Pipejọ Pẹlu Awọn Olùfẹ́ Ominira Ti Ọlọrun Fifunni
AWỌN ẸLẸ́RÌÍ Jehofa dáyàtọ̀ ni ọpọlọpọ ọna gidi gan-an. Awọn nikan ni wọn ń sọ “èdè mimọgaara.” (Sefanaya 3:9, NW) Awọn nikan ni wọn sopọṣọkan, ni wọn ni ami ìdánimọ̀ ifẹ ti Jesu Kristi ṣapejuwe. (Johanu 13:35) Awọn nikan ni wọn sì ń gbadun ominira ti Jesu Kristi sọ pe otitọ yoo mu wa, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Johanu 8:32 pe: “Ẹ o sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di ominira.”
Awọn ọrọ wọnni tí Jesu Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun, sọ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti jasi otitọ. A sì mọriri wọn nisinsinyi ju ti ìgbàkígbà ri lọ nipasẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn pesẹ si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Ominira.” Itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa ti mu oniruuru ìhà ominira wọn, bi wọn ṣe gbọdọ lo o, ìjíhìn ti ó lọ pẹlu ominira wọn, ati bi a ti bukun wọn tó lati jẹ́ eniyan olominira, ṣe kedere fun wọn.
Awọn apejọpọ ti ó bágbàmu ti ó sì ṣee mulo wọnyi bẹrẹ ni Apa Ilaji Iha-ariwa Ilẹ-aye ni June 7, 1991, ni Los Angeles, California, U.S.A. Itolẹsẹẹsẹ bẹrẹ ni 10:20 a.m. pẹlu igbekalẹ ohùn orin, tí orin ati adura tẹle. Ọrọ asọye ibẹrẹ jẹ́ igbekalẹ gbankọgbìì ti a gbekari Jakobu 1:25. Ni ibamu pẹlu The New Jerusalem Bible (Gẹẹsi), ẹsẹ yii kà pe: “Ọkunrin naa ti o tẹjumọ ofin pipe ti ominira laiyiju pada ti ó si sọ iyẹn di aṣa rẹ̀—kii ṣe ni fifetisilẹ ki ó sì gbagbe, ṣugbọn ti ń fi i silo pẹlu itara—yoo jẹ́ alayọ ninu gbogbo ohun ti ó ń ṣe.” Gan-an bi a ti ń wo awòjíji kan lati ri ibi ti a ti nilati ṣe awọn imusunwọnsi ninu irisi wa, bẹẹ gan-an ni a nilati tẹpẹlẹmọ bibojuwo ofin pipe Ọlọrun ti o jẹ́ ti ominira lati mọ ibi ti a ti nilati ṣe awọn iyipada ninu awọn animọ wa. A sì gbọdọ tẹpẹlẹmọ wiwo inu awòjíji yẹn.
Lẹhin naa ni ó kan ọrọ-awiye alaga, “Ẹ Kaabọ, Gbogbo Ẹyin Olùfẹ́ Ominira.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nífẹ̀ẹ́ ominira, wọn sì fẹ lati wà lominira. Olubanisọrọ naa ṣayọlo awọn ọrọ aṣẹ ti ofin tí wọn fihan pe kò lè sí ominira laisi ofin. Bẹẹni, awọn Kristẹni kò si lominira lati ṣe ohun ti ó wù wọn ṣugbọn wọn lominira lati ṣe ifẹ-inu Jehofa. Wọn fẹ lati lo ominira wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ṣugbọn kii ṣe lati ṣì í lò. Ni pataki lati 1919 ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń gbadun ominira ti ó pọ sii. Olubanisọrọ naa tọpasẹ itẹnumọ ominira ninu awọn ẹṣin-ọrọ apejọpọ ati awọn itẹjade Kristẹni. Gbogbo awọn olupejọpọ naa yoo mọ pupọ sii nipa ominira ti Ọlọrun fifunni ati bi wọn ṣe lè lò ó.
