ORIN 29
À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà ológo, Olódùmarè,
Orísun òótọ́, ọlọ́gbọ́n pípé.
Òdodo, agbára àtìfẹ́ rẹ pọ̀;
Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run.
Àwa èèyàn rẹ ń láyọ̀ báa ṣe ńsìn ọ́.
À ń fayọ̀ sọ òótọ́ Ìjọba rẹ.
(ÈGBÈ)
Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá.
2. Ìfẹ́ ń mú ká máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́.
Ó ń mú ká ṣiṣẹ́ pọ̀ lálàáfíà.
Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń mú káyé wa dára;
Inú wa ń dùn bá a ṣe ń gbógo rẹ yọ.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà laráyé ń pè wá,
Èyí ń jẹ́ ká lè fi kún iyì rẹ.
(ÈGBÈ)
Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá.
(Tún wo Diu. 32:4; Sm. 43:3; Dán. 2:20, 21.)