June
Sunday, June 1
A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 14:22.
Jèhófà bù kún àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ torí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Wọ́n máa ń ṣenúnibíni sí wọn nígbà tí wọn ò retí ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n ń wàásù ní agbègbè Lísírà. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn èèyàn náà tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì gbọ́ ìwàásù. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn alátakò dé, wọ́n sì “yí àwọn èrò náà lọ́kàn pa dà.” Kódà, àwọn kan lára àwọn èèyàn náà sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta débi pé wọ́n rò pé ó ti kú. (Ìṣe 14:19) Ṣùgbọ́n Bánábà àti Pọ́ọ̀lù lọ sí ibòmíì láti máa wàásù. Àǹfààní wo ni wọ́n rí? Wọ́n sọ “àwọn díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn,” wọ́n gba àwọn ará níyànjú, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára. (Ìṣe 14:21, 22) Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló jàǹfààní torí pé Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sí wọn. Táwa náà ò bá dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà ní ká máa ṣe dúró, ó dájú pé ó máa bù kún wa. w23.04 16 ¶13-14
Monday, June 2
Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi; sì fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́. Mo ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi, torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.—Sm. 86:6, 7.
Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọ̀tá fẹ́ pa Ọba Dáfídì, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà gbọ́ àwọn àdúrà òun, ó sì dáhùn wọn. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà ẹ. Bíbélì ti jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro wa. Ó lè lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́, àmọ́ a mọ̀ pé ó máa dáhùn wọn. Ó máa pèsè ohun tá a nílò gan-an lásìkò tá a nílò ẹ̀. Torí náà máa gbàdúrà, kó o sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ àti pé ó máa bójú tó ẹ ní báyìí, ó sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́” nínú ayé tuntun.—Sm. 145:16. w23.05 8 ¶4; 13 ¶17-18
Tuesday, June 3
Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?—Sm. 116:12.
Ó yẹ kó o ronú lórí àǹfààní tó o máa rí tọ́wọ́ ẹ bá tẹ àfojúsùn ẹ. Àwọn àǹfààní wo ló yẹ kíwọ náà máa ronú nípa ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé àfojúsùn ẹ ni pé kó o túbọ̀ máa ka Bíbélì déédéé, kí àdúrà ẹ sì sunwọ̀n sí i, á dáa kó o ronú lórí bí àwọn nǹkan yẹn ṣe máa mú kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Sm. 145:18, 19) Tó bá jẹ́ pé àfojúsùn ẹ ni pé kó o ní ànímọ́ Kristẹni kan, ronú lórí bíyẹn ṣe máa jẹ́ kí àárín ìwọ àtàwọn míì túbọ̀ gún régé. (Kól. 3:14) Torí náà, á dáa kó o kọ ìdí tó fi ń wù ẹ́ pé kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn àfojúsùn ẹ sílẹ̀, kó o sì máa gbé wọn yẹ̀ wò déédéé. Mú àwọn tó máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ lọ́rẹ̀ẹ́. (Òwe 13:20) Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì máa ń wà tí kì í wù wá pé ká ṣe nǹkan kan. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí nǹkan tá a lè ṣe kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn wa ni? Rárá o. Ó yẹ káwa náà túbọ̀ máa ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa bí ò tiẹ̀ wù wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ní rọrùn, inú wa máa dùn gan-an tọ́wọ́ wa bá tẹ àfojúsùn wa. w23.05 27-28 ¶5-8
Wednesday, June 4
Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.—Gál. 6:7.
Tá a bá gbà pé a máa jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìyẹn á jẹ́ ká jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ náà, ká ṣàtúnṣe, ká má sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè máa sá eré ìyè nìṣó. Tó o bá ti ṣe ìpinnu tí ò tọ́, kí lo lè ṣe? Gbà pé ohun tó ṣelẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Má fi àkókò ẹ ṣòfò, kó o wá máa sọ pé ohun tó o ṣe ò burú tàbí kó o wá máa dá ara ẹ àtàwọn ẹlòmíì lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbà pé o ti ṣàṣìṣe, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ṣàtúnṣe. Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá ń dà ẹ́ láàmú nítorí àṣìṣe tó o ṣe, rẹ ara ẹ sílẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà, jẹ́ kó mọ̀ pé o ṣàṣìṣe, kó o sì ní kó dárí jì ẹ́. (Sm. 25:11; 51:3, 4) Lọ bẹ àwọn tó o ṣẹ̀. Tó bá sì pọn dandan, lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jém. 5:14, 15) Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó o ṣe, kó o má sì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí ẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Sm. 103:8-13. w23.08 28-29 ¶8-9
Thursday, June 5
Jèhóáṣì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí àlùfáà Jèhóádà fi ń tọ́ ọ sọ́nà.—2 Ọba 12:2.