Awọn ọrọ ti ó bágbàmu wọnni ni ifọrọ wa awọn olùfẹ́ ominira lẹnuwo ti wọn layọ lati wà nibẹ ni apejọpọ naa tẹ̀lé. Iru awọn apejọpọ bẹẹ jẹ́ akoko yíyọ̀, ani gẹgẹ bi ayọ ńlá ti sami si awọn ayẹyẹ ẹlẹẹmẹta lọdun ti Isirẹli igbaani. Ọpọlọpọ awọn ifọrọwanilẹnuwo jẹrii sii pe awọn apejọpọ jẹ́ akoko ìgbéniró ti yíyọ̀ nipa tẹmi.
Lẹhin naa ni ó kan koko ọrọ apejọpọ, “Ète ati Ìlò Ominira Ti Ọlọrun Fifun Wa.” Lati inu ọrọ-asọye yii awọn olupejọpọ naa kẹkọọ pe Jehofa nikan ni ó ní ominira patapata nitori pe oun ni Alaṣẹ Gigajulọ ó sì jẹ́ olodumare. Nititori orukọ rẹ̀ ati fun anfaani awọn ẹ̀dá rẹ̀, bi o ti wu ki o ri, oun nigba miiran maa ń pààlà si agbara rẹ̀ nipa lílọ́ra lati binu ati lilo ikora-ẹni-nijaanu. Gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ ní ominira ti ó ní ààlà, nitori pe wọn jẹ́ ọmọ abẹ fun Jehofa a sì ká wọn lọ́wọ́ kò nipasẹ awọn ofin ti ara ati ti iwarere rẹ̀. Jehofa ti fun wọn ni ominira fun igbadun wọn ṣugbọn ni pataki ni o ri bẹẹ ki wọn baa lè mu ọla ati ayọ wa bá a nipa jijọsin rẹ̀. Nitori lilo ominira wọn lọna rere, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti jere iyì fun iwa rere ati itara fun iṣẹ-ojiṣẹ wọn yika ayé.
Ọsan Friday
“Ọwọ Rẹ Dí—Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ́ Isin Jehofa?” ni àkọlé ọrọ-asọye ti ń ru ironu soke ti ó ṣí akoko ijokoo ọsan Friday. Awọn òkú iṣẹ́ ni kii ṣe kiki awọn wọnni tii ṣe ti ara ninu ṣugbọn awọn miiran ti wọn jẹ́ òkú, asán, ati alaileso nipa tẹmi paapaa—iru bii ìhùmọ̀ rírí-owó. Ni ọna yii, ayẹwo ara-ẹni oloootọ-inu ṣe pataki lati pinnu bi a ba ń fi Ijọba naa ṣe akọkọ ninu igbesi-aye.
Eyi ti ó tun ni ọpọ koko pataki bakan naa ni ọrọ asọye ti o tẹle e, “Mimu iṣẹ Wa Ṣẹ Gẹgẹ bi Ojiṣẹ Ọlọrun.” Olubanisọrọ naa fihan pe awọn Kristẹni kò gbọdọ tẹ́ araawọn lọ́rùn pẹlu iṣẹ-isin gbà-má-póòrọ́wọ́ọ̀mi lasan tabi pẹlu wiwulẹ doju wakati ti a beere. Wọn nilati fẹ́ lati jẹ́ ẹni ti o gbéṣẹ́ ninu gbogbo ìhà iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni wọn. Awọn koko wọnyi ni a tẹ̀ mọ́ ọkan awọn awujọ nipasẹ aṣefihan kan ati awọn ifọrọwanilẹnuwo. Gbogbo eniyan ni a gbaniyanju lati mu iṣẹ-ojiṣẹ wọn ṣẹ dé iwọn kikun rẹrẹ julọ ti ó ṣeeṣe.
