Ǹjẹ́ O Ń Wàásù Láìṣojo?
1 Pétérù àti Jòhánù ń bá a nìṣó láti máa polongo iṣẹ́ Ìjọba náà láìṣojo bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò fàṣẹ ọba mú wọn, tí wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn. (Ìṣe 4:17, 21, 31) Kí ni wíwàásù láìṣojo túmọ̀ sí fún wa lónìí?
2 Jíjẹ́rìí Láìṣojo: Ọ̀rọ̀ kan tó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú “àìṣojo” ni “ìgboyà,” tó túmọ̀ sí pé “kéèyàn má bẹ̀rù rárá, kéèyàn láyà, kéèyàn sì ní ìfaradà.” Ní ti àwọn Kristẹni tòótọ́, wíwàásù láìṣojo túmọ̀ sí pé kéèyàn má fòyà láti sọ̀rọ̀ nígbà tí àkókò yíyẹ bá wà láti sọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 4:20; 1 Pét. 3:15) Ó túmọ̀ sí pé ojú kò tì wá láti sọ ìhìn rere náà. (Sm. 119:46; Róòmù 1:16; 2 Tím. 1:8) Nípa báyìí, àìṣojo jẹ́ ànímọ́ kan tí a nílò láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà tí a gbé lé wa lọ́wọ́ ní àkókò òpin yìí. Ó ń mú ká sọ ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn níbikíbi tí a bá ti lè rí wọn.—Ìṣe 4:29; 1 Kọ́r. 9:23.
3 Àìṣojo ní Ilé Ẹ̀kọ́: Ǹjẹ́ ìbẹ̀rù tàbí ìfòyà máa ń mú kó ṣòro fún ọ láti wàásù fún àwọn tí ẹ jọ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́? Ìgbà míì, kì í rọrùn; ká sòótọ́, ó lè jẹ́ ìpèníjà gidi. Ṣùgbọ́n, Jèhófà yóò fún ọ lókun tí o bá gbàdúrà fún àìṣojo láti lè wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. (Sm. 138:3) Àìṣojo yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ara rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yóò sì jẹ́ kí o lè kojú ìfiṣẹ̀sín. Ní àbájáde rẹ̀, wíwàásù tí o ń wàásù ní ilé ẹ̀kọ́ lè gba àwọn tó bá ń fetí sí ọ là.—1 Tím. 4:16.
4 Àìṣojo ní Ibi Iṣẹ́: Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ ọ́ ní ibi iṣẹ́ pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ fi lè gbọ́ nípa ìhìn rere ni pé kí o wàásù fún wọn. Àìṣojo rẹ yóò tún jẹ́ kí o lè tọrọ àyè níbi iṣẹ́ láti máa lọ sí àwọn ìpàdé àti àpéjọpọ̀ Kristẹni.
5 Àìṣojo Lábẹ́ Àdánwò: Ó ṣe pàtàkì pé ká máyà le nígbà tí a bá dojú kọ àtakò. (1 Tẹs. 2:1, 2) Ó máa ń jẹ́ kí a lè di ìgbàgbọ́ wa mú gírígírí nígbà tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ wa, tí wọ́n bá fi wá ṣẹ̀sín, tàbí tí wọ́n bá tilẹ̀ ṣenúnibíni sí wa ní tààràtà. (Fílí. 1:27, 28) Ó ń fún wa lágbára láti dúró ṣinṣin nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fagbára mú wa láti jáwọ́ nínú títẹ̀lé ìlànà Jèhófà, Ọlọ́run wa. Ó ń fún wa lókun láti máa wá àlàáfíà nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá dá awuyewuye sílẹ̀.—Róòmù 12:18.
6 Ìṣòro yòówù kí olúkúlùkù wa dojú kọ, ǹjẹ́ kí a tẹra mọ́ wíwàásù ìhìn rere náà láìṣojo.—Éfé. 6:18-20.