Máa Ṣàṣàrò Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 TÍM. 4:15.
1, 2. Àwọn nǹkan wo ló mú kí ọpọlọ èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀?
ỌLỌ́RUN dá ọpọlọ àwa èèyàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwa èèyàn lè kọ́ èdè, èyí sì ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kàwé tàbí láti kọ̀wé, ó tún ń mú ká lóye ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹlòmíì bá sọ, ká gbàdúrà ká sì kọrin ìyìn sí Jèhófà. Àwọn nǹkan yìí jẹ́ àgbàyanu, ọpọlọ wa ló sì ń mú kí gbogbo rẹ̀ ṣeé ṣe, kódà àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lóye bí èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó kẹ́kọ̀ọ́ èdè sọ pé: “Bí àwọn ọmọdé ṣe lè kọ́ èdè tuntun kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó mú káwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀.”
2 Èdè jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti kọ́ ọ, ká sì máa lò ó. (Sm. 139:14; Ìṣí. 4:11) Síbẹ̀, ọ̀nà pàtàkì míì wà tí ọpọlọ wa gbà ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọlọ́run dá wa ní “àwòrán” ara rẹ̀, ìyẹn ló sì mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko. A ní òmìnira láti pinnu ohun tá a bá fẹ́, a sì lè fi èdè tá a gbọ́ yin Ọlọ́run lógo.—Jẹ́n. 1:27.
3. Ẹ̀bùn àgbàyanu wo ni Jèhófà fún wa ká lè jẹ́ ọlọgbọ́n?
3 Ọlọ́run tún fún gbogbo àwọn tó fẹ́ máa bọlá fún un ní ẹ̀bùn àgbàyanu kan, ìyẹn Bíbélì. Odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ti wà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800]. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Sm. 40:5; 92:5; 139:17) Nípa bẹ́ẹ̀, wàá máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan “tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.”—Ka 2 Tímótì 3:14-17.
4. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣàṣàrò, àwọn ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò?
4 Ẹni tó bá ń ṣàṣàrò máa ń pọkàn pọ̀, ó sì máa ń fẹ̀sọ̀ ronú lé nǹkan lórí. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ohun tó dára tàbí ohun tó burú. (Sm. 77:12; Òwe 24:1, 2) Àwọn méjì tó dára jù lọ tá a lè ṣàṣàrò lé lórí ni Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. (Jòh. 17:3) Àmọ́, kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín kíkàwé àti ṣíṣe àṣàrò? Àwọn nǹkan wo la lè ṣàṣàrò lé lórí? Báwo la ṣe lè máa ṣàṣàrò déédéé ká sì mú kó gbádùn mọ́ wa?
RÍ I DÁJÚ PÉ Ò Ń JÀǸFÀÀNÍ LÁTINÚ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ
5, 6. Tó o bá ń kàwé, kí ló máa mú kó o túbọ̀ lóye ohun tó ò ń kà, kó o sì rántí rẹ̀?
5 Ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu ni ọpọlọ wa ń ṣe tá ò sì ní mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a kì í mọ gbogbo nǹkan tó ń lọ nínú ọpọlọ wa tá a bá ń mí, tá à ń rìn, tá à ń wa kẹ̀kẹ́ tàbí tá à ń tẹ̀wé. Bó ṣe máa ń rí tá a bá ń kàwé náà nìyẹn, a lè máa kàwé lọ ṣùgbọ́n kí ọkàn wa máà sí nínú ohun tá à ń kà torí pé ọpọlọ wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan míì. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká pọkàn pọ̀ sórí ìtumọ̀ ohun tá à ń kà. Bá a ṣe ń kàwé lọ, a lè dúró díẹ̀ tá a bá parí ìpínrọ̀ kan tàbí ká tó lọ sí ìsọ̀rí míì, ká wá fẹ̀sọ̀ ronú lórí ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán, ká lè rí i dájú pé a lóye rẹ̀ dáadáa. Tá a bá jẹ́ kí àwọn ohun míì gbà wá lọ́kàn, a lè má pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń kà, a ò sì ní jàǹfààní látinú rẹ̀. Kí la wá lè ṣe kí ìyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa?