Ninu ọrọ-asọye naa “Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn ti Wọn Yoo Jihin,” olubanisọrọ naa tẹnumọ ọn pe bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan Jehofa ṣikẹ ominira ti otitọ ti mu wa fun wọn, wọn nilati ranti pe ìjíhìn lọ pẹlu rẹ̀. Wọn nilati lo ominira wọn, kii ṣe gẹgẹ bi gááfárà fun iwa buburu, ṣugbọn lati yin Jehofa. Gẹgẹ bii Kristẹni, wọn yoo jíhìn fun “awọn alaṣẹ onipo-gigaju” wọn sì nilati fọwọsowọpọ pẹlu awọn alagba ijọ pẹlu. (Roomu 13:1, NW) Siwaju sii, wọn yoo jihin aṣọ, ìmúra, ati iwa wọn. Wọn kò nilati gbagbe lae pe “olukuluku wa ni yoo jihin araarẹ fun Ọlọrun.”—Roomu 14:12; 1 Peteru 2:16.
Lẹhin naa ni ijiroro kan nipa aini naa fun gbogbo awọn Kristẹni lati jẹ́ ‘Alaibẹru Bi Opin Aye Yii Ti Nsunmọ Etile’ tẹle e. Nigba ti araye kun fun ibẹru nipa ohun ti ọjọ-ọla lè mu wa, awọn Kristẹni nilati jẹ́ alaibẹru lati ṣe iṣẹ-ojiṣẹ wọn. Jíjẹ́ alaibẹru jẹ́ iyọrisi igbẹkẹle ninu Jehofa, nitori bi Kristẹni kan ba ti bẹru lati ṣe ohun ti kò dun mọ Ọlọrun ninu tó, bẹẹ ni oun yoo ṣe bẹru awọn ẹ̀dá mọniwọn tó. Kíkọ́ awọn iwe mimọ ti ń tuni ninu sórí lè fun ẹnikan lokun lati jẹ́ alaibẹru. Lati jẹ́ alagbara ati alaibẹru nipa tẹmi, awọn iranṣẹ Ọlọrun tun nilati lo gbogbo awọn anfaani lati kẹgbẹpọ pẹlu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn lọna rere. Ẹnikọọkan tun nilati ranti ipa ti adura ń kó ninu jijẹ alaibẹru. Nipa wiwa laibẹru, awọn Kristẹni yoo pa ipo ibatan rere mọ pẹlu Jehofa Ọlọrun.
Ọjọ akọkọ itolẹsẹẹsẹ naa pari pẹlu àwòkẹ́kọ̀ọ́ akún fun ẹkọ gidigidi naa A Da Wọn Silẹ Lominira Lati Gbé Ijọsin Tootọ Ga. Ó fihan bi idile ode-oni kan ṣe lè kẹkọọ lati ọdọ Ẹsira ati awọn 7,000 ẹgbẹ́ rẹ̀, ti wọn ṣe awọn irubọ lati pada si Jerusalẹmu. Ó mu ki o ṣeeṣe fun olupejọpọ kọọkan lati ṣayẹwo awọn ohun àkọ́múṣe rẹ̀ ki o sì rí bi oun ṣe lè mu awọn anfaani iṣẹ-isin rẹ̀ pọ sii. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ yii ni ohun kan fun tewe tagba papọ.
Owurọ Saturday
Lẹhin itolẹsẹẹsẹ ohùn orin, orin, adura, ati ijiroro ẹsẹ Bibeli ojumọ, owurọ Saturday gbe apinsọ ọrọ asọye kan jade “Ominira Pẹlu Ẹru iṣẹ Ninu Agbo Idile.” Ni apa akọkọ, “Bi Awọn Baba Ṣe Le Ṣafarawe Jehofa,” awọn baba ni a gbanimọran lori oniruuru awọn ọna ninu eyi ti wọn lè gbà ṣafarawe Baba wa ọrun. Timoti Kìn-ín-ní 5:8 beere pe ki wọn pese kii ṣe kiki nipa ti ara nikan ṣugbọn nipa tẹmi pẹlu. Wọn ṣafarawe Jehofa nipa jijẹ olukọ rere fun idile wọn ati nipa fifunni ni ibawi onifẹẹ gẹgẹ bi aini ba ti wà fun un. Awọn koko wọnyi ni a ṣapejuwe nipa awọn ifọrọwanilẹnuwo melookan.
