Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”—MÁTÍÙ 22:37.
1, 2. Kí ló ti ní láti fa ìbéèrè tó jẹ yọ nípa àṣẹ títóbi jù lọ?
Ẹ̀RÍ fi hàn pé ìbéèrè táwọn Farisí máa ń jiyàn lé lórí gan-an nígbà ayé Jésù ni pé, èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn Òfin Mósè tó lé ní ẹgbẹ̀ta? Ṣé òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú ìrúbọ ni? Kò sí àní-àní pé ìdí tí wọ́n fi máa ń rúbọ ni kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà kí wọ́n sì lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Àbí òfin nípa ìdádọ̀dọ́ ló ṣe pàtàkì jù lọ ni? Ìyẹn náà ṣe pàtàkì, nítorí pé ìdádọ̀dọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àmì májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá.—Jẹ́nẹ́sísì 17:9-13.
2 Àmọ́, àwọn tó máa ń rin kinkin mọ́ nǹkan lè máa rò pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo òfin tí Ọlọ́run fúnni ló ṣe pàtàkì, bó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn kan ò ṣe pàtàkì tó àwọn mìíràn, síbẹ̀ kò yẹ kéèyàn máa gbé òfin èyíkéyìí ga ju àwọn òfin tó kù lọ. Àwọn Farisí wá pinnu láti bí Jésù ní ìbéèrè tí wọ́n ń jiyàn lé yìí. Wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá yóò sọ ohun kan tí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn lè fọkàn tán an mọ́. Ọ̀kan lára wọn wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì béèrè pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?”—Mátíù 22:34-36.
3. Àṣẹ wo ni Jésù sọ pé ó tóbi jù lọ?
3 Èsì tí Jésù fún wọn ṣe pàtàkì gan-an fún àwa náà lóde òní. Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè náà, ó ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tó ṣe pàtàkì àtohun tí yóò tún máa ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. Jésù wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Diutarónómì 6:5, ó ní: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣẹ kan ṣoṣo tó tóbi jù lọ ni Farisí náà béèrè lọ́wọ́ Jésù, síbẹ̀ Jésù tún sọ òmíràn fún un. Ó fa ọ̀rọ̀ tó wà nínú Léfítíkù 19:18 yọ, ó ní: “Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” Jésù wá sọ pé orí àwọn òfin méjì yìí ni ìjọsìn tòótọ́ dá lé. Nítorí pé Jésù ò fẹ́ kí ọkùnrin náà sọ fún òun láti to àwọn òfin yòókù tẹ̀ léra bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.” (Mátíù 22:37-40) Èyí tó tóbi jù nínú àwọn àṣẹ méjèèjì yìí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Báwo la ṣe ń fi hàn pé a nírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà wo la sì lè gbà mú kí ìfẹ́ náà túbọ̀ pọ̀ sí i? Ó ṣe pàtàkì láti mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nítorí pé ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ fi gbogbo àyà wa, gbogbo ọkàn wa, àti gbogbo èrò inú wa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ìdí Tí Ìfẹ́ Fi Ṣe Pàtàkì
4, 5. (a) Kí nìdí tí ohun tí Jésù sọ kò fi jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Farisí yẹn? (b) Kí lohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run ju ẹbọ àtàwọn ọrẹ ẹbọ sísun?
