Ṣíṣe Ìlapa Èrò
NÍGBÀ tí wọ́n bá yan ọ̀rọ̀ fún àwọn èèyàn kan láti sọ, wọ́n máa ń ṣe wàhálà, wọ́n á kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa sọ pátá, látorí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ títí lọ dé ìparí ọ̀rọ̀. Kó tó di pé wọ́n parí ìmúra ọ̀rọ̀ yẹn, wọ́n lè ti kọ ọ̀pọ̀ ẹ̀dà rẹ̀ bí wọ́n ti ń tún un ṣe. Gbogbo èyí lè gba ọ̀pọ̀ wákàtí.
Ṣé bó o ṣe ń múra ọ̀rọ̀ sísọ tìẹ nìyẹn? Ṣé wàá fẹ́ mọ ọ̀nà rírọrùn tó o lè gbà ṣe é? Bí o bá mọ bó o ṣe lè ṣe ìlapa èrò kan, kò ní sídìí fún ọ láti máa kọ gbogbo èrò rẹ sílẹ̀ mọ́. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè túbọ̀ ráyè fi sísọ ọ̀rọ̀ yẹn dánra wò dáadáa ṣáájú kó o tóó sọ ọ́. Yàtọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ yẹn á rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti sọ, yóò tún dùn-ún gbọ́, yóò sì ta àwùjọ jí.
Lóòótọ́, ìwé àsọyé tó ṣe ṣókí ti máa ń wà fáwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn tí a máa ń sọ nínú ìjọ. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ yòókù tí a máa ń sọ nínú ìjọ ni kò ní ìlapa èrò. Ó lè jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tàbí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ni wọ́n kàn máa yàn fún ọ. Tàbí kí wọ́n yan àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ti wà nínú ìwé kan fún ọ pé kó o sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà mìíràn, wọ́n kàn lè fún ọ ní ìsọfúnni díẹ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo irú ọ̀rọ̀ sísọ bẹ́ẹ̀ ló gba pé kí o ṣe ìlapa èrò tìrẹ nígbà tí a bá yàn án fún ọ láti sọ.
Àpẹẹrẹ tó wà lójú ewé 41 yóò jẹ́ kí o rí òye bí o ṣe lè ṣe ìlapa èrò tó ṣe ṣókí. Ṣàkíyèsí pé etí ìwé lápá òsì ni àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì ti bẹ̀rẹ̀, lẹ́tà gàdàgbà-gàdàgbà la sì fi kọ wọ́n. A to àwọn èrò tó ti kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan lẹ́yìn sí ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn kókó mìíràn tí a ó lò láti fi ṣàlàyé àwọn èrò wọ̀nyí síwájú sí i la tò sí ìsàlẹ̀ wọn, a sì jẹ́ kí ibi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ wọnú díẹ̀ sí i létí ìwé apá òsì. Ṣàkíyèsí ìlapa èrò yìí dáadáa. Kíyè sí i pé kókó pàtàkì méjèèjì jẹ mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn ní tààràtà. Tún ṣàkíyèsí pé ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kéékèèké ibẹ̀ kì í ṣe ìsọfúnni tó kàn ṣáà fani mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan ló ṣètìlẹ́yìn fún kókó pàtàkì tó wà lókè rẹ̀.
Bí o bá ń ṣe ìlapa èrò kan, ó lè máà rí bí èyí tí a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí gẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n tí ìlànà nípa bí a ṣe ń ṣe ìlapa èrò bá ti yé ọ, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣètò ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ, kí o sì lè múra ọ̀rọ̀ tó jíire sílẹ̀ láìfi àkókò ṣòfò. Báwo ni wàá ṣe bẹ̀rẹ̀ ná?
Ṣàyẹ̀wò, Ṣàṣàyàn, Kí O sì Ṣètò Ọ̀rọ̀ Rẹ
O nílò ẹṣin ọ̀rọ̀ kan. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ kò ní láti jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ bọrọgidi kan, bíi pé kí o kàn lo ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo péré. Òun ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ rọ̀ mọ́, òun ló sì ń fi ìhà tí o fẹ́ gbé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ gbà hàn. Bí a bá yan ẹṣin ọ̀rọ̀ kan fún ọ, gbé ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú rẹ̀ yẹ̀ wò kínníkínní. Tó bá jẹ́ pé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ inú ìwé kan lo fẹ́ lò láti fi múra ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún ọ, fi ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn bó o ṣe ń ka ìwé yẹn. Tó bá jẹ́ pé wọ́n kàn yan kókó kan fún ọ láti sọ̀rọ̀ lé lórí ni, a jẹ́ pé ńṣe lo máa fúnra rẹ yan ẹṣin ọ̀rọ̀ fún un. Ṣùgbọ́n tó o bá kọ́kọ́ ṣe ìwádìí díẹ̀ ná kó o tó yàn án, ó lè ṣèrànwọ́ gan-an ni. Bí o bá ṣe tán láti gba èrò ẹlòmíràn yẹ̀ wò, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé wàá rí àwọn àfikún èrò tó o lè lò.
