Iwọ Yoo Ha Ṣafarawe Aanu Ọlọrun Bi?
“Ẹ di alafarawe Ọlọrun, gẹgẹ bi awọn ọmọ olufẹ ọ̀wọ́n.”—EFESU 5:1, NW.
1. Eeṣe ti ṣiṣafarawe awọn ẹlomiran fi nilati jẹ aniyan gbogbo wa?
FUN rere tabi fun buburu, ọpọ julọ eniyan ṣafarawe awọn ẹlomiran. Awọn ti a wà ni ayika wọn, ti a sì lè ṣafarawe, lè nipa lori wa lọna titobi. Onkọwe onimiisi naa ti Owe 13:20 kilọ pe: “Ẹni ti o nba ọlọgbọ́n rìn yoo gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ́ awọn aṣiwere ni yoo ṣègbé.” Pẹlu ìdí rere, nigba naa, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wi pe: “Jẹ alafarawe, kii ṣe ti ohun ti o buru, bikoṣe ti ohun ti o dara. Ẹni ti o ba nṣe daradara pilẹṣẹ lọdọ Ọlọrun.”—3 Johanu 11, NW.
2. O yẹ ki awa ṣafarawe ta ni, ni awọn ọna wo sì ni?
2 Awa ní awọn apẹẹrẹ Bibeli ti awọn ọkunrin ati obinrin ti wọn tayọ ti a lè ṣafarawe. (1 Kọrinti 4:16; 11:1; Filipi 3:17) Sibẹ, ẹni ti o gba ipo iwaju julọ fun wa lati ṣafarawe ni Ọlọrun. Ni Efesu 4:31–5:2, lẹhin ṣiṣakiyesi awọn animọ ati awọn àṣà ti awa nilati yẹra fun, apọsteli Pọọlu rọ̀ wá pe ki a ‘ni ìyọ́nú onipẹlẹtu, ki a maa dariji araawa fàlàlà ẹnikinni keji.’ Eyi ṣamọna si igbani niyanju pataki naa: “Nitori naa, ẹ di alafarawe Ọlọrun, bi awọn ọmọ olufẹ ọ̀wọ́n, ẹ sì maa baa lọ ni ririn ninu ifẹ.”
3, 4. Ọlọrun pese apejuwe wo nipa ara rẹ̀, eeṣe ti a sì fi nilati gbé jijẹ ti o jẹ Ọlọrun onidaajọ ododo yẹwo?
3 Ki ni awọn ọna ati animọ Ọlọrun ti awa nilati ṣafarawe? Ọpọlọpọ awọn apa iha akopọ animọ ati iṣe ni wọn wà, gẹgẹ bi a ti lè rí i lati inu ọna ti oun gbà ṣapejuwe ara rẹ̀ fun Mose: “Oluwa [“Jehofa,” NW], Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ; ẹni ti o npa aanu mọ́ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedeedee ati irekọja ati ẹ̀ṣẹ̀ ji, ati nitootọ ti kii jẹ ki ẹlẹbi lọ laijiya; a maa bẹ ẹ̀ṣẹ̀ awọn baba wo lara awọn ọmọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ.”—Ẹkisodu 34:6, 7.
4 Niwọnbi Jehofa ti jẹ “olufẹ iwa òdodo ati idajọ ododo,” awa dajudaju nilati mọ̀ ki a sì ṣafarawe apa akopọ animọ rẹ̀ yii. (Saamu 33:5, NW; 37:28) Oun ni Ẹlẹdaa, o si jẹ Onidaajọ ati Olufunni ni ilana ofin gigajulọ fun araye pẹlu, nitori naa oun fi idajọ ododo hàn si gbogbo eniyan. (Aisaya 33:22) Eyi ni a tọka jade kedere ninu ọna ti oun gbà beere fun idajọ ododo ti o sì mu ki a tẹle e laaarin awọn eniyan rẹ̀ Israẹli ati lẹhin naa laaarin ijọ Kristian.
A Mu Idajọ Ododo Atọrunwa Ṣẹ
5, 6. Bawo ni a ṣe fi idajọ ododo hàn ninu ibalo Ọlọrun pẹlu Israẹli?
