ORIN 135
Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́bìnrin,
Múnú mi dùn.
Jẹ́ kígbèésí ayé
Rẹ bá ìfẹ́ mi mu.
Kó o lo àkókò ọ̀dọ́
Rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n,
Kó o lè dójú tọ̀tá
Tó ń gan orúkọ mi.
(ÈGBÈ)
Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin,
Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin;
Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi
Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.
2. Máa fi ayọ̀ ṣe ìfẹ́ mi
Látọkàn wá.
Jẹ́ kí àwọn èèyàn
Mọ̀ pé tèmi ni ọ́.
Ẹni fọwọ́ kàn ẹ́
Ń wá ojú pípọ́n mi,
Bó o bá tiẹ̀ ṣubú,
Èmi yóò gbé ọ dìde.
(ÈGBÈ)
Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin,
Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin;
Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi
Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.
(Tún wo Diu. 6:5; Oníw. 11:9; Àìsá. 41:13.)