà burúkú Júdà dé ògógóró rẹ̀ nígbà kan lásìkò ìṣàkóso Mánásè Ọba afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ẹni tí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù sọ pé ó ṣìkà pa Aísáyà, wòlíì olóòótọ́ nì, nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n fi ayùn rẹ́ ẹ sí méjì. (Fi wé Hébérù 11:37.) Ọba burúkú yìí “ń bá a nìṣó ní sísún Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù dẹ́ṣẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (2 Kíróníkà 33:9) Nígbà tí Mánásè fi ń ṣàkóso, wọ́n tiẹ̀ sọ ilẹ̀ náà dìbàjẹ́ ju ti ìgbà tó wà níkàáwọ́ àwọn ọmọ Kénáánì pàápàá. Ìyẹn ni Jèhófà fi kéde pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí Jerúsálẹ́mù àti Júdà, èyí tí ó jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì yóò hó yee. . . . Èmi yóò wulẹ̀ nu Jerúsálẹ́mù mọ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹní nu àwokòtò aláìní iga-ìdìmú mọ́, ní nínù ún mọ́ àti ní dídojú rẹ̀ délẹ̀. Èmi yóò sì ṣá àṣẹ́kù ogún mi tì ní ti tòótọ́, èmi yóò sì fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, wọn yóò wulẹ̀ di ohun tí a piyẹ́ àti ìkógun lọ́dọ̀ gbogbo ọ̀tá wọn, nítorí ìdí náà pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú mi, tí wọ́n sì ń bá a lọ láti mú mi bínú.”—2 Àwọn Ọba 21:11-15.
4. Kí ni Jèhófà yóò ṣe sí Júdà, báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣe ṣẹ?
4 Bí ẹní dojú abọ́ délẹ̀ láti da nǹkan inú rẹ̀ nù ni wọ́n ṣe máa da àwọn èèyàn tí ń gbé inú ilẹ̀ yẹn jáde. Àsọtẹ́lẹ̀ ìsọdahoro Júdà àti Jerúsálẹ́mù tí ń bọ̀ yìí ni Aísáyà wá gbẹ́nu lé. Ó ní: “Wò ó! Jèhófà sọ ilẹ̀ di òfìfo, ó sì sọ ọ́ di ahoro, ó sì ti lọ́ ojú rẹ̀, ó sì ti tú àwọn olùgbé rẹ̀ ká.” (Aísáyà 24:1) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì, tí Nebukadinésárì Ọba kó wá jagun, pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, àti nígbà tí idà, ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ará Júdà ku ìwọ̀nba díẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù tó là á já ni wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì, tí àwọn díẹ̀ tó kù sì sá lọ sí Íjíbítì. Bí wọ́n ṣe run ilẹ̀ Júdà tí wọ́n sì sọ ọ́ dahoro nìyẹn. Kódà, àwọn ẹran ọ̀sìn pàápàá ò ṣẹ́ ku síbẹ̀. Ilẹ̀ tó dahoro yẹn wá di aginjù àwókù tó dá páropáro, tó jẹ́ pé àwọn ẹyẹ oko àti ẹranko nìkan ló ń gbé ibẹ̀.
5. Ǹjẹ́ ìdájọ́ Jèhófà á yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀? Ṣàlàyé.
5 Ǹjẹ́ wọ́n á ṣojú àánú sí ẹnikẹ́ni ní Júdà nígbà ìdájọ́ tí ń bọ̀? Aísáyà dáhùn pé: “Yóò sì wá rí bákan náà fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún àlùfáà; bákan náà fún ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ọ̀gá rẹ̀; bákan náà fún ìránṣẹ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún olúwa rẹ̀ obìnrin; bákan náà fún olùrà gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún olùtà; bákan náà fún awínni gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ayá-nǹkan; bákan náà fún olùgba èlé gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ẹni tí ń san èlé. Láìkùnà, a ó sọ ilẹ̀ náà di òfìfo, láìkùnà, a ó sì piyẹ́ rẹ̀, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.” (Aísáyà 24:2, 3) Ọrọ̀ tàbí ẹrù iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì kò ní kó ẹnikẹ́ni yọ rárá. Wọn ò ní yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Wọ́n ti sọ ilẹ̀ yẹn dìbàjẹ́ dépò pé, gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti ń mí, títí kan wòlíì, ẹrú àti ọ̀gá, olùrà àti olùtà, ni yóò dèrò ìgbèkùn ní túláàsì.