“Ojuṣe Onítìlẹhìn ti Aya” ni apa ti ó kan ninu apinsọ ọrọ asọye yii. Ó bẹrẹ nipa titẹnumọ ọn pe aya gba ipo ti o ni ọla ninu idile Kristẹni, ti jijẹ atinilẹhin. Ki ni eyi beere fun lọdọ rẹ̀? Pe ki o wà ni itẹriba ti o bojumu, lai fi ipa dari ọkọ rẹ̀ lati ṣe kiki ohun ti oun nikan ń fẹ́. Ó nilati bojuto awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe rẹ̀ fun ọkọ ati awọn ọmọ rẹ̀ daradara, ó sì lè ri itẹlọrun gidi gba lati inu mimu ki ile rẹ̀ mọ tonitoni ati nigínnigín. Ati gẹgẹ bi ojiṣẹ Kristẹni kan, ó lè ni ọpọlọpọ anfaani lati lọwọ ninu iṣẹ-isin pápá. Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu idile kan nú-ẹnu-mọ́ ọgbọn iru imọran ti ó bá Iwe Mimọ mu bẹẹ.
Awọn ọdọ eniyan gba afiyesi ni apa naa “Awọn Ọmọ ti Wọn Nfetisilẹ ti Wọn Si Nkẹkọọ.” Nipa titọ awọn ọmọ wọn lati fetisilẹ ki wọn sì kẹkọọ, awọn obi mu ọla wa fun Jehofa wọn sì fi ifẹ han fun awọn arakunrin wọn tẹmi ati fun awọn ọmọ tiwọn funraawọn. Ìdè lilagbara yoo wà laaarin awọn obi ati awọn ọmọ bi wọn ba lo akoko ti o niye lori papọ. Awọn obi ni a gbọdọ murasilẹ lati dahun awọn ibeere awọn ọmọ wọn ki wọn sì ru òùngbẹ wọn fun ìmọ̀ soke. Lẹẹkan sii, awọn ifọrọwanilẹnuwo fi bi a ti lè ṣe eyi han.
Eyi ti ó kàn ni imọran rere naa “Mu Araarẹ Wà Lominira Lati Ṣiṣẹsin Jehofa.” Bawo ni a ṣe ń ṣe eyi? Nipa wiwa lominira kuro ninu lilepa awọn iṣẹ igbesi-aye, awọn iṣẹ́-ọwọ́-dilẹ̀ ti ń jẹ akoko, ati awọn gongo ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ayé. Jesu ati apọsiteli Pọọlu gbé awọn apẹẹrẹ rere kalẹ fun wa nipa jíjẹ́ olufara-ẹni-rubọ. Awọn eniyan Jehofa nilati pa oju wọn mọ́ láìgùn, pa afiyesi pọ sori awọn ire Ijọba naa. Nigba ti o ba kan wíwá awọn ohun ti ara rí, o bọgbọnmu jù lati fowopamọ nisinsinyi ki a sì rà á nigba ti o ba yá ju ki a rà á nisinsinyi ki a sì sanwo lẹhin naa lọ. Awọn ọdọ gbọdọ ṣọra lodisi lílá àlá asán nipa igbadun ibalopọ takọtabo ati iṣẹ igbesi-aye ti ayé. Ifọrọwa aṣaaju-ọna kan ti kò tii ṣegbeyawo lẹnuwo fi awọn ibukun ti ó ń wá nigba ti ẹnikan ba wà lominira lati ṣiṣẹsin Jehofa han.
Itolẹsẹẹsẹ owurọ Saturday pari pẹlu ọrọ-asọye naa “Bọ Sinu Ominira Nipa Iyasimimọ ati Iribọmi.” Awọn olùnàgà fun anfaani iribọmi ni a ran leti pe nigba ti a ti gbé ẹ̀dá sọ sinu oko ẹrú nipasẹ iṣọtẹ Adamu, Oludanisilẹ alagbara, Jesu Kristi, ṣí ọna naa si ominira silẹ nipa ẹbọ rẹ̀. Olubanisọrọ naa fi ohun ti jija ajabọ lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun ni ninu han ó sì tẹnumọ awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe ati awọn ibukun ti yoo jẹ́ ipin awọn wọnni ti a ń ṣe iribọmi fun.
