Lilepa Gongo Kan Ti Mo Ti Gbekalẹ Ní Ọmọ Ọdun Mẹfa
GẸGẸ BI SANDRA COWAN TI SỌ Ọ
Ọpọlọpọ awọn obi yan iṣẹ igbesi-aye kan fun awọn ọmọ wọn, iru bii orin kikọ tabi eré ballet, wọn sì bẹrẹ sii dá wọn lẹkọọ lati kutukutu ayé wọn gan-an. Eyi gan-an ní wẹ́kú ni ohun ti mama mi ṣe fun mi. Lati igba ti mo ti jẹ́ ọmọ ọsẹ meji, ni a ti ń mú mi lọ si gbogbo awọn ipade Kristẹni ati jade lọ sinu iṣẹ-ojiṣẹ pápá.
NIGBA TI mo jẹ ọmọ ọdun mẹrin, Mama mi ronu pe mo ti ṣetan lati waasu funraami. Mo ranti igbidanwo mi akọkọ daadaa. A ti wa ọkọ dé iwaju abúléko kan, nigba ti Mama mi ati awọn miiran duro ninu ọkọ ayọkẹlẹ, mo jade mo sì rin lọ sẹnu ọna. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obinrin oninuure kan fetisilẹ nigba ti mo fi iwe pẹlẹbẹ mẹwaa lọ̀ ọ́. Lati sanwo wọn fun mi, ó fun mi ni ọṣẹ gbọọrọ titobi kan. Ọwọ mi mejeeji ni mo lè fi gbé e. Mo yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀!
Ni ọdun yẹn kan naa, 1943, Watchtower Bible School of Gilead ṣí ilẹkun rẹ̀ fun dídá awọn ojiṣẹ aṣaaju-ọna alakooko kikun lẹkọọ fun iṣẹ ijihin-iṣẹ-Ọlọrun. Mama mi fun mi niṣiiri lati fi iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣe gongo mi ninu igbesi-aye. Ogun Agbaye Keji ń lọ lọwọ nigba naa ni Europe, Mama mi yoo sì sọ fun mi nipa awọn ọmọ Ẹlẹ́rìí ni Europe ti a mú kuro lọdọ awọn obi wọn. Ó fẹ́ ki n ní agbara ti o tó lati dojukọ iru idanwo eyikeyii.
Ni ìgbà ẹ̀rùn 1946, mo ṣe bamtisi ni apejọpọ jakejado awọn orilẹ-ede ni Cleveland, Ohio. Bi o tilẹ jẹ pe mo jẹ́ ọmọ ọdun mẹfa péré, mo pinnu lati mu iyasimimọ mi si Jehofa ṣẹ. Ni ìgbà iruwe yẹn mo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan fun ìgbà akọkọ. Mo ranti àárọ̀ ọjọ kan ti mo fi 40 iwe irohin sode lọdọ awọn eniyan ti wọn jokoo nibi Awọn Búkà itaja ni San Diegc, California. Ó dá mi loju, pe jijẹ ọmọde pínníṣín mi ati sọrọsọrọ ni ohun pupọ lati ṣe pẹlu rẹ̀.
Niye igba a waasu lẹbaa Beth–Sarim, ti o jẹ ibi ti aarẹ Watch Tower Society, Arakunrin Rutherford ti araarẹ kò dá, ti lo ìgbà otutu ṣaaju iku rẹ̀ ni 1942. A ṣebẹwo deedee a sì jẹun pẹlu awọn iranṣẹ alakooko kikun nibẹ. Iru awọn ibẹwo alayọ bẹẹ mu mi pinnu pe eyi gan-an nitootọ ni iru igbesi-aye ti mo fẹ́. Nigba naa mo fi Ile-ẹkọ Gilead ati iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣe gongo mi ninu igbesi-aye.
Ni ọdun ti o tẹle e awọn obi mi kọ araawọn silẹ, ṣugbọn ipo idile ti o yipada naa kò bomi pa ina ipo tẹmi wa. Mama mi jẹ́ aṣaaju-ọna kan ó sì daniyan nipa idanilẹkọọ tí arakunrin mi ati emi gba. Ilé àgbérìn kekere wa jẹ́ ibi idunnu pẹlu ibẹwo awọn arakunrin ati arabinrin Kristẹni. Mama mi ṣe isapa akanṣe lati jẹ́ ki n pade awọn akẹkọọyege Gilead. Meji iru awọn akẹkọọyege bẹẹ ni Lloyd ati Melba Barry, ti wọn ń ṣebẹwo ninu iṣẹ irin-ajo nigba ti wọn ń duro de iṣẹ ayanfunni ilẹ ajeji wọn ni Japan. Wọn lo akoko lati fun mi niṣiiri—ọdọmọbinrin kan ti o yánhànhàn lati di ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan—iyẹn sì wú mi lori niti tootọ.