Bí o ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ wọ̀nyí, máa bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì fún àwọn ti mo fẹ́ sọ ọ́ fún? Kí ni ohun tí mo fẹ́ fi ọ̀rọ̀ mi yìí ṣe?’ Kò yẹ kó kàn jẹ́ pé ohun tó o ní lọ́kàn láti ṣe ni pé o kàn fẹ́ kárí ibi tí a yàn fún ọ tàbí kó o kàn sọ ọ̀rọ̀ tó dùn mọ́ni, bí kò ṣe pé kí o rí i pé àwùjọ rẹ jàǹfààní kan pàtó nínú rẹ̀. Bí ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yẹn ṣe bá ti ṣe kedere lọ́kàn rẹ, kọ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe gbàgbé rẹ̀ bó o ṣe ń múra ọ̀rọ̀ rẹ.
Tó o bá ti wá pinnu ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe, tó o sì ti yan ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tó bá a mu (tàbí pé o ti yẹ ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún ọ wò láti rí bó ṣe bá ète yẹn mu), o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí nípa kókó yẹn ní pàtó. Wá ìsọfúnni tí yóò ṣe àwùjọ rẹ láǹfààní ní pàtó. Má kàn kó ọ̀rọ̀ tí kò lórí tí kò nídìí jọ, kàkà bẹ́ẹ̀, wá àwọn kókó pàtó tó kún fún ẹ̀kọ́ tó sì ń ranni lọ́wọ́ ní ti gidi. Ṣe ìwádìí ní ìwọ̀n tó bọ́gbọ́n mu. Lọ́pọ̀ ìgbà, kò ní pẹ́ tí wàá fi kó ọ̀rọ̀ tó pọ̀ ju ohun tó o lè lò jọ, nípa bẹ́ẹ̀, o tún ní láti ṣe àṣàyàn.
Yan àwọn kókó pàtàkì tó o máa sọ̀rọ̀ lé lórí láti lè ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ kí àwùjọ rẹ sì lè jàǹfààní tó o fẹ́ kí wọ́n jẹ. Ìwọ̀nyí ló máa di òpómúléró ọ̀rọ̀ rẹ, ìyẹn ni ìlapa èrò tí wàá lò. Báwo ló ṣe yẹ kí kókó pàtàkì ibẹ̀ pọ̀ tó? Ó ṣeé ṣe kí méjì péré ti tó fún ọ̀rọ̀ kúkúrú kan, márùn-ún sì sábà máa ń tó fún àsọyé oníwákàtí kan pàápàá. Bí kókó pàtàkì bá ṣe mọ níwọ̀n sí, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe rọrùn tó fún àwùjọ láti rántí wọn.
Tí ẹṣin ọ̀rọ̀ àti àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ bá sì ti ṣe kedere lọ́kàn rẹ, bẹ̀rẹ̀ sí to àwọn ohun tó o ti kó jọ látinú ìwádìí rẹ lẹ́sẹẹsẹ. Mú èyí tó bá jẹ mọ́ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ. Yan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí yóò mú kí ọ̀nà tó o gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ jẹ́ ọ̀tun létí àwùjọ rẹ. Nígbà tó o bá yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ láti fi ti àwọn kókó pàtàkì lẹ́yìn, ṣàkíyèsí àwọn èrò tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn lọ́nà tó nítumọ̀. Fi ìsọfúnni kọ̀ọ̀kan sábẹ́ kókó pàtàkì tó jẹ mọ́ ọn. Bí àwọn kan lára ìsọfúnni náà kò bá jẹ mọ́ kókó pàtàkì kankan, mú un kúrò, kódà ì báà tiẹ̀ wù ọ́ gan-an, tàbí kó o tọ́jú rẹ̀ sínú fáìlì kan kí o lè lò ó nígbà mìíràn. Àwọn tó bá dára jù lọ nínú ìsọfúnni rẹ nìkan ni kó o lò. Bí o bá gbìyànjú láti kárí ohun tó pọ̀ jù, yóò di dandan pé kó o sáré sọ̀rọ̀, o ò sì ní lé ṣàlàyé délẹ̀ dáadáa. Ó sàn kí ó jẹ́ ìwọ̀nba kókó mélòó kan tó wúlò gidi fún àwùjọ lo sọ̀rọ̀ lé lórí, kí o sì sọ ọ́ dáadáa. Má kọjá àkókò tí a yàn fún ọ̀rọ̀ rẹ o.