Ọba Jèhóáṣì jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere Jèhóádà. Ìyẹn jẹ́ kó lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà látìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhóádà kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sáwọn ìjòyè Júdà tí ò sin Jèhófà mọ́. (2 Kíró. 24:4, 17, 18) Ọ̀rọ̀ náà dun Jèhófà gan-an, torí náà, “ó ń rán àwọn wòlíì sáàárín wọn léraléra láti mú wọn pa dà wá . . . , àmọ́ wọn ò gbọ́.” Kódà, wọn ò fetí sí Sekaráyà tó jẹ́ ọmọ Jèhóádà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì àti àlùfáà ni, tó sì tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Jèhóáṣì. Ó ṣeni láàánú pé Ọba Jèhóáṣì ní kí wọ́n lọ pa Sekaráyà. (2 Kíró. 22:11; 24:19-22) Jèhóáṣì ò bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó tọ́. Jèhófà ti sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Màá kórìíra àwọn tí kò kà mí sí.” (1 Sám. 2:30) Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ogun Síríà tí ò tó nǹkan ṣẹ́gun Jèhóáṣì àtàwọn ‘ọmọ ogun ẹ̀ tó pọ̀ gan-an,’ ó sì fara ‘gbọgbẹ́ yán-na-yàn-na.’ (2 Kíró. 24:24, 25) Àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ sì pa á torí pé ó pa Sekaráyà. w23.06 18-19 ¶16-17
Friday, June 6
Ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, àmọ́ ẹ ti di ìmọ́lẹ̀.—Éfé. 5:8.
Pọ́ọ̀lù wàásù, ó sì kọ́ni nílùú Éfésù. (Ìṣe 19:1, 8-10; 20:20, 21) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kí àwọn ará Éfésù tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe, wọ́n sì máa ń gba ohun tí ò jóòótọ́ gbọ́. Àwọn ará Éfésù máa ń ṣèṣekúṣe, wọ́n sì máa ń hùwàkiwà. Wọ́n sábà máa ń sọ ìsọkúsọ láwọn gbàgede ìlú àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ. (Éfé. 5:3) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀ ló ti “kọjá gbogbo òye ìwà rere.” Lédè míì, “wọn kì í kábàámọ̀ nǹkan tí wọ́n bá ṣe, wọn ò sì gbà pé nǹkan táwọn ṣe ò dáa.” (Éfé. 4:17-19) Kí àwọn ará Éfésù tó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn ò sì ṣiṣẹ́ dáadáa. Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run.” Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn ará Éfésù kan kúrò nínú òkùnkùn. w24.03 20 ¶2, 4; 21 ¶5-6
Saturday, June 7
Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà. . . . Kò sì ní rẹ̀ wọ́n.—Àìsá. 40:31.
Torí pé onídàájọ́ ni Gídíónì, ó máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára. Nígbà táwọn ará Mídíánì sá lọ ní alẹ́ tí Gídíónì gbéjà kò wọ́n, Gídíónì lé wọn láti Àfonífojì Jésírẹ́lì títí dé Odò Jọ́dánì. (Oníd. 7:22) Ṣé Odò Jọ́dánì ni Gídíónì ti pa dà? Rárá o! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ òun àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀, wọ́n sọdá odò náà, wọ́n sì ń lé àwọn ọ̀tá náà lọ. Nígbà tó yá, wọ́n lé àwọn ará Mídíánì náà bá, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. (Oníd. 8:4-12) Gídíónì fọkàn tán Jèhófà pé ó máa fún òun lókun, Jèhófà ò sì já a kulẹ̀. (Oníd. 6:14, 34) Ìgbà kan wà tí Gídíónì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ fẹsẹ̀ sáré lé àwọn ọba Mídíánì méjì kan tó ṣeé ṣe kí wọ́n gun ràkúnmí. (Oníd. 8:12, 21) Síbẹ̀, torí pé Gídíónì àtàwọn èèyàn ẹ̀ ò jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n, Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí ‘kì í rẹ̀, tí okun rẹ̀ kì í sì í tán.’ Torí náà, ó dájú pé ó máa fún yín lókun nígbà tẹ́ ẹ nílò ẹ̀ gan-an.—Àìsá. 40:28, 29. w23.06 6-7 ¶14, 16
Sunday, June 8
[Jèhófà] kò ní pa yín tì, kò sì ní fi yín sílẹ̀.—Diu. 31:6.