Nigba ti mo jẹ́ ọmọ ọdun mẹwaa, Mama mi fẹ́ Ẹlẹ́rìí agbayanu kan ti oun pẹlu jẹ́ ojiṣẹ aṣaaju-ọna kan. Ó gba arakunrin mi ati emi ṣọmọ kii ṣe kiki lori iwe ṣugbọn ninu ọkan-aya rẹ̀ pẹlu. Ifẹ rẹ̀ fun Jehofa ati itara fun iṣẹ-isin jẹ́ eyi ti ń ranni gan-an.
Mama ati Baba mi ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi ẹgbẹ́ lati tọ́ awa mejeeji ti a jẹ́ ọmọ sọna la awọn ọdun ọdọlangba ti o ṣoro já. Ile wa jẹ èbúté tẹmi ti mo ń bojuwẹhin wò tifẹtifẹ. Fun wọn lati ṣe aṣaaju-ọna lori owo taṣẹrẹ ti ń wọle nigba ti wọn ń tọ́ awa ọmọ meji kò rọrun; o gba ifara-ẹni-rubọ. Ṣugbọn Mama ati Baba mi gbarale Jehofa wọn sì fi ire Ijọba ṣe akọkọ.
Mo ti ranti apejọpọ jakejado awọn orilẹ-ede ni New York City ni 1950 daradara tó! Baba mi gba ẹ̀yáwó kan lati banki, a sì gbé awọn ero mẹta lati ṣeranwọ ninu inawo naa. Mama, Baba, arakunrin mi, ati emi jokoo papọ ni ijokoo iwaju lati San Diego si New York, nigba ti awọn ti o kù jokoo ni ẹhin. Nitori pe agbanisiṣẹ Baba mi kọ̀ lati fun un ni isinmi ọsẹ meji lẹnu iṣẹ, lilọ si apejọpọ yẹn mú ki o padanu iṣẹ rẹ̀. Ṣugbọn gẹgẹ bi Baba mi ti mú un dá wa loju, Jehofa yoo pese fun awọn aini wa, Ó sì ṣe bẹẹ. Baba ta ọkọ ayọkẹlẹ lati san ẹ̀yáwó banki pada, ó sì gba iṣẹ didara ju kan. Eyi ati awọn iriri ti o farajọ ọ ṣeyebiye pupọpupọ fun mi ni awọn ọdun lẹhin naa nigba ti ọkọ mi ati emi dojukọ awọn ipo ṣiṣoro.
Ni irin-ajo wa pada lati New York, a ṣebẹwo si Kingdom Farm, nibi ti mo ti ri Ile-ẹkọ Gilead fun igba akọkọ. Mo ranti diduro ninu ọ̀kan lara awọn yàrá ìkàwé naa ti mo sì sọ fun araami pe, ‘Emi kò tíì pe ọmọ ọdun 11 tán. Emi kò ni lè wa síhìn-ín lae. Amagẹdọni ni yoo kọkọ dé.’ Ṣugbọn ibẹwo yẹn mu mi tubọ pinnu sii ju ti igbakigba ri lọ lati fi Gilead ṣe gongo mi.
Ṣiṣiṣẹ Siha Gongo Mi
Ni gbogbo isinmi ìgbà ẹ̀rùn jalẹ ile-ẹkọ, lati kilaasi akọkọ lọ, mo ṣe aṣaaju-ọna. Lẹhin naa, ni ọsẹ meji lẹhin jijade kuro ni ile-ẹkọ giga ni June 1957, mo di aṣaaju-ọna deedee.