5 Nigba ti o nyan Israẹli gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ̀, Ọlọrun beere boya wọn yoo ‘ṣegbọran si ohùn rẹ̀ laiyẹhun ki wọn sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́ nitootọ.’ Ni pipejọ si apa isalẹ Oke Sinai, wọn dahun pe: “Ohun gbogbo ti Oluwa [“Jehofa,” NW] wi ni awa yoo ṣe.” (Ẹkisodu 19:3-8) Ẹ wo iru idawọle wiwuwo ti iyẹn jẹ! Nipasẹ awọn angẹli, Ọlọrun fun awọn ọmọ Israẹli ni 600 ofin, eyi ti wọn ni ẹrù-iṣẹ́ lati pamọ́, gẹgẹ bi awọn eniyan ti a yà si mimọ fun un. Ki ni bi ẹnikan ko ba ni ṣe bẹẹ? Ògbóǹtagí kan ninu Ofin Ọlọrun ṣalaye pe: “Ọ̀rọ̀ ti a tipa awọn angẹli sọ . . . fidimulẹṣinṣin . . . olukuluku irekọja ati iṣẹ́ aigbọran sì gba ẹsan ni ibamu pẹlu idajọ ododo.”—Heberu 2:2, NW.
6 Bẹẹni, ọmọ Israẹli kan ti ki yoo ṣegbọran dojukọ “ẹsan ni ibamu pẹlu idajọ ododo,” kii ṣe idajọ eniyan alaitootun, ṣugbọn idajọ ododo lati ọdọ Ẹlẹdaa wa. Ọlọrun fi oniruuru ijiya pato lelẹ fun riru ofin. Ijiya ti o wuwo julọ ni ‘ikekuro,’ tabi ìyà iku. Iyẹn kan riru ofin ti o wuwo, iru bii ibọriṣa, panṣaga, ibalopọ takọtabo laaarin ibatan ti o sunmọra, biba ẹranko dapọ, ibalopọ takọtabo laaarin ẹya kan naa, fifi ọmọ rubọ, iṣikapaniyan, ati ilokulo ẹ̀jẹ̀. (Lefitiku 17:14; 18:6-17, 21-29) Ju bẹẹ lọ, ọmọ Israẹli eyikeyii ti o ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹṣẹ si ofin Ọlọrun eyikeyii laironupiwada ni a lè “ke kuro.” (Numeri 4:15, 18; 15:30, 31) Nigba ti a ba mu iru idajọ ododo atọrunwa bẹẹ ṣẹ, awọn iyọrisi rẹ̀ ni àtìrandíran oniwa aitọ naa yoo mọlara pẹlu.
7. Ki ni diẹ lara awọn abajade fifi idajọ ododo silo laaarin awọn eniyan Ọlọrun igbaani?
7 Iru awọn ijiya bẹẹ nu ẹnu mọ́ bi riru ofin atọrunwa ti wuwo tó. Fun apẹẹrẹ, bi ọmọkunrin kan ba di ọmuti ati alajẹki, a nilati mú un wa siwaju awọn onidaajọ adagbadenu. Bi wọn ba rii pe o jẹ àmọ̀ọ́mọ̀ huwa aitọ, ti ko si ronupiwada, awọn òbí rẹ nilati ṣajọpin ninu mimu idajọ ododo ṣẹ. (Deuteronomi 21:18-21) Awọn ti wọn jẹ́ òbí ninu wa le ronu pe ko rọrun lati ṣe iyẹn. Sibẹsibẹ Ọlọrun mọ pe o pọndandan ki iwa buburu má baa tankalẹ laaarin awọn olujọsin tootọ. (Esekiẹli 33:17-19) Eyi ni a ṣeto lati ọwọ Ẹni naa nipa ẹni ti a lè wi pe: “Ẹtọ ni gbogbo ọna rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alaiṣegbe, ododo ati otitọ ni oun.”—Deuteronomi 32:4.
8. Bawo ni idajọ ododo ṣe sami si ibalo Ọlọrun pẹlu ijọ Kristian?
8 Lẹhin ọpọlọpọ ọrundun Ọlọrun ṣá orilẹ-ede Israẹli tì ó sì yan ijọ Kristian. Ṣugbọn Jehofa ko yipada. Oun ṣì wà fun idajọ ododo sibẹ a ṣì le ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “ina ti njonirun.” (Heberu 12:29; Luuku 18:7, 8) Nitori naa oun nbaa lọ lati pese fun títẹ ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun mọ́ gbogbo ijọ lọkan nipa lile awọn oniwa aitọ kuro. Awọn Kristian oluṣeyasimimọ ti wọn di oniwa aitọ alaironupiwada ni a nilati yọ lẹ́gbẹ́.
