ORIN 45
Àṣàrò Ọkàn Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Kí àwọn èrò ọkàn mi,
Tí mò ń ṣàṣàrò lé lórí
Máa múnú rẹ dùn, Jèhófà,
Kó sì mú kí n dúró ṣinṣin.
T’àníyàn bá bò mí mọ́lẹ̀,
Tí kò jẹ́ kí n lè sùn lóru,
Kí n máa rántí rẹ, Jèhófà,
Àti àwọn ohun tó tọ́.
2. Gbogbo ohun tó jẹ́ mímọ́
Àti àwọn ìwà rere;
Ohun tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa,
Ni mo fẹ́ máa rò lọ́kàn mi.
Jáà, ìrònú rẹ dára gan-an!
Ó pọ̀ kọjá àfẹnusọ.
Màá ṣàṣàrò lé ọ̀rọ̀ rẹ,
Jọ̀ọ́, jẹ́ kó máa gbà mí lọ́kàn.
(Tún wo Sm. 49:3; 63:6; 139:17, 23; Fílí. 4:7, 8; 1 Tím. 4:15.)