Ọsan Saturday
Itolẹsẹẹsẹ ọsan Saturday bẹrẹ pẹlu ibeere awadii ọkan naa “Anfaani Ta ni Iwọ Nwa?” Ayé ń fi ẹmi wíwá ire ti ara ẹni nikan ti i ṣe ti Eṣu hàn. Bi o ti wu ki o ri, awọn Kristẹni nilati ṣafarawe ẹmi ifara-ẹni-rubọ Jesu Kristi. Iru apẹẹrẹ wo ni ó gbekalẹ! Ó fi ogo ti ọrun silẹ ò si fi iwalaaye eniyan rẹ̀ rubọ lẹhin naa fun anfaani wa. Awọn ipenija niti anfaani ta ni awa ń wá yọju nigba ti awọn èdèkòyédè laaarin awọn Kristẹni ba wà ninu iṣẹ́-ajé tabi ọran iṣunna owo, nigba ti iforigbari animọ ba wà, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Iru awọn nǹkan bẹẹ ń dán ifẹ Kristẹni wò. Ṣugbọn nipa wiwa anfaani awọn ẹlomiran, ó daju pe ẹnikan yoo ri ibukun titobi ju ti fifunni gba, oun yoo sì jere itẹwọgba Jehofa.
Lẹhin naa ni ẹṣin-ọrọ ti o tanmọ́ ọn pẹkipẹki “Mímọ̀ ati Bibori Ailera Tẹmi” tẹle e. Ọrọ-asọye yii tẹnumọ aini naa lati dá awọn ami ailera tẹmi mọ̀ ati lẹhin naa gbegbeesẹ pẹlu ipinnu ni jíjà lati ṣẹpa Satani ati ìkẹ́kùn rẹ̀. Awọn iranṣẹ Jehofa gbọdọ mu ifẹ jijinlẹ fun un ati ikoriira fun ohun ti o jẹ́ buburu dagba. Eyi beere fun pe ki wọn mọ Jehofa nipasẹ ikẹkọọ Bibeli onipinnu, ti ara-ẹni ati ti idile ti a ń ṣe deedee. Wọn gbọdọ yẹra fun gbogbo iru eré ìnàjú ti o gbe iwa-ipa ati iwapalapala takọtabo larugẹ. (Efesu 5:3-5) Adura ati lilọ si ipade deedee tun ṣe pataki fun aṣeyọrisirere ninu bíborí awọn ailera tẹ̀mí.
Boya eyi ti o ṣokunfa ijiroro ti o pọ ju ọrọ-asọye eyikeyii miiran ti a sọ ni apejọpọ naa laaarin awọn eniyan ni a fun ni àkọlé naa “Igbeyawo Ha Ni Kọkọrọ Naa Si Ayọ Bi?” Ọpọlọpọ awọn ọdọ eniyan ni wọn rò bẹẹ! Ṣugbọn olubanisọrọ naa mu un ṣe kedere pe ailonka awọn ẹ̀dá ẹmi oluṣotitọ ti wọn jẹ́ alayọ ni n bẹ bi o tilẹ jẹ pe wọn kò gbeyawo, ani bi ọpọlọpọ awọn Kristẹni oluṣeyasimimọ ti jẹ́ alayọ bi o tilẹ jẹ pe wọn kò tọrun bọ ajaga ninu igbeyawo. Ju bẹẹ lọ, ọpọlọpọ awọn tọkọtaya ti wọn ti ṣegbeyawo ni wọn kò layọ, gẹgẹ bi a ti fihan nipasẹ iwọn ìkọ̀sílẹ̀ ti o ga. Ẹnikan wulẹ nilati ronu lori ọpọlọpọ ibukun ti gbogbo awọn Kristẹni oluṣeyasimimọ ń gbadun lati mọ pe igbeyawo, bi o tilẹ jẹ pe ó lè jẹ́ ibukun, kii ṣe kọkọrọ naa si ayọ.
