ORÍ 1
“Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Ni O Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìdí tó fi yẹ kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò
1, 2. Báwo ni Jésù ṣe dé inú aginjù Jùdíà nígbà ìwọ́wé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
LỌ́DÚN 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù wà ní aginjù Jùdíà nígbà ìwọ́wé, ní apá àríwá Òkun Òkú. Ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ lọ síbẹ̀ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, tí Ọlọ́run sì ti fòróró yàn án. Ogójì (40) ọjọ́ ni Jésù fi wà ní àfonífojì náà, ibẹ̀ pa rọ́rọ́, òkúta sì pọ̀ níbẹ̀. Jésù fi àkókò náà gbààwẹ̀, ó gbàdúrà, ó sì ṣàṣàrò. Ó ṣeé ṣe kí Jèhófà fi àkókò yẹn bá Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, kó sì mú kó gbára dì fún àwọn ohun tó máa tó bẹ̀rẹ̀.
2 Ebi wá ń pa Jésù, èyí sì mú kó rẹ̀ ẹ́ gan-an. Ìgbà yẹn ni Sátánì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tó kan gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn mímọ́, títí kan ìwọ náà.
“Tí O Bá Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run . . .”
3, 4. (a) Gbólóhùn wo ni Sátánì fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nígbà méjì àkọ́kọ́ tó dán Jésù wò? Kí ló sì ṣeé ṣe kó fẹ́ kí Jésù máa ṣiyèméjì nípa rẹ̀? (b) Báwo ni Sátánì ṣe ń lo irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn lóde òní?
3 Ka Mátíù 4:1-7. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì lò nígbà méjì àkọ́kọ́ tó dán Jésù wò, ó ní, “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” Àbí kò dá Sátánì lójú pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run ni? Ó kúkú mọ̀. Áńgẹ́lì tó fìgbà kan rí jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí mọ̀ dájú pé Jésù ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run. (Kól. 1:15) Ó dájú pé Sátánì náà mọ ohun tí Jèhófà sọ láti ọ̀run nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Sátánì fẹ́ kí Jésù máa ṣiyèméjì bóyá lóòótọ́ ni Jèhófà tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ ṣeé fọkàn tán, tó sì nífẹ̀ẹ́ Jésù. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ nígbà tó kọ́kọ́ dán Jésù wò pé kó sọ òkúta di búrẹ́dì ni pé: ‘Ṣebí Ọmọ Ọlọ́run lo pe ara rẹ, kí ló dé tí Bàbá rẹ ò ṣe fún ẹ ní oúnjẹ nínú aginjù yìí?’ Nígbà tó dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kejì, tó ní kó fò sílẹ̀ látorí ògiri orí òrùlé tẹ́ńpìlì, ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘Ṣebí Ọmọ Ọlọ́run lo pe ara rẹ, ṣé ó dá ẹ lójú lóòótọ́ pé Bàbá rẹ máa dáàbò bò ẹ́?’
4 Irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí náà ni Sátánì ń lò lóde òní. (2 Kọ́r. 2:11) Adánniwò yìí máa ń dúró de ìgbà tí àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tá ò lókun kó lè fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbéjà kò wá. (2 Kọ́r. 11:14) Ó ń wá bó ṣe máa tàn wá ká lè máa rò pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì lè tẹ́wọ́ gbà wá. Adánniwò yìí tún ń fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà ò ṣeé fọkàn tán, pé kò ní mú àwọn ìlérí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, irọ́ ńlá ni. (Jòh. 8:44) Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kó fi àwọn irọ́ yìí tàn wá jẹ?
5. Kí ni Jésù ṣe nígbà méjì àkọ́kọ́ tí Sátánì dán an wò?
5 Wo ohun tí Jésù ṣe nígbà méjì àkọ́kọ́ tí Sátánì dán an wò. Jésù ò ṣiyèméjì rárá bóyá Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun, ó gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá rẹ̀ pátápátá. Jésù ò jáfara rárá, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló tọ́ka sí Ọ̀rọ̀ tí Bàbá rẹ̀ mí sí láti fi gbá ohun tí Sátánì sọ dà nù. Kódà, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. (Diu. 6:16; 8:3) Bí Jésù ṣe lo orúkọ Ọlọ́run fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá rẹ̀. Orúkọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.a
6, 7. Kí la lè ṣe tá ò bá fẹ́ kí Sátánì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tàn wá jẹ?
