Kọ́ Igbọran Nipa Titẹwọgba Ibawi
FINUWOYE diduro ni gegele apata giga fiofio kan pẹlu imọlara wíwà lori ayé niti gidi. Ẹ wo iru ironu alayọ ti ominira ti eyi jẹ́!
Sibẹ ominira rẹ ni ààlà niti gidi. Ofin oofa-mọlẹ ká irin rẹ kọọkan lọwọko lọna giga; ìṣisẹ̀gbé kanṣoṣo pere lè yọrisi jamba. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, bawo ni o ti gbadunmọni tó lati mọ̀ pe ofin oofa-mọlẹ kan-naa yii ń daabobo ọ kuro lọwọ didi ẹni ti a fà lọ sinu gbangba ojude ofuurufu. Nitori naa, ó ṣe kedere pe ofin naa wà fun ire rẹ. Titẹwọgba ààlà ti o ni lori irin rẹ nibẹ lọhun-un lori oke yẹn ní anfaani, ani ti o lè daabobo iwalaaye.
Bẹẹni, ni awọn ìgbà miiran awọn ofin ati iṣegbọran sí wọn lè pààlà si ominira wa, ṣugbọn eyi ha mu ki igbọran jẹ́ alaiyẹ ni fifẹ́ bi?
Oju Ti Ọlọrun Fi Ń Wo Igbọran
Gẹgẹ bi “Atobilọla Ẹlẹdaa,” Jehofa ni “orisun ìye.” Fun idi yii gbogbo awọn ẹda rẹ̀ jẹ ẹ́ ni gbèsè igbọran lọna títọ́. Ni ṣíṣàṣefihàn iṣarasihuwa ti o tọ́, olorin naa kọwe pe: “Ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: Ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹdaa wa. Nitori oun ni Ọlọrun wa; awa si ni eniyan papa rẹ̀, ati agutan ọwọ́ rẹ̀.”—Oniwasu 12:1, NW; Orin Dafidi 36:9; 95:6, 7.
Lati ibẹrẹ ni Jehofa ti beere igbọran lọwọ awọn ẹ̀dá rẹ̀. Bibaa niṣo lati walaaye Adamu ati Efa ninu Paradise sinmi le igbọran. (Genesisi 2:16, 17) Igbọran ni a reti bakan-naa lati ọ̀dọ̀ awọn angẹli, ani bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ́ iru ẹ̀dá ti o ga ju ti awọn eniyan lọ. Nitori ti awọn kan lara awọn ẹda-ẹmi wọnyi jẹ́ “alaigbọran . . . nigba ti suuru Ọlorun duro pẹ ni saa kan ni ọjọ Noa,” a jẹ wọn niya nipa fifi wọn sinu “ọ̀gbun okunkun biribiri awọn ti a pamọ de idajọ.”—1 Peteru 3:19, 20; 2 Peteru 2:4.
Ni sisọ ọ ni kedere, Ọlọrun wo igbọran gẹgẹ bi ohun abeere-fun lati jere itẹwọgba rẹ̀. A kà pe: “Oluwa ha ni inudidun si ọrẹ sísun ati ẹbọ bii pe ki a gba ohùn Oluwa gbọ? Kiyesii, igbọran sàn ju ẹbọ lọ, ifetisilẹ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.”—1 Samueli 15:22.
A Gbọdọ Kọ́ Igbọran—Eeṣe ati Bawo?
Igbọran ń ṣamọna si iduro olododo pẹlu Ọlọrun, nitori naa bawo ni o ti jẹ́ kanjukanju tó pe ki a kẹkọọ rẹ̀! Bii kíkọ́ ede ajeji kan, iwa igbọran ni a le kọ́ nigba ti a wa ni ọmọde. Idi niyẹn ti Bibeli fi tẹnumọ títọ́ awọn ọmọ lati ìgbà ọmọ-ọwọ.—Joṣua 8:35.
Awọn eniyan ode-iwoyi kan tako oju-iwoye Bibeli naa, ni wiwi pe bibeere igbọran awọn ọmọ ni a le pe ni fifi ipá jà wọn lólè ero-ori. Wọn jiyan pe awọn ọmọ ni a gbọdọ gbà láàyè lati mu ero ara-ẹni tiwọn dagba ati awọn ọpa-idiwọn nipa eyi ti wọn lè fi gbé igbesi-aye laisi ìyọjúràn awọn àgbà nibẹ.