4 Ó dà bíi pé èsì tí Jésù fún Farisí tó béèrè ìbéèrè yìí kò bí Farisí náà nínú, kò sì yà á lẹ́nu. Ó mọ̀ pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an nínú ọ̀rọ̀ ìjọsìn tòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fi ìfẹ́ yìí hàn. Nínú sínágọ́gù láyé ìgbà yẹn, àṣà àwọn èèyàn ni pé kí wọ́n máa ka àkọ́sórí kan tí wọ́n pè ní Ṣémà, tàbí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́, ọ̀rọ̀ inú Diutarónómì 6:4-9 tí Jésù fà yọ yẹn sì wà lára rẹ̀. A rí i ka nínú àkọsílẹ̀ Máàkù nípa ìtàn yìí pé, Farisí náà sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, ìwọ wí dáadáa ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́, ‘Ọ̀kan ṣoṣo ni Òun, kò sì sí òmíràn yàtọ̀ sí Òun’; àti pé nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yìí pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà ẹni àti pẹ̀lú gbogbo òye ẹni àti pẹ̀lú gbogbo okun ẹni àti nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni gẹ́gẹ́ bí ara ẹni yìí níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ.”—Máàkù 12:32, 33.
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ mìíràn jẹ́ ara ohun tí Òfin ní kí wọ́n máa ṣe, síbẹ̀ ohun tí Ọlọ́run kà sí pàtàkì jù lọ ni ìfẹ́ àtọkànwá táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní fún un. Ológoṣẹ́ kan téèyàn fi rúbọ sí Ọlọ́run pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfọkànsìn ṣeyebíye gan-an lójú rẹ̀ ju ọrẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò téèyàn ò fọkàn tó dáa ṣe. (Míkà 6:6-8) Rántí ìtàn opó aláìní tí Jésù kíyè sí nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ẹyọ owó kéékèèké méjì tó fi sínú àpótí ìṣúra kò tiẹ̀ tóó ra ológoṣẹ́ kan ṣoṣo pàápàá. Síbẹ̀, ọrẹ tó ṣe fún Jèhófà látọkànwá yẹn ṣe pàtàkì gan-an lójú Jèhófà ju owó rẹpẹtẹ táwọn ọlọ́rọ̀ ń dá látinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n ní. (Máàkù 12:41-44) Inú wa mà dùn o, láti mọ̀ pé ohun tí gbogbo wá lè fi hàn láìfi ipòkípò tá a wà pè ni ohun tí Jèhófà mọyì rẹ̀ jù lọ, ìyẹn ìfẹ́ tá a ní fún un!
6. Kí ni Pọ́ọ̀lù kọ tó fi hàn pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an?
6 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọsìn tòótọ́, ó kọ̀wé pé: “Bí mo bá ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n ènìyàn àti ti áńgẹ́lì ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ kan tí ń dún tàbí aro aláriwo gooro. Bí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì di ojúlùmọ̀ gbogbo àṣírí ọlọ́wọ̀ àti gbogbo ìmọ̀, bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò padà, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan. Bí mo bá sì yọ̀ǹda gbogbo nǹkan ìní mi láti fi bọ́ àwọn ẹlòmíràn, tí mo sì fi ara mi léni lọ́wọ́, kí èmi bàa lè ṣògo, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò ní èrè rárá.” (1 Kọ́ríńtì 13:1-3) Láìsí àní-àní, ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ kí ìjọsìn wa múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́, ọ̀nà wo la gbà ń fìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn?
Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Fìfẹ́ Tá A Ní fún Jèhófà Hàn
7, 8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
7 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìfẹ́ jẹ́ ohun kan tó máa ń pani bí ọtí, téèyàn ò sì lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi máa ń sọ pé ìfẹ́ kó sáwọn lórí. Àmọ́, ojúlówó ìfẹ́ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ohun téèyàn bá ṣe la fi ń mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ohun téèyàn ń rò lọ́kàn. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ jẹ́ ohun téèyàn ń fi hàn ní “ọ̀nà títayọ ré kọjá,” ó sì tún jẹ́ ohun téèyàn ń “lépa.” (1 Kọ́ríńtì 12:31; 14:1) Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́, “kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:18.
8 Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká ṣe ohun tó ń múnú rẹ̀ dùn, òun ló sì ń jẹ́ ká máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé òun la gbà pé ó jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run. Òun ni kò jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ayé àtàwọn ọ̀nà búburú rẹ̀. (1 Jòhánù 2:15, 16) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń kórìíra ohun búburú. (Sáàmù 97:10) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run tún kan nínífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa, èyí tá a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Síwájú sí i, ìfẹ́ fún Ọlọ́run tún gba pé ká jẹ́ onígbọràn. Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòhánù 5:3.
9. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run hàn?
9 Jésù fi ohun tó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láìkù síbì kan hàn. Ìfẹ́ ló mú kó fi ọ̀run sílẹ̀ tó wá ń gbé orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Òun ló mú kó yin Bàbá rẹ̀ lógo nípa àwọn ohun tó ṣe àtàwọn ohun tó fi kọ́ni. Ìfẹ́ ló sún un láti jẹ́ “onígbọràn títí dé ikú.” (Fílípì 2:8) Ìgbọràn yìí, tó fi ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run hàn, ló sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn olóòótọ́ èèyàn láti jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan [Ádámù] ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Kristi Jésù], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.”—Róòmù 5:19.
10. Kí nìdí tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi kan ṣíṣe ìgbọràn?
10 Bíi ti Jésù, àwa náà ń fìfẹ́ tá a ní hàn nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Jòhánù tí Jésù fẹ́ràn gan-an kọ̀wé pé: “Èyí sì ni ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí, pé kí a máa bá a lọ ní rírìn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ rẹ̀.” (2 Jòhánù 6) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn máa ń fẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà. Ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n gbára lé, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé kò sí báwọn ṣe lè darí ìṣísẹ̀ ara àwọn káwọn sì kẹ́sẹ járí. (Jeremáyà 10:23) Wọ́n dà bí àwọn ọlọ́kàn-rere tó wà nílùú Bèróà ìgbàanì, tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú “ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú” wọn, nítorí pé ó wù wọ́n gan-an láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 17:11) Wọ́n fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fìfẹ́ hàn bí wọ́n ti ń ṣègbọràn nínú àwọn nǹkan mìíràn.
11. Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, èrò inú wa, ọkàn wa, àti okun wa?
11 Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, ìfẹ́ fún Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn wa, èrò inú wa, àti okun wa. (Máàkù 12:30) Inú ọkàn ni irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ti máa ń wá, ó kan bá a ṣe máa ń rára gba nǹkan sí, ó tún kan ìfẹ́ ọkàn wa, àti ohun tá à ń rò nínú wa lọ́hùn-ún, ó sì wù wá gan-an láti múnú Jèhófà dùn. Ohun tá à ń rò lọ́kàn tún máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́. Kì í ṣe pé a kàn ń ṣe ìjọsìn wa láìronú, a ti mọ Jèhófà, ìyẹn ni pé a mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fọ́mọ aráyé. A ń lo ọkàn wa, gbogbo ara wa àti ẹ̀mí wa, láti sin Jèhófà àti láti fìyìn fún un. A tún ń lo gbogbo okun wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
12 Ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ó fẹ́ ká ní àwọn ànímọ̀ tóun ní. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, òun sì lẹni tó nífẹ̀ẹ́ tó ga jù lọ. Àpọ́sítélì Jòhánù tí Ọlọ́run mí sí kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Àwòrán Ọlọ́run ni a dá èèyàn, ìyẹn ni pé a dá wa lọ́nà tá a fi lè nífẹ̀ẹ́. Kódà, orí ìfẹ́ ni jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ dá lé. Kìkì àwọn tí Jèhófà gbà pé ó jẹ́ tòun làwọn tó ń sìn ín nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì fara mọ́ ọ̀nà òdodo tó gbà ń ṣàkóso. Ní ti tòótọ́, ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó lè wà láàárín gbogbo ẹ̀dá Ọlọ́run.
13. (a) Kí nìdí tí Jésù fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ”? (b) Kí nìdí tí fífẹ́ tí Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun fi bọ́gbọ́n mu?