Eyi ni apinsọ ọrọ asọye naa “Ominira Kristẹni Ni Ọjọ Wa” tẹ̀lé. Olubanisọrọ akọkọ jiroro “Awọn Ẹka Ominira Kristẹni Wa.” Iwọnyi ní ominira kuro ninu awọn ẹkọ isin èké gẹgẹ bii Mẹtalọkan, aileku ọkàn eniyan, ati idaloro ayeraye nínú. Lẹhin naa ominira kuro ninu ìdè oko ẹrú sinu ẹṣẹ wà. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Kristẹni jẹ́ alaipe, wọn wà lominira kuro lọwọ iru awọn aṣa buburu bii sìgá mímu, tẹtẹ tita, ọti amupara, ati nini ju alajọṣe ibalopọ takọtabo kan lọ. Ominira kuro ninu ipo ainireti tun wà, nitori ti wọn ni ireti ti Paradise ti o ń sún wọn lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa rẹ̀.
Olubanisọrọ ti o tẹle e beere ibeere naa pe “Iwọ Gẹgẹ bi Ẹnikan Ha Ṣìkẹ́ Iru Ominira Bẹẹ Bi?” Lati ṣìkẹ́ tumọsi lati gbà si ọ̀wọ́n, lati tọju pẹlu iṣọra. Lati ṣe iyẹn, iranṣẹ Ọlọrun gbọdọ ṣọra lodisi jijẹ ẹni ti a danwo lati lọ rekọja ààlà ominira Kristẹni. Ominira ayé jẹ́ irọ́ atannijẹ, nitori ti o ń yọri si oko ẹrú si ẹṣẹ ati idibajẹ.
Olubanisọrọ ti ó kẹhin ninu apinsọ ọrọ asọye yii sọrọ lori koko-ẹkọ naa “Awọn Olùfẹ́ Ominira Duro Ṣinṣin.” Lati ṣe iyẹn, awọn Kristẹni gbọdọ dìrọ̀ timọtimọ mọ́ awọn obi wọn ti ọrun, Jehofa ati eto-ajọ bi aya rẹ̀. Awọn eniyan Jehofa kò lè yọnda araawọn lati di ẹni ti a yi sapakan nipasẹ ìgbékèéyíde apẹhinda; wọn gbọdọ ṣá awọn wọnni ti wọn wá pẹlu idamọran iwapalapala tì. Lati duro gbọnyingbọnyin ninu ominira oniwa-bi-Ọlọrun, awọn Kristẹni gbọdọ maa “wà láàyè sipa ti ẹmi.”—Galatia 5:25.
Ọrọ-asọye ti ó gbẹhin ọjọ naa jẹ́ orisun idunnu tootọ. A fun un ni àkọlé naa “Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti o Tíì Gbé Ayé Ri.” Jesu Kristi ni ọkunrin titobilọla naa, nitori pe ó nipa lori igbesi-aye iran araye lọna ti ó lagbara ju gbogbo awọn ọmọ-ogun ori ilẹ, ọmọ ogun oju-omi, igbimọ aṣofin, ati awọn ọba lákòópọ̀. Oun ni Ọmọkunrin Ọlọrun, ẹni ti o wà ni ọrun ṣaaju ki o to wa si ori ilẹ-aye. Daradara gan-an ni Jesu ṣafarawe Baba rẹ̀ ọrun ninu ohun ti ó sọ ti ó sì kọni ati bi ó ṣe gbé igbesi-aye debi pe ó lè sọ pe: “Ẹni ti o ba ti ri mi, o ti ri Baba.” (Johanu 14:9) Bawo ni Jesu ti ṣaṣefihan pe “Ọlọrun jẹ́ ifẹ” tó! (1 Johanu 4:8, NW) Lẹhin sisọrọ lori awọn animọ Jesu dé iwọn gigun kan, olubanisọrọ naa mẹnukan an pe ọ̀wọ́ awọn ọrọ-ẹkọ ti a pè ni “Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu” ni a ti tẹjade ninu Ilé-Ìṣọ́nà lati April 1985. Ni idahunpada si ọpọlọpọ ibeere, Society ń mu iwe titun naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti o Tíì Gbé Ayé Ri jade nisinsinyi. Ó ni 133 ori-iwe a sì tẹ̀ ẹ́ ni àwọ̀ mèremère. Ọrọ ẹkọ ninu ọ̀wọ́ yii ni a ti tẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a sì ti mu wọnu iwe oloju-ewe 448 naa. Loootọ, ọjọ apejọpọ yii pari pẹlu ayọ giga!