Wàyí o, wá to àwọn ohun tó o ti kó jọ lẹ́sẹẹsẹ bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra wọn, tí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ohun tí òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà Lúùkù ṣe nìyẹn. Lẹ́yìn tó ti kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òtítọ́ ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ kókó tó ń ṣèwádìí lé lórí jọ, ó tò wọ́n “ní ìṣètò tí ó bọ́gbọ́n mu.” (Lúùkù 1:3) O lè to ọ̀rọ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìtàn wọn ṣe tẹ̀ léra tàbí bí àkòrí rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra, bóyá látorí ìdí tí ọ̀ràn fi wáyé títí dé ibi tó yọrí sí, tàbí kí o kọ́kọ́ sọ ohun tó jẹ́ ìṣòro kí o sì wá sọ ojútùú rẹ̀, ó sinmi lórí ọ̀nà tó bá gbéṣẹ́ jù lọ tó o lè gbà ṣe ohun tó o ní lọ́kàn láṣeyọrí. Má ṣe ti orí èrò kan fò mọ́ òmíràn láìparí èyí tí ò ń bá bọ̀ tẹ́lẹ̀ o. Ńṣe ló yẹ kó o ṣamọ̀nà àwọn olùgbọ́ rẹ látorí èrò kan bọ́ sí òmíràn lọ́nà tó rọrùn, láìjẹ́ kí àlàfo kankan tí kò ní ṣeé ṣàlàyé wà. Ó yẹ kí ẹ̀rí tí o bá mú jáde darí àwùjọ rẹ sí èrò tó bọ́gbọ́n mu. Bí o ṣe ń to àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́sẹẹsẹ, ronú nípa bí ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ yóò ṣe dún létí àwọn olùgbọ́ rẹ. Ǹjẹ́ ohun tó o fẹ́ sọ yóò tètè yé wọn? Ǹjẹ́ yóò sún wọn láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́ gẹ́gẹ́ bí o ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe?
Lẹ́yìn náà, wá múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa mú kí àwùjọ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o fẹ́ sọ, tí yóò sì jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ mọ̀ pé ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí wúlò fún àwọn gidigidi. Ó lè dára tó o bá kọ gbólóhùn mélòó kan tó o máa kọ́kọ́ sọ sílẹ̀. Níkẹyìn, wá ìparí ọ̀rọ̀ tó tani jí, tó sì bá ohun tó o ní lọ́kàn mu.
Bí o bá tètè ṣe ìlapa èrò rẹ sílẹ̀, wàá ní àsìkò tó pọ̀ tó láti fi ṣàtúnṣe tó yẹ sí ìlapa èrò náà kó tó di pé o sọ ọ̀rọ̀ rẹ. O lè rí i pé ó yẹ kó o fi ìsọfúnni oníṣirò mélòó kan, àpèjúwe kan, tàbí ìrírí kan ti àwọn èrò kan lẹ́yìn. Tó o bá lo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí àwọn ohun kan tó gbàfiyèsí ládùúgbò, ìyẹn lè mú kí àwùjọ rẹ tètè rí bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n. Bí o ṣe ń ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ rẹ, o lè wá rí àwọn àǹfààní tó o lè lò láti fi mú ìsọfúnni náà bá àwùjọ rẹ mu. Kí o tó lè sọ àwọn ìsọfúnni dáadáa tó o rí kó jọ di ọ̀rọ̀ tó gbéṣẹ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí o ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ kí o sì ṣe àtúnṣe sí i.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan lè nílò àkọsílẹ̀ tó gún ju ti àwọn mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n tó o bá to ọ̀rọ̀ rẹ sábẹ́ ìwọ̀nba kókó pàtàkì mélòó kan, tí o mú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún kókó wọ̀nyí kúrò, tó o sì to àwọn èrò rẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, wàá rí i pé tó o bá ti ní ìrírí díẹ̀ sí i, kò ní sídìí fún ọ láti tún máa kọ gbogbo ohun tó o fẹ́ sọ pátápátá sílẹ̀ mọ́. Ìyẹn á sì dín ọ lákòókò kù gan-an ni! Ọ̀nà tó o gbà ń sọ̀rọ̀ rẹ á sì tún dára sí i. Yóò hàn gbangba pé ò ń jàǹfààní ní tòótọ́ látinú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.