9. Ki ni iyọlẹgbẹ, ki ni o sì ṣaṣepari rẹ̀?
9 Ki ni iyọlẹgbẹ ni ninu? A ri ẹkọ arikọgbọn kan ninu ọna ti a ngba bojuto iṣoro ni ọrundun kìn-ínní. Kristian kan ni Kọrinti lọwọ ninu ìwà pálapàla pẹlu aya baba rẹ̀ kò sì ronupiwada, nitori naa Pọọlu funni ni itọni pe ki a lé e kuro ninu ijọ. Eyi ni a nilati ṣe lati daabobo ijẹmimọ awọn eniyan Ọlọrun, nitori “ìwúkàrà diẹ ni nmu gbogbo iyẹfun di wíwú.” Lílé e kuro yoo ṣediwọ fun iwa buburu rẹ̀ lati maa tabuku si Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ̀. Ibawi mimuna naa ti didi ẹni ti a yọ lẹgbẹ lè pe orí rẹ̀ wálé ki o sì tẹ ibẹru yiyẹ fun Ọlọrun mọ́ oun ati ijọ lọkan.—1 Kọrinti 5:1-13; fiwe Deuteronomi 17:2, 12, 13.
10. Bawo ni awọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe nilati dahunpada bi a ba yọ ẹnikan lẹgbẹ?
10 Àṣẹ atọrunwa ni pe bi a ba lé ẹni buburu kan kuro, awọn Kristian gbọdọ jawọ ‘kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹlu rẹ̀ . . . ki wọn ma tilẹ ba iru eniyan bẹẹ jẹun.’a Oun ni a tipa bayii ke kuro ninu ibakẹgbẹpọ ati ajọṣe ẹgbẹ oun ọgba, pẹlu awọn aduroṣinṣin ti wọn bọwọ ti wọn sì fẹ́ lati rìn ni ibamu pẹlu ofin Ọlọrun. Diẹ ninu wọn lè jẹ́ ibatan ti kii ṣe apakan idile tiwa gan-an, ti a ko jọ wa ninu agbo ile kan naa. O lè ṣoro fun awọn ibatan wọnni lati fi itọni atọrunwa yii silo, ani gẹgẹ bi ko ti ṣe rọrun fun awọn òbí Heberu labẹ Ofin Mose lati ṣajọpin ninu pipa ọmọkunrin buburu kan. Sibẹ, aṣẹ Ọlọrun ṣe kedere; nipa bayii a le ni idaniloju pe iyọlẹgbẹ ba idajọ ododo mu.—1 Kọrinti 5:1, 6-8, 11; Titu 3:10, 11; 2 Johanu 9-11; wo Ilé-ìṣọ́nà, January 15, 1982, oju-iwe 26-31; April 15, 1988, oju-iwe 28-31.
11. Bawo ni oniruuru apa iha akopọ animọ Ọlọrun ṣe le di hihan kedere ni isopọ pẹlu iyọlẹgbẹ?
11 Bi o ti wu ki o ri, ranti pe, Ọlọrun wa ko wulẹ jẹ onidaajọ ododo nikan; oun tun jẹ ‘ẹni ti o pọ̀ ni aanu, ti ndari ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣedeedee jì.’ (Numeri 14:18) Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú un ṣe kedere pe ẹni kan ti a yọ lẹgbẹ le ronupiwada, ni wiwa idariji atọrunwa. Lẹhin naa ki ni? Awọn alaboojuto oniriiri lè pade pọ̀ pẹlu rẹ̀ lati pinnu taduratadura ati tiṣọratiṣọra boya oun fi àmì jijẹ onironupiwada hàn lori ìṣe buburu ti o ṣamọna si yiyọ ti a yọ ọ́ lẹgbẹ. (Fiwe Iṣe 26:20.) Bi o ba ri bẹẹ, a lè gbà á pada sinu ijọ, gẹgẹ bi 2 Kọrinti 2:6-11 ti fihan pe o ṣẹlẹ si ọkunrin naa ni Kọrinti. Sibẹ, diẹ lara awọn ti a lé kuro ti fi ijọ Ọlọrun silẹ fun ọpọlọpọ ọdun, nitori naa ohunkohun ha wà ti a lè ṣe lati ran wọn lọwọ lati rí ọna bá pada bi?