Ìṣòro yòówù kó dé bá wa, àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin. Torí náà, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bárákì ṣe ṣàṣeyọrí torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣe ohun tó sọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní apata àti aṣóró kankan, Jèhófà sọ fún Bárákì pé kí wọ́n lọ dojú ìjà kọ Sísérà olórí ọmọ ogun Kénáánì tí wọ́n ní ohun ìjà tó pọ̀. (Oníd. 5:8) Wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Dèbórà sọ fún Bárákì pé kó lọ kojú Sísérà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú. Bárákì mọ̀ pé kò ní rọrùn láti bá wọn jà torí pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn máa sáré dáadáa lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú, síbẹ̀ ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Bí àwọn ọmọ ogun Bárákì ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Tábórì, Jèhófà jẹ́ kí ọ̀yamùúmùú òjò rọ̀. Bí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà ṣe rì sínú ẹrẹ̀ nìyẹn, Jèhófà sì jẹ́ kí Bárákì ṣẹ́gun. (Oníd. 4:1-7, 10, 13-16) Bákan náà, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì ń ṣe ohun tí ètò ẹ̀ sọ, àwa náà máa ṣẹ́gun. w23.07 18-19 ¶17-18
Monday, June 9
Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.—Mát. 24:13.
Ká tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ní sùúrù. Bíi tàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́, ó ṣe pàtàkì káwa náà máa ní sùúrù títí dìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. (Héb. 6:11, 12) Bíbélì fi àwa ìránṣẹ́ Jèhófà wé àgbẹ̀ kan. (Jém. 5:7, 8) Àwọn àgbẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ kára láti gbin nǹkan, kí wọ́n sì bomi rin ín, àmọ́ wọn ò mọ ìgbà tí nǹkan náà máa dàgbà. Ṣe ni wọ́n máa ń ní sùúrù, ó sì dá wọn lójú pé àwọn máa kórè lọ́jọ́ kan. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Ó yẹ ká tẹra mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé a “ò mọ ọjọ́ tí Olúwa [wa] ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Torí náà, ó yẹ ká ní sùúrù kó sì dá wa lójú pé tó bá tó àkókò, Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá dẹni tí ò ní sùúrù mọ́ torí pé ohun tá à ń dúró dè ò tètè dé, ó lè sú wa, ó sì lè jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. A tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan tá a rò pé ó lè mára tù wá lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká lè fara dà á dé òpin, àá sì rí ìgbàlà.—Míkà 7:7. w23.08 22 ¶7
Tuesday, June 10
Ọmọ ìka ẹsẹ̀ náà jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀.—Dán. 2:42.
Tá a bá fi àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 2:41-43 wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú ìwé Dáníẹ́lì àti Ìfihàn, a máa rí i pé ẹsẹ̀ ère yẹn ṣàpẹẹrẹ ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé báyìí, ìyẹn ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Dáníẹ́lì sọ pé ìjọba yẹn “máa lágbára lápá kan,” “kò sì ní lágbára lápá kan.” Kí nìdí tí ò fi ní lágbára lápá kan? Ìdí ni pé àwọn mẹ̀kúnnù tó ṣàpẹẹrẹ amọ̀ rírọ̀ ò jẹ́ kí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso wọn lo agbára ẹ̀ tó dà bí irin bó ṣe fẹ́. Àlàyé tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère inú àlá yẹn jẹ́ ká mọ àwọn òótọ́ pọ́ńbélé kan. Àkọ́kọ́, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé òun lágbára. Bí àpẹẹrẹ, àwọn orílẹ̀-èdè méjì yìí ló gbawájú lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́gun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́, ìjọba alágbára yìí ò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ torí pé àwọn ará ìlú máa ń bá ara wọn àti ìjọba jà. Ìkejì, ìjọba alágbára yìí ló máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn kí Ìjọba Ọlọ́run tó fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. w23.08 11 ¶12-13
Wednesday, June 11
Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi, mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́. Ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀.—Sm. 18:6.
Nígbà míì, nǹkan máa ń tojú sú Dáfídì nítorí àwọn ìṣòro tó ní àti àdánwò tó dé bá a. (Sm. 18:4, 5) Síbẹ̀, ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí i àti bó ṣe bójú tó o tù ú lára. Jèhófà darí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ti rẹ̀ lọ sí “ibi ìjẹko tútù” àti “ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.” Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí ló fún Dáfídì lókun, tó sì jẹ́ kó máa fayọ̀ sìn ín nìṣó. (Sm. 18:28-32; 23:2) Bákan náà lónìí, “ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé” láwọn ìgbà tá a níṣòro. (Ìdárò 3:22; Kól. 1:11) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí Dáfídì wà nínú ewu, ó láwọn ọ̀tá tó lágbára, wọ́n sì pọ̀. Síbẹ̀ torí pé ó mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, Jèhófà sì dáàbò bò ó. Dáfídì mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà wà pẹ̀lú òun, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀ nígbà ìṣòro. Ìdí nìyẹn tó fi kọrin pé: “[Jèhófà] gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù.” (Sm. 34:4) Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà kan wà tí ẹ̀rù ba Dáfídì, àmọ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí i mú kó borí ìbẹ̀rù náà. w24.01 30 ¶15-17
Thursday, June 12
Tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá fẹ́ fa ojú rẹ mọ́ra, má gbà.—Òwe 1:10.
Kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Jèhóáṣì ṣe. Lẹ́yìn tí Àlùfáà Àgbà Jèhóádà kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. (2 Kíró. 24:17, 18) Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè Júdà tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ìwọ náà á gbà pé kò yẹ kí Jèhóáṣì máa bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́ torí èèyàn burúkú ni wọ́n. Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ burúkú yìí ló fetí sí. Ó tún ṣe é débi pé nígbà tí Sekaráyà ìbátan ẹ̀ fẹ́ tọ́ ọ sọ́nà, ṣe ló ní kí wọ́n lọ pa á. (2 Kíró. 24:20, 21; Mát. 23:35) Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà àti ìwà òmùgọ̀ ni Jèhóáṣì hù yìí! Èèyàn dáadáa ni Jèhóáṣì tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ó di apẹ̀yìndà àti apààyàn. Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pa òun náà. (2 Kíró. 24:22-25) Ẹ ò rí i bí ìgbésí ayé ẹ̀ ì bá ṣe dáa tó ká ní ó tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tó sì fetí sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! w23.09 9 ¶6
Friday, June 13
Má bẹ̀rù mọ́.—Lúùkù 5:10.
Jésù mọ̀ pé Pétérù máa jẹ́ olóòótọ́. Torí náà, ó sọ fún Pétérù pé kó “má bẹ̀rù mọ́.” Torí pé Jésù fọkàn tán Pétérù, ìyẹn jẹ́ kó ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ̀. Pétérù àti Áńdérù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò fi iṣẹ́ ẹja pípa tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, àwọn àti Jésù jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà sì bù kún wọn gan-an. (Máàkù 1:16-18) Ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí Jésù ṣe ló ṣojú Pétérù nígbà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù mú àwọn èèyàn tó ń ṣàìsàn lára dá, nígbà tó lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde àti nígbà tó jí òkú dìde. (Mát. 8:14-17; Máàkù 5:37, 41, 42) Pétérù tún fojú ara ẹ̀ rí i nígbà tí Jèhófà yí Jésù pa dà di ológo, ìyẹn jẹ́ kó rí bí Jésù ṣe máa rí nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ohun tó rí yẹn sì fún un lókun gan-an. (Máàkù 9:1-8; 2 Pét. 1:16-18) Ó dájú pé tí Pétérù ò bá tẹ̀ lé Jésù, àwọn nǹkan yìí ò ní ṣojú ẹ̀. Ẹ ò rí i pé inú Pétérù máa dùn gan-an pé ó borí èrò tí ò tọ́ tó ní, ó sì tún láǹfààní láti rí àwọn nǹkan rere tí Jésù ṣe! w23.09 21 ¶4-5
Saturday, June 14
Jésù sọ fún un pé: “Mò ń sọ fún ọ pé, kì í ṣe ìgbà méje, àmọ́ kó tó ìgbà àádọ́rin lé méje (77).”—Mát. 18:22.
Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ, ó lo gbólóhùn náà “ìfẹ́ tó jinlẹ̀.” “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀” ni irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń bò mọ́lẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀. (1 Pét. 4:8) Ó ṣeé ṣe kí Pétérù rántí ohun tí Jésù kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa dárí jini. Nígbà tá à ń sọ yìí, Pétérù gbà pé èèyàn dáadáa lòun nígbà tó sọ pé òun máa dárí ji arákùnrin òun ní “ìgbà méje.” Àmọ́ ohun tí Jésù kọ́ Pétérù àti àwa náà ni pé ká máa dárí ji ara wa ní “ìgbà àádọ́rin lé méje (77),” ìyẹn ni pé ká máa dárí ji ara wa fàlàlà. (Mát. 18:21) Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tí Jésù sọ yìí, má jẹ́ kó sú ẹ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa ń ṣòro fún láti dárí jini torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù báyìí ni pé kó o dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, kó o sì wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀. w23.09 29 ¶12
Sunday, June 15
Mo ké pe Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn.—Jónà 2:2.
Nígbà tí Jónà wà nínú ikùn ẹja, ó dá a lójú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà tó fìrẹ̀lẹ̀ gbà torí ó ti ronú pìwà dà, ó sì dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́. Nígbà tó yá, Jèhófà gba Jónà sílẹ̀, ó sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. (Jónà 2:10–3:4) Tó o bá níṣòro, ṣé ìdààmú máa ń bá ẹ débi pé o ò ní lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà? Ṣé ó máa ń rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò ní lè kẹ́kọ̀ọ́? Má gbàgbé pé ọ̀rọ̀ ẹ yé Jèhófà dáadáa. Torí náà, tó o bá tiẹ̀ gbàdúrà ṣókí, ó dájú pé Jèhófà máa ṣe ohun tó o fẹ́. (Éfé. 3:20) Tí ìrora àti ìdààmú tó bá ẹ ò bá jẹ́ kó o lè kàwé tàbí kó o lè kẹ́kọ̀ọ́, o lè máa gbọ́ Bíbélì tàbí àwọn ìwé ètò Ọlọ́run tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Ó tún máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá gbọ́ ọ̀kan lára àwọn orin wa tàbí kó o wo fídíò kan lórí ìkànnì jw.org. Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tó o sì ń lo gbogbo ohun tí Jèhófà pèsè kó o lè rí ìdáhùn àdúrà ẹ, wàá fi hàn pé o fẹ́ kí Jèhófà fún ẹ lókun. w23.10 13 ¶6; 14 ¶9
Monday, June 16
Ẹ̀mí mímọ́ tipasẹ̀ èyí fi hàn kedere pé a ò tíì fi ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́ hàn nígbà tí àgọ́ àkọ́kọ́ ṣì wà.—Héb. 9:8.
