ORÍ 129
Pílátù Sọ Pé: “Ẹ Wò Ó! Ọkùnrin Náà Nìyí!”
MÁTÍÙ 27:15-17, 20-30 MÁÀKÙ 15:6-19 LÚÙKÙ 23:18-25 JÒHÁNÙ 18:39–19:5
PÍLÁTÙ GBÌYÀNJÚ LÁTI TÚ JÉSÙ SÍLẸ̀
ÀWỌN JÚÙ NÍ KÍ WỌ́N TÚ BÁRÁBÀ SÍLẸ̀
WỌ́N FI JÉSÙ ṢE YẸ̀YẸ́, WỌ́N SÌ FÌYÀ JẸ Ẹ́
Pílátù sọ fáwọn èèyàn tó fẹ̀sùn èké kan Jésù pé: “Mi ò rí ẹ̀rí pé ọkùnrin yìí jẹ̀bi ìkankan nínú ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án. Kódà, Hẹ́rọ́dù náà ò rí ẹ̀rí.” (Lúùkù 23:14, 15) Àmọ́ torí pé ó wu Pílátù láti dá Jésù sílẹ̀, ó dá ọgbọ́n kan, ó sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá. Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”—Jòhánù 18:39.
Pílátù rántí pé ọkùnrin kan wà lẹ́wọ̀n tó ń jẹ́ Bárábà, ògbójú olè ni, ó máa ń dìtẹ̀ síjọba, apààyàn sì ni. Torí náà Pílátù bi wọ́n pé: “Ta lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín, ṣé Bárábà ni àbí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Àwọn èèyàn náà ní kí Pílátù tú Bárábà sílẹ̀, àwọn olórí àlùfáà ló sì mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀. Pílátù béèrè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Èwo nínú àwọn méjèèjì lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín?” Àwọn èèyàn náà tún pariwo pé: “Bárábà”!—Mátíù 27:17, 21.
Ohun tí wọ́n sọ yẹn ya Pílátù lẹ́nu, ló bá bi wọ́n pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Àwọn èèyàn náà pariwo pé: “Kàn án mọ́gi!” (Mátíù 27:22) Kò tiẹ̀ jọ wọ́n lójú pé aláìṣẹ̀ ni wọ́n fẹ́ pa. Pílátù wá bi wọ́n pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Mi ò rí ohunkóhun tó ṣe tí ikú fi tọ́ sí i; torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́, màá sì tú u sílẹ̀.”—Lúùkù 23:22.
Pàbó ni gbogbo ìsapá Pílátù láti tú Jésù sílẹ̀ ń já sí, torí pé inú ń bí àwọn èèyàn yẹn, ṣe ni wọ́n pohùn pọ̀, tí wọ́n sì ń sọ fún Pílátù pé: “Kàn án mọ́gi!” (Mátíù 27:23) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ṣi àwọn èèyàn yẹn lọ́nà débi pé wọ́n ṣáà fẹ́ ta ẹ̀jẹ̀ Jésù sílẹ̀! Ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ni wọ́n fẹ́ ta sílẹ̀, ẹni tí kì í ṣe ọ̀daràn tàbí apààyàn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ márùn-ún sẹ́yìn làwọn èèyàn kí i káàbọ̀ sí Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ, tí wọ́n sì pọ́n ọn lé bí Ọba. Ó dájú pé táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá wà níbi tí wọ́n ti ní kí wọ́n kàn án mọ́gi yìí, ṣe ni wọ́n máa dákẹ́, tí wọ́n á sì fara pa mọ́.
Pílátù rí i pé ọ̀rọ̀ òun ò tà létí àwọn èèyàn tó ń fẹ̀sùn kan Jésù. Ṣe làwọn èèyàn náà kàn ń pariwo ṣáá, torí náà Pílátù bu omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó wá sọ pé: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ wá nǹkan ṣe sí i.” Ìyẹn ò tiẹ̀ tu irun kankan lára wọn, ṣe ni wọ́n tún ń sọ pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí àwa àti àwọn ọmọ wa.”—Mátíù 27:24, 25.
Gómìnà yìí mọ ohun tó yẹ kó ṣe, àmọ́ ó wù ú láti tẹ́ àwọn èèyàn yẹn lọ́rùn. Torí náà, ó tú Bárábà sílẹ̀, ó wá ní kí wọ́n bọ́ aṣọ Jésù kí wọ́n sì nà án.
Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun yẹn na Jésù nínàkunà, wọ́n mú un pa dà sí ààfin gómìnà. Àwọn ọmọ ogun náà wá kóra jọ, wọ́n sì túbọ̀ ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé kan, wọ́n dé e fún un, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọn lórí. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi ọ̀pá esùsú sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ ìlékè rírẹ̀dòdò kan bò ó lára, irú èyí tí àwọn ọba máa ń wọ̀. Wọ́n wá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “A kí ọ o, ìwọ Ọba Àwọn Júù!” (Mátíù 27:28, 29) Wọ́n ń tutọ́ sí i lára, wọ́n sì ń gbá ojú rẹ̀. Wọ́n gba ọ̀pá esùsú lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbá orí rẹ̀ kí wọ́n lè túbọ̀ tẹ ẹ̀gún tó wà lára “adé” náà mọ́ ọn lórí.
Pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fojú Jésù rí, bí Jésù ṣe dúró digbí láìmikàn wú Pílátù lórí gan-an, torí náà ó fẹ́ wá bó ṣe máa yọ ara ẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí, ó wá sọ pé: “Ẹ wò ó! Mo mú un jáde wá bá yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.” Ṣé ó ṣeé ṣe kí Pílátù ronú pé àwọn èèyàn yẹn máa jáwọ́ tí wọ́n bá rí bí ara Jésù ṣe bẹ́ yánnayànna, tí ẹ̀jẹ̀ sì ti bò ó? Bí wọ́n ṣe mú Jésù dúró síwájú àwọn ọ̀dájú yẹn, Pílátù sọ pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin náà nìyí!”—Jòhánù 19:4, 5.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ti dá ọgbẹ́ sí i lára, bí Jésù ṣe dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní láti wú Pílátù lórí, torí ohun tó sọ fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún Jésù, ó sì káàánú rẹ̀.