13 Ìdí mìíràn tó tún fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mímọ̀ tá a mọrírì ohun tó ti ṣe fún wa. Rántí pé Jésù sọ fáwọn Júù pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Kò sọ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òrìṣà kan tó wà lọ́nà jíjìn tí wọ́n ò sì mọ̀. Ó ní kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó ti fìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wọn. Jèhófà ni Ọlọ́run wọn. Òun ló mú wọn jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, òun lẹ́ni tó ń dáàbò bò wọ́n, tó ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn, tó ń ṣìkẹ́ wọn, tó sì tún ń fìfẹ́ bá wọn wí. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lóde òní, Jèhófà ni Ọlọ́run wa, òun ló fi Ọmọ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún wa ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an bí Jèhófà ṣe sọ pé káwa náà nífẹ̀ẹ́ òun! Bíbélì sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, Ẹni tó “kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa” là ń fìfẹ́ hàn sí.—1 Jòhánù 4:19.
14. Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ Jèhófà gbà dà bíi ti òbí rere kan?
14 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún ọmọ aráyé dà bí èyí tí òbí rere kan ní fáwọn ọmọ rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwa èèyàn, àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára fún ọ̀pọ̀ ọdún láti bójú tó àwọn ọmọ wọn, èyí sì máa ń ná wọn lówó gan-an àtàwọn nǹkan míì. Àwọn òbí máa ń tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, wọ́n máa ń gbà wọ́n níyànjú, wọ́n máa ń tì wọ́n lẹ́yìn, wọ́n sì máa ń bá wọn wí, nítorí pé wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ wọn láyọ̀ kí wọ́n sì jẹ́ ọmọ rere. Kí làwọn òbí fẹ́ káwọn ọmọ náà ṣe fáwọn padà? Wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn, wọ́n tún fẹ́ káwọn ọmọ náà fi ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wọn sọ́kàn, kó lè dáa fún wọn. Ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu kí Bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ ẹni pípé retí pé ká nífẹ̀ẹ́ òun ká sì fi ìmọrírì hàn nítorí gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa?
Bá A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
15. Kí ló yẹ kéèyàn kọ́kọ́ ṣe tó bá fẹ́ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
15 A kò rí Ọlọ́run rí, a ò sì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí. (Jòhánù 1:18) Síbẹ̀, ó ń pè wá pé ká jẹ́ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwa àti òun. (Jákọ́bù 4:8) Ọ̀nà wo la ó gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ohun àkọ́kọ́ téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan ni kó kọ́kọ́ mọ onítọ̀hún dáadáa, nítorí pé kì í rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fẹ́ni tá ò mọ̀ dáadáa. Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká lè mọ irú ẹni tí òun jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ gbà wá níyànjú pé ká máa ka Bíbélì déédéé. Bíbélì ló kọ́ wa nípa Ọlọ́run, òun ló jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti irú ẹni tó jẹ́, títí kan ọ̀nà tó ń gbà bá àwọn èèyàn lò láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Báa ṣe ń ṣe àṣàrò lórí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ìmọrírì àti ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i.—Róòmù 15:4.
16. Báwo ni ríronú nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe túbọ̀ ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
16 Ọ̀nà pàtàkì kan tí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà fi lè pọ̀ sí i ni ká máa ronú lórí ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti bó ṣe ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó ṣe tán, Jésù ṣe bíi ti Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́ débi tó fi sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Àbí àánú tí Jésù fi hàn nígbà tó jí ọmọ kan ṣoṣo tí opó yẹn bí dìde kò wú ọ lórí? (Lúùkù 7:11-15) Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo ẹni tó tíì gbé ayé rí, ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ débi pé ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (Jòhánù 13:3-5) Ǹjẹ́ kò jọ ẹ́ lójú gan-an láti mọ̀ pé bí kò tiẹ̀ sẹ́ni tó lọ́lá tó Jésù tí kò sì sẹ́ni tó gbọ́n tó o, síbẹ̀ ó jẹ́ kí onírúurú èèyàn wá sọ́dọ̀ òun, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá? (Máàkù 10:13, 14) Bá a ṣe ń fi ìmọrírì ronú nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, a dà bí àwọn Kristẹni tí Pétérù kọ̀wé nípa wọn pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí [Jésù] rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Pétérù 1:8) Bí ìfẹ́ tá a ní fún Jésù ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ wa fún Jèhófà yóò máa pọ̀ sí i.
17, 18. Àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè wo la lè máa ṣàṣàrò lé lórí tí ìfẹ́ tá a ní fún un yóò fi máa pọ̀ sí i?
17 Ọ̀nà mìíràn tí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run fi lè pọ̀ sí i ni pé ká máa ṣàṣàrò lórí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn nǹkan tó fìfẹ́ pèsè fún wa ká lè gbádùn ìgbésí ayé wa. Àwọn nǹkan náà ni: àwọn ohun rírẹwà tó dá, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun tá à ń jẹ tá a sì máa ń gbádùn wọn, àwọn ọ̀rẹ́ rere tá a máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wọn, títí kan àìlóǹkà àwọn ohun tó ń múnú ẹni dùn tó sì máa ń fúnni láyọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Ìṣe 14:17) Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run la túbọ̀ ń rí i pé ó yẹ ká mọyì oore rẹ̀ àti jíjẹ́ tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ìwọ alára. Ǹjẹ́ o ò gbà pé ó yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
18 Lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀bùn tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àǹfààní tá a ní láti tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà nígbàkigbà tá a bá fẹ́, nítorí a mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” yóò tẹ́tí sí wa. (Sáàmù 65:2) Jèhófà ti fún Ọmọ rẹ̀ ní àṣẹ láti ṣàkóso àti láti ṣèdájọ́. Àmọ́, kò yan ẹnikẹ́ni láti máa gbọ́ àdúrà, kódà kò yan Ọmọ rẹ̀ pàápàá. Òun fúnra rẹ̀ ló máa ń gbọ́ àdúrà wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa àti bó ṣe ń bìkítà nípa wa ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn dáadáa.
19. Àwọn ìlérí wo ni Jèhófà ṣe tó ń mú ká sún mọ́ ọn?
19 A tún máa ń sún mọ́ Jèhófà nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣe fọ́mọ aráyé lọ́jọ́ iwájú. Ó ti ṣèlérí pé òun máa fòpin sí àìsàn, ìbànújẹ́, àti ikú. (Ìṣípayá 21:3, 4) Tí ìran èèyàn bá ti dẹni pípé, kò sẹ́ni tó máa ní ìdààmú ọkàn, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìbànújẹ́ ọkàn mọ́. Kò ní sí ebi àti ogun mọ́, bẹ́ẹ̀ lèèyàn ò ní tòṣì mọ́. (Sáàmù 46:9; 72:16) Ayé yóò di Párádísè. (Lúùkù 23:43) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa ló máa jẹ́ kó mú àwọn ìbùkún wọ̀nyí wá, kì í ṣe nítorí pé ó di dandan kó ṣe bẹ́ẹ̀.
20. Kí ni Mósè sọ nípa àǹfààní tó wà nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
20 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí fi hàn pé kò sídìí tí kò fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ yẹn máa pọ̀ sí i. Ṣé wàá jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run máa lágbára sí i, ṣé wàá sì jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí àwọn ọ̀nà rẹ? Ó kù sọ́wọ́ rẹ. Mósè gbà pé àǹfààní pọ̀ nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí ìfẹ́ yẹn sì máa wà títí lọ. Ohun tó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ni pé: “Yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ.”—Diutarónómì 30:19, 20.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
• Báwo la ṣe lè fìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run hàn?
• Àwọn ìdí wo ló fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
• Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Jèhófà mọyì ohun kan tí gbogbo wa lè fi hàn, ìyẹn ìfẹ́ tá a ní fún un
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:9