6. Èé ṣe tí Jèhófà fi fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn lórí ilẹ̀ náà?
6 Kí àṣìlóye kankan má baà sí, Aísáyà ṣàpèjúwe bí ìjábá tó ń bọ̀ yìí ṣe máa jẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tó, ó sì ṣàlàyé ìdí rẹ̀, ó ní: “Ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀, ó ti ṣá. Ilẹ̀ eléso ti gbẹ, ó ti ṣá. Àwọn ẹni gíga lára àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ti gbẹ. A ti sọ ilẹ̀ náà gan-an di eléèérí lábẹ́ àwọn olùgbé rẹ̀, nítorí pé wọ́n ti pẹ́ òfin kọjá, wọ́n ti yí ìlànà padà, wọ́n ti da májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ìdí nìyẹn tí ègún pàápàá fi jẹ ilẹ̀ náà run, tí a sì ka àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ sí ẹlẹ́bi. Ìdí nìyẹn tí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà fi pẹ̀dín ní iye, tí ìwọ̀nba kéréje ẹni kíkú sì fi ṣẹ́ kù.” (Aísáyà 24:4-6) Nígbà tí wọ́n fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n bá a pé ó jẹ́ “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” (Diutarónómì 27:3) Síbẹ̀síbẹ̀, ìbùkún Jèhófà ni wọ́n gbára lé. Bí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́, ilẹ̀ náà ‘yóò fi èso rẹ̀ fúnni,’ ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pẹ́ àwọn òfin àti àṣẹ rẹ̀ kọjá, ńṣe ni wọn yóò kàn máa “lo agbára [wọn] lásán” lẹ́nu iṣẹ́ oko wọn, ilẹ̀ ‘kì yóò mú èso rẹ̀ jáde.’ (Léfítíkù 26:3-5, 14, 15, 20) Ègún Jèhófà ni yóò ‘jẹ ilẹ̀ náà tán.’ (Diutarónómì 28:15-20, 38-42, 62, 63) Wàyí o, kí Júdà máa retí kí ègún yẹn ṣẹ lé òun lórí ló kù.
7. Báwo ni májẹ̀mú Òfin yóò ṣe jẹ́ ìbùkún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
7 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fínnúfíndọ̀ bá Jèhófà dá májẹ̀mú, wọ́n sì gbà láti pa májẹ̀mú yẹn mọ́. (Ẹ́kísódù 24:3-8) Ohun tí Májẹ̀mú Òfin tí wọ́n jọ dá sọ ni pé, bí wọ́n bá pa àṣẹ Jèhófà mọ́, yóò bù kún wọn yanturu, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá da májẹ̀mú yẹn, wọn ò ní rí ìbùkún rẹ̀ gbà mọ́, àwọn ọ̀tá wọn yóò sì kó wọn nígbèkùn. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Diutarónómì 28:1-68) Ńṣe ni májẹ̀mú Òfin, tó tipasẹ̀ Mósè fún wọn yìí, yóò máa bá a lọ fún àkókò tó lọ kánrin, láìlópin. Ṣe ni yóò dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí Mèsáyà yóò fi dé.—Gálátíà 3:19, 24.
8. (a) Báwo làwọn èèyàn yìí ṣe “pẹ́ òfin kọjá,” tí wọ́n sì “yí ìlànà padà”? (b) Àwọn ọ̀nà wo ló fi máa jẹ́ pé “àwọn ẹni gíga,” ló máa kọ́kọ́ “gbẹ”?
