Ẹ̀KỌ́ 14
Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
Hébérù 8:1
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa fọkàn bá ẹ lọ, kó o sì jẹ́ kí wọ́n rí bí kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ ohun tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe àti ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Mọ ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe. Ṣé o fẹ́ fún wọn ní ìsọfúnni kan ni? Ṣé o fẹ́ fi ohun kan dá wọn lójú ni? Àbí o fẹ́ gbà wọ́n níyànjú? Rí i pé o múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ lọ́nà táá fi lè ṣe iṣẹ́ tó o fẹ́ kó ṣe. Kó o sì rí i dájú pé gbogbo kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ló bá ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe mu.
Tẹnu mọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. Jálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, máa tẹnu mọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. O lè máa tún àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú rẹ̀ sọ tàbí kó o lo àwọn ọ̀rọ̀ míì tó ní ìtúmọ̀ kan náà.
Jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere kó sì rọrùn. Àwọn kókó pàtàkì tó bá ọ̀rọ̀ rẹ mu tó o sì mọ̀ pé wàá lè ṣàlàyé dáadáa láàárin àkókò tó o máa fi sọ̀rọ̀ nìkan ni kó o yàn. Ìwọ̀nba kókó pàtàkì ni kó o yàn, jẹ́ kí kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan ṣe kedere, máa dánu dúró díẹ̀ bó o ṣe ń sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, kó o sì ṣàlàyè kókó kan yanjú kó o tó bọ́ sórí èyí tó kàn.