6 Tá ò bá fẹ́ kí Sátánì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tàn wá jẹ, àfi ká gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ronú lórí ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí. Tá a bá ń fọkàn sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa àti bí ọ̀rọ̀ àwa tí à ń jọ́sìn rẹ̀ ṣe jẹ ẹ́ lógún, títí kan àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn, àá lè já àwọn irọ́ tí Sátánì ń pa, pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì lè tẹ́wọ́ gbà wá. (Sm. 34:18; 1 Pét. 5:8) Tá a bá sì ń fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà á máa ṣe ohun tó bá ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mu, ó máa dá wa lójú gbangba pé ó yẹ ká fọkàn tán Ẹni tó ń mú ìlérí ṣẹ yìí.—Òwe 3:5, 6.
7 Àmọ́, kí ni olórí ohun tí Sátánì ń wá gan-an? Kí ló fẹ́ ká fún òun? Ìdáhùn ìbéèrè yìí ṣe kedere nígbà tó dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta.
“Tí O Bá Wólẹ̀, Tí O sì Jọ́sìn Mi Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo”
8. Báwo ni Sátánì ṣe sọ ohun tó ń fẹ́ gan-an nígbà tó dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta?
8 Ka Mátíù 4:8-11. Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, kò wulẹ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ mọ́, ṣe ló sọ ohun tó ń fẹ́ ní tààràtà. Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” han Jésù (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nínú ìran), àmọ́ kò fi ìwà ìbàjẹ́ inú wọn hàn án. Ó wá sọ fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”b Ìjọsìn ni ohun ti Sátánì ń fẹ́! Ó fẹ́ kí Jésù pa Bàbá rẹ̀ tì, kó sì gbà pé Adánniwò yìí ni ọlọ́run òun. Ohun tó dà bíi pé kò le rárá ni Sátánì fẹ́ kí Jésù ṣe. Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé gbogbo agbára àti ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè máa jẹ́ ti Jésù. Ìyà kankan ò ní jẹ ẹ́, kò ní dé adé ẹ̀gún, kò ní sí pé wọ́n ń nà án lẹ́gba, wọn ò sì ní kàn án mọ́ òpó igi oró. Àdánwò yìí kì í ṣọ̀rọ̀ eré rárá. Jésù ò bá Sátánì jiyàn pé kì í ṣe aláṣẹ àwọn ìjọba ayé. (Jòh. 12:31; 1 Jòh. 5:19) Ó dájú pé kò sí ohun tí Sátánì ò ní fún Jésù, kó lè mú kí Jésù pa ìjọsìn mímọ́ tó jẹ́ ti Bàbá rẹ̀ tì.
9. (a) Kí ni Sátánì fẹ́ kí àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ ṣe, báwo ló sì ṣe máa ń fẹ́ tàn wá? (b) Kí ni ìjọsìn wa ní nínú? (Wo àpótí náà, “Kí Ni Ìjọsìn?”)
9 Bákan náà, lóde òní, ṣe ni Sátánì fẹ́ ká máa jọ́sìn òun, yálà ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà. Bó ṣe jẹ́ pé òun ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” òun ló ń gba gbogbo ìjọsìn èké tí àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá ń ṣe. (2 Kọ́r. 4:4) Àmọ́, bí àwọn tó ń ṣe ìjọsìn èké ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ ò tíì tẹ́ Sátánì lọ́rùn, ó ṣì fẹ́ máa dán àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ wò kí wọ́n lè ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó fẹ́ dọ́gbọ́n tàn wá ká lè máa wá ọrọ̀ àti agbára nínú ayé tó wà níkàáwọ́ rẹ̀, dípò ká máa hùwà tó yẹ Kristẹni, èyí tó lè mú ká “jìyà nítorí òdodo.” (1 Pét. 3:14) Tá a bá gba Sátánì láyè pẹ́nrẹ́n, tá a pa ìjọsìn mímọ́ tì, tá a wá ń ṣe ohun táyé ń ṣe, ṣe ló máa dà bíi pé a ti ń forí balẹ̀ fún Sátánì, a ti ń jọ́sìn rẹ̀, a sì ti sọ ọ́ di ọlọ́run wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba Sátánì láyè?
10. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí Sátánì dán an wò lẹ́ẹ̀kẹta, kí sì nìdí?
10 Kíyè sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí Sátánì dán an wò lẹ́ẹ̀kẹta. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan lòun jẹ́ adúróṣinṣin sí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lé Adánniwò náà dà nù, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” Bíi ti àwọn àdánwò méjì àkọ́kọ́, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Diutarónómì, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ó ní: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’ ” (Mát. 4:10; Diu. 6:13) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ láti gba ipò tó fani mọ́ra, tó sì gbayì gan-an nínú ayé, àmọ́ tí kò ní tọ́jọ́, ó sì tún kọ ayé ìdẹ̀rùn tí kò ní mú kó jìyà. Ó mọ̀ pé Bàbá òun nìkan ni ìjọsìn tọ́ sí àti pé tí kò bá tiẹ̀ ju ‘ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ téèyàn jọ́sìn’ Sátánì, onítọ̀hún ti fi ara rẹ̀ sábẹ́ Sátánì nìyẹn. Jésù jẹ́ adúróṣinṣin, ó kọ̀ láti fi Adánniwò burúkú náà ṣe ọlọ́run. Bí Jésù ò ṣe gbọ́ ti Sátánì yìí mú kí ‘Èṣù fi í sílẹ̀.’c
11. Kí la lè ṣe láti gbéjà ko Sátánì àtàwọn ìdẹwò tó ń gbé wá?
11 A lè gbéjà ko Sátánì àti àwọn ìdẹwò ayé búburú rẹ̀ torí pé bíi ti Jésù, a lè pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe. Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ni òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Torí náà, kò sẹ́ni tó lè fipá mú wa láti pa ìjọsìn mímọ́ tì, títí kan Adánniwò burúkú náà tó jẹ́ alágbára. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, tá a sì ‘kọjú ìjà sí Sátánì’ tá a “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,” ṣe là ń sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (1 Pét. 5:9) Má gbàgbé pé, Sátánì fi Jésù sílẹ̀ nígbà tí Jésù kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tó fẹ́. Bákan náà, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jém. 4:7.
Ọ̀tá Ìjọsìn Mímọ́
12. Báwo ni ohun tí Sátánì ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì ṣe fi hàn pé òun ni ọ̀tá ìjọsìn mímọ́?
12 Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, Sátánì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni olórí ọ̀tá ìjọsìn mímọ́. Inú ọgbà Édẹ́nì ni Sátánì ti kọ́kọ́ fi hàn pé òun kórìíra ìjọsìn Jèhófà, ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà tó wá dán Jésù wò. Bí Sátánì ṣe tan Éfà jẹ, tí Éfà náà sì sún Ádámù láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó mú kí wọ́n wá sábẹ́ àkóso òun, ó sì ń darí wọn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; 2 Kọ́r. 11:3; Ìfi. 12:9) Bí wọn ò tiẹ̀ mọ ẹni tó ń ṣì wọ́n lọ́nà ní tààràtà, ohun tí Sátánì ṣe gan-an ni pé ó sọ ara rẹ̀ di ọlọ́run wọn, àwọn náà sì ń jọ́sìn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bí Sátánì ṣe pilẹ̀ ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, kì í kàn ṣe pé ó fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ tàbí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ṣe ló tún gbéjà ko ìjọsìn mímọ́. Lọ́nà wo?