8 Àmọ́, ńṣe làwọn èèyàn yìí “da májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Wọ́n pẹ́ àwọn òfin tí Ọlọ́run fún wọn kọjá, wọn ò sì kà wọ́n sí. Wọ́n “yí ìlànà padà,” wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn òfin mìíràn tó yàtọ̀ sí èyí tí Jèhófà fún wọn. (Ẹ́kísódù 22:25; Ìsíkíẹ́lì 22:12) Nítorí náà, kíkó ni wọ́n máa kó àwọn èèyàn náà kúrò ní ilẹ̀ náà. Kò sójú àánú kankan nígbà ìdájọ́ tó ń bọ̀ yìí. Lára àwọn ẹni tó máa kọ́kọ́ “gbẹ” nítorí bí Jèhófà ṣe fawọ́ ààbò àti ojú rere rẹ̀ sẹ́yìn lọ́dọ̀ wọn ni “àwọn ẹni gíga,” ìyẹn àwọn ọ̀tọ̀kùlú. Èyí ṣẹ ní ti pé, bí ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ará Íjíbítì ló kọ́kọ́ sọ àwọn ọba Júdà di baálẹ̀ abẹ́ àkóso wọn, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n tún di baálẹ̀ lábẹ́ àwọn ará Bábílónì. Lẹ́yìn náà, Jèhóákínì Ọba àti àwọn ará ilé ọba wà lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.—2 Kíróníkà 36:4, 9, 10.
Ayọ̀ Yíyọ̀ Dá ní Ilẹ̀ Náà
9, 10. (a) Ipa wo ni iṣẹ́ àgbẹ̀ kó ní Ísírẹ́lì? (b) Kí ni jíjókòó tí wọ́n ní ‘olúkúlùkù jókòó sábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀’ dúró fún?
9 Iṣẹ́ àgbẹ̀ niṣẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Látìgbà tí Ísírẹ́lì sì ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, iṣẹ́ oko àti iṣẹ́ sísin ẹran ni wọ́n ń ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ipò pàtàkì ni iṣẹ́ àgbẹ̀ wà nínú òfin tí wọ́n fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n pàṣẹ fún wọn pé dandan gbọ̀n ni kí wọ́n máa fún ilẹ̀ náà ní ìsinmi sábáàtì lọ́dún méje-méje, kí ọ̀rá ilẹ̀ náà fi lè padà bọ̀ sípò. (Ẹ́kísódù 23:10, 11; Léfítíkù 25:3-7) Àsìkò ìkórè ni wọ́n fi àjọ̀dún mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ní kí orílẹ̀-èdè náà máa ṣe lọ́dọọdún sí.—Ẹ́kísódù 23:14-16.
10 Ọgbà àjàrà pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. Ìwé Mímọ́ sọ pé wáìnì, tó wá látinú èso àjàrà, jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run tó “ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” (Sáàmù 104:15) Jíjókòó tí wọ́n ní ‘olúkúlùkù jókòó sábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀,’ dúró fún aásìkí, àlàáfíà, àti ààbò tí yóò wà lábẹ́ ìṣàkóso òdodo ti Ọlọ́run. (1 Àwọn Ọba 4:25; Míkà 4:4) Bí àjàrà bá so dáadáa, wọ́n kà á sí ìbùkún, àkókò orin kíkọ àti ayọ̀ yíyọ̀ ló sì máa ń jẹ́. (Àwọn Onídàájọ́ 9:27; Jeremáyà 25:30) Àmọ́ òdìkejì rẹ̀ tún máa ń ṣẹlẹ̀. Bí àwọn àjàrà bá rọ, tàbí pé kò so, tí ọgbà àjàrà sì jẹ́ kìkì ẹ̀gún wọ́nganwọ̀ngan, ẹ̀rí pé Jèhófà ti fawọ́ ìbùkún sẹ́yìn nìyẹn, àkókò ìbànújẹ́ gbáà ni.
11, 12. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ohun tí ìdájọ́ Jèhófà máa mú bá ilẹ̀ náà? (b) Àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ wo ni Aísáyà ṣàpèjúwe rẹ̀?
11 Nígbà náà, ó bá a mu wẹ́kú bí Aísáyà ṣe lo ọgbà àjàrà àti ohun tó ti ibẹ̀ wá láti fi ṣàpèjúwe ohun tí yóò yọrí sí fún ilẹ̀ náà bí Jèhófà bá ti fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn, ó ní: “Wáìnì tuntun ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀, àjàrà ti rọ, gbogbo àwọn tí ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn-àyà ti bẹ̀rẹ̀ sí mí ìmí ẹ̀dùn. Ayọ̀ ńláǹlà àwọn ìlù tanboríìnì ti kásẹ̀ nílẹ̀, ariwo àwọn ẹni tí ayọ̀ kún inú wọn fọ́fọ́ ti dẹ́kun, ayọ̀ ńláǹlà háàpù ti kásẹ̀ nílẹ̀. Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin; ọtí tí ń pani ti di kíkorò fún àwọn tí ń mu ún. Ìlú tí a kọ̀ tì ni a ti wó lulẹ̀; gbogbo ilé ni a ti tì pa, kí ó má bàa ṣeé wọ̀. Igbe ẹkún ń bẹ ní àwọn ojú pópó nítorí àìsí wáìnì. Gbogbo ayọ̀ yíyọ̀ ti kọjá lọ; ayọ̀ ńláǹlà ilẹ̀ náà ti lọ. Nínú ìlú ńlá, ipò ìyàlẹ́nu ni a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn; ẹnubodè ni a ti fọ́ túútúú di òkìtì àlàpà lásán-làsàn.”—Aísáyà 24:7-12.