Ṣugbọn ni awọn ọdun 1960 nigba ti ọpọlọpọ awọn obi di oju-iwoye yii mú, Wilhelm Hansen, olukọni, oluyẹwoṣatunṣe-iwe, ati ọjọgbọn ninu ifiṣemọronu-ẹda, takò ó. Ó kọwe pe: “Fun ọmọde kan ni kutukutu ìgbà idagbasoke rẹ̀, ni akoko kan ti ipo ibatan rẹ̀ pẹlu awọn obi rẹ̀ ṣì jẹ́ onipinnu, ‘ibi’ ni ohun ti awọn obi naa kaleewọ ti ‘ire’ si jẹ ohun ti wọn damọran tabi gboriyin fun. Nitori naa igbọran nikan, ni ń tọ́ ọmọ naa sọna iwa-mimọ ati pataki iwa-rere lori eyi ti ipo ibatan rẹ̀ si ilana iwarere sinmi lé.”—Fiwe Owe 22:15.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tẹnumọ aini naa lati kọ́ igbọran. A kà pe: “Emi mọ̀, Óò OLUWA, pe ọ̀nà eniyan kìí ṣe yíyàn tirẹ; bẹẹni kìí ṣe ti eniyan lati pinnu ipa-ọna igbesi-aye rẹ̀.” (Jeremiah 10:23, The New English Bible) Ìtàn ti kún fun awọn apẹẹrẹ nibi ti awọn eniyan ti la ipa-ọna igbesi-aye wọn ni ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn ara-ẹni ti wọn sì ti kowọnu awọn iṣoro wiwuwo nitori ṣiṣe bẹẹ. Eeṣe ti eyi fi sábà maa ń ṣẹlẹ? Nitori eniyan ṣalaini ìmọ̀, ọgbọ́n, ati òye lati la ipa-ọna igbesi-aye wọn laisi iranlọwọ. Eyi ti o tun buru ju iyẹn lọ, wọn ni itẹsi ti wọn ti jogun lati ṣe awọn ipinnu ti o lodi. Kete lẹhin Ikun-omi, Jehofa sọ niti eniyan pe: “Ìrò ọkàn eniyan ibi ni lati ìgbà èwe rẹ̀ wá.”—Genesisi 8:21.
Nitori naa, kò si ẹnikankan ti ó jogun itẹsi lati ṣe igbọran si Jehofa. A nilati gbìn-ín si inu awọn ọmọ wa ki a si maa baa lọ ni kikẹkọọ rẹ̀ jalẹ gbogbo igbesi-aye wa. Ẹnikọọkan ninu wa nilati mú iru ipo ọkan-aya Ọba Dafidi dagba, ẹni ti o kọwe pe: “Fi ọ̀nà rẹ hàn mi Oluwa; kọ́ mi ní ipa tirẹ. Sìn mi ni ọ̀nà otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ ni Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì ni ọjọ gbogbo.”—Orin Dafidi 25:4, 5.
Kọ́ni Ní Igbọran Nipa Jíjẹ Onigbọran
Ìyá Jesu ati baba rẹ̀ ti ó gbà á ṣọmọ mọ awọn ipo ti o rọgba yí ìbí Jesu ká daradara. Nitori naa, wọn mọ̀ pe oun nilati kó ipa pataki ninu mimu awọn ète Jehofa ṣẹ. (Fiwe Luku 1:35, 46, 47.) Ninu ọ̀ràn tiwọn ọ̀rọ̀ naa “Kiyesii awọn ọmọ ni ìní Oluwa” ní itumọ alailẹgbẹ kan. (Orin Dafidi 127:3) Wọn tẹwọgba ẹru-iṣẹ wọn titobi lẹkun-unrẹrẹ a si tipa bẹẹ sún wọn lati ṣegbọran si awọn itọsọna atọrunwa, bii iru ìgbà ti a sọ fun wọn lati sálọ si Egipti tabi lẹhin naa lati lọ si Galili.—Matteu 2:1-23.
Awọn obi Jesu tun mọ ẹru-iṣẹ wọn nipa ibawi. Loootọ, nigba wíwà rẹ̀ ṣaaju jíjẹ́ eniyan, Jesu ti figba gbogbo jẹ́ onigbọran. Ṣugbọn nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé, oun kẹkọọ lati jẹ́ onigbọran labẹ ayika-ipo titun patapata. Fun ohun kan, oun nilati ṣegbọran si awọn obi alaipe nitori pe ọmọ pípé kan paapaa nilo ibawi ni iru ọ̀nà ti itọni ati idanilẹkọọ. Eyi ni awọn obi rẹ̀ si pese. Ibawi niti iru ọ̀nà jijẹniya, ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀ ni kò pọndandan. Jesu figba gbogbo ń ṣegbọran; oun kìí ṣe agbọ́rọ̀ kan lẹẹmeji. A kà pe: “Nigba naa o lọ si ile pẹlu wọn [awọn obi rẹ̀] si Nasareti o si ń ṣegbọran si wọn.”—Luku 2:51, Phillips.
Josefu ati Maria tun mọ bi wọn ṣe lè kọ́ Jesu nipasẹ ọ̀nà apẹẹrẹ. A kà, fun apẹẹrẹ pe: “Awọn obi rẹ̀ a si maa lọ si Jerusalemu ni ọdọọdun si ajọ-irekọja.” (Luku 2:41) Nipa ṣiṣeto lati mú idile rẹ̀ lọwọ lọ, Josefu fihàn pe oun ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ire-alaaafia tẹmi wọn ati pe oun fi ọwọ́ pataki mú ijọsin Jehofa. Ni iru awọn ọ̀nà kan-naa, awọn obi nipa igbọran tiwọn ninu ọ̀ràn ijọsin le kọ́ awọn ọmọ wọn ni igbọran lonii.