6 Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé téèyàn bá ń ka ọ̀rọ̀ sókè nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́, ó máa rọrùn fún un láti rántí ohun tó kà. Ọlọ́run tó dá ọpọlọ wa náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Jóṣúà pé kó máa fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” ka ìwé Òfin Ọlọ́run. (Ka Jóṣúà 1:8.) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti rí i pé tó o bá ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Bíbélì, wàá lè pọkàn pọ̀ dáadáa, ohun tó ò ń kà á sì túbọ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn.
7. Ìgbà wo ló dáa jù láti ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé kíkà lè má gba ìsapá rẹpẹtẹ, èèyàn gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ kó tó lè ṣàṣàrò. Ìdí nìyẹn tí ọpọlọ àwa ẹ̀dá aláìpé fi máa ń fẹ́ ṣe ohun tí kò gba ìsapá púpọ̀. Torí náà, ìgbà tí ara wa bá silé, tá a wà níbi tí kò sí ariwo, tí ọkàn wa sì pa pọ̀ ló dáa jù ká ṣe àṣàrò. Onísáàmù náà rí i pé ìgbà tóun bá jí lóru ló wu òun jù lọ láti máa ṣàṣàrò. (Sm. 63:6) Kódà, Jésù tó ní ọpọlọ pípé mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wá ibi tó parọ́rọ́ láti ṣàṣàrò àti láti gbàdúrà.—Lúùkù 6:12.
ÀWỌN OHUN TÓ DÁA KÁ ṢÀṢÀRÒ LÉ LÓRÍ
8. (a) Yàtọ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí la tún lè ṣàṣàrò lé lórí? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àkókò tá a fi ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn?
8 Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà ṣàṣàrò ni pé ká máa ronú lórí àwọn ohun tá a kà nínú Bíbélì. Àmọ́, kò mọ síbẹ̀ o. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń wo ohun àgbàyanu kan tí Ọlọ́run dá, máa ronú lórí ohun tó o rí. Èyí á mú kó o máa yin Jèhófà torí oore rẹ̀, tó o bá sì wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, wàá sọ bó o ṣe mọyì àwọn ohun tí Jèhófà dá fún wọn. (Sm. 104:24; Ìṣe 14:17) Ǹjẹ́ Jèhófà mọyì bá a ṣe ń yìn ín torí àwọn ohun tó dá àti bá a ṣe ń sọ fáwọn ẹlòmíì nípa Rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn lọ sínú Bíbélì. Jèhófà ṣèlérí nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko yìí pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.”—Mál. 3:16.
9. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì máa ṣàṣàrò lé lórí? (b) Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò tá a bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó máa “fẹ̀sọ̀ ronú” tàbí kó máa ṣàṣàrò lórí bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwà rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run. (Ka 1 Tímótì 4:12-16.) Bíi ti Tímótì, àwa náà ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa tá a lè ronú lé lórí. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò tá a bá ń múra sílẹ̀ láti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká ronú lórí ìbéèré tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tàbí àpèjúwe tó máa mú kí ohun tá à ń kọ́ wọn tètè yé wọn, kí wọ́n sì lè fi sílò. Àkókò tá a fi ń ronú nípa àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni gan-an torí pé ó máa mú kí ìgbàgbọ́ tiwa náà lágbára sí i, a ó sì lè máa fi ìtara darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́nà tó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Bó ṣe máa rí náà nìyẹn tá a bá ń múra ohun tá a máa sọ sílẹ̀ ká tó lọ sóde ẹ̀rí. (Ka Ẹ́sírà 7:10.) Tá a bá ka orí kan nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì ká tó lọ sóde ẹ̀rí, ó máa “rú” ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù “sókè bí iná.” Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn, àá lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà tó múná dóko. (2 Tím. 1:6) Ẹ máa ronú nípa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín àti ohun tó máa mú kí wọ́n fẹ́ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ yín. Tá a bá ń múra sílẹ̀ láwọn ọ̀nà tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, àá lè wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́ “pẹ̀lú ìfihàn ẹ̀mí àti agbára” látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 2:4.