12 Tanboríìnì àti háàpù jẹ́ ohun èlò alárinrin tí wọ́n fi ń yin Jèhófà àti fún fífi ìdùnnú ẹni hàn. (2 Kíróníkà 29:25; Sáàmù 81:2) A ò ní gbúròó orin wọn lákòókò ìbínú Ọlọ́run yìí. Kò ní sí ayọ̀ ìkórè àjàrà. Kò ní sí ìró ayọ̀ kankan nínú ahoro àlàpà Jerúsálẹ́mù, ìlú tí wọ́n ti “fọ́” ẹnubodè rẹ̀ “túútúú di òkìtì àlàpà lásán-làsàn,” tí àwọn ilé rẹ̀ sì di èyí tí wọ́n “ti pa” kẹ́nikẹ́ni máa baà wọ̀ ọ́. Àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn olùgbé ilẹ̀ tó jẹ́ ọlọ́ràá gidigidi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ yìí mà ga o!
Àṣẹ́kù “Fi Ìdùnnú Ké Jáde”
13, 14. (a) Àwọn òfin wo ni Jèhófà ṣe lórí ọ̀ràn ìkórè? (b) Báwo ni Aísáyà ṣe lo àwọn òfin tó wà nípa ọ̀ràn ìkórè láti fi ṣàpèjúwe bí àwọn kan yóò ṣe la ìdájọ́ Jèhófà já? (d) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ìdẹwò tó bani nínú jẹ́ ń bọ̀, kí làwọn olóòótọ́ ní Júdà mọ̀ dájú pé ó ń bẹ níwájú fún àwọn?
13 Ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi ọ̀pá lu igi ólífì kí èso rẹ̀ lè já bọ́ tí wọ́n bá ń kórè rẹ̀. Òfin Ọlọ́run wá kà á léèwọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ padà gun igi rẹ̀ láti ká èso tó bá ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Wọn kò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́ ọgbà àjàrà wọn lẹ́yìn ìkórè. Àwọn tálákà lèyí tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn ìkórè wà fún, ìyẹn ni, “fún àwọn àtìpó, fún àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti fún àwọn opó” láti pèéṣẹ́ rẹ̀. (Diutarónómì 24:19-21) Òfin táwọn èèyàn mọ̀ dunjú yìí ni Aísáyà lò láti fi ṣàlàyé ọ̀ràn kan tó dùn mọ́ni, ìyẹn ni pé, àwọn kan yóò la ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ yẹn já, ó ní: “Nítorí pé báyìí ni yóò dà ní àárín ilẹ̀ náà, láàárín àwọn ènìyàn, bí lílu igi ólífì, bí èéṣẹ́ nígbà tí kíkó èso àjàrà jọ bá ti wá sí òpin. Àwọn alára yóò gbé ohùn wọn sókè, wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde. Dájúdájú, nínú ìlọ́lájù Jèhófà ni wọn yóò ké jáde lọ́nà híhan gan-an-ran láti òkun wá. Ìdí nìyẹn tí wọn yóò fi máa yin Jèhófà lógo ní ẹkùn ilẹ̀ ìmọ́lẹ̀, wọn yóò máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lógo ní àwọn erékùṣù òkun. Láti ìkángun ilẹ̀ náà, àwọn orin atunilára ń bẹ tí àwa ti gbọ́, pé: ‘Ìṣelóge fún Olódodo!’”—Aísáyà 24:13-16a.
14 Bí èso ṣe máa ń ṣẹ́ kù sórí igi tàbí àjàrà lẹ́yìn ìkórè, bẹ́ẹ̀ làwọn kan ṣe máa ṣẹ́ kù lẹ́yìn ìdájọ́ Jèhófà, ìyẹn àwọn “èéṣẹ́ nígbà tí kíkó èso àjàrà jọ bá ti wá sí òpin.” Wòlíì yìí ti sọ ọ́ ṣáájú, ìyẹn ní Ais 24 ẹsẹ kẹfà, pé ‘ìwọ̀nba kéréje ẹni kíkú sì ṣẹ́ kù.’ Àwọn kan yóò la ìparun Jerúsálẹ́mù àti Júdà já síbẹ̀síbẹ̀, bó ti wù kí iye wọ́n kéré tó, lẹ́yìn náà, àṣẹ́kù yóò tún padà wá láti ìgbèkùn láti máa wá gbé ilẹ̀ náà. (Aísáyà 4:2, 3; 14:1-5) Lóòótọ́, àkókò ìdẹwò tó bani nínú jẹ́ yóò dé bá àwọn ọlọ́kàn títọ́, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìdáǹdè àti ayọ̀ ń bẹ níwájú fún wọn. Àwọn tó là á já yìí yóò rí i bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣe ń ṣẹ, wọn yóò wá rí i pé wòlíì Ọlọ́run ni Aísáyà jẹ́ lóòótọ́. Ayọ̀ yóò kún inú wọn bí wọ́n ṣe ń rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò yẹn. Láti ibikíbi tí wọ́n bá fọ́n ká sí, ìbáà jẹ́ inú àwọn erékùṣù Mẹditaréníà níhà Ìwọ̀ Oòrùn, tàbí Bábílónì ní “ẹkùn ilẹ̀ ìmọ́lẹ̀” (ìyẹn ìhà yíyọ oòrùn, tàbí Ìlà Oòrùn), tàbí ọ̀nà jíjìn rere yòówù kó jẹ́, wọn yóò máa yin Ọlọ́run nítorí pé ó dá wọn sí, wọn yóò sì kọrin pé: “Ìṣelóge fún Olódodo!”
Ẹnikẹ́ni Ò Ní Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdájọ́ Jèhófà
15, 16. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà Aísáyà nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Àjálù wo ni yóò já lu àwọn olùgbé ilẹ̀ náà?
15 Àmọ́ ní báyìí, àsìkò ayọ̀ ò tíì tó. Aísáyà wá dá àwọn èèyàn ìgbà tirẹ̀ padà sí ohun tó ṣì ń ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ní: “Ṣùgbọ́n mo wí pé: ‘Rírù ń bẹ fún mi, rírù ń bẹ fún mi! Mo gbé! Àwọn olùṣe àdàkàdekè ti ṣe àdàkàdekè. Àní àwọn olùṣe àdàkàdekè ti fi àdàkàdekè hùwà lọ́nà àdàkàdekè.’ Ìbẹ̀rùbojo àti ibi jíjinkòtò àti pańpẹ́ ń bẹ lórí rẹ, ìwọ olùgbé ilẹ̀ náà. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sá fún ìró ohun tí ń kó ìbẹ̀rùbojo bá a yóò já sínú ibi jíjinkòtò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń gòkè bọ̀ láti inú ibi jíjinkòtò ni pańpẹ́ yóò mú. Nítorí pé, àní àwọn ibodè ibú omi ibi gíga lókè ni a óò ṣí ní ti tòótọ́, àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ náà yóò sì mì jìgìjìgì. Ilẹ̀ náà ti fọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ dájúdájú, ilẹ̀ náà ni a ti gbọ̀n jìgìjìgì dájúdájú, ilẹ̀ náà ni a ti mú ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ dájúdájú. Ilẹ̀ náà ń rìn tàgétàgé dájúdájú bí ọ̀mùtípara, ó sì ń fì síhìn-ín sọ́hùn-ún bí ahéré alóre. Ìrélànàkọjá rẹ̀ sì ti di wíwúwo lórí rẹ̀, yóò sì ṣubú, tí kì yóò tún dìde mọ́.”—Aísáyà 24:16b-20.
16 Ìbànújẹ́ bá Aísáyà nítorí àjálù tí yóò já lu àwọn èèyàn rẹ̀. Bí nǹkan ṣe ń lọ láyìíká rẹ̀ dá àìsàn sí i lára, ó sì tún ń bà á lọ́kàn jẹ́. Àwọn aládàkàdekè gbòde kan, wọ́n sì ń kó ìbẹ̀rùbojo bá àwọn olùgbé ilẹ̀ náà. Bí Jèhófà bá ti fawọ́ ààbò rẹ̀ sẹ́yìn, tọ̀sán tòru ni jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ará Júdà aláìṣòótọ́. Inú-fu ẹ̀dọ̀-fu ni wọn yóò máa wà. Wọn ò lè mórí bọ́ nínú àjálù tí ń bọ̀ wá sórí wọn nítorí pé wọ́n kọ òfin Jèhófà sílẹ̀, wọn ò sì ka ọgbọ́n Ọlọ́run sí. (Òwe 1:24-27) Ègbé ń bọ̀ dandan ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aládàkàdekè ilẹ̀ náà ń fi èké àti ẹ̀tàn ti àwọn olùgbé ibẹ̀ sọ́nà ìparun bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. (Jeremáyà 27:9-15) Ńṣe làwọn ọ̀tá yóò ti ibòmíràn wọlé tọ̀ wọ́n wá, wọn óò kó wọn lẹ́rù, wọn óò sì mú wọn lóǹdè. Gbogbo ìwọ̀nyí ló kó ìdààmú bá Aísáyà gidigidi.
17. (a) Èé ṣe tí ẹnikẹ́ni kò fi ní lè mórí bọ́? (b) Bí Jèhófà bá ti rán agbára ìdájọ́ rẹ̀ jáde láti òkè ọ̀run, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ náà?
17 Síbẹ̀, dandan ni kí wòlíì yìí sọ ọ́ gbangba pé kò sẹ́ni tó máa mórí bọ́. Ibi yòówù kí àwọn èèyàn gbìyànjú láti sá gbà, ọwọ́ á tẹ̀ wọ́n ṣáá ni. Àwọn kan lè mórí bọ́ nínú àgbákò kan, ṣùgbọ́n wọ́n á kó sínú òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni, kó ní sí ààbò kankan fún wọn. Ọ̀ràn wọn yóò rí bí ìgbà tí ẹranko tó ń sá fún ọdẹ fo kòtò tó sì wá kó sínú pańpẹ́. (Fi wé Ámósì 5:18, 19.) Jèhófà yóò rán agbára ìdájọ́ rẹ̀ jáde láti òkè ọ̀run, yóò sì mi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ náà tìtì. Ilẹ̀ náà yóò ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ọ̀mùtí, yóò ṣubú, kò ní lè dìde mọ́, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóò rìn ín mọ́lẹ̀ síbẹ̀. (Ámósì 5:2) Kò sóhun tó lè yí ìdájọ́ Jèhófà padà. Ìparun yán-án yán-án ni yóò dé bá ilẹ̀ náà.
Jèhófà Yóò Jọba Tògo-Tògo
18, 19. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga” tọ́ka sí, báwo ni wọ́n sì ṣe kó wọn jọ sí “inú àjà ilẹ̀”? (b) Báwo ló ṣe jọ pé wọ́n máa yí àfiyèsí sí “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga” lẹ́yìn “ọjọ́ púpọ̀ yanturu”? (d) Báwo ni Jèhófà ṣe yí àfiyèsí sí “àwọn ọba lórí ilẹ̀”?
18 Wàyí o, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá rìn jìnnà kọjá ọ̀ràn àwọn ará Júdà, ó wá sọ nípa bí ète Jèhófà yóò ṣe ṣẹ ní paríparì rẹ̀, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga ní ibi gíga, àti sí àwọn ọba ilẹ̀ lórí ilẹ̀. Ṣe ni a ó fi ìkójọ bí ti àwọn ẹlẹ́wọ̀n kó wọn jọ sínú kòtò, a ó sì tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀; a ó sì fún wọn ní àfiyèsí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀ yanturu. Òṣùpá àrànmọ́jú sì ti tẹ́, ìtìjú sì ti bá oòrùn tí ń ràn yòò, nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti di ọba tògo-tògo ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù àti ní iwájú àwọn àgbàlagbà ọkùnrin rẹ̀.”—Aísáyà 24:21-23.
19 Ó ṣeé ṣe kí “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga” tọ́ka sí àwọn ẹ̀mí èṣù tó jẹ́ “àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Àwọn wọ̀nyí ló ti nípa lórí àwọn agbára ayé gan-an ni. (Dáníẹ́lì 10:13, 20; 1 Jòhánù 5:19) Góńgó wọn ni láti yí àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti kúrò nínú ìjọsìn rẹ̀ mímọ́ gaara. Wọ́n sì rí Ísírẹ́lì tàn jẹ gan-an ni, tí wọ́n fi mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí hu àwọn ìwà ìbàjẹ́ táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọ́n ká ń hù, tí ìdájọ́ Ọlọ́run fi dé sórí wọn! Àmọ́ dandan ni kí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gba ìdájọ́ Ọlọ́run nígbà tí Ọlọ́run bá yí àfiyèsí sí àwọn àtàwọn alákòóso ayé, ìyẹn “àwọn ọba ilẹ̀ lórí ilẹ̀,” tí wọ́n ti mú kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa rú àwọn òfin rẹ̀. (Ìṣípayá 16:13, 14) Aísáyà lo èdè àpèjúwe, ó ní wọ́n máa kó wọn jọ, wọ́n á sì “tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀.” “Lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀ yanturu,” bóyá nígbà tí wọ́n bá tú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi (èyí kò kan “àwọn ọba ilẹ̀ lórí ilẹ̀”), Ọlọ́run yóò wá fi ìyà ìkẹyìn tó tọ́ sí wọn jẹ wọ́n.—Ìṣípayá 20:3, 7-10.
20. Báwo ni Jèhófà ṣe “di ọba” láyé àtijọ́ àti lóde òní, ìgbà wo ló sì “di ọba”?
20 Ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí wá tipa báyìí fún àwọn Júù ní ìdánilójú ńláǹlà. Bí àkókò bá ti tó lójú Jèhófà, yóò mú kí Bábílónì àtijọ́ ṣubú, yóò sì dá àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tó lo agbára àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lọ́nà yìí nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n lè sọ fún wọn ní tòótọ́ pé: “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!” (Aísáyà 52:7) Lóde òní, Jèhófà “di ọba” lọ́dún 1914 nígbà tó fi Jésù Kristi jẹ Ọba nínú Ìjọba Rẹ̀ ti Ọ̀run. (Sáàmù 96:10) Ó tún “di ọba” lọ́dún 1919 nígbà tó lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba láti fi dá Ísírẹ́lì tẹ̀mí nídè kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá.
21. (a) Báwo ni ‘òṣùpá àrànmọ́jú yóò ṣe tẹ́, tí ìtìjú yóò sì fi bá oòrùn tí ń ràn yòò’? (b) Ìpè tó dún lọ rére wo ni yóò ní ìmúṣẹ rẹ̀ títóbi jù lọ?
21 Jèhófà yóò tún “di ọba” nígbà tó bá pa Bábílónì Ńlá àti ìyókù ètò nǹkan burúkú yìí run. (Sekaráyà 14:9; Ìṣípayá 19:1, 2, 19-21) Lẹ́yìn náà, ọlá ńlá Ìjọba Jèhófà yóò wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó jẹ́ pé ògo ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ọ̀sán ganrínganrín kò ní lè tó ògo tirẹ̀. (Fi wé Ìṣípayá 22:5.) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìtìjú yóò bá òṣùpá àti oòrùn bí wọ́n bá fi ara wọn wé ọ̀gá ògo, Jèhófà ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Jèhófà ni yóò borí ohun gbogbo. Agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè àti ògo rẹ̀ yóò wá hàn gbangba sí ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:8-11; 5:13, 14) Ìrètí yìí mà ga lọ́lá o! Ní ìgbà náà, ìpè tó wà nínú Sáàmù 97:1 yóò wá dún lọ rére jákèjádò ayé ní ìmúṣẹ rẹ̀ títóbi jù lọ, pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba! Kí ilẹ̀ ayé kún fún ìdùnnú. Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù máa yọ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 262]
A ò ní gbúròó orin àti ayọ̀ yíyọ̀ mọ́ ní ilẹ̀ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 265]
Àwọn kan yóò la ìdájọ́ Jèhófà já, gẹ́gẹ́ bí èso ṣe ń ṣẹ́ kù sórí igi lẹ́yìn ìkórè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 267]
Ìbànújẹ́ bá Aísáyà nítorí àjálù tí yóò já lu àwọn èèyàn rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 269]
Ògo òṣùpá tàbí ti oòrùn kò ní tó ògo Jèhófà