Ṣọọṣi Ijimiji Ha Kọni Pe Ọlọrun Jẹ́ Mẹtalọkan Bi?
Apa Keji—Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
Ninu Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1991, Apa Kìn-ín-ní ọ̀wọ́ yii jiroro yala Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi ẹkọ Mẹtalọkan kọni—ero naa pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ jẹ́ awọn ẹni mẹta ti wọn dọgba sibẹ ti wọn jẹ́ Ọlọrun kan. Ẹ̀rí kedere lati inu Bibeli, lati ọdọ awọn opitan, ati lati ọdọ awọn ẹlẹkọọ isin paapaa ni pe wọn kò ṣe bẹẹ. Ki ni nipa awọn aṣaaju ṣọọṣi ti wọn tẹle e kété lẹhin naa—wọn ha kọni ni Mẹtalọkan bi?
“AWỌN ONKỌWE LẸHIN AKOKO AWỌN APỌSITELI” ni orukọ ti a lo fun awọn ọkunrin ṣọọṣi ti wọn kọwe nipa isin Kristẹni ni opin ọrundun kìn-ín-ní ati ibẹrẹ ọrundun keji ti Sanmani Tiwa. Diẹ ninu wọn ni Clement ti Roomu, Ignatius, Polycarp, Hermas, ati Papias.
A sọ pe wọn jẹ́ alajọgbaye awọn apọsiteli melookan. Nipa bayii, wọn ti nilati dojulumọ pẹlu ẹkọ awọn apọsiteli. Nipa ohun ti awọn ọkunrin wọnni kọ, iwe gbedegbẹyọ naa The New Encyclopædia Britannica sọ pe:
“Lapapọ iwe Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli tubọ niye lori niti itan ju iwe Kristẹni eyikeyii miiran lẹhin ode Majẹmu Titun lọ.”1
Bi awọn apọsiteli ba kọni ni ẹkọ Mẹtalọkan, nigba naa Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli wọnni ìbá ti fi i kọni pẹlu. Ìbá ti tayọ ninu ikọni wọn, niwọn bi o ti jẹ pe kò si ohun ti o tubọ ṣe pataki ju sisọ ẹni ti Ọlọrun jẹ́ fun awọn eniyan. Nitori naa wọn ha fi ẹkọ Mẹtalọkan kọni bi?
Gbolohun Igbagbọ Ijimiji Kan
Ọ̀kan lara awọn gbolohun ti kii ṣe ti Bibeli ti igbagbọ Kristẹni ijimiji julọ ni a ri ninu iwe kan ti o ni akori 16 ti a mọ si The Didache, tabi Teaching of the Twelve Apostles (Ẹkọ Awọn Apọsiteli Mejila). Awọn opitan kan dá ọjọ rẹ̀ ṣaaju tabi sí nǹkan bi ọdun 100 C.E. Onṣewe rẹ̀ ni a kò mọ̀.2
Iwe The Didache dá lori awọn ohun ti awọn eniyan yoo nilati mọ lati di Kristẹni. Ni ori keje rẹ̀, ó lànà bamtisimu “ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti Ẹmi Mímọ́,” awọn ọrọ kan naa ti Jesu lo ni Matiu 28:19.3 Ṣugbọn kò sọ ohunkohun nipa pe awọn mẹtẹẹta jẹ́ ọgba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọn. Ni ori kẹwaa rẹ̀, iwe The Didache fi ijẹwọ igbagbọ ni iru ọna adura kan ti o tẹle e yii kun un:
“A dupẹ lọwọ rẹ, Baba Mímọ́, fun Orukọ mímọ́ rẹ ti o ti jẹ́ ki ó gbé inu ọkan-aya wa; ati fun ìmọ̀ ati igbagbọ ati aileku ti o ti sọ di mímọ̀ fun wa nipasẹ Jesu Iranṣẹ rẹ. Ogo ni fun ọ titilae! Iwọ, Olodumare Ọga, ni ó da ohun gbogbo nititori Orukọ rẹ . . . Iwọ sì ti fi aanu fun wa ni jíjẹ ati mímu tẹmi, ati ìyè ayeraye nipasẹ Jesu Iranṣẹ rẹ.”4