Owurọ Sunday
Ni ibẹrẹ ijokoo owurọ Sunday ni apinsọ ọrọ asọye naa “Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan” wáyé. Ọrọ-asọye naa “Ẹja Pipa—Gidi ati Iṣapẹẹrẹ” fi ipilẹ lélẹ̀ fun awọn ọrọ asọye ti o tẹle e. Olubanisọrọ naa fihan pe lẹhin ti Jesu ti ṣokunfa ìpẹja oniṣẹ iyanu, ó ké sí awọn apẹja ti ọrọ kàn lati di awọn apẹja eniyan. Fun akoko kan, Jesu dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹkọọ lati di apẹja eniyan, ati bẹrẹ ni Pẹntikọsi 33 C.E., wọn ṣaṣeyọri ninu riran ògìdìgbó awọn ọkunrin ati obinrin lọwọ lati di ọmọ-ẹhin.
Olubanisọrọ ti ó kan sọrọ lori owe àkàwé ti àwọ̀n ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matiu 13:47-50. Ó ṣalaye pe àwọ̀n iṣapẹẹrẹ ní awọn Kristẹni ẹni ami ororo ati Kristẹndọmu ninu, o kan Kristẹndọmu nitori iṣẹ ti wọn ṣe ni titumọ, titẹjade, ati pipin Bibeli kiri, bi o tilẹ jẹ pe awọn isapa wọnyi kó ọpọ jantirẹrẹ ògìdìgbó awọn ẹja ti kò yẹ jọ. Ni pataki lati 1919 ni iṣẹ iyasọtọ kan ti wà, pẹlu awọn ẹja ti kò yẹ ti o di sisọnu, nigba ti awọn ti ó yẹ di eyi ti a kójọ sinu awọn ijọ ti ó dabi ọkọ̀ ti ó ti ṣeranwọ lati daabobo ati lati pa awọn Kristẹni tootọ mọ fun iṣẹ-isin atọrunwa.
Ọrọ-asọye kẹta, “Pipẹja Eniyan Ninu Awọn Omi Agbaye,” tẹnumọ iṣẹ aigbọdọmaṣe gbogbo awọn Kristẹni oluṣeyasimimọ lati ṣajọpin ninu ẹja pipa yika ayé naa. Nisinsinyi iye ti o ju 4,000,000 lọ ń ṣajọpin ninu iṣẹ yii ni iye ti o ju 200 ilẹ lọ, ati ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́ yii iye ti o ju 230,000 daadaa ni a ti ń bamtisi lọdọọdun. Gbogbo awọn eniyan Jehofa ni a rọ̀ lati mu ijafafa ẹja pipa wọn sunwọn sii, “awọn apẹja” alaṣeyọrisi rere melookan pato ni a sì fi ọrọ walẹnuwo.
Ninu ọrọ-asọye ti ó tẹle e, ti o ni àkọlé naa “Wíwàlójúfò Ni ‘Akoko Opin,’” olubanisọrọ ka awọn aranṣe meje lati ran awọn eniyan Ọlọrun lọwọ lati wà lojufo: biba awọn ipinya ọkan jà, gbigbadura, ṣiṣe ikilọ nipa opin eto igbekalẹ awọn nǹkan yii, fifaramọ eto-ajọ Jehofa, ṣiṣe ayẹwo ara-ẹni, rironu jinlẹ lori awọn asọtẹlẹ ti o ti ni imuṣẹ, ati fifi sọkan pe igbala wọn ti sunmọ tosi ju igba ti wọn di onigbagbọ lọ.