Idajọ Ododo Ni A Mu Ṣe Deedee Pẹlu Aanu
12, 13. Eeṣe ti ṣiṣafarawe Ọlọrun wa fi nilati ni ninu ju fifi idajọ ododo rẹ̀ han?
12 Awọn ohun ti a mẹnukan ṣaaju ti jiroro ni pataki apa iha kanṣoṣo ti awọn animọ Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti mẹnukan an ni Ẹkisodu 34:6, 7. Bi o ti wu ki o ri, awọn ẹsẹ wọnni ṣetolẹsẹẹsẹ pupọ sii ju idajọ ododo Ọlọrun, awọn wọnni ti wọn sì fẹ lati ṣafarawe rẹ̀ kò kórí afiyesi jọ kiki sori fifi ipa mu idajọ ododo ṣẹ. Bi iwọ ba nṣe awoṣe iru tẹmpili ti Solomoni kọ́, iwọ yoo ha kẹkọọ kiki ọkan ninu awọn ọwọ̀n rẹ̀ bi? (1 Ọba 7:15-22) Bẹẹkọ, nitori èkukáká ni iyẹn yoo fi fun ọ ni aworan ti o wa deedee nipa irisi ati ipa ti tẹmpili naa ńkó. Lọna ti o farajọra, bi awa ba fẹ lati ṣafarawe Ọlọrun, awa tun nilati ṣafarawe awọn ọna ati animọ rẹ̀ miiran, iru bii jijẹ “alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ; ẹni ti o npa aanu mọ́ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedeedee jì.”
13 Aanu ati idariji jẹ ipilẹṣẹ awọn animọ Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti rii ni ọna ti oun gbà ba Israẹli lò. Ọlọrun idajọ ododo ko da wọn si kuro ninu ijiya fun aṣiṣe ti wọn nṣe leralera, sibẹ oun fi aanu ati idariji ti o pọ̀ tó hàn. “O fi ọna rẹ̀ hàn fun Mose, iṣẹ rẹ̀ fun awọn ọmọ Israẹli. Oluwa [“Jehofa,” NW] ni alaaanu ati oloore, o lọ́ra lati binu, o sì pọ̀ ni aanu. Oun kii baniwi nigba gbogbo: bẹẹ ni kii pa ibinu rẹ̀ mọ́ laelae.” (Saamu 103:7-9; 106:43-46) Bẹẹni, wiwẹhin pada wo awọn ibalo rẹ̀ la awọn ọgọrun-un ọdun kọja mu awọn ọrọ wọnni jasi otitọ.—Saamu 86:15; 145:8, 9; Mika 7:18, 19.
14. Bawo ni Jesu ṣe fihan pe oun ṣafarawe aanu Ọlọrun?
14 Niwọn igba ti Jesu Kristi ti jẹ “itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan oun tikaraarẹ,” awa nilati reti pe ki oun lọna kan naa fi aanu ati imuratan lati dariji han. (Heberu 1:3) Oun ṣe bẹẹ, gẹgẹ bi ìwà rẹ̀ si awọn ẹlomiran ti fihan. (Matiu 20:30-34) Oun tun tẹnumọ aanu nipa awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a kà ninu Luuku ori 15. Awọn akawe mẹta nibẹ fihan pe Jesu ṣafarawe Jehofa, wọn sì pese awọn ẹkọ pataki fun wa.
Aniyan fun Ohun Ti O Ti Sọnu
15, 16. Ki ni o sun Jesu lati funni ni awọn akawe ti o wà ninu Luuku 15?
15 Awọn akawe wọnni jẹrii si ifẹ alaaanu tí Ọlọrun ní ninu awọn ẹlẹṣẹ, ni yiya aworan ti o ṣọkandelẹ fun wa lati ṣafarawe. Ronu lori ọna igbekalẹ awọn akawe naa: “Awọn agbowoode [“agbowo ori,” NW] ati awọn ẹlẹṣẹ sì sunmọ ọn lati gbọ ọrọ rẹ̀. Ati awọn Farisi ati awọn akọwe ńkùn, wi pe, ọkunrin yii ńgba ẹlẹṣẹ, o sì nba wọn jẹun.”—Luuku 15:1, 2.