Kò si Mẹtalọkan ninu eyi. Ninu iwe naa The Influence of Greek Ideas on Christianity, Edwin Hatch ṣayọlo àyọkà-ọ̀rọ̀ ti a sọ tan yii ó sì sọ lẹhin naa pe:
“Ninu papa isin Kristẹni ipilẹṣẹ kò farahan bi ẹni pe itẹsiwaju ńláǹlà eyikeyii wa lori awọn èròǹgbà rirọrun wọnyi wà. Ẹkọ lori eyi ti a gbe itẹnumọ kà ni, pé Ọlọrun wà, pé Oun jẹ́ ọ̀kan, pé Oun ni olodumare ati ainipẹkun, pé Oun dá ayé, pé aanu Rẹ̀ wà lori gbogbo awọn iṣẹ Rẹ̀. A kò tẹ̀ wọ́n si iha ijiroro ti ọgbọn imọ-ọran.”5
Clement ti Roomu
Clement ti Roomu, ti a ronu pe o jẹ́ “biṣọọbu” kan ni ilu yẹn, jẹ́ orisun ikọwe ipilẹṣẹ miiran lori isin Kristẹni. A gbagbọ pe ó kú ni nǹkan bii 100 C.E. Ninu ọrọ ẹkọ ti a tànmọ́-ọ̀n pe o ti nilati kọ, kò mẹnukan Mẹtalọkan rárá, yala ni taarata tabi lọna àpẹ́sọ. Ninu iwe naa The First Epistle of Clement to the Corinthians [Episteli Akọkọ ti Clement si Awọn Ara Kọrinti], ó sọ pe:
“Aanu fun ọ, ati ki alaafia, lati ọdọ Ọlọrun Olodumare nipasẹ Jesu Kristi, di pupọ.”
“Awọn apọsiteli ti waasu Ihinrere fun wa lati ọdọ Oluwa Jesu Kristi; Jesu Kristi ti ṣe bẹẹ lati ọdọ Ọlọrun. Nitori naa Kristi ni a rán jade lati ọdọ Ọlọrun, ati awọn apọsiteli lati ọdọ Kristi.”
“Njẹ ki Ọlọrun, ẹni ti ń rí ohun gbogbo, ti o sì jẹ Oluṣakoso gbogbo awọn ẹmi ati Oluwa gbogbo ẹran ara—ẹni ti ó yan Oluwa wa Jesu Kristi ati awa nipasẹ Rẹ̀ lati jẹ́ awọn eniyan akanṣe—fi igbagbọ, ibẹru, alaafia, suuru, ipamọra fun gbogbo ọkàn ti ń képe Orukọ Rẹ mímọ́ ti o sì logo.”6
Clement kò sọ pe Jesu tabi ẹmi mímọ́ dọgba pẹlu Ọlọrun. Ó fi Ọlọrun Olodumare han (kii wulẹ ṣe “Baba”) gẹgẹ bi ẹni ti ó yatọ gedegbe si Ọmọkunrin. Ọlọrun ni a sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni gigaju, niwọn bi o ti jẹ pe Kristi ni a “rán jade” lati ọdọ Ọlọrun, ti Ọlọrun sì “yan” Kristi. Ni fifihan pe Ọlọrun ati Kristi jẹ́ ẹni meji ọtọọtọ ti wọn kò baradọgba, Clement sọ pe:
“Awa yoo gbadura pẹlu ifọkansi ati ẹbẹ pe Ẹlẹdaa agbaye yoo maa pa iye awọn ayanfẹ rẹ̀ gẹ́lẹ́ mọ́ ni gbogbo ayé, nipasẹ Ọmọ rẹ olufẹ ọ̀wọ́n Jesu Kristi. . . . A mọ daju pe iwọ [Ọlọrun] nikan ni ó ‘tobi julọ laaarin awọn ti o tobi julọ’ . . . Iwọ nikan ni alaabo awọn ẹmi ati Ọlọrun gbogbo ẹran ara.”
“Jẹ ki gbogbo orilẹ-ede ki o mọ daju pe iwọ ni Ọlọrun kanṣoṣo, pe Jesu Kristi ni Ọmọ rẹ.”7
Clement pe Ọlọrun (kii wulẹ ṣe “Baba”) ni “ẹni gigalọla julọ,” ó sì tọka si Jesu gẹgẹ bi “Ọmọ” Ọlọrun. Ó tun ṣakiyesi nipa Jesu pe: “Niwọn igba ti ó ti ṣagbeyọ ọláńlá Ọlọrun, oun ga ju awọn angẹli bi orukọ oyè rẹ̀ ti tubọ tayọ ju tiwọn lọ.”8 Jesu ṣagbeyọ ọláńlá Ọlọrun, ṣugbọn kò bá a dọgba, gan-an gẹgẹ bi oṣupa ti ṣagbeyọ imọlẹ oorun ṣugbọn ti kò ba orisun imọle yẹn, oorun, dọgba.