Itolẹsẹẹsẹ owurọ pari pẹlu ijiroro kan “Ta ni Yoo Yèbọ́ Ni ‘Akoko Ipọnju’ Naa?” Olubanisọrọ fi bi asọtẹlẹ Joẹli ṣe ni iwọn imuṣẹ kan ni akoko awọn apositeli han, bi o ṣe ń ni imuṣẹ siwaju sii nisinsinyi, ati bi yoo ṣe ni imuṣẹ patapata ni ọjọ-ọla ti kò jinna mọ́.
Ọsan Sunday
Itolẹsẹẹsẹ ọsan bẹrẹ pẹlu awiye fun gbogbo eniyan, “Kíkókìkí Ayé Titun Olómìnira ti Ọlọrun!” Ọrọ yii ń ba ẹṣin-ọrọ ominira apejọpọ naa lọ. A ṣalaye rẹ̀ pe Ọrọ Ọlọrun sọ asọtẹlẹ ayé titun kan nibi ti ominira kuro lọwọ itẹloriba nipasẹ awọn apa ti o papọ jẹ ti isin èké, oṣelu, ọrọ aje ati ti ẹyà yoo wà. Ominira kuro lọwọ ẹṣẹ ati ikú yoo tun wà. Ilera pipe ni a o mu padabọsipo ki awọn eniyan ba lè wà láàyè titilae ninu ayọ lori paradise ilẹ-aye. Nipa bayii, awọn olùfẹ́ ododo ní gbogbo idi lati kókìkí Oluṣe ayé titun naa nipa pipolongo pe: “O ṣeun, Jehofa fun ominira tootọ nígbẹ̀hìngbẹ́hín!”
Ọrọ-asọye naa ni ohun titun kan fun apejọpọ naa tẹle—ijiroro ẹkọ ninu Ilé-Ìṣọ́nà ti ọsẹ naa. Lẹhin naa apejọpọ naa wá si ipari pẹlu ọrọ asọye ati iṣileti arunisoke naa “Ẹyin Olùfẹ́ Ominira, Ẹ Maa Tẹsiwaju.” Olubanisọrọ naa bojuto awọn koko pataki ẹṣin-ọrọ ominira ti apejọpọ naa ni ṣoki. Ó tẹnumọ bi awọn eniyan Jehofa ti layọ tó nitori ominira wọn, ó ka awọn ọna ninu eyi ti awọn Kristẹni lè gba ṣe itẹsiwaju, ó sì rọ̀ wọn lati maa tẹsiwaju pẹlu iṣọkan ki wọn baa lè ká awọn ibukun siwaju sii. Ó fi awọn ọrọ yii pari rẹ̀: “Bi a ti ń ṣe eyi, njẹ ki Jehofa maa baa lọ lati bukun wa lapapọ ati lẹnikọọkan gẹgẹ bi olùfẹ́ ominira.”
“A tẹri ẹ̀dá ba fun asan, kii ṣe ifẹ rẹ̀, ṣugbọn nitori ẹni ti o tẹ ori rẹ̀ ba, ni ireti, nitori a o sọ ẹ̀dá tikaraarẹ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.” —Roomu 8:20, 21.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọdọ ayànṣaṣoju kan ti ó lọ si apejọpọ ni Prague, Czechoslovakia
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
1. Awọn olùnàgà fun anfaani ń lọ si ibi iribọmi ni Prague, Czechoslovakia
2. Ṣiṣe iribọmi gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Tallinn, Estonia
3. Awọn itẹjade titun mú ayọ wá fun awọn olupejọpọ ni Usolye-Sibirskoye, Siberia
4. Imujade “New World Translation of the Holy Scripture” ní èdè Czech ati Slovak ni apejọpọ ni Prague