Àgọ́ ìjọsìn àtàwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ sí Jerúsálẹ́mù nígbà tó yá jọra wọn láwọn ọ̀nà kan. Yàrá méjì ló wà nínú wọn, ìyẹn “Ibi Mímọ́” àti “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.” Aṣọ ìdábùú tí wọ́n kóṣẹ́ sí ni wọ́n fi pín wọn sí méjì. (Héb. 9:2-5; Ẹ́kís. 26:31-33) Àwọn ohun tó wà nínú Ibi Mímọ́ ni ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi wúrà ṣe, pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun tùràrí àti tábìlì búrẹ́dì àfihàn. “Àwọn àlùfáà tí wọ́n fòróró yàn” nìkan ló lè wọ Ibi Mímọ́ láti ṣiṣẹ́ àlùfáà. (Nọ́ń. 3:3, 7, 10) Ohun tó sì wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni àpótí májẹ̀mú tí wọ́n fi wúrà ṣe. Ibẹ̀ ni Jèhófà sì ti máa ń sọ̀rọ̀. (Ẹ́kís. 25:21, 22) Àlùfáà àgbà nìkan ló lè kọjá aṣọ ìdábùú sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. (Léf. 16:2, 17) Ó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran wọ ibẹ̀ láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ara ẹ̀ àti ti orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó yá, Jèhófà jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ mọ ohun táwọn nǹkan tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ.—Héb. 9:6, 7. w23.10 27 ¶12
Tuesday, June 17
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.—Jòh. 15:17.
Nínú Bíbélì, léraléra ni Jèhófà pa á láṣẹ fún wa pé ká “nífẹ̀ẹ́ ara wa.” (Jòh. 15:12; Róòmù 13:8; 1 Tẹs. 4:9; 1 Pét. 1:22; 1 Jòh. 4:11) Àmọ́ inú ọkàn ni ìfẹ́ ti ń wá, kò sì séèyàn kankan tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Torí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ohun tá à ń sọ àtohun tá à ń ṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ rèé: “Ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́.” (Sek. 8:16) ‘Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín yín.’ (Máàkù 9:50) Ẹ máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ “nínú bíbu ọlá fún ara yín.” (Róòmù 12:10) “Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín.” (Róòmù 15:7) “Ẹ máa . . . dárí ji ara yín.” (Kól. 3:13) “Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo.” (Gál. 6:2) ‘Ẹ máa tu ara yín nínú.’ (1 Tẹs. 4:18) “Ẹ máa . . . gbé ara yín ró.” (1 Tẹs. 5:11) ‘Ẹ máa gbàdúrà fún ara yín.’—Jém. 5:16. w23.11 9 ¶7-8
Wednesday, June 18
Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀.—Róòmù 12:12.
Lójoojúmọ́, a máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ṣe ìpinnu lórí irú ẹni tá a máa bá ṣọ̀rẹ́, irú eré ìnàjú tá a máa ṣe, ilé ẹ̀kọ́ gíga, ìgbéyàwó, bóyá a máa bímọ àti irú iṣẹ́ tá a máa ṣe. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé mo gbà pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run, tí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí sì máa rọ́pò ẹ̀? Àbí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé mo dà bí àwọn tó ń jayé orí wọn, tí wọ́n sì ń sọ pé táwọn bá ti kú, ó parí nìyẹn?’ (Mát. 6:19, 20; Lúùkù 12:16-21) Torí náà, ìpinnu tó dáa là á máa ṣe, tá a bá gbà pé ayé tuntun ti dé tán. Nígbà míì, àwọn ìṣòro máa ń dé bá wa tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára. Ó lè jẹ́ pé à ń fara da inúnibíni, àìsàn kan tó le gan-an tàbí àwọn ìṣòro míì tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Tí ìṣòro náà bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, a lè máa rò pé a lè fara dà á. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣòro náà kì í tètè lọ. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára ká lè fara dà á, ká sì lè máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.—1 Pét. 1:6, 7. w23.04 27 ¶4-5
Thursday, June 19
Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.—1 Tẹs. 5:17.
