ORIN 96
Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
(Òwe 2:1)
1. Ìwé kan wà tó ṣeyebíye jù lọ,
Tó ń mú ‘rètí, ayọ̀, àlàáfíà wá.
Ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ lágbára gan-an;
Ó ń lani lóye, ó ń fúnni níyè.
Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìwé yẹn.
Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ ọ́.
Àwọn èèyàn yìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an,
Ó sì fẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn.
2. Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí ‘ṣẹ̀dá ṣe bẹ̀rẹ̀,
Bí Ọlọ́run ṣe dá àgbáyé yìí.
Wọ́n sọ bọ́kùnrin pípé náà ṣe dẹ́ṣẹ̀,
Tó sì pàdánù Párádísè náà.
Wọ́n sọ̀rọ̀ áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀,
Tó ta ko Ọlọ́run, tó fẹ̀sùn kàn án.
Èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àtikú fún wa,
Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Jèhófà yóò ṣẹ́gun!
3. Inú wa ń dùn gan-an lákòókò táa wà yìí
Pé Jèhófà ti fọmọ rẹ̀ jọba.
Èyí ló ń mú ká wàásù ìhìnrere;
À ń sọ̀rọ̀ ìbùkún ọjọ́ ‘wájú.
Ìwé ìṣúra tí Jèhófà fún wa,
Gbogbo ayé ló máa ṣe láǹfààní.
Ìwé tó yẹ kí gbogbo wa máa kà ni;
Ó ń jẹ́ ká ní àlàáfíà Ọlọ́run.
(Tún wo 2 Tím. 3:16; 2 Pét. 1:21.)