Laipẹ Ko ni Si Aisan Tabi Iku mọ!
KO SI ẹni ti ngbadun ṣiṣaisan, bẹẹ ni awọn eniyan ko fẹ lati ku. Ọjọgbọn kan ninu ihuwasi ẹgbẹ-oun-ọgba nipa iṣegun fi itẹnumọ polongo pe: “Iwakiri fun iwalaaye gigun sii dabi ẹni pe o jẹ́ kari aye jalẹjalẹ itan ati ninu ọpọjulọ awọn awujọ. O tan mọ́ òòfà ṣiṣekoko fun pipa ara ẹni mọ laaye . . . Ponce de Leon nikan ṣoṣo ni ó lokiki julọ lara ila gigun awọn eniyan ti wọn lo igbesi-aye wọn ni wiwa ẹmi gigun sii. Ọpọjulọ lara imọ ijinlẹ iṣegun ni o doju kọ pipa ẹmi gigun mọ nipa biba arun ati iku jagun.”
Iku ṣẹ̀ sí o si mu irora wa fun iru ẹda ti a jẹ ninu tó bẹ́ẹ̀ ti o fi jẹ pe nigba ti o ba pa awọn ọrẹ ati mẹmba idile, a maa nfẹrẹẹ gbiyanju lati mu ipa ti o ni lori wa fuyẹ lọna adanida. Iwe naa Funeral Customs the World Over ṣakiyesi pe: “Ko si awujọ kankan, bi o ti wu ki o jẹ alailaju tó ni ipẹkun kan tabi ọ̀làjú tó ni ipẹkun miiran, ti a fi silẹ funraarẹ lominira ati ni ibi ti agbara rẹ ká a dé ti ki yoo palẹ oku awọn mẹmba rẹ mọ pẹlu ayẹyẹ. . . . O tẹ́ òòfà jijinlẹ ti o kari aye lọ́rùn. Lati ṣe é dabi ohun ti o ‘tọ́,’ ati lati ma ṣe é ni pataki fun awọn wọnni ti wọn so mọra pẹkipẹki nipasẹ idile, imọlara, ajọgbe, iriri kan naa tabi awọn isopọ miiran, jọ bi ‘aláìtọ́,’ ìfòdá ti ko bá iwa ẹda mu, ọran kan lati tọrọ aforiji fun tabi lati tiju fun. . . . [Eniyan] jẹ olùwà kan ti nsin oku rẹ pẹlu ayẹyẹ.”
Orisun Aisan ati Iku
Ero naa pe aisan ati iku ni a o mu kuro ni ọjọ kan tipa bayii ni ifanimọra alagbara, ṣugbọn ipilẹ kan ha wà fun iru igbagbọ bẹẹ bi? Nitootọ o wà, o ba ọgbọn mu, o si ṣee fọkantẹ, ko si le ni aṣiṣe ninu. O jẹ Ọrọ Ẹlẹdaa wa ti a mí sí—Bibeli Mimọ.
Iwe yẹn ṣalaye orisun ibanujẹ eniyan ni kedere. O sọ fun wa pe eniyan akọkọ, Adamu, ni a dá lati ọwọ Ọlọrun ti a si fi sinu ibugbe ọgba paradise kan ti o wà nibikan ni Aarin Ila-oorun. Adamu ni a dá ni pipe; aisan ati iku ni oun kò mọ. Oun ni aya pipe lọna ti ó dọ́gba kan dara pọ mọ́ laipẹ, wọn si gbadun ireti iye ayeraye lori ilẹ-aye papọ.—Jẹnẹsisi 2:15-17, 21-24.
Ipo alayọ yii ni ko tọ́jọ́. Eeṣe? Nitori pe Adamu fi imọtara ẹni nikan yan ọna iwalaaye kan ti o wa lominira si Ọlọrun. Ó yọrisi iṣẹ́ aṣekara, irora, aisan, ati lẹhin-ọ-rẹhin iku. (Jẹnẹsisi 3:17-19) Iran ọmọ rẹ̀ jogun iru igbesi aye ailayọ naa ti Adamu ti yàn. Roomu 5:12 ṣalaye pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti ti ipa ọdọ eniyan kan wọ aye, ati iku nipa ẹṣe; bẹẹ ni iku si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.” Roomu 8:22 fikun un pe: “Awa mọ pe gbogbo ẹda ni o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ titi di isinsinyi.”
Lori Ilẹ-aye Tabi ni Ọrun?
Bi o ti wu ki o ri, Bibeli mu un dá wa loju pe Ọlọrun yoo mu araye onigbọran pada bọ si ipo alayọ ti Adamu ati Efa sọnu. Iṣipaya 21:3, 4 wi pe: “Ọlọrun tikaararẹ yoo wà pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.” Wolii igbaani kan lọna ti o fara jọra ri akoko naa nigba ti “awọn ara ibẹ ki yoo wi pe, ootu npa mi [“ara mi kò dá,” New World Translation].”—Aisaya 33:24.
