Iwọ Lè Ri Itunu ni Awọn Akoko Idaamu
OJU wo ni a gbọdọ fi wo awọn imọlara idaamu? Bi a ba ti ṣeyasimimọ fun Jehofa, a ha nilati wò wọn gẹgẹ bi ohun ti o ṣajeji nitori ireti agbayanu wa ati awọn ohun amuṣọrọ wa nipa tẹmi bi? Ǹjẹ́ iru awọn imọlara bẹẹ ha tumọsi pe awa kò yẹ nipa tẹmi fun iṣẹ-isin Ọlọrun bi?
“Eniyan oniru iwa bi awa ni Elijah,” ni ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe. (Jakọbu 5:17) Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun lo Elijah lọna kan ti o ṣàrà-ọ̀tọ̀, ani wolii oluṣotitọ yẹn paapaa nimọlara idaamu. “Ó tó!” ni Elijah polongo ni akoko iṣẹlẹ kan. “Nisinsinyi, Oluwa [“Jehofa,” NW], gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn ju awọn baba mi lọ!” (1 Ọba 19:4) Jobu ọkunrin olupawatitọmọ naa, Hanna obinrin oluṣotitọ naa, ati awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin miiran niriiri idaamu. Ani olorin oniwa-bi-Ọlọrun naa Dafidi gbadura pe: “Ìṣẹ́ aya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi.”—Orin Dafidi 25:17.
Lilo ti Jehofa ń lo awọn ẹda eniyan ninu iṣẹ-isin rẹ̀ ko mu ki wọn jẹ alaini iṣoro ni gbogbo ọ̀nà. Wọn ṣì ni awọn ailera-ara ati imọlara ti ẹda eniyan tí wọn si lè niriiri idaamu nigba ti wọn ba wà labẹ idanwo. (Iṣe 14:15) Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn iranṣẹ Ọlọrun ní iranwọ ti o sàn jù ti awọn ẹlomiran lọ ni kikoju pakanleke ti ero-imọlara. Ẹ jẹ ki a gbe awọn apẹẹrẹ Bibeli diẹ yẹwo lati ri ohun ti awọn ẹnikan ṣe lati bori isorikọ ti ọpọlọ ati imọlara idaamu wọn.
Aposteli ti o ní Idaamu Ri Itunu
Aposteli Paulu mọ̀ bi o ṣe rí lati ní isorikọ. Oun wi pe, “Nitori pe nigba ti awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, . . . ìjà ń bẹ lode, ẹ̀rù ń bẹ ninu. Ṣugbọn ẹni ti ń tu awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa dídé Titu.” (2 Korinti 7:5, 6) Oniruuru awọn ipo ọ̀ràn amunisorikọ ti ń ṣẹlẹ ni akoko kan-naa ni o ń ṣokunfa isorikọ Paulu. “Ìja ń bẹ lode”—inunibini mimuna ń wu iwalaaye funraarẹ lewu. (Fiwe 2 Korinti 1:8.) Siwaju sii, “ẹ̀rù ń bẹ ninu” ni iru ọ̀nà ti idaamu ọkàn nipa awọn ijọ, iru eyi ti o wà ni Korinti.
Ni awọn oṣu diẹ ṣaaju, Paulu ti kọ lẹta rẹ̀ akọkọ si awọn Kristian ni Korinti. Ninu rẹ̀ ó ti dẹbi fun oniruuru awọn ipo buburu ti o wà ninu ijọ naa ati lọna ti o hàn gbangba ó daniyan nipa bi awọn ará Korinti yoo ṣe huwapada si lẹta rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, Paulu ni a tù ninu nigba ti Titu de lati Korinti pẹlu irohin rere nipa ihuwapada wọn. Lọna ti o jọra, Jehofa lè lo ọkàn ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ ode-oni lati mu irohin rere wa fun wa ki o si mu idaamu wa dinku.
Oju Ti O Yẹ Ki A Fi Wo Iṣẹ-Ayanfunni ti Ọlọrun Fifun Wa
Awọn Kristian kan ní idaamu diẹ nipa iṣẹ-ojiṣẹ wọn. Nitootọ, awọn iranṣẹ Jehofa melookan ti ronu pe awọn iṣẹ-ayanfunni ti Ọlọrun fifun wa yoo ti beere ohun pupọ jù lọwọ wọn lati muṣẹ. Fun apẹẹrẹ, Mose nimọlara aitootun lati jẹ aṣoju Ọlọrun fun awọn ọmọ Israeli ni Egipti. Yatọ si awọn nǹkan miiran, o ti sọ pe oun kì í ṣe olubanisọrọ kan ti ọrọ yọ̀ mọ́ lẹnu. (Eksodu 3:11; 4:10) Ṣugbọn pẹlu igbẹkẹle ninu Ọlọrun ati ninu Aaroni gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ̀, Mose bẹrẹ sii mu iṣẹ-ayanfunni rẹ̀ ṣẹ.
Bi akoko ti ń lọ Mose kò tun sinmile Aaroni mọ́. Lọna ti o jọra, awọn melookan ni ibẹrẹ ri iṣẹ-ojiṣẹ Kristian gẹgẹ bi eyi ti o ṣoro, ṣugbọn wọn gba idanilẹkọọ ti wọn si di ọjafafa ajihinrere. Fun apẹẹrẹ, ọpọ awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa ti dàgbà lati di oniwaasu alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ati ojihin-iṣẹ Ọlọrun. O ń tunininu lati mọ̀ pe a lè gbarale Jehofa nigba gbogbo lati mu ki awọn ojiṣẹ Kristian tootun ki o si fun wọn lagbara lati mú iṣẹ-ayanfunni wọn ti Ọlọrun fifunwọn ṣẹ.—Sekariah 4:6; 2 Korinti 2:14-17; Filippi 4:13.
Itunu Nigba ti Àbámọ̀ Ba Ń Danilaamu
A lè bà wá nínújẹ́ nitori pe a kabaamọ pe a kò tíì ṣe pupọ tó ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Arakunrin kan ti o ti jẹ́ alaiṣiṣẹ mọ́ fun ọpọ ọdun bẹrẹ sii ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá lẹẹkan sii. Ni kété lẹhin ìgbà naa, o ṣaisan gidigidi a sì se e mọ́ ori ibusun titilọ. Arakunrin ti ọkàn rẹ̀ rẹwẹsi naa sọ pe: “Ní iṣaaju, nigba ti ó ti yẹ kí ń maa ṣiṣẹ tokuntokun, mo ṣèmẹ́lẹ́ ẹrù-iṣẹ́. Nisinsinyi, nigba ti mo fẹ́ lati gbékánkánṣiṣẹ́, kò ṣeeṣe fun mi.”
Kò ha ni bọgbọnmu lati ṣe ohun ti a lè ṣe julọ nisinsinyi dipo lilo okun èrò imọlara wa lori ohun ti o ti ṣẹlẹ ni ìgbà ti o ti kọja? Jakọbu ati Juda ti wọn jẹ iyekan Jesu nipa ti ara kò di onigbagbọ titi di lẹhin ikú ati ajinde rẹ̀. Bi wọn bá ni ikabaamọ diẹ lori eyi, kò dá wọn duro kuro ninu jíjẹ́ iranṣẹ Ọlọrun ati onkọwe Bibeli paapaa.
Maṣe Ṣainaani Adura
Nigba ti a bá mú wọn sorikọ, awọn eniyan Ọlọrun gbọdọ fi ìgbóná-ọkàn gbadura. Nitootọ, Iwe Mimọ ni ọpọlọpọ adura ti a gbà ni akoko idaamu ninu. (1 Samueli 1:4-20; Orin Dafidi 42:8) Awọn kan lè ronu pe: ‘Isorikọ bá mi debi pe emi kò lè gbadura.’ Nigba naa eeṣe ti o ko fi gbé ọ̀ràn ti Jona yẹwo? Nigba ti ó wà ninu ikùn ẹja, ó sọ pe: “Nigba ti ó rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi sì wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ rẹ. . . . Ṣugbọn emi yoo fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi yoo san ẹ̀jẹ́ ti mo ti jẹ́. Ti Oluwa ni igbala.” (Jona 2:4-9) Bẹẹni, Jona gbadura, Ọlọrun sì tù ú ninu ó sì gbà á là.
Bi o tilẹ jẹ pe arabinrin kan ni Sweden ti jẹ́ aṣaaju-ọna fun ọpọ ọdun, ó nimọlara ibanujẹ ati ìtánlókun lojiji laika iṣẹ-ojiṣẹ ti ń tẹnilọrun si. Ó mẹnukan níní irẹwẹsi ọkàn rẹ̀ ninu adura si Jehofa. Ni ọjọ diẹ lẹhin naa, a gba ikesini ori tẹlifoonu kan lati ọdọ arakunrin kan ni ẹ̀ka ile iṣẹ Watch Tower Society. Ẹni naa beere bi ó bá lè ṣeranlọwọ nibẹ fun nǹkan bi ọsẹ kan ni isopọ pẹlu imugbooro Beteli. Arabinrin yii sọ lẹhin naa pe: “Imọlara ayika ni Beteli ati níní anfaani rírí iṣẹ imugbooro naa ati ṣiṣajọpin ninu rẹ̀ fun mi ni afikun okun ti mo nilo.”
Bi a bá sorikọ, ó dara lati ranti pe adura ni ọ̀nà kan lati fi gbejako ikimọlẹ. (Kolosse 4:2) Ni idahun si awọn adura wa, Jehofa lè ṣí ilẹkun ti ń ṣamọna si igbokegbodo pupọ sii ninu iṣẹ-isin rẹ̀, tabi ó lè bukun iṣẹ-ojiṣẹ wa pẹlu imesojade pupọ sii. (1 Korinti 16:8, 9) Lọnakọna, “ibukun Oluwa [“Jehofa,” NW] ni i mú ni ílà, ki i sìí fi làálàá pẹlu rẹ̀.” (Owe 10:22) Ó daju pe eyi yoo mú ẹmi wa laraya gágá.
O Ha Ni Isorikọ Nipasẹ Iyemeji Bi?
Lẹẹkọọkan, ọ̀kan lara awọn iranṣẹ Jehofa lè ni iyemeji. Bi iyẹn bá nilati ṣẹlẹ si wa, a kò gbọdọ yara pari ero si pe a ti padanu ojurere Ọlọrun. Jesu kò kọ aposteli Tomasi silẹ fun ṣiṣiyemeji awọn irohin ẹni ti ọ̀rọ̀ ṣoju rẹ̀ nipa ajinde Ọga rẹ̀. Kaka bẹẹ, Jesu fi tifẹtifẹ ran Tomasi lọwọ lati bori iyemeji rẹ̀. Ẹ sì wo bi ó ti dùn mọ Tomasi tó nigba ti o mọ daju pe Jesu walaaye!—Johannu 20:24-29.
Nipa ẹ̀kọ́ èké, kíkùn wọn, ati bẹẹ bẹẹ lọ, “awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun” ti wọn ti yọ́ wọnu ijọ Kristian ọrundun kìn-ín-ní ń mú ki awọn kan ní iyemeji ti ń munisorikọ. Fun idi yii, ọmọ-ẹhin naa Juda kọwe pe: “Ẹ maa ba a lọ ni fifi aanu hàn fun awọn kan ti wọn ni iyemeji; ẹ gbà wọn là nipa jíjá wọn gbà kuro ninu iná.” (Juda 3, 4, 16, 22, 23, NW) Lati maa ba a lọ lati rí igbatẹniro alaaanu Ọlọrun gbà, awọn olujọsin ẹlẹgbẹ Juda—ni pataki awọn alagba ijọ—nilati fi aanu hàn fun awọn oniyemeji ti wọn lẹtọọ fun un. (Jakọbu 2:13) Ìyè ainipẹkun wọn wà ninu ewu, nitori pe wọn wà ninu ewu “iná” ti iparun ayeraye. (Fiwe Matteu 18:8, 9; 25:31-33, 41-46.) Ẹ sì wo ayọ ti ó wà nibẹ nigba ti a bá fi inurere ran awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni ti wọn ń ṣiyemeji lọwọ ti wọn si di alagbara nipa tẹmi!
Bi awọn adanwo abanininujẹ bá mú wa ṣiyemeji pe Ọlọrun wà pẹlu wa, a nilati ṣe pàtó ninu awọn adura wa. Labẹ iru awọn ipo ayika bẹẹ, ẹ jẹ ki a foriti i ninu bibeere fun ọgbọ́n lọdọ Jehofa. Oun ń funni lọna ọlọlawọ laisi gígàn wá fun aini ọgbọ́n ti a sì ń gbadura fun un. A gbọdọ ‘maa beere ninu igbagbọ, láláì ṣiyemeji rárá,’ nitori olùṣiyèméjì kan “dabi ìgbì omi òkun, ti ń ti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin tí a sì ń ru soke” ni gbogbo ìhà.” Iru awọn ẹni bẹẹ kìí rí ohunkohun gbà lọdọ Ọlọrun nitori pe wọn jẹ́ alainipinnu “alaiduro sojukan” ninu adura ati ninu gbogbo ọ̀nà wọn. (Jakọbu 1:5-8) Nitori naa ẹ jẹ ki a ní igbagbọ pe Jehofa yoo ràn wa lọwọ lati wo awọn adanwo wa lọna bibojumu ki a sì farada wọn. Awọn iwe mimọ ni a lè mú wá si afiyesi wa nipasẹ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni tabi nigba ikẹkọọ Bibeli. Awọn iṣẹlẹ ti a dari nipasẹ agbara Ọlọrun lè ràn wá lọwọ lati rí ohun ti a gbọdọ ṣe. Awọn angẹli lè ṣajọpin ninu didari wa, tabi a lè gba itọsọna nipasẹ ẹmi mimọ. (Heberu 1:14) Ohun pataki naa ni pe ki a gbadura fun ọgbọ́n pẹlu igbẹkẹle kikun ninu Ọlọrun wa onifẹẹ.—Owe 3:5, 6.
Ranti Pe Jehofa Ń Funni Ni Itunu
Paulu fi taduratadura gbarale Jehofa ó sì mọ̀ ọ́n pe o jẹ́ Orisun itunu. Aposteli naa kọwe pe: “Olubukun ni Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ìyọ́nú, ati Ọlọrun itunu gbogbo; ẹni ti ń tù wá ninu ni gbogbo wahala wa, nipa itunu naa ti a fi ń tu awa tikaraawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o lè maa tu awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.”—2 Korinti 1:3, 4.
Ọlọrun itunu gbogbo mọ̀ nipa idaamu ti awọn iranṣẹ rẹ̀ ń jiya ó sì ń fẹ́ fun wọn ni itura alaafia. Ninu ọ̀ràn aniyan Paulu lori awọn ará Korinti, itura alaafia wá nipasẹ Titu ti o jẹ́ Kristian alabaakẹgbẹ rẹ̀. Eyi jẹ́ ọ̀nà kan ti a lè gbà tù wá ninu lonii. Nigba ti a bá ni idaamu, awa nitori naa gbọdọ yẹra fun mimu araawa dádó. (Owe 18:1) Ibakẹgbẹ pẹlu awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa jẹ́ ọ̀kan ninu awọn ọ̀nà ti Ọlọrun ń gbà tù wá ninu. A lè ronu pe: ‘Ọkàn mi rẹwẹsi tobẹẹ debi pe emi ko lagbara tó lati wà pẹlu awọn ọ̀rẹ́ mi ti wọn jẹ́ Kristian.’ Bi o ti wu ki o ri, a gbọdọ bá iru awọn imọlara bẹẹ jà ki a má sì fi itunu ti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa lè fifun wa du araawa.
Maṣe Jọ̀gọ̀nù!
Awọn kan ninu wa lè má tíì niriiri adanwo ti o ni ipa iyọrisi bẹẹ ti a fi lè sọ pe a ti jiya isorikọ mimuna. Ṣugbọn amodi ti ń sọni di alailera, ikú ẹnikeji ẹni ninu igbeyawo, tabi ipo miiran kan ti ń dánniwò gidigidi lè mú idaamu ti ero-imọlara wá. Bi iyẹn bá nilati wáyé, ẹ maṣe jẹ ki a pari ero si pe a ń ṣaisan nipa tẹmi lọna bàbàrà kan. Ẹnikan ti o sorikọ lè tootun daadaa fun iṣẹ-isin Ọlọrun, ani ki o lè ran awọn ẹlomiran lọwọ nipa tẹmi paapaa. Paulu rọ awọn ará lati “maa sọrọ itunu fun awọn ọkàn ti o sorikọ,” kì í ṣe lati maa ronu lọna ifura pe wọn ti ṣe ohun aitọ kan ti wọn sì ń ṣaisan nipa tẹmi. (1 Tessalonika 5:14, NW) Bi o tilẹ jẹ pe isorikọ nigbamiran ni a ń sopọ mọ iwa-aitọ ati ẹ̀bi, iyẹn kì í ṣe bẹẹ pẹlu awọn wọnni ti wọn ń ṣiṣẹsin Ọlọrun lati inu ọkan-aya mimọgaara. Ijọsin wọn, boya ti wọn ṣe pẹlu iṣoro gan-an, ni ó setẹwọgba fun Jehofa. Ó nifẹẹ wọn ó sì ń ṣe aranṣe fun wọn iranlọwọ ati itunu ti wọn nilo.—Orin Dafidi 121:1-3.
Awọn wọnni ti wọn papọ jẹ́ ti aṣẹku Israeli tẹmi ni awọn idanwo ní ọdun 1918 dalaamu gidigidi. (Fiwe Galatia 6:16.) Eto iwaasu wọn ni a fẹrẹẹ parun, diẹ ninu wọn ni a fi sẹwọn laitọ, ọpọlọpọ ninu awọn alabaakẹgbẹ wọn tẹlẹri sì di alaiduroṣinṣin, awọn apẹhinda ti ń takoni. Ju bẹẹ lọ, awọn ẹni-ami-ororo oluṣotitọ kò loye idi ti Ọlọrun fi yọnda gbogbo eyi lati ṣẹlẹ. Fun akoko kan “wọn fi omije fún irugbin,” ṣugbọn wọn kò jọ̀gọ̀nù. Wọn ń baa lọ ni ṣiṣiṣẹsin Jehofa wọn sì ṣayẹwo araawọn. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Wọn ‘fi ayọ pada wá, wọn sì ru ìtí rẹ̀.’ (Orin Dafidi 126:5, 6) Awọn ẹni-ami-ororo wá mọ̀ nisinsinyi pe Ọlọrun yọnda iru awọn adanwo bẹẹ lati wẹ̀ wọn mọ́ gaara fun iṣẹ ikore wọn jakejado ayé ti ń bọ̀ lọna.
Bi a ba di ẹni ti o sorikọ nitori pe oniruuru adanwo ṣubú lù wa, a lè janfaani lati inu iriri awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo. Dipo jíjọ̀gọ̀nù, ẹ jẹ ki a maa baa lọ ni ṣiṣe ohun ti o tọna, ani bi a bá tilẹ nilati ṣe bẹẹ pẹlu omije. Laipẹ, ọ̀nà abajade kan yoo wà kuro ninu awọn adanwo naa, awa yoo sì ‘fi ayọ pada wa.’ Bẹẹni, ayọ—eso ẹmi mimọ Ọlọrun—yoo jẹ tiwa fun fifarada ti a ti farada awọn adanwo wa. Ó daju pe, Jehofa yoo jásí “Ọlọrun itunu gbogbo” fun wa.