Nitori ibawi didara ninu òdodo ni ìhà ọdọ Josefu ati Maria, “Jesu si ń pọ̀ ni ọgbọ́n, o si ń dagba, o si wà ni ojurere ni ọdọ Ọlọrun ati eniyan.” Ẹ wo iru apẹẹrẹ didara ti eyi jẹ́ fun awọn obi Kristian lati tẹle lonii!—Luku 2:52.
‘Igbọran . . . Ninu Ohun Gbogbo’
“Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ́ ti awọn obi yin ni ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa.” (Kolosse 3:20) Jesu le jẹ́ onigbọran si awọn obi rẹ̀ ninu ohun gbogbo nitori pe igbọran wọn si Jehofa ṣedilọwọ fun bibeere lọwọ Jesu—tabi awọn arakunrin ati awọn arabinrin rẹ̀—ohunkohun ti o lodi si ifẹ-inu Jehofa.
Ọpọ awọn obi lonii ń fi aṣeyọrisirere kọ́ awọn ọmọ wọn lati jẹ́ onigbọran ninu ohun gbogbo. Fetisilẹ si awọn baba mẹta, awọn ẹni ti awọn ọjọ títọ́ ọmọ wọn ti di ohun ìtàn, ti wọn si ń ṣiṣẹsin lọwọlọwọ ni ẹ̀ka ile-iṣẹ Watch Tower Society.
Theo sọrọ nipa bi oun ati iyawo rẹ̀ ṣe tọ́ ọmọkunrin marun-un. Ó wi pe: “Ó ṣe pataki lati jẹ́ ki awọn ọmọ mọ̀ lati ibẹrẹ gan-an pe awa ti a jẹ àgbà pẹlu ń ṣe aṣiṣe. Lọna ti o banininujẹ, a tilẹ maa ń tun wọn ṣe paapaa ti a si nilati figba gbogbo beere lọwọ Baba wa ọrun fun idariji ati iranlọwọ. A ń mọọmọ gba awọn ọmọ wa laaye lati rii pe gan-an gẹgẹ bi awọn ti ń jijakadi pẹlu awọn aniyan èwe, awa pẹlu ń jijakadi pẹlu awọn aniyan agba.”
Bi ọmọ kan ba nilati kọ́ igbọran, ipo ibatan onifẹẹ laaarin oun ati awọn obi rẹ̀ ṣekoko. Hermann sọ nipa iyawo rẹ̀ pe: “Kìí ṣe kìkì pe oun jẹ́ ìyá awọn ọmọkunrin naa nikan ni ṣugbọn ọ̀rẹ́ wọn pẹlu. Eyi ni wọn sì mọriri, nipa bẹẹ kò nira fun wọn lati jẹ́ onigbọran.” Lẹhin naa ni fifi imọran wiwulo kan kun un lori mimu ipo ibatan obi-si-ọmọ sunwọn sii, ó wi pe: “A mọọmọ ṣailo ẹrọ ti a fi ń fọ abọ́ fun ọpọ awọn ọdun, ki o baa lè jẹ́ pe awọn abọ́ naa ni a fọwọ́ fọ̀ ti a o si nùgbẹ. Awọn ọmọkunrin wa ni a yàn lati ṣe nínùgbẹ naa, ni ọ̀kan tẹle omiran. Kò si akoko ti o dara ju bẹẹ lọ fun ijumọsọrọpọ ti a kò pete tẹlẹ.”
Ipo ibatan obi-si-ọmọ didara ṣiṣẹ gẹgẹ bi awokọṣe fun ipo ibatan ti Kristian kan gbọdọ ni pẹlu Jehofa. Rudolf ṣalaye bi oun ati iyawo rẹ̀ ti ṣe ran awọn ọmọkunrin wọn meji lọwọ lati ni iru ipo ibatan bẹẹ: “Ipilẹ wa jẹ́ ikẹkọọ idile ti ń lọ deedee. A yan oniruuru awọn akori bibaamu fun awọn ọmọ naa lati ṣe iwadii lé lori. A si ń ṣe Bibeli kíkà wa papọ ti a o si jiroro akojọpọ ọ̀rọ̀ naa pẹlu. Awọn ọmọ wa lè rii pe Jehofa reti igbọran lọdọ awọn obi, kìí ṣe kìkì lọwọ awọn ọmọ nikan.”
Awọn Kristian obi loye pe ọ̀rọ̀ ti a misi naa “Ibawi ẹ̀kọ́ ni ọ̀nà ìyè” ni o kàn wọn ati awọn ọmọ wọn pẹlu. Nipa bẹẹ nigba ti awọn ọmọ ni ẹrù-iṣẹ́ lati ṣe igbọran si awọn obi wọn ninu ohun gbogbo, awọn obi pẹlu gbọdọ ṣe igbọran ninