“Iwọ Yoo Wà Pẹlu Mi ni Paradise”
BI Ó ti ńrọ̀ dirodiro lori opo igi ifiya iku jẹni, tí ó ńkú lọ ninu irora, ọdaran naa bẹ ọkunrin ti o wà ni ẹgbẹ rẹ̀ pe: “Jesu, ranti mi nigba ti o ba dé ijọba rẹ.” Jesu, bi o tilẹ jẹ pe oun pẹlu nku lọ ninu irora ti o burujai, fesi pe: “Lootọ ni mo sọ fun ọ lonii, Iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise.” (Luuku 23:42, 43, NW) Iru ireti atunininu wo ni eyi jẹ fun ọkunrin ti nku lọ kan!
Bi o ti wu ki o ri, njẹ iwọ ṣakiyesi pe New World Translation—ẹda itumọ ti a fa ọrọ rẹ̀ yọ ninu ipinrọ akọkọ yii—fi ami iwe kíkọ sẹhin ọrọ naa “lonii” nigba ti o ntumọ awọn ọrọ Jesu wọnyi? Eyi gbe ero naa yọ pe ani ni ọjọ iku oun tikaraarẹ paapaa, Jesu le ṣeleri iye ninu Paradise fun ọdaran yẹn. Ni ọwọ keji ẹwẹ, The New English Bible pin awọn ọrọ Jesu ni ọna yii: “Mo sọ eyi fun ọ: lonii iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise.” Ọpọjulọ awọn itumọ miiran fohùnṣọ̀kan pẹlu The New English Bible, ni gbigbe ero naa yọ pe Jesu ati ọdaran ti nku lọ naa nlọ si Paradise ni ọjọ yẹn gan an. Eeṣe ti iyatọ fi wa? Ami iwe kíkọ wo ni o sì tọna?
Nitootọ, ko si ami iwe kikọ kankan ninu awọn iwe afọwọkọ Bibeli ijimiji julọ lede Giriiki. Fun idi yii, nigba ti a mu ami ikọwe wọle, awọn aṣàdàkọ ati olutumọ Bibeli nilati fi sii ni ibamu pẹlu oye wọn nipa otitọ Bibeli. Nigba naa, ọna itumọ atọwọdọwọ naa ha tọna bi? Njẹ Jesu ati oluṣe buburu naa ha lọ si Paradise ni ọjọ ti wọn ku naa bi?
Bẹẹkọ, gẹgẹ bi Bibeli ti wi, wọn lọ si ibi ti a npe ni Haʹdes ni ede Giriiki ati Sheʹol ni ede Heberu, ti mejeeji tọka si isà oku araye ni gbogbogboo. (Luuku 18:31-33; 24:46; Iṣe 2:31) Nipa awọn wọnni ti wọn wà ni ibẹ, Bibeli wi pe: “Awọn oku ko mọ ohun kan . . . Ko si ete, bẹẹ ni ko si imọ, tabi ọgbọn, ni ipo oku [Giriiki, Haʹdes] nibi ti iwọ nre.” Kii ṣe paradise niti gidi!—Oniwaasu 9:5, 10.
A kò ji Jesu dide kuro ninu Hades titi di ọjọ kẹta. Nigba naa, laaarin akoko ohun ti o fẹrẹẹ to ọsẹ mẹfa ó ṣe ọpọlọpọ ifarahan fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni ayika ilẹ Palestine. Ni ọkan lara awọn akoko wọnni, Jesu sọ fun Maria pe: “Emi ko tii goke lọ sọdọ Baba mi.” (Johanu 20:17) Nitori naa, ani nigba naa oun ko tii de ibi kankan ti a le pe ni paradise.—Iṣipaya 2:7
Ni ọrundun kẹta C.E.—nigba ti pipa ẹkọ Kristẹni pọ pẹlu àbá ero ori Giriiki nṣẹlẹ lọna ìyára kánkán—Origen fa ọrọ Jesu yọ bi ẹni ti nwi pe: “Lonii iwọ yoo wà pẹlu mi ninu Paradise ti Ọlọrun.” Ni ọrundun kẹrin C.E., awọn onkọwe ṣọọṣi jiyan lodi si fifi ami iwe kikọ kan sẹhin “lonii.” Eyi fihan pe ọna itumọ atọwọdọwọ ti kika awọn ọrọ Jesu ní itan onigba gigun kan. Ṣugbọn o tun fihan pe ani ni ọgọrun un ọdun kẹrin C.E. paapaa, awọn ọrọ Jesu ní awọn kan kà ni ibamu pẹlu ọna ti a gbà tumọ rẹ̀ ninu New World Translation.
Lonii pẹlu, bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ atumọ ede fi ami gbolohun sí Luuku 23:43 ni ibamu pẹlu itumọ atọwọdọwọ ṣọọṣi, awọn diẹ fi ami sii bii ti New World Translation. Fun apẹẹrẹ, ninu itumọ ede German lati ọwọ Ọjọgbọn Wilhelm Michaelis awọn ọrọ Jesu kà pe: “Lootọ, mo fun ọ ni idaniloju yii ani lonii: iwọ yoo wà pẹlu mi (ni ọjọ kan) ninu Paradise.”
Nigba naa, ki ni awọn ọrọ Jesu tumọsi fun oluṣe buburu naa? Oun ti le gbọ ipolongo naa pe Jesu ni Ọba ti a ṣeleri naa. Ko si iyemeji, oun mọ nipa orukọ oye naa “Ọba awọn Juu” ti Pilatu ti kọ ti o si gbé kọ́ soke ori Jesu. (Luuku 23:35-38) Bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣaaju isin fi orikunkun ṣá Jesu tì, ọdaran aronupiwada yii fi igbagbọ rẹ̀ han, ni wiwi pe: “Jesu, ranti mi nigba ti o ba de ijọba rẹ.” Oun ko reti lati ṣakoso pẹlu Jesu, ṣugbọn ó fẹ janfaani lati inu iṣakoso Jesu. Fun idi yii, Jesu, ani ni ọjọ ti o ṣoro julọ yẹn ṣeleri pe oluṣebuburu naa yoo wà pẹlu oun ni Paradise.
Ninu paradise wo? Ninu Bibeli, Paradise ipilẹṣẹ ni ọgba Edẹni ti o dabi ọgba itura tí awọn obi wa akọkọ padanu. Bibeli ṣeleri pe Paradise ilẹ-aye yẹn ni a o mupada bọsipo labẹ Ijọba Ọlọrun, eyi ti Jesu jẹ Ọba fun. (Saamu 37:9-11; Mika 4:3, 4) Fun idi yii, Jesu yoo wà pẹlu oluṣebuburu yẹn ati aimọye awọn miiran ti wọn ti kú nigba ti o ba ji wọn dide lati inu isa oku si iye lori paradise ilẹ-aye kan ati si anfaani kikẹkọọ lati ṣe ifẹ inu Ọlọrun ki wọn si walaaye titilae.—Johanu 5:28, 29; Iṣipaya 20:11-13; 21:3, 4.