Ipade apejọpọ agbegbe fún awọn wọnni ti wọn nifẹẹ ninu Gilead tí a ṣe ni apejọpọ Los Angeles ni 1957 jẹ́ akanṣe kan fun mi. Bi mo ti ń rin lọ sinu àtíbàbà fun ipade yẹn, mo pade Bill, arakunrin ọdọ kan ti mo ti mọ lati ìgbà ti mo ti jẹ́ ọmọ ọdun mẹfa. Ni gbogbo ọdun ti o ti kọja, ó ti lọ ni ṣiṣiṣẹsin nibi ti aini ti pọ ju ni Louisiana. Ó yà wá lẹnu lati ṣawari bi awa mejeeji ti nifẹẹ ninu iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun tó. Oṣu mẹfa lẹhin naa a pinnu lati ṣe idawọle ajumọṣe kan. A kọwe si Society ni bibeere fun iṣẹ ayanfunni kan ati ni oṣu kan ṣaaju igbeyawo wa, a gba ọ̀kan ni Romney, West Virginia.
A ṣí lọ si ibẹ ni oju ọna wa lọ si apejọpọ New York ni 1958. Nigba ti a wà ni apejọpọ yẹn, a lọ si ipade fun awọn wọnni ti wọn nifẹẹ ninu Gilead. Ọgọrọọrun wà nibẹ. Ni wíwo ogunlọgọ yẹn, a nimọlara pe ireti wa fun jíjẹ́ ẹni ti a pe si Gilead kere pupọ gan-an. Sibẹ, a fi iwe iwọṣẹ akọkọ ṣọwọ́, ani bi o tilẹ jẹ pe a ti ṣegbeyawo fun kiki ọsẹ 11. Ni ọdun ti o tẹle ni apejọpọ agbegbe ni Philadelphia, a kọ ọrọ kún iwe iwọṣẹ ni ìgbà keji.
Bill ati emi kẹkọọ ni Romney lati gbarale Jehofa lati ran wa lọwọ la awọn ipo iṣoro já. Romney jẹ́ ilu kan ti o ni nǹkan bii 2,000 awọn eniyan olugbe. Iṣẹ ṣoro lati rí. A gbé ninu ilé àgbérìn ti a gbéléṣe ẹlẹsẹ bata 16 ti a pilẹṣe fun oju-ọjọ California. A kò ni omi ẹ̀rọ, kò si ìmúlé gbóná, kò sì sí ẹ̀rọ amóhun tutù. Ó tutù ninu ile debi pe a nilati fọ́ yìnyín ti o wà ninu garawa lati ri omi. Awọn ará ran wa lọwọ lọpọlọpọ gẹgẹ bi wọn ti lè ṣe tó, ni ṣiṣajọpin ounjẹ ti wọn ti gbiyanju lati rí. A jẹ àgbọ̀nrín, ẹran raccoon, ati ọ̀kẹ́rẹ́. Ni eyi ti o ju igba kanṣoṣo lọ a ronu pe awa ki yoo ri ohunkohun jẹ fun ọjọ naa, ati lẹhin naa nigba ti a bá dé ile lati ẹnu iṣẹ-isin, awa yoo rí awọn eso ápù tabi wàràkàṣì diẹ ni ẹnu ọna wa. A tiraka fun oṣu mẹsan-an pẹlu owó taṣẹrẹ ti ó fẹrẹẹ má tòóná lati igba dé igba. Nikẹhin, a pinnu pe yoo ba ọgbọn mu lati ṣí lọ si Baltimore, Maryland, nibi ti Bill ati emi ti lè ri iṣẹ. Nigba ti a sọ fun awọn ará nipa ipinnu wa, wọn sunkun awa naa sì sunkun. Nitori naa a pinnu lati wulẹ foriti i fun ìgbà diẹ sii.
Ni gẹ́lẹ́ lẹhin igba yẹn Ẹlẹ́rìí kan ti o jẹ alaboojuto ile itaja mú-un-fúnraàrẹ ni Westernport, Maryland, nǹkan ti o jinna tó 40 ibusọ, fun Bill ni iṣẹ àbọ̀ṣẹ́ kan. Ni oṣu kan naa ọ̀kan lara awọn akẹkọọ Bibeli wa fun wa ni ile kekere mèremère kan ti a ti ṣe aga ijokoo si ti o ni ibi ìdáná eleedu ńlá. Ìgbà yẹn ni Malaki 3:10 di ẹsẹ iwe mímọ́ ti mo yàn laayo. Jehofa ti tú ibukun sori wa rekọja awọn ohun ti a reti.
Gilead Nigbẹhingbẹhin!