13. Báwo ni ọ̀rọ̀ nípa ipò ọba aláṣẹ ṣe kan ìjọsìn mímọ́?
13 Ọ̀rọ̀ nípa ipò ọba aláṣẹ kan ìjọsìn mímọ́. Ọba Aláṣẹ tòótọ́ nìkan, ìyẹn Ẹni tó “dá ohun gbogbo” ni ìjọsìn tọ́ sí. (Ìfi. 4:11) Nígbà tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé, tó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì, ohun tó ní lọ́kàn ni pé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, kí àwọn èèyàn pípé táá máa jọ́sìn Òun látọkàn wá kún ayé, kí wọ́n máa ṣe ìjọsìn mímọ́ látinú ọkàn mímọ́. (Jẹ́n. 1:28) Sátánì pe ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso níjà torí pé ojú rẹ̀ wọ ìjọsìn tó jẹ́ pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ nìkan ló tọ́ sí.—Jém. 1:14, 15.
14. Ǹjẹ́ Sátánì ṣàṣeyọrí nígbà tó gbéjà ko ìjọsìn mímọ́? Ṣàlàyé.
14 Ǹjẹ́ Sátánì ṣàṣeyọrí nígbà tó gbéjà ko ìjọsìn mímọ́? Ó mú kí Ádámù àti Éfà kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti ń gbógun ti ìjọsìn tòótọ́, ó ń wá bó ṣe máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà Ọlọ́run bí wọ́n bá ṣe lè pọ̀ tó. Sátánì ò jáwọ́ nínú bó ṣe ń dán àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà wò ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó mú kì àwọn apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọṣẹ́, èyí ṣàkóbá fún ìjọ Kristẹni, ó sì mú kó dà bíi pé ìjọsìn mímọ́ ti pòórá. (Mát. 13:24-30, 36-43; Ìṣe 20:29, 30) Níbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé mú àwọn olùjọsìn nígbèkùn. Àmọ́ ohun tí Sátánì ṣe kò yí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ìjọsìn mímọ́ pa dà. Kò sóhun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Àìsá. 46:10; 55:8-11) Ọ̀rọ̀ yìí kan orúkọ Jèhófà, ohun tó sì bá ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ mu ló máa ń ṣe nígbà gbogbo. Jèhófà máa ń mú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ṣẹ láìkùnà!
Aṣáájú Nínú Ká Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
15. Kí làwọn ohun tí Jèhófà ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ní ọgbà Édẹ́nì, kó lè rí i dájú pé ohun tí òun ní lọ́kàn ṣẹ?
15 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ní ọgbà Édẹ́nì kó lè rí i dájú pé ohun tí òun ní lọ́kàn ṣẹ. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:14-19.) Kí Ádámù àti Éfà tó kúrò nínú ọgbà náà ni Jèhófà ti ṣèdájọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, bẹ̀rẹ̀ látorí ẹni tó kọ́kọ́ ṣẹ̀, ìyẹn Sátánì, lẹ́yìn náà ó ṣèdájọ́ Éfà kó tó wá ṣèdájọ́ Ádámù. Nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Sátánì tó pilẹ̀ ọ̀tẹ̀ yìí lábẹ́lẹ̀, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ọmọ” kan máa wá ṣàtúnṣe gbogbo ọṣẹ́ tí ọ̀tẹ̀ náà ṣe. “Ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà máa kó ipa pàtàkì láti mú kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ìjọsìn mímọ́ ṣẹ.
16. Lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, àwọn ètò wo ni Jèhófà ṣe kí àwọn ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ?
16 Lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà ń bá ètò lọ kí ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ. Ó ṣètò bí àwa èèyàn aláìpé á ṣe máa sin òun lọ́nà tí òun tẹ́wọ́ gbà, a máa rí èyí ní orí tó tẹ̀ lé e. (Héb. 11:4–12:1) Ó mí sí àwọn tó kọ Bíbélì láti kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, àwọn bí Àìsáyà, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì. Ọ̀rọ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò jẹ́ kókó pàtàkì nínú Bíbélì. “Ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà máa mú gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ, Jésù Kristi sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sí ní pàtàkì. (Gál. 3:16) Jésù ni Aṣáájú nínú ká gbèjà ìjọsìn mímọ́, èyí sì hàn kedere nínú èsì tó fún Sátánì nígbà tó dán an wò lẹ́ẹ̀kẹta. Jésù ni Jèhófà yàn láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. (Ìfi. 19:10) Ó máa dá àwọn èèyàn Ọlọ́run nídè kúrò nígbèkùn tẹ̀mí, ó sì máa mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà sípò tó yẹ.
