ORÍ 52
Ó Fi Ìwọ̀nba Búrẹ́dì àti Ẹja Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Èèyàn
MÁTÍÙ 14:13-21 MÁÀKÙ 6:30-44 LÚÙKÙ 9:10-17 JÒHÁNÙ 6:1-13
JÉSÙ BỌ́ ẸGBẸ̀RÚN MÁRÙN-ÚN ỌKÙNRIN
Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ti wàásù káàkiri Gálílì, wọ́n ròyìn “gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì fi kọ́ni” fún Jésù. Ó dájú pé á ti rẹ̀ wọ́n. Síbẹ̀, wọn ò ráyè sinmi débi tí wọ́n á jẹun torí pé báwọn èèyàn ṣe ń wá ni wọ́n ń lọ. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”—Máàkù 6:30, 31.
Torí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi níbì kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìtòsí Kápánáúmù, wọ́n sì forí lé ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì ní ìkọjá Bẹtisáídà. Àmọ́, àwọn kan rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ, àwọn míì sì gbọ́ nípa rẹ̀, torí náà wọ́n sáré dé ibẹ̀ ṣáájú wọn.
Nígbà tó sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn sì ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í “kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan” nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 6:34) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń “ṣe ìwòsàn fún àwọn tó nílò ìwòsàn.” (Lúùkù 9:11) Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ fún un pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”—Mátíù 14:15.
Jésù wá sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” (Mátíù 14:16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti mọ ohun tóun máa tó ṣe, ó dán Fílípì wò, ó bí i pé: “Ibo la ti máa ra búrẹ́dì táwọn èèyàn yìí máa jẹ?” Fílípì ló sì yẹ kí wọ́n bi torí pé ìlú Bẹtisáídà tó wà nítòsí wọn ló ti wá. Àmọ́ tí wọ́n bá tiẹ̀ ríbi tí wọ́n ti máa ra búrẹ́dì, wọn ò lè rí èyí tó máa ká gbogbo wọn torí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀. Iye yẹn sì máa jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n bá ka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀. Fílípì wá sọ pé: “Búrẹ́dì igba (200) owó dínárì [dínárì kan ni owó tí òṣìṣẹ́ ń gbà fún iṣẹ́ ọjọ́ kan] ò lè tó wọn, ká tiẹ̀ ní díẹ̀ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa jẹ.”—Jòhánù 6:5-7.
Áńdérù gbà pé kò sí báwọn ṣe fẹ́ rí oúnjẹ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, torí náà ó sọ pé: “Ọmọdékùnrin kan nìyí tó ní búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì. Àmọ́ kí ni èyí já mọ́ láàárín àwọn tó pọ̀ tó yìí?”—Jòhánù 6:9.
Ìgbà ìrúwé ni àsìkò yìí, Ìrékọjá ọdún 32 S.K. ti sún mọ́lé, koríko tútù sì ti bo àwọn òkè. Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta (50) sí ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn. Jésù wá mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn ìyẹn, ó bu búrẹ́dì, ó sì pín àwọn ẹja náà. Ó wá gbé e fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n pín in fáwọn èèyàn. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé gbogbo wọn ló jẹ tí wọ́n sì yó bámúbámú!
Nígbà tó yá, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.” (Jòhánù 6:12) Ó yani lẹ́nu pé odindi apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12) ni wọ́n tún rí kó jọ!