Bi Ọmọkunrin Ọlọrun bá dọgba pẹlu Ọlọrun, ẹni ti o jẹ Baba ọrun naa, kì bá ti ṣai pọndandan fun Clement lati sọ pe Jesu ga ju awọn angẹli, niwọn igba ti iyẹn yoo ti han gbangba. Awọn ọrọ rẹ̀ sì fi mímọ̀ ti ó mọ daju naa hàn pe nigba ti Ọmọkunrin ga ju awọn angẹli, oun kere ni ipo si Ọlọrun Olodumare.
Ipo ti Clement duro si ṣe kedere gan-an: Ọmọkunrin rẹlẹ si Baba ó sì wà ni ipo keji si i. Clement kò wo Jesu lae gẹgẹ bi ẹni ti ń ṣajọpin ninu ọlọrun ẹlẹni mẹta pẹlu Baba. Ó fihan pe Ọmọkunrin naa gbarale Baba, iyẹn ni, Ọlọrun, ó sì sọ ni pato pe Baba ni ‘Ọlọrun nikan,’ ti kò ṣajọpin ipo Rẹ̀ pẹlu ẹnikẹni. Kò sì sí ibi kankan ti Clement ti fun ẹmi mímọ́ ni ibaradọgba pẹlu Ọlọrun. Nipa bayii, kò si Mẹtalọkan rárá ninu awọn ikọwe Clement.
Ignatius
Ignatius, biṣọọpu ti Antioku, gbe lati nǹkan bii ilaji ọrundun kìn-ín-ní C.E. si ibẹrẹ ọrundun keji. Ki a gbà pe gbogbo iwe kikọ ti a kà sí tirẹ ni wọn jẹ́ otitọ, kò sí ibaradọgba Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ ninu eyikeyii ninu wọn.
Ani bi Ignatius ba ti sọ pe Ọmọkunrin baradọgba pẹlu Baba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọn, kì yoo jẹ́ Mẹtalọkan sibẹ, nitori pe kò si ibi kankan ti o ti sọ pe ẹmi mímọ́ baradọgba pẹlu Ọlọrun ni awọn ọna wọnyẹn. Ṣugbọn Ignatius kò sọ pe Ọmọkunrin naa dọgba pẹlu Ọlọrun Baba ni iru awọn ọna yẹn tabi ni eyikeyii miiran. Kaka bẹẹ, ó fihan pe Ọmọkunrin wà ni itẹriba si Ẹni naa ti o jẹ́ ẹni gigaju, Ọlọrun Olodumare.
Ignatius pe Ọlọrun Olodumare ni “Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, ẹni ti a kò bí tí kò si ṣee sunmọ, Oluwa gbogbo eniyan, Baba ati Ẹni ti o Bi Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo naa,” ni fifi iyatọsira laaarin Ọlọrun ati Ọmọkunrin Rẹ̀ han.9 Ó sọrọ nipa “Ọlọrun Baba, ati Oluwa Jesu Kristi.”10 Ó sì polongo pe: “Ọlọrun kan ni ń bẹ, Olodumare, ẹni ti o ti fi Araarẹ han nipasẹ Jesu Kristi Ọmọkunrin Rẹ̀.”11
Ignatius fihan pe Ọmọkunrin kii ṣe ayeraye gẹgẹ bi ẹnikan ṣugbọn pe a dá a, nitori ó sọ pe Ọmọkunrin wi pe: “Oluwa [Ọlọrun Olodumare] dá Mi, ibẹrẹ awọn ọ̀nà Rẹ̀.”12 Lọna ti o farajọra, Ignatius wi pe: “Ọlọrun agbaye kan ni ń bẹ, Baba Kristi, ‘ti ẹni tí ohun gbogbo jẹ́;’ ati Oluwa kan Jesu Kristi, Oluwa wa, ‘nipasẹ ẹni ti ohun gbogbo wà.’”13 Ó tun kọwe pe:
“Ẹmi Mímọ́ kò sọrọ awọn ohun Tirẹ, ṣugbọn ti Kristi, . . . ani bi Oluwa pẹlu ti kéde awọn ohun ti Ó rí gbà lati ọdọ Baba fun wa. Nitori, Oun [Ọmọkunrin] sọ pe, ‘ọrọ ti ẹ gbọ kii ṣe Temi, ṣugbọn ti Baba, ẹni ti ó ran Mi.’”14