Ọ̀kan lara awọn ọjọ ti o muni layọ julọ fun wa ni ọjọ naa, ni November 1959, nigba ti a gba ikesini lọ si Gilead. A pè wá sí kilaasi ikarundinlogoji, eyi ti a ṣe kẹhin ni Kingdom Farm. Nigba ti mo duro ninu yàrá ìkàwé kan naa ti mo ti ṣebẹwo si nigba ti mo jẹ ọmọde, mo ni imọlara ọlọyaya, ati onidunnu ti ọrọ kò lè ṣapejuwe daradara.
Gilead jẹ́ ibi omi ninu aṣalẹ nipa tẹmi. Ó dabi gbigbe ninu ayé titun fun oṣu marun-un. Ó ṣọwọn ninu igbesi-aye ki a duro fun ọpọ ọdun fun ohun kan ki a sì rí i pe ó dara ju bi a ti reti rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bẹẹ gan-an ni Gilead rí.
A yàn wa si India, ṣugbọn lẹhin-ọ-rẹhin a fi iwe iwọle si orilẹ-ede miiran dù wá. Nitori naa lẹhin ọdun kan ti a ti ń duro ni New York City, Watch Tower Society tun wa yàn si Morocco, Ariwa Africa.
Awọn Ojihin-Iṣẹ-Ọlọrun ni Morocco
A lo ọdun alayọ 24 ni Morocco, a bẹrẹ sii nifẹẹ awọn eniyan naa ni gbàrà ti a dé ibẹ. A kẹkọọ èdè French ati Spanish, eyi ti o ran wa lọwọ lati jumọsọrọpọ pẹlu ọpọlọpọ awọn ara orilẹ-ede ti ń gbé nibẹ. Ọpọ julọ ninu awọn wọnni ti wọn ti wá lati orilẹ-ede miiran ni wọn dahun pada si ihin-iṣẹ Ijọba naa.
Obinrin kan ti mo bá kẹkọọ Bibeli jẹ́ oníjó flamenco ti Spain tí awọn ile ounjẹ afijódánilárayá gbà siṣẹ ni Casablanca. Lẹhin mímọ awọn ilana Bibeli, ó fi olootu awọn ile ounjẹ afijódánilárayá ti o ti ń bá gbé silẹ ó sì pada si Spain. Nibẹ ni o ti jẹrii fun gbogbo awọn ti o wà ninu idile rẹ̀, ti awọn diẹ ninu wọn sì tẹwọgba otitọ Bibeli ti o ṣajọpin pẹlu wọn. Lẹhin naa ó pada si Casablanca, nibi ti o duro ni oluṣotitọ si Ọlọrun titi di ìgbà iku rẹ̀ ni 1990.
Iwọnba awọn ọdun diẹ wa akọkọ ni Morocco ri awọn ibisi ninu iye awọn akede Ijọba. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti o ṣoro fun awọn ajeji lati ri iwe ifọwọsi iṣẹ ati ilé gbígbé gbà, ìṣílọ Awọn Ẹlẹ́rìí si Europe wà. Diẹ lara awọn ti a bá ṣe ikẹkọọ wà ni New Zealand, Canada, United States, Bulgaria, Russia, ati France nisinsinyi, ti diẹ ninu wọn sì ń ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun.
Lojiji, ni April 1973 iṣẹ iwaasu wa ni Morocco ni a fofin dè. Iru àjálù wo ni iyẹn jẹ́! Ni irọlẹ ọjọ Thursday kan, gbogbo wa ti a pọ̀ niye ti fi ayọ wà ninu Gbọngan Ijọba, a ń sọrọ titi di ìgbà ti a pa ina lati jẹ ki a mọ̀ pe akoko ti tó lati lọ si ile. A kò mọ pe awa ki yoo tun rí awọn imọlẹ wọnni ti ń tàn sori idapọ Kristẹni ni gbangba bẹẹ mọ́. Labẹ awọn ipo ifofinde, awọn ipade ati apejọ ayika wa ni a fimọ si awujọ kekere ninu ile àdáni. Lati lọ si awọn apejọpọ agbegbe, Awọn Ẹlẹ́rìí yoo ririn-ajo lọ si France tabi Spain.
Bi iye wa ti ń pọ sii, iwọnba Awọn Ẹlẹ́rìí ti o kù ni Morocco sopọ mọra pẹkipẹki gan-an mọ araawọn. Nitori naa nigba ti Watch Tower Society pinnu nikẹhin lati ti ẹka ọfiisi naa pa ati lati yàn wa si ibomiran, gbogbo wa da ọpọlọpọ omije loju.