16 Gbogbo awọn eniyan tí ọran kàn jẹ awọn Juu. Awọn Farisi ati awọn akọwe ofin ni itẹlọrun pẹlu araawọn lori ohun ti wọn rò pe o jẹ rírọ̀ timọtimọ mọ́ Òfin Mose, ti o jẹ iru iwa ododo ti ofin kan. Bi o ti wu ki o ri, Ọlọrun ko fohunṣọkan pẹlu iru ipokiki òdodo ara ẹni bẹẹ. (Luuku 16:15) Lọna ti o han gbangba, awọn agbowo ori ti a mẹnukan jẹ awọn Juu ti wọn ngba owo ori fun Roomu. Nitori ọpọlọpọ fi agbara gba iye ti o pọ̀ jù lọwọ awọn Juu ẹlẹgbẹ wọn, awọn agbowo ori jẹ awujọ ti a kẹgan. (Luuku 19:2, 8) A kà wọn mọ́ “awọn ẹlẹṣẹ,” ti o ni awọn eniyan oniwa palapala takọtabo ninu, ani awọn aṣẹ́wó paapaa. (Luuku 5:27-32; Matiu 21:32) Ṣugbọn Jesu beere lọwọ awọn aṣiwaju isin ti nṣaroye pe:
17. Ki ni akawe Jesu akọkọ ninu Luuku 15?
17 “Ọkunrin wo ninu yin, ti o ni ọgọrun-un agutan, bi o ba sọ ọkan nù ninu wọn, ti ki yoo fi mọkandinlọgọrun-un yooku silẹ ni iju, ti ki yoo sì tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yoo fi ri i? Nigba ti o sì ri i tán, o gbé e le ejika rẹ̀, o ńyọ̀. Nigba ti o sì de ile, o pe awọn ọrẹ ati aladuugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, ẹ ba mi yọ̀; nitori ti mo ri agutan mi ti o ti nù. Mo wi fun yin, gẹgẹ bẹẹ ni ayọ̀ yoo wà ni ọ̀run lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, ju lori oloootọ mọkandinlọgọrun-un lọ, ti ko ṣe aini ironupiwada.” Awọn aṣiwaju isin le loye aworan naa ti o gbeyọ sọkan, nitori awọn agutan ati awọn oluṣọ agutan jẹ ohun ti wọn nri lọpọ igba. Nitori aniyan, oluṣọ agutan naa fi agutan mọkandinlọgọrun-un silẹ lati jẹko ninu papa ti o mọ̀ daradara nigba ti oun nwa eyi ti o nù kiri. Ni titẹramọ ọn titi yoo fi ri i, o gbe agutan ti a ti dayafo naa ni jẹlẹnkẹ pada sinu agbo.—Luuku 15:4-7.
18. Gẹgẹ bi a ti tẹnumọ ọn ninu akawe keji ninu Luuku 15, ki ni o rú ayọ̀ jade?
18 Jesu fi akawe keji kún un: “Tabi obinrin wo ni o ni fadaka [“owo ẹyọ drachma,” NW] mẹwaa, bi o ba sọ ọkan nù, ti ki yoo tan fitila, ki o sì gbá ile, ki o sì wá a gidigidi titi yoo fi ri i? Nigba ti o sì ri i, o pe awọn ọrẹ ati aladuugbo rẹ̀ jọ, o wi pe, ẹ ba mi yọ; nitori mo ri fadaka [“owo ẹyọ drachma,” NW] ti mo ti sọnu. Mo wi fun yin, gẹgẹ bẹẹ ni ayọ nbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada. (Luuku 15:8-10) Gbogbo drachma naa fẹrẹẹ to owo ọ̀yà ojumọ fun lébìrà kan. Owo ẹyọ obinrin naa ti lè jẹ ajogunba kan, tabi o lè jẹ́ apakan ọgọọrọ ti a fi ṣe ohun ọ̀ṣọ́. Nigba ti o sọnu, o ṣe iwakiri kinnikinni lati ri owo ẹyọ naa, lẹhin naa oun ati awọn obinrin ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì yọ̀. Ki ni eyi sọ fun wa nipa Ọlọrun?
Yiyọ Ni Ọrun—Lori Ki Ni?
19, 20. Awọn akawe meji akọkọ Jesu ninu Luuku 15 jẹ nipa ta ni ni ipilẹṣẹ, ki sì ni koko pataki ti wọn sọ?
19 Awọn akawe meji wọnyi jẹ idahunpada si ofintoto ti a ṣe si Jesu, ẹni ti o fi ara rẹ̀ hàn niwọnba oṣu diẹ ṣaaju gẹgẹ bi “oluṣọ agutan rere” ti yoo fi ẹ̀mí rẹ̀ fun awọn agutan rẹ̀. (Johanu 10:11-15) Laika eyiini si, awọn akawe naa ni ipilẹṣẹ ko niiṣe pẹlu Jesu. Ẹkọ ti awọn akọwe ofin ati Farisi nilati kọ́ kó afiyesi jọ sori ẹmi-ironu ati awọn ọ̀nà Ọlọrun. Nipa bayii, Jesu sọ pe ayọ̀ wà ni ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada. Awọn onisin wọnni sọ pe awọn nsin Jehofa, sibẹ wọn kii ṣe afarawe rẹ̀. Ni idakeji ẹ̀wẹ̀, awọn ọna alaaanu ti Jesu duro fun ifẹ inu Baba rẹ̀.—Luuku 18:10-14; Johanu 8:28, 29; 12:47-50; 14:7-11.
20 Bi ọkan ninu ọgọrun-un ba jẹ ipilẹ fun ayọ̀, owo ẹyọ kan ninu mẹwaa jẹ ayọ̀ ju bẹẹ lọ. Ani lonii paapaa awa le mòye imọlara awọn obinrin ti wọn nyọ lori riri owo-ẹyọ naa! Nihin-in, pẹlu, ẹkọ naa kori jọ si ọrun, niti pe “awọn angẹli Ọlọrun” yọ pẹlu Jehofa “lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.” Ṣakiyesi ọ̀rọ̀ ti o kẹhin yẹn “ronupiwada.” Awọn akawe wọnyi jẹ nipa awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada niti gidi. Iwọ sì lè ri pe mejeeji tẹnumọ yiyẹ ti o yẹ lati yọ ayọ̀ lori ironupiwada wọn.
21. Ẹkọ wo ni a nilati kọ́ lati inu awọn akawe Jesu ni Luuku 15?
21 Awọn aṣaaju isin ti a ti ṣìlọ́nà wọnni ti wọn ni imọlara itẹlọrun lori iṣegbọran oréfèé si Òfin gbojufo jijẹ ti Ọlọrun jẹ “alaaanu ati oloore ọfẹ, . . . ti ndari aiṣedeedee ati irekọja ati ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Ẹkisodu 34:6, 7) Bi wọn ba ti nṣafarawe apa iha awọn ọna ati animọ Ọlọrun yii ni, wọn iba ti mọriri aanu Jesu si awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada. Bawo ni o ti ri nipa wa? Awa ha ngba ẹkọ naa sinu ọkan-aya wa ti a sì nfi silo bi? O dara, ṣakiyesi akawe kẹta ti Jesu.
Ironupiwada ati Aanu lẹnu Iṣẹ
22. Ni ṣoki, ki ni Jesu funni gẹgẹ bi akawe kẹta ninu Luuku 15?
22 Eyi ni a saba maa ńpè ni akawe ọmọ onínàákúnàá. Sibẹ, ni kika a iwọ yoo ri idi ti a fi ronu rẹ̀ gẹgẹ bi akawe ifẹ ti baba. O sọ nipa ọdọmọde kan ninu idile kan, ti o gba ogún tirẹ lọwọ baba rẹ̀. (Fiwe Deuteronomi 21:17.) Ọmọkunrin yii fi ile silẹ lọ si ilẹ jijinna réré, nibi ti o ti na gbogbo rẹ̀ ni ìná wọ̀bìà, o nilati gba iṣẹ ṣíṣọ́ agbo ẹlẹ́dẹ̀, a tilẹ fipa mú un lati di arébipa fun ounjẹ awọn ẹlẹ́dẹ̀. Òye rẹ̀ pada wa nikẹhin o sì pinnu lati pada wa sile, ani bi o ba tilẹ jẹ́ kiki lati maa ṣiṣẹ fun baba rẹ̀ gẹgẹ bi lébìrà ti a nsanwo fun. Bi o ti sunmọ ile, baba rẹ̀ gbe igbesẹ ọlọkan rere lati ki i kaabọ, ani o tilẹ se àsè kan. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ti o ti duro ni ile fi ibinu hàn si aanu ti a fihan. Ṣugbọn baba rẹ̀ wi pe wọn nilati yọ̀ nitori ọmọkunrin ti o ti ku ti walaaye nisinsinyi.—Luuku 15:11-32.
23. Ki ni a nilati kẹkọọ rẹ̀ lati inu akawe ọmọ onínàákúnàá?
23 Awọn akọwe ofin ati awọn Farisi diẹ le ti ni imọlara pe a fi awọn wé ẹ̀gbọ́n, ni iyatọ si awọn ẹlẹṣẹ ti wọn dabi aburo. Bi o ti wu ki o ri, njẹ wọn ha ri koko pataki akawe naa dìmú bí, awa nkọ? O tẹnumọ animọ titayọ ti Baba wa alaaanu ni ọrun, imuratan rẹ̀ lati dariji lori ipilẹ ironupiwada ati iyikanpada atinuwa ẹlẹṣẹ kan. O ti nilati sun awọn olugbọ lati dahunpada pẹlu ayọ si itunrapada awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada. Bẹẹ yẹn ni Ọlọrun ṣe nwo awọn ọran ati bi o ṣe nhuwa, awọn wọnni ti wọn sì nṣafarawe rẹ̀ gbọdọ ṣe bakan naa.—Aisaya 1:16, 17; 55:6, 7.
24, 25. Awọn ọna Ọlọrun wo ni a nilati maa wa ọna lati ṣafarawe?
24 Ni kedere, idajọ ododo sami si gbogbo awọn ọna Ọlọrun, nitori naa awọn wọnni ti wọn fẹ lati ṣafarawe Jehofa ṣìkẹ́ wọn sì lepa idajọ ododo. Sibẹ, Ọlọrun wa ni a kò sún ṣiṣẹ nipasẹ idajọ ododo ero ọkan lasan tabi eyi ti o lekoko. Aanu ati ifẹ rẹ̀ tobi. Oun fi eyi hàn nipa mimuratan lati gbe idariji ka ori ojulowo ironupiwada. O ba a mu, nigba naa, pe Pọọlu so jijẹ oludarijini wa pọ̀ mọ́ ṣiṣe afarawe Ọlọrun wa: “Ẹ maa dariji araayin fàlàlà gẹgẹ bi Ọlọrun pẹlu nipasẹ Kristi ti dariji yin fàlàlà. Nitori naa, ẹ di alafarawe Ọlọrun, bi awọn ọmọ olufẹ ọ̀wọ́n, ẹ sì maa baa lọ ni ririn ninu ifẹ.”—Efesu 4:32–5:2, NW.
25 Tipẹtipẹ ni awọn Kristian tootọ ti gbiyanju lati ṣafarawe idajọ ododo Jehofa pẹlu aanu ati imuratan rẹ̀ lati darijini. Bi a ba ṣe mọ̀ ọ́n si bẹẹ ni yoo ṣe rọrun ju fun wa si lati ṣafarawe rẹ̀ ninu awọn ọna wọnyi. Bawo, nigba naa, ni awa ṣe lè fi eyi silo fun ẹni kan ti o ti gba ibawi mimuna lọna ti o ba idajọ ododo mu nitori pe o lepa ọna ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ jẹ ki a wò ó.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Iyọkurolẹgbẹ ni itumọ rẹ̀ gbigbooro julọ jẹ́ igbesẹ àmọ̀ọ́mọ̀ gbé ninu eyi ti awujọ kan fi anfaani ipo mẹmba rẹ̀ du awọn wọnni ti wọn jẹ mẹmba ti wọn ni iduro rere ni igba kan rí. . . . Iyọkurolẹgbẹ ni sanmanni Kristian wá tọka si ìṣe iyọnikuro nipa eyi ti awujọ ẹgbẹ onisin kan fi sakaramẹnti, ijọsin ninu ijọ, ati boya ajọṣepọ ẹgbẹ oun ọgba eyikeyii du awọn arufin.”—The International Standard Bible Encyclopedia.
Ki Ni O Ti Kẹkọọ Rẹ̀?
◻ Bawo ni a ṣe fi idajọ ododo Ọlọrun hàn kedere ninu ijọ Israẹli ati ninu ijọ Kristian?
◻ Eeṣe ti a fi nilati ṣafarawe aanu Ọlọrun, ni afikun si idajọ ododo rẹ̀?
◻ Ki ni o gbe awọn akawe mẹta ninu Luuku ori 15 dide, awọn ẹkọ wo sì ni o yẹ ki wọn fi kọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Pẹtẹlẹ er-Raha niwaju Oke Sinai (aworan ipilẹ apa òsì)
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Garo Nalbandian
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Garo Nalbandian