“Ọlọrun kan ni ń bẹ ti o fi araarẹ han nipasẹ Jesu Kristi Ọmọkunrin rẹ̀, ẹni ti o jẹ́ Ọrọ rẹ̀ ti ó ti inu idakẹrọrọ jade ti o sì tẹ́ [Ọlọrun] ẹni ti ó ran an lọ́rùn ni gbogbo ọna. . . . Jesu Kristi jẹ́ ọmọ abẹ fun Baba.”15
Loootọ, Ignatius pe Ọmọkunrin ni “Ọlọrun Ọrọ.” Ṣugbọn lilo ọrọ naa “Ọlọrun” fun Ọmọkunrin kò fi dandan tumọ si ibaradọgba pẹlu Ọlọrun Olodumare. Bibeli tun pe Ọmọkunrin ni “Ọlọrun” ni Aisaya 9:6. Johanu 1:18 pe Ọmọkunrin ni “ọlọrun bíbí-kanṣoṣo naa.” Bi o ti jẹ́ ẹni ti a fi agbara ati aṣẹ wọ̀ lati ọdọ Jehofa Ọlọrun, Baba, Ọmọkunrin naa ni a lè fi ẹtọ kà si “ẹni alagbara” kan, eyi ti o jẹ itumọ “ọlọrun” ni ipilẹṣẹ.—Matiu 28:18; 1 Kọrinti 8:6; Heberu 1:2.
Bi o ti wu ki o ri, a ha tẹwọgba awọn lẹta 15 ti a kà si ti Ignatius gẹgẹ bi eyi ti o jẹ ootọ bi? Ninu iwe naa The Ante-Nicene Father, Idipọ Kìn-ín-ní, ontẹwe Alexander Roberts ati James Donaldson sọ pe:
“Ó jẹ́ èrò awọn lameyiitọ kari ayé nisinsinyi, pe akọkọ ninu lẹta mẹjọ ti a tànmọ́-ọ̀n pe ó jẹ ti Ignatius wọnyi jẹ èké. Wọn ni awọn ẹ̀rí ti kò ṣee janikoro pe wọn jẹ́ imujade sanmani ẹhin naa . . . a sì ti pa wọn tì nisinsinyi gẹgẹ bi ayédèrú nipa itẹwọgba gbogbogboo.”
“Ninu awọn Episiteli meje tí Eusebius gbà . . . , a ni awọn ọrọ iwe Giriiki meji ti a ṣatunṣe, kukuru kan ati gigun kan. . . . Bi o tilẹ jẹ pe eyi ti o kuru ju . . . ni a ti gbà ni gbogbogboo ni ayanlaayo ju eyi ti o gun lọ, ọpọlọpọ èrò ti o gbilẹ laaarin awọn ọmọwe ni o ṣì wà sibẹ, pe a kò tilẹ le kà a si eyi ti o wà lominira kuro lọwọ awọn afikun ọrọ patapata, tabi gẹgẹ bi eyi ti o jẹ otitọ ti kò ṣee ṣiyemeji sí.”16
Bi a bá tẹwọgba ẹ̀dà itumọ kukuru ti awọn iwe kikọ rẹ̀ gẹgẹ bii ojulowo, ko mu awọn àpólà ọ̀rọ̀ kan (ninu ẹ̀dà itumọ gigun) ti wọn fi Jesu han bí ẹni ti o jẹ́ oṣiṣẹ ọmọ abẹ́ si Ọlọrun kuro, ṣugbọn ohun ti ó ṣẹ́kù sibẹ ninu ẹ̀dà itumọ kukuru kò fi Mẹtalọkan han. Laifi ewo ninu awọn iwe kikọ rẹ̀ ni o jẹ́ ojulowo pè, pátápinrá wọn fihan pe Ignatius gbagbọ ninu mejilọkan ti Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀. Ó daju pe eyi kii ṣe mejilọkan ti ibaradọgba, nitori Ọmọkunrin ni a saba maa ń fihan gẹgẹ bi ẹni ti o rẹlẹ̀ ju Ọlọrun ti o sì jẹ́ ọmọ-abẹ fun un. Nipa bayii, laika oju ti ẹnikan fi wo awọn ikọwe Ignatius si, ẹkọ Mẹtalọkan ni a kò ri ninu wọn.