Jèhófà fẹ́ ká ṣe ipa tiwa kó lè dáhùn àdúrà wa. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n fún òun láyè níbi iṣẹ́ kóun lè lọ sí àpéjọ agbègbè. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà yẹn? Ó lè fún arákùnrin náà nígboyà tó máa fi lọ bá ọ̀gá ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́ arákùnrin náà ṣì gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀. Kódà, ó lè gba pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra. Ó sì lè gba pé kó yí àkókò tó máa ṣiṣẹ́ pa dà, kí ẹlòmíì lè bá a ṣe é tàbí kó ní kí wọ́n yọ owó ọjọ́ tóun ò ní wá síbi iṣẹ́ kóun lè lọ sí àpéjọ náà. Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà léraléra nípa àwọn nǹkan tó ń kó wa lọ́kàn sókè. Ohun tí Jésù sọ jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà máa dáhùn gbogbo àdúrà wa. (Lúùkù 11:9) Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ! Máa gbàdúrà tọkàntọkàn, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́. (Lúùkù 18:1-7) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á mọ̀ pé nǹkan náà ṣe pàtàkì sí wa. Ìyẹn tún fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. w23.11 22 ¶10-11
Friday, June 20
Ìrètí kì í yọrí sí ìjákulẹ̀.—Róòmù 5:5.
Jèhófà sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ̀ Ábúráhámù pé ó máa bí ọmọ kan tí gbogbo orílẹ̀-èdè máa gba ìbùkún nípasẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́n. 15:5; 22:18) Torí pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, ó dá a lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Kódà, nígbà tí Ábúráhámù pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí ìyàwó ẹ̀ sì jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, tọkọtaya tó nígbàgbọ́ yìí ò tíì bímọ kankan. (Jẹ́n. 21:1-7) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Lórí ìrètí, [Ábúráhámù] ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti sọ.” (Róòmù 4:18) Ìwọ náà sì mọ̀ pé ohun tí Ábúráhámù ń retí yìí ṣẹ nígbà tó yá torí ó di bàbá Ísákì, ọmọkùnrin tó ti ń wá tipẹ́tipẹ́. Àmọ́, kí ló mú kí Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Torí pé Ábúráhámù ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó “dá a lójú hán-ún pé Ọlọ́run lè ṣe ohun tí Ó ṣèlérí.” (Róòmù 4:21) Inú Jèhófà dùn sí Ábúráhámù, ó sì pè é ní olódodo torí ìgbàgbọ́ tó ní.—Jém. 2:23. w23.12 8 ¶1-2
Saturday, June 21
Ẹni tó bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré jù jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó kéré jù jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tó pọ̀ pẹ̀lú.—Lúùkù 16:10.
Ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni tó ṣe é fọkàn tán máa ń bójú tó gbogbo ojúṣe ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ tó dáa tí Jésù fi lélẹ̀ yẹ̀ wò. Ọwọ́ pàtàkì ló fi máa ń múṣẹ́, kò sì ya ọ̀lẹ. Gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un ló ṣe, kódà nígbà tí kò rọrùn fún un. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì tún kú nítorí wọn. (Jòh. 13:1) Bíi ti Jésù, tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún ẹ, rí i pé o ṣe é dáadáa. Tó ò bá mọ bó o ṣe máa ṣe é, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó o sọ fún àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má kàn ṣe iṣẹ́ náà láàbọ̀. (Róòmù 12:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o parí ẹ̀ torí “Jèhófà [lò] ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.” (Kól. 3:23) Lóòótọ́, o kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ ó yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ, kó o sì gba àwọn àṣìṣe tó o bá ṣe.—Òwe 11:2. w23.12 26 ¶8
Sunday, June 22
Ìbùkún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Jer. 17:7.
Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá ṣèrìbọmi, tá a sì di ara ìdílé Jèhófà. Gbogbo àwọn tó ti ṣèrìbọmi ló máa gbà pẹ̀lú Dáfídì tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.” (Sm. 65:4) Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń gbà láyè láti wá sínú àgbàlá ẹ̀. Àwọn tó bá pinnu láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ló máa ń sún mọ́. (Jém. 4:8) Tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó o sì ti ṣèrìbọmi, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ‘tú ìbùkún sórí ẹ títí o ò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.’ (Mál. 3:10; Jer. 17:8) Má rò pé lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, o ò ní níṣòro kankan. Máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ ẹ ṣẹ, kódà tó o bá níṣòro tàbí tí nǹkan kan bá dán ìgbàgbọ́ ẹ wò. (Oníw. 5:4, 5) Ní báyìí tó o ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wàá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀, wàá sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́ tó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—Mát. 28:19, 20; 1 Pét. 2:21. w24.03 8 ¶1-3
Monday, June 23
Ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀.—Jẹ́n. 2:24.
Ká sọ pé ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ṣègbéyàwó kì í gbádùn àkókò tẹ́ ẹ jọ máa ń lò ńkọ́? Kí lo lè ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ iná igi. Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iná náà máa ràn, táá sì máa jó lala. Ó máa gba pé ká kọ́kọ́ máa ki àwọn igi kéékèèké sínú ẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn, a lè wá máa ki igi ńláńlá sínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ẹ ò ṣe máa lo àkókò díẹ̀ pa pọ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? Ẹ rí i pé nǹkan tẹ́yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí lẹ jọ ń ṣe. (Jém. 3:18) Tẹ́ ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò díẹ̀díẹ̀ pa pọ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín á túbọ̀ jinlẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara yín. A lè fi wé afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ sí iná igi kan kó lè jó dáadáa. Tí ò bá sí afẹ́fẹ́, iná náà máa tètè kú. Lọ́nà kan náà, tí tọkọtaya kan kì í bá bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn máa tètè di tútù. Lọ́wọ́ kejì, tí tọkọtaya kan bá ń ṣiṣẹ́ kára láti máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn ò ní yẹ̀ láé. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ká kàn rò pé à ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì wa, àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí ọkọ tàbí aya wa mọ̀ pé à ń bọ̀wọ̀ fún òun lóòótọ́. w23.05 22 ¶9; 23-24 ¶14-15
Tuesday, June 24
Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.—Sm. 94:19.
Nínú Bíbélì, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ìdààmú bá wọn, tí jìnnìjìnnì sì bò wọ́n nítorí àwọn ọ̀tá tàbí nítorí àwọn nǹkan míì. (Sm. 18:4; 55:1, 5) Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ ilé ìwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ìdílé wa tàbí ìjọba lè máa ta kò wá. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀rù lè máa bà wá pé a máa kú nítorí àìsàn tó ń ṣe wá. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe wá bíi ti ọmọ kékeré kan tó rò pé kò sẹ́ni tó máa ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀? Ó máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń tù wá lára. Torí náà, máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì déédéé. (Sm. 77:1, 12-14) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tíṣòro bá dé, ẹni tí wàá kọ́kọ́ ronú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni Bàbá rẹ ọ̀run. Sọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún Jèhófà àtohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Lẹ́yìn náà máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá rí i pé Jèhófà máa tù ẹ́ nínú.—Sm. 119:28. w24.01 24-25 ¶14-16
Wednesday, June 25
Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára . . . ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.—Fílí. 2:13.
Kọ́wọ́ ẹ tó lè tẹ àfojúsùn ẹ, nǹkan tó o fẹ́ ṣe yẹn gbọ́dọ̀ máa wù ẹ́. Tí nǹkan tó o fẹ́ ṣe yẹn bá ń wù ẹ́ gan-an, á rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ̀ ẹ́. Tí àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe yẹn bá ń wù wá gan-an, á rọrùn fún wa láti ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ̀ ẹ́. Torí náà, kí làwọn nǹkan tó yẹ kó o máa ṣe táá jẹ́ kí àwọn àfojúsùn ẹ túbọ̀ máa wù ẹ́? Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ káwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe túbọ̀ máa wù ẹ́. Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ. Nígbà míì, a máa ń fẹ́ ṣe àwọn nǹkan kan torí a mọ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn, ìyẹn sì dáa. Àmọ́, ó lè má wù wá. Máa ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. (Sm. 143:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ronú lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí i, ìyẹn sì jẹ́ kó pinnu pé òun máa lo gbogbo okun òun lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:9, 10; 1 Tím. 1:12-14) Lọ́nà kan náà, bó o bá ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa wù ẹ́ pé kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn àfojúsùn ẹ.—Sm. 116:12. w23.05 26-27 ¶3-5
Thursday, June 26
Ẹ yin orúkọ Jèhófà.—Sm. 113:1.
A máa múnú Baba wa ọ̀run dùn tá a bá ń yin orúkọ rẹ̀. (Sm. 119:108) Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé Ọlọ́run Olódùmarè dà bí àwa èèyàn aláìpé tá à ń fẹ́ káwọn èèyàn máa yìn wá kínú wa lè máa dùn? Rárá o. Tá a bá ń yin Bàbá wa ọ̀run, à ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Sátánì sọ pé kò sẹ́ni tó máa sọ nǹkan rere nípa orúkọ Ọlọ́run. Ó tún sọ pé kò sẹ́nì kankan tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé gbogbo wa la máa kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tá a bá gbà pé ìyẹn ló máa ṣe wá láǹfààní. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Àmọ́ Jóòbù olóòótọ́ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ṣé ìwọ náà máa jẹ́ olóòótọ́? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá ń sọ nǹkan rere nípa orúkọ rẹ̀, tá a sì ń múnú ẹ̀ dùn bá a ṣe ń sìn ín tọkàntọkàn. (Òwe 27:11) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. w24.02 8-9 ¶3-5
Friday, June 27
Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀, ẹ ó sì ṣàṣeyọrí.—2 Kíró. 20:20.
Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Mósè àti Jóṣúà, Jèhófà gbé àwọn onídàájọ́ dìde kí wọ́n lè máa tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Lásìkò táwọn ọba sì ń jẹ ní Ísírẹ́lì, Jèhófà yan àwọn wòlíì láti máa tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń ṣe ohun táwọn wòlíì yẹn bá sọ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí wòlíì Nátánì fún un. (2 Sám. 12:7, 13; 1 Kíró. 17:3, 4) Ọba Jèhóṣáfátì gbà kí wòlíì Jáhásíẹ́lì tọ́ òun sọ́nà, ó sì gba àwọn èèyàn Júdà níyànjú pé kí wọ́n “ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì” Ọlọ́run. (2 Kíró. 20:14, 15) Nígbà tí ìdààmú bá Ọba Hẹsikáyà, ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wòlíì Àìsáyà. (Àìsá. 37:1-6) Gbogbo ìgbà táwọn ọba yẹn bá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn ni Jèhófà máa ń bù kún wọn, ó sì máa ń dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn. (2 Kíró. 20:29, 30; 32:22) Torí náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà ń lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. w24.02 21 ¶8
Saturday, June 28
Ẹ má ṣe di alájọpín pẹ̀lú wọn.—Éfé. 5:7.
Sátánì fẹ́ ká máa ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó máa jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé kì í ṣe àwọn tá à ń rí lójúkojú nìkan là ń bá kẹ́gbẹ́. A tún máa ń ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn lórí ìkànnì àjọlò. A ò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn èèyàn ayé tí wọ́n gbà pé ìṣekúṣe ò burú. Ní tiwa, a mọ̀ pé ó burú jáì. (Éfé. 4:19, 20) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń yẹra fún àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé mi àtàwọn míì tí kì í pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́? Ṣé mo máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà táwọn kan bá tiẹ̀ ń bú mi, tí wọ́n sì ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́?’ Bí 2 Tímótì 2:20-22 ṣe sọ, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra tá a bá fẹ́ yan àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ. Ìdí sì ni pé àwọn kan lára wọn lè mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. w24.03 22-23 ¶11-12
Sunday, June 29
Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an.—Jém. 5:11.
Ṣé o ti ronú rí nípa bí Jèhófà ṣe rí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Jèhófà, onírúurú ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ẹ̀. Bíbélì pe Jèhófà ní “oòrùn àti apata,” ó sì tún pè é ní “iná tó ń jóni run.” (Sm. 84:11; Héb. 12:29) Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó sọ pé Jèhófà dà bí òkúta sàfáyà, ó tún sọ pé ó dà bí ohun kan tó ń dán yanran àti òṣùmàrè tó mọ́lẹ̀ yòò. (Ìsík. 1:26-28) Torí pé a ò lè rí Jèhófà, ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn kan rò pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn láé nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn. Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe mú kó ṣòro fáwọn kan láti sún mọ́ ọn. Àmọ́ torí pé ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, ó jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ dáadáa tóun ní nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ kan tá a lè fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ ni ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Jèhófà jẹ́ ìfẹ́. Ìfẹ́ ló sì fi máa ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa lágbára gan-an, kódà ó máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Mát. 5:44, 45. w24.01 26 ¶1-3
Monday, June 30
Ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ látinú ọwọ̀n ìkùukùu.—Sm. 99:7.
Jèhófà yan Mósè láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Ó máa ń fi ọwọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, ó sì ń fi ọwọ̀n iná darí wọn lálẹ́. (Ẹ́kís. 13:21) Mósè tẹ̀ lé ọwọ̀n náà, ọwọ̀n yẹn ló sì darí òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Òkun Pupa. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lé wọn bọ̀, tí wọ́n sì rí Òkun Pupa níwájú. Àmọ́, kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀. Jèhófà ló mọ̀ọ́mọ̀ lo Mósè láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ lọ síbẹ̀. (Ẹ́kís. 14:2) Torí náà, Ọlọ́run gbà wọ́n là lọ́nà ìyanu. (Ẹ́kís. 14:26-28) Odindi ogójì (40) ọdún ni Mósè fi tẹ̀ lé ọwọ̀n ìkùukùu náà, ó sì gbà pé òun ni Jèhófà ń lò láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ nínú aginjù. (Ẹ́kís. 33:7, 9, 10) Jèhófà máa ń bá Mósè sọ̀rọ̀ látinú ọwọ̀n náà, Mósè á wá lọ sọ ohun tí Jèhófà sọ fún un fáwọn èèyàn náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ṣe láti jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Mósè ni òun ń lò láti darí wọn. w24.02 21 ¶4-5