Kí Lo Máa Ṣe?
17. Kí nìdí tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa bí àwọn nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò fi ṣe pàtàkì sí wa gan-an?
17 Inú wa máa ń dùn, ìgbàgbọ́ wa sì máa ń lágbára sí i tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó dá lórí bí àwọn nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe pàtàkì sí wa gan-an torí à ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí gbogbo ẹ̀dá lọ́run àti láyé máa wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa torí inú rẹ̀ la ti lè rí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo wa là ń fojú sọ́nà láti rí bí àwọn ìlérí Jèhófà ṣe máa ṣẹ, irú bí àjíǹde àwọn èèyàn wa tó ti kú, bí ayé ṣe máa di Párádísè àti bá a ṣe máa wà láàyè títí láé nínú ìlera pípé.—Àìsá. 33:24; 35:5, 6; Ìfi. 20:12, 13; 21:3, 4.
18. Kí la máa jíròrò nínú ìwé yìí?
18 Nínú ìwé yìí, a máa jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà dá lórí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. A máa rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe tan mọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù, bí wọ́n ṣe máa ṣẹ nípasẹ̀ Kristi àti bí wọ́n ṣe kàn wá.—Wo àpótí náà, “Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì.”
19. Kí lo pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?
19 Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní aginjù Jùdíà lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Sátánì gbìyànjú láti mú kí Jésù kẹ̀yìn sí ìjọsìn mímọ́, àmọ́ kò rí i ṣe. Àwa ńkọ́? Sátánì túbọ̀ ń sapá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti fà wá kúrò nínú ìjọsìn mímọ́. (Ìfi. 12:12, 17) Àdúrà wa ni pé kí ìwé yìí ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé a ò ní gba Adánniwò burúkú náà láyè. Ká sì máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà wa pé tọkàntọkàn la fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé, “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn.” Èyí á jẹ́ ká lè wà lára àwọn táá máa fojú sọ́nà láti rí bí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ní lọ́kàn ṣe máa ṣẹ níkẹyìn. Nígbà tí gbogbo àwọn tó wà ní ọ̀run àti ayé á máa sin Jèhófà níṣọ̀kan, tí wọ́n á sì máa fi ọkàn mímọ́ ṣe ìjọsìn mímọ́, torí ohun tí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ sí gan-an nìyẹn!
a Àwọn kan gbà pé orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Ìtumọ̀ yìí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ohun tí Jèhófà ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti Ẹni tó ń mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.
b Ìwé kan tó dá lórí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sátánì yìí pé: “Bó ṣe rí nígbà ìdẹwò àkọ́kọ́, tí Ádámù àti Éfà kó sọ́wọ́ Sátánì . . . , ọ̀rọ̀ yìí dá lórí ṣíṣe ìfẹ́ Sátánì tàbí ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ní láti pinnu ẹni tí wọ́n máa jọ́sìn nínú àwọn méjèèjì. Ṣe ni Sátánì ń gbéra ga, tó sì ń fi ara rẹ̀ ṣe ọlọ́run dípò Ọlọ́run kan ṣoṣo náà.”
c Bí Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù ṣe to àwọn ìdẹwò náà yàtọ̀ sí ti Mátíù, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé bí Mátíù ṣe to ìṣẹ̀lẹ̀ náà tẹ̀ léra bá bó ṣe wáyé mu. Jẹ́ ká wo ẹ̀rí mẹ́ta yìí. (1) Ohun tí Mátíù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìdẹwò kejì, ìyẹn “lẹ́yìn náà” fi hàn pé ó sọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà bó ṣe tẹ̀ léra. (2) Ó bọ́gbọ́n mu pé ìdẹwò méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe tààrà, tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn yìí pé, “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run” máa ṣáájú èyí tó ti sọ ní ṣàkó pé kí Jésù tẹ òfin àkọ́kọ́ lójú. (Ẹ́kís. 20:2, 3) (3) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” ló bọ́gbọ́n mu pé ó máa tẹ̀ lé ìdẹwò kẹta tó kẹ́yìn yẹn.—Mát. 4:5, 10, 11.