Njẹ iwọ le woye aye kan laisi awọn ile iwosan, ilé-ìgbókùú si ati iboji? Njẹ iwọ le woye wiwalaaye titi lọ gbére, lominira kuro lọwọ ihalẹ mọni ijiya ati iku paapaa? Bẹẹni, ileri Ọlọrun wọ gbogbo wa lọkan ṣinṣin. Sibẹ, bawo ni a ṣe le ní idaniloju pe ifojusọna agbayanu yii wà fun planẹti Ilẹ-aye wa—kii ṣe fun ọrun? Ṣakiyesi ọrọ ti o yi awọn ẹsẹ Iwe mimọ ti a mẹnukan ṣaaju ká. Awọn ẹsẹ akọkọ Iṣipaya ori 21 sọrọ nipa “ọrun titun kan ati aye titun kan.” Gbolohun ọrọ kedere naa ni a sọ pe Ọlọrun yoo wà pẹlu araye ati pe wọn yoo jẹ́ eniyan rẹ. Ileri naa ninu iwe Aisaya pe ko ni si ẹni kan ti ara rẹ ko ni dá ni itọka si “awọn eniyan ti ngbe ibẹ” ti a ti ‘dari aiṣedeedee wọn jì’ tẹle.
Nitori naa awọn ileri afunni niṣiiri wọnyi tọka si iwalaaye lori ilẹ-aye! Wọn si wà ni ibamu pẹlu adura Jesu si Baba rẹ pe: “Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹẹ ni ní aye.”—Matiu 6:10.
Eeṣe Ti O Fi Jẹ Laipẹ?
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ran araadọta ọkẹ lọwọ lati wá mọ pe awọn ileri wọnyi ni a o mu ṣẹ ni ọjọ ọla ti o sunmọle. Bi o ti wu ki o ri, lori ipilẹ wo ni wọn gba nimọlara didaju háún-háún nipa eyi? Lori ipilẹ ẹri pupọ jaburata pe a ńgbé ninu “ikẹhin ọjọ” eto igbekalẹ isinsinyi, tabi iṣeto, awọn nǹkan lori ilẹ-aye. (2 Timoti 3:1-5) Awọn ọmọ-ẹhin Jesu beere fun ami nipa igba ti opin eto igbekalẹ awọn nǹkan yoo jẹ́. Ni idahun pada Jesu sọtẹlẹ ṣaaju ni kulẹkulẹ awọn iṣẹlẹ aye ti npeleke sii ti o ti ṣẹlẹ lati igba ibẹsilẹ Ogun Agbaye Kìn-ínní ni 1914.a Lẹhin naa o fi kun un pe: “Nigba ti ẹyin ba ri gbogbo nǹkan wọnyi, ki ẹ mọ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lootọ ni mo wi fun yin, iran yii ki yoo rekọja, titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ.” Nitori naa diẹ lara iran ti o walaaye ni 1914 yoo walaaye lati ri opin eto igbekalẹ aye isinsinyi.—Matiu 24:33, 34.
Ni akoko naa Jehofa Ọlọrun yoo fun Ọmọkunrin rẹ, Jesu Kristi, laṣẹ lati jade lọ ki o si pa gbogbo awọn okunfa ijiya ati ibanujẹ run kuro loju planẹti Ilẹ-aye ẹlẹwa yii. Bibeli sọrọ nipa imukuro iwa buburu gẹgẹ bi “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ni Amagẹdọn.—Iṣipaya 16:14, 16.
Iye pupọ jaburata awọn eniyan olubẹru Ọlọrun yoo la ìṣẹ̀lẹ̀ bibani lẹru yii já wọn yoo si walaaye lati ri ibẹrẹ Ijọba alalaafia ti Kristi Jesu. (Iṣipaya 7:9, 14; 20:4) Bi o tilẹ jẹ pe iṣakoso rẹ yoo jẹ lati ọrun, awọn iyọrisi alanfaani rẹ ni gbogbo awọn wọnni ti ngbe ori ilẹ-aye yoo gbadun—ati awọn olula ogun Amagẹdọn já ati araadọta ọkẹ lori araadọta ọkẹ ti a o ji dide kuro ninu oku lẹhin naa. Ileri naa yoo wa di otitọ nigba naa: “Oun ko le ṣai ma jọba titi yoo fi fi gbogbo awọn ọta rẹ sabẹ ẹsẹ rẹ. Iku ni ọta ikẹhin ti a o parun.”—1 Kọrinti 15:25, 26.
A le tipa bayi fi igbọkanle kigbe soke pe: “Laipẹ ko ni si aisan tabi iku mọ!” Eyi kii ṣe ireti ti ko ṣeeṣe bẹẹ ni kii ṣe igbagbọ ninu ohun ti ẹnikan fẹ ki o ṣẹlẹ. O jẹ ileri ti o daju ti Jehofa Ọlorun, “ẹni ti ko le ṣeke.” Iwọ yoo ha fi igbẹkẹle rẹ sinu ireti yii bi? O le ṣe ọ lanfaani titilae!—Titu 1:2.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun ẹri siwaju sii pe araye ngbe ni awọn ọjọ ikẹhin, wo ori 18 iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ti a tẹ̀ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Aisan ati iku ni a o fi ilera ara yíyá gágá ati iye ainipẹkun rọpo laipẹ