ORIN 105
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Bàbá wa ọ̀run jẹ́ ìfẹ́,
Ó ní káwa náà nífẹ̀ẹ́.
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa,
Tá a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn,
Ìgbé ayé wa á ládùn,
Ó sì máa jẹ́ ká níyè.
Jésù Kristi náà fìfẹ́ hàn;
Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
2. Ìfẹ́ tòótọ́ máa ń ta wá jí;
Ó máa ń mú ká fìfẹ́ hàn.
Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run
Máa s’agbára wa dọ̀tun.
Ìfẹ́ máa ń ṣoore, kìí jowú;
Ìfẹ́ máa ń ní ‘faradà.
Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;
Ká gbádùn ìfẹ́ tòótọ́.
3. Má di ẹnikẹ́ni sínú;
Má fàyè gba ìbínú.
Jèhófà ni kó o yíjú sí,
Àwọn òfin rẹ̀ dára.
Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,
Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa jinlẹ̀.
Ká fara wé Ọlọ́run wa;
Ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn.
(Tún wo Máàkù 12:30, 31; 1 Kọ́r. 12:31–13:8; 1 Jòh. 3:23.)