10. Kí làwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa tá a tún lè ṣàṣàrò lé lórí?
10 Ṣé o máa ń ṣe àkọsílẹ̀ tó o bá ń tẹ́tí sí àsọyé, tó o bá wà ní àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè? Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀ yìí, wàá lè máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bákan náà, a lè ṣàṣàrò lórí àwọn ìwé ìròyìn wa irú bí Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àtàwọn ìtẹ̀jáde tuntun tá à ń rí gbà láwọn àpéjọ wa. Tó o bá ń ka Ìwé Ọdọọdún wa, máa dúró díẹ̀ lẹ́yìn tó o bá ka ìrírí kan tán kó o tó bọ́ sórí òmíràn. Ìyẹn á mú kó o lè fẹ̀sọ̀ ronú lórí ìrírí tó o kà, ìrírí náà á sì wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. O lè fàlà sábẹ́ àwọn kókó pàtàkì tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ tó máa wúlò fún ẹ sí etí ìwé náà. Àwọn àkọsílẹ̀ náà máa wúlò tó o bá ń múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò, ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tàbí àsọyé tó o máa sọ lọ́jọ́ iwájú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tó o bá ń dúró díẹ̀ láti ṣàṣàrò bó o ṣe ń ka àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ohun tó ò ń kà á túbọ̀ yé ẹ sí i wàá sì lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn ohun rere tó ò ń kọ́.
MÁA ṢÀṢÀRÒ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN LÓJOOJÚMỌ́
11. Kí ló yẹ ká máa ṣàṣàrò lé lórí jù lọ, kí sì nìdí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Ohun tó yẹ ká máa ṣàṣàrò lé lórí jù lọ ni Bíbélì tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ká tiẹ̀ sọ pé o wà níbì kan tí wọn ò ti gbà ẹ́ láyè láti ka Bíbélì, kò sẹ́ni tó máa ní kó o má ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀, irú bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o yàn láàyò àtàwọn orin Ìjọba Ọlọ́run.a (Ìṣe 16:25) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run á sì jẹ́ kó o rántí gbogbo nǹkan rere tó o ti kọ́.—Jòh. 14:26.
12. Ètò wo ló yẹ ká ṣe fún kíka Bíbélì déédéé?
12 A lè ya àwọn ọjọ́ kan sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ láti múra sílẹ̀ fún Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ká sì ṣàṣàrò lé e lórí. A lè fi àwọn ọjọ́ mìíràn ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó sọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Àwọn ìwé yìí ló ṣàlàyé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti ìgbésí ayé rẹ̀, wọ́n sì wà lára àwọn ìwé Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ jù. (Róòmù 10:17; Héb. 12:2; 1 Pét. 2:21) Kódà, àwa èèyàn Ọlọ́run ní ìwé kan tó ṣàlàyé nípa Jésù àtohun tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Wàá jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ tó o bá fara balẹ̀ ka ìwé yìí tó o sì ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú ìtàn kọ̀ọ̀kan.—Jòh. 14:6.
KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ MÁA ṢÀṢÀRÒ?
13, 14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò nípa Jèhófà àti Jésù, kí nìyẹn sì máa mú ká ṣe?
13 Tá a bá ń ṣàṣàrò nípa Jèhófà àti Jésù, òtítọ́ á jinlẹ̀ nínú wa. (Héb. 5:14; 6:1) Bí àkókò tí ẹnì kan ń lò láti ṣàṣàrò nípa Jèhófà àti Jésù ò bá tó nǹkan, ìgbàgbọ́ rẹ̀ á jó rẹ̀yìn. Ó ṣeé ṣe kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sú lọ díẹ̀díẹ̀ tàbí kó lọ kúrò nínú òtítọ́. (Héb. 2:1; 3:12) Jésù kìlọ̀ fún wa pé tá ò bá gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí ká gbà á “pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere,” a ò ní lè “dì í mú ṣinṣin.” “Àwọn àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn ìgbésí ayé yìí” lè gbé wa lọ, a ò sì ní lè mú “nǹkan kan wá sí ìjẹ́pípé.”—Lúùkù 8:14, 15.