Lọ si Central Africa
Ibi ayanfunni wa titun jẹ́ Central African Republic. Iyatọ ńláǹlà wo ni o jẹ́ si North Africa! Nigba ti o jẹ́ pe Morocco ni ipo oju-ọjọ ti o farajọ ti guusu California daadaa, a wá bá araawa ninu ilẹ olooru gbigbona, ti o lọ́rinrin nisinsinyi.
Awọn iṣoro titun wà lati dojukọ. Fun apẹẹrẹ, mo nilati káwọ́ ibẹru mi fun kokoro ìrẹ̀ ti ń fà. Ni ìgbà mẹta aláǹgbá jabọ lé mi lori bi mo ti ń rin gba oju ẹnu-ọna kan kọja. Ni ìgbà miiran kan, bi mo ti ń dari ikẹkọọ Bibeli, eku kan yoo pinnu lati darapọ mọ wa! Bi o tilẹ jẹ pe mo fẹ lati bẹ́ ki n sì salọ, mo kẹkọọ lati kó araami nijaanu, laigbe oju mi kuro lara Ọ́gbẹni Eku ati gbigbe apo iwe ati ẹsẹ mi kuro ni ilẹ titi yoo fi pinnu lati lọ kuro. Mo ri i pe ohunkohun lè mọ ọ lara bi iwọ bá wulẹ tẹra mọ ọn.
Nigba ti a ti wà ni ibẹ fun oṣu mẹfa, ikede kan ni a ṣe lori redio pe iṣẹ wa ni a fofinde. Nitori naa awọn Gbọngan Ijọba wa ni a tì pa, a sì sọ fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lati fi ilu silẹ. Awa nikan ati tọkọtaya miiran ni o lè wà ninu ẹka ọfiisi naa fun ọdun mẹta sii. Lẹhin naa ni owurọ ọjọ Sunday kan lakooko Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà wa, ọlọpaa ti o di ihamọra mu wa lọ si orile-iṣẹ ọlọpaa. Wọn dá awọn obinrin ati ọmọde silẹ, ṣugbọn wọn dá awọn arakunrin 23 duro, papọ pẹlu ọkọ mi, Bill. Lẹhin ọjọ mẹfa wọn dá a silẹ lati lọ si ile ki o sì kẹru rẹ̀, ọjọ mẹta lẹhin naa, nipa aṣẹ ijọba, a fi orilẹ-ede naa silẹ, ni May 1989. Ó tun jẹ ilọkuro miiran ti o kun fun omije ni ibudo ọkọ ofuurufu, nibi ti ọpọlọpọ awọn ará wa ti wá juwọ odigbooṣe si wa.
Nikẹhin, si Sierra Leone
Ibi ayanfunni wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ni Sierra Leone, Iwọ-oorun Africa, orilẹ-ede daradara kan ti o ni awọn etikun ẹlẹwa, oniyanrin funfun. Awọn eniyan jẹ ẹni bi ọrẹ gan-an, iṣẹ-isin pápá sì jẹ́ igbadun kan. A ké sí wa lati jokoo ni gbogbo ile, niye igba labẹ ojiji igi máńgòrò tabi igi àgbọn kan. Awọn eniyan fẹran lati sọrọ nipa Ọlọrun ki wọn sì ni ẹ̀dà Bibeli tiwọn lati maa foju baa lọ.
Bill ati emi ń ṣiṣẹ ni Ile Bẹtẹli Freetown. Mo ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi olugbalejo mo sì tun ń ṣiṣẹ pẹlu awọn asansilẹ-owo ati awọn akọsilẹ inawo ijọ. Lẹhin ọdun 16 ti ṣiṣiṣẹsin ni awọn orilẹ-ede ti a ti fofinde iṣẹ wiwaasu wa, ó jẹ́ agbayanu lati wà ni ilẹ ti iṣẹ naa ti wà lominira ti o sì ń laasiki.
Mo pari 30 ọdun iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni June 1991. Loootọ, Mama mi fi gongo ti o yẹ fun isapa si iwaju mi! Bi o bá walaaye sibẹ, emi yoo fẹ lati sọ fun un lẹẹkan sii pe, “Ẹ ṣeun, Mama mi!” Pẹlu ayọ mo lè sọ sibẹ pe: “Ẹ ṣeun, Baba mi!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Apejọpọ New York, 1958
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
35th class—July, 1960
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Bill ati Sandra Cowan, 1991