ORIN 73
Fún Wa Ní Ìgboyà
(Ìṣe 4:29)
1. Báa ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba náà,
Tá à ń kéde orúkọ rẹ,
Àwọn tó ń ta kò wá pọ̀ gan-an;
Wọ́n fẹ́ kó ‘tìjú bá wa.
Àwa kò bẹ̀rù èèyàn.
Ìwọ la gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí.
Fún wa ní ẹ̀mí rẹ, Jèhófà;
Jọ̀ọ́ bàbá, gbọ́ àdúrà wa.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígboyà, ká wàásù.
Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.
Kì wá láyà, fún wa lókun
Ká lè wàásù fáráyé
Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán.
Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé,
Fún wa nígboyà, ká wàásù;
Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
2. Nígbà míì, ẹ̀rù lè bà wá.
O mọ̀ pérùpẹ̀ ni wá.
A mọ̀ pé wàá dúró tì wá;
Atóófaratì ni ọ́.
Àwọn ọ̀tá wa ń halẹ̀.
Wo bí wọ́n ṣe ń gbógun tì wá.
Ràn wá lọ́wọ́, ká má ṣe bọ́hùn
Báa ṣe ń wàásù lórúkọ rẹ.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígboyà, ká wàásù.
Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.
Kì wá láyà, fún wa lókun
Ká lè wàásù fáráyé
Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán.
Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé,
Fún wa nígboyà, ká wàásù;
Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
(Tún wo 1 Tẹs. 2:2; Héb. 10:35.)