14 Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí á mú ká máa gbé ògo Jèhófà yọ, ká sì fìwà jọ ọ́. (2 Kọ́r. 3:18) Àfi ká máa dúpẹ́ pé a láǹfààní láti mọ Ọlọ́run àti pé ó jẹ́ ká máa gbé ògo òun yọ. Bá a ṣe ń bá a nìṣó láti fìwà jọ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, títí láé la ó máa ní ìmọ̀ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, tá ó sì máa gbé ògo rẹ̀ yọ. Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́!—Oníw. 3:11.
15, 16. (a) Báwo lo ṣe lè jàǹfààní tó o bá ń fẹ̀sọ̀ ronú nípa Jèhófà àti Jésù? (b) Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣàṣàrò nígbà míì, àmọ́ kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró?
15 Tá a bá ń bá a nìṣó láti máa fẹ̀sọ̀ ronú nípa Jèhófà àti Jésù, ìtara tá a ní fún òtítọ́ ò ní jó rẹ̀yìn. Ìtara wa á máa fún àwọn ará àtàwọn ẹni tuntun tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí níṣìírí. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún wa, àá mọyì àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà, Baba wa Mímọ́. (Róòmù 3:24; Ják. 4:8) Arákùnrin Mark tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa tó lo ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n nítorí ohun tó gbà gbọ́, sọ pé: “Bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn-àjò tó gbádùn mọ́ni ni àṣàrò rí. Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ la ó máa mọ àwọn ohun tuntun nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa. Nígbà míì tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí mò ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, ńṣe ni màá gbé Bíbélì, màá ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ọkàn mi á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.”
16 Àwọn ohun tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ kún inú ayé lónìí débi pé ó máa ń ṣòro nígbà míì láti ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Arákùnrin Patrick tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Ńṣe ni ọkàn mi dà bí ibi tá à ń kó lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà sí, ó kún fún onírúurú ìsọfúnni tó wúlò àti èyí tí kò wúlò. Ojoojúmọ́ ni mo sì ní láti pinnu èyí tí màá lò. Bí mo ṣe ń yiiri ọkàn mi wò, mo sábà máa ń rí i pé àwọn ohun kan ‘ń gbé mi lọ́kàn sókè,’ mo sì ní láti gbàdúrà sí Jèhófà nípa wọn kí ọkàn mi lè fúyẹ́. Ìgbà yẹn ni màá tó lè ṣàṣàrò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gba àkókò kí n tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ ṣíṣe àṣàrò máa ń mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ lóye òtítọ́.” (Sm. 94:19) Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń “ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́” tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n kọ́ máa jàǹfààní lọ́pọ̀ yanturu.—Ìṣe 17:11.
WÁ ÀKÓKÒ LÁTI ṢÀṢÀRÒ
17. Báwo ló ṣe lè wá àkókò láti ṣàṣàrò?
17 Àwọn kan máa ń jí láàárọ̀ kùtù kí wọ́n lè kàwé, kí wọ́n ṣàṣàrò, kí wọ́n sì gbàdúrà. Awọn míì sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà oúnjẹ ọ̀sán. Ó lè jẹ́ pé ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ló máa rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí lálẹ́ kó o tó sùn. Àwọn kan fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì láàárọ̀ àti lálẹ́ kí wọ́n tó lọ sùn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń kà á “ní ọ̀sán àti ní òru,” tàbí déédéé. (Jóṣ. 1:8) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká máa lò lára àkókò tá a fi ń ṣe àwọn nǹkan míì láti máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́.—Éfé. 5:15, 16.
18. Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn tó ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ tí wọ́n sì ń sapá láti fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò?
18 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé òun máa bù kún gbogbo àwọn tó ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ òun tí wọ́n sì ń sapá láti fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, a jẹ́ ká lè máa bọlá fún Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá tó dá ọpọlọ wa. Kí wá lèyí á yọrí sí? Jèhófà á mú ká láyọ̀ nísinsìnyí a ó sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀.—Ják. 1:25; Ìṣí. 1:3.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “A Jà Fitafita Ká Lè Dúró Gbọin-gbọin Nínú Ìgbàgbọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2006.