Polycarp
A bí Polycarp ará Smyrna ni ìdákẹta ti o gbẹhin ninu ọrundun akọkọ ó sì kú ni ilaji ọrundun keji. A sọ pe ó ni ifarakanra pẹlu apọsiteli Johanu, a sì sọ pe oun ni ó kọ Epistle of Polycarp to the Philippians (Episteli ti Polycarp si Awọn Ara Filipi).
Ohunkohun ha wà ninu ikọwe Polycarp ti o lè tọka si Mẹtalọkan bi? Bẹẹkọ, a kò mẹnukan an. Nitootọ, ohun ti o sọ ṣedeedee delẹ pẹlu ohun ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn apọsiteli fi kọni. Fun apẹẹrẹ, ninu Epistle rẹ̀, Polycarp sọ pe:
“Ǹjẹ́ ki Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, ati Jesu Kristi Funraarẹ, ẹni ti o jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun, . . . gbé yin ró ninu igbagbọ ati otitọ.”17
Ṣakiyesi pe, bii Clement, Polycarp kò sọrọ nipa ipo ibatan Mẹtalọkan ti “Baba” ati “Ọmọkunrin” ti wọn jẹ́ ọgba ninu ọlọrun ẹlẹ́ni mẹta. Kaka bẹẹ, ó sọrọ nipa “Ọlọrun ati Baba” Jesu, kii wulẹ ṣe ‘Baba Jesu.’ Nitori naa oun ya Ọlọrun sọtọ si Jesu, gan-an bi awọn onkọwe Bibeli ti ṣe leralera. Pọọlu sọ ni 2 Kọrinti 1:3 pe: “Olubukun ni Ọlọrun naa ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa.” Oun kò wulẹ sọ pe, ‘Olubukun ni Baba Jesu’ ṣugbọn, “Olubukun ni Ọlọrun naa ati Baba” Jesu.
Pẹlupẹlu, Polycarp sọ pe: “Alaafia lati ọdọ Ọlọrun Olodumare, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Olugbala wa.”18 Nihin-in lẹẹkan sii ni Jesu ti yatọ gedegbe si Ọlọrun Olodumare, kii ṣe eniyan kan ti o jẹ́ alabaadọgba Ọlọrun ẹlẹ́ni mẹta ti mẹtalọkan.
Hermas ati Papias
Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli miiran ni Hermas, ẹni ti o kọwe ni apa akọkọ ti ọrundun keji. Ninu iwe rẹ̀ Shepherd, tabi Pastor, ó ha sọ ohunkohun ti o lè ṣamọna ẹnikan lati gbagbọ pe ó mọ Ọlọrun lati jẹ́ Mẹtalọkan bi? Ṣakiyesi awọn apẹẹrẹ diẹ nipa ohun ti ó sọ:
“Bẹẹ ni kii ṣe igba ti eniyan bá daniyan pe ki ẹmi sọrọ ni Ẹmi Mímọ́ ń sọrọ, ṣugbọn ó ń sọrọ kiki nigba ti Ọlọrun bá daniyan pe ki o sọrọ. . . . Ọlọrun gbin ọgbà àjàrà, iyẹn ni lati sọ pe, Ó dá awọn eniyan, ó sì fi wọn fun Ọmọkunrin Rẹ̀; Ọmọkunrin sì yan awọn angẹli Rẹ̀ sipo lori wọn lati maa ṣọ́ wọn.”19
“Ọmọkunrin Ọlọrun dagba ju gbogbo iṣẹda rẹ̀ lọ.”20
Nihin-in Hermas sọ pe nigba ti Ọlọrun (kii wulẹ ṣe Baba) bá daniyan ki ẹmi sọrọ, ó ń sọrọ, ni fifi ipo ajulọ Ọlọrun lori ẹmi han. Ó sì sọ pe Ọlọrun fi ọgbà àjàrà fun Ọmọkunrin rẹ̀, ni fifi ipo ajulọ Ọlọrun lori Ọmọkunrin han. Oun tun sọ pe Ọmọkunrin Ọlọrun dagba ju awọn iṣẹda, Ọmọkunrin, rẹ̀ iyẹn ni pe, awọn wọnni ti Ọmọkunrin Ọlọrun dá gẹgẹ bi Ọga Oṣiṣẹ Ọlọrun, “nitori ninu rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ohun ti ń bẹ ni ọrun, ati ohun ti ń bẹ ni ayé.” (Kolose 1:15, 16) Otitọ naa ni pe Ọmọkunrin kii ṣe ayeraye. Oun ni a dá gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi onipo giga kan, ṣaaju awọn ẹ̀dá ẹmi miiran, iru bii awọn angẹli, ti a dá nipasẹ rẹ̀.
Ninu iwe rẹ̀ Early Christian Doctrines, J. N. D. Kelly kọwe nipa oju iwoye Hermas nipa Ọmọkunrin Ọlọrun pe:
“Ninu ọpọ àyọkà a kà nipa angẹli kan ti o ga ju awọn angẹli mẹfa ti ó papọ jẹ́ igbimọ inu lọhun-un ti Ọlọrun, ti a sì saba ń ṣapejuwe gẹgẹ bi ‘ẹni àkúnlẹ̀bọ julọ’, ‘mímọ́’, ati ‘ologo’. Angẹli yii ni a fun ni orukọ naa Maikẹli, ipari ero naa sì ṣoro yẹra fun pe Hermas ri i ni Ọmọkunrin Ọlọrun ó sì mu un dọgba pẹlu Maikẹli olori angẹli naa.”
“Ẹ̀rí tun wa pẹlu . . . niti igbidanwo lati tumọ Kristi gẹgẹ bi iru angẹli giga julọ kan . . . Niti ẹkọ Mẹtalọkan ní itumọ pọnbele kò si ami kankan nitootọ.”21
Papias ni a tun sọ pe o mọ apọsiteli Johanu. Ó ṣeeṣe pe ó kọwe ni ibẹrẹ ọrundun keji, ṣugbọn kiki àjákù awọn iwe rẹ̀ ni ó wà lonii. Ninu wọn kò sọ ohunkohun nipa ẹkọ Mẹtalọkan.
Ẹkọ Ti Ó Ṣe Deedee Délẹ̀
Niti ọran ipo giga julọ ti Ọlọrun ati ibatan rẹ̀ pẹlu Jesu, ẹkọ Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli ni ó ṣe deedee pẹlu ẹkọ Jesu, awọn ọmọ-ẹhin, ati awọn apọsiteli dáadáa, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli. Gbogbo wọn sọrọ nipa Ọlọrun, kii ṣe bii Mẹtalọkan kan, ṣugbọn bii Olùwà ọ̀tọ̀, ayeraye, olodumare, ti ó mọ ohun gbogbo. Wọn si sọrọ nipa Ọmọkunrin Ọlọrun gẹgẹ bii ẹ̀dá ẹmi ọ̀tọ̀, rirẹlẹ jù, ọmọ abẹ́ ti Ọlọrun dá lati ṣiṣẹsin In ni ṣiṣaṣepari ifẹ-inu Rẹ̀. Ẹmi mímọ́ ni a kò si fikun un nibikibi gẹgẹ bi alabaadọgba Ọlọrun.
Nipa bayii, ninu ikọwe Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli ni igbẹhin ọrundun kìn-ín-ní ati ibẹrẹ ọrundun keji wọnni, kò sí itilẹhin kankan fun Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu. Wọn sọrọ nipa Ọlọrun, Jesu, ati ẹmi mímọ́ gan-an gẹgẹ bi Bibeli ti ṣe. Fun apẹẹrẹ, wo Iṣe 7:55, 56:
“Sitefanu, ti o kun fun Ẹmi Mímọ́, bojuwo ọrun ó sì ri ogo Ọlọrun, ati Jesu ti ń duro ni ọwọ ọ̀tún Ọlọrun. ‘Mo lè ri ọrun ti a ṣí gbayawu,’ ni ó wí, ‘ati Ọmọkunrin Eniyan ti ń duro ni ọwọ ọtun Ọlọrun.’”—Jerusalem Bible ti Katoliki (Gẹẹsi).
Sitefanu rí iran Ọlọrun ní ọrun tí Jesu ń duro lẹgbẹẹ Rẹ̀. Ọmọkunrin naa duro lẹgbẹẹ Ẹni naa ti a pè ní, kii wulẹ ṣe “Baba” nikan, ṣugbọn “Ọlọrun,” ẹnikan ti o yatọ patapata ni ìdámọ̀ si Jesu. Kò sì sí ẹnikẹta kankan ti ó wà ninu ohun ti Sitefanu rí. Ẹmi mímọ́ ni a kò ri ni ọrun pẹlu Jesu ati Baba.
Iyẹn ri bakan naa pẹlu Iṣipaya 1:1, eyi ti o sọ pe: “Eyi ni iṣipaya ti Ọlọrun fifun Jesu Kristi.” (The Jerusalem Bible) Lẹẹkan sii, Kristi ti a ji dide ni a fihan ni ọrun pe ó jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ patapata si Ọlọrun, ẹmi mímọ́ ni a kò si mẹnukan. Bi Jesu ba nilati jẹ́ ẹnikeji Mẹtalọkan, ti ó mọ ohun gbogbo, bawo ni a ṣe lè “fi” iṣipaya kan “fun” un?
Iwe mimọ bii iru iwọnyi fihan kedere pe kò si Mẹtalọkan. Kò sì sí ẹsẹ iwe mimọ kankan ninu odindi Bibeli ti o sọ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti o jẹ́ Mẹtalọkan. Iwe Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli fi eyi han. Ó daju hán-unhán-un pe wọn kò fi Mẹtalọkan Kristẹndọmu kọni.
Awujọ pataki miiran ti awọn iwe lori isin Kristẹni dé lẹhin naa ni ọrundun keji. Iwọnyi ni iwe awọn ọkunrin ṣọọṣi ti a pe ni awọn agbeja igbagbọ. Wọn ha fi Mẹtalọkan kọni bi? Ninu itẹjade ọjọ iwaju kan, Apa Kẹta ninu ọ̀wọ́ yii yoo sọrọ lori awọn ẹkọ wọn.
Awọn itọka:
1. The New Encyclopædia Britannica, Itẹjade Kẹẹdogun, 1985, Micropædia, Idipọ 1, oju-iwe 488.
2. A Dictionary of Christian Theology, ti a tunṣe lati ọwọ Alan Richardson, 1969, oju-iwe 95; The New Encyclopædia Britannica, Itẹjade Kẹẹdogun, 1985, Micropædia, Idipọ 4, oju-iwe 79.
3. The Apostolic Fathers, Idipọ 3, lati ọwọ Robert A. Kraft, 1965, oju-iwe 163.
4. Ibid., oju-iwe 166 si 167.
5. The Influence of Greek Ideas on Christianity, lati ọwọ Edwin Hatch, 1957, oju-iwe 252.
6. The Ante-Nicene Fathers, Alexander Roberts ati James Donaldson, awọn oluyẹwoṣatunṣe, Àtúntẹ̀ Ẹ̀dà Itẹjade Edinburgh ti America, 1885, Idipọ Kìn-ín-ní, oju-iwe 5, 16, 21.
7. The Library of Christian Classics, Idipọ 1, Awọn Baba Kristẹni Ijimiji, ti a tumọ ti a sì tẹ̀ lati ọwọ Cyril C. Richardson, 1953, oju-iwe 70 si 71.
8. Ibid., oju-iwe 60.
9. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ Kìn-ín-ní, oju-iwe 52.
10. Ibid., oju-iwe 58.
11. Ibid., oju-iwe 62.
12. Ibid., oju-iwe 108.
13. Ibid., oju-iwe 116.
14. Ibid., oju-iwe 53.
15. The Apostolic Fathers, Idipọ 4, lati ọwọ Robert M. Grant, 1966, oju-iwe 63.
16. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ Kìn-ín-ní, oju-iwe 46 si 47; Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, lati ọwọ John McClintock ati James Strong, ti a túntẹ̀ lati ọwọ Baker Book House Co., 1981, Idipọ Kẹrin, oju-iwe 490 si 493; The Catholic Encyclopedia, 1910, Idipọ Keje, oju-iwe 644 si 647.
17. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ Kìn-ín-ní, oju-iwe 35.
18. Ibid., oju-iwe 33.
19. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ Keji, oju-iwe 27, 35.
20. The Apostolic Fathers (Loeb’s Classical Library) pẹlu Itumọ èdè Gẹẹsi lati ọwọ Kirsopp Lake, 1976, oju-iwe 249.
21. Early Christian Doctrines, lati ọwọ J. N. D. Kelly, Itẹjade Keji, 1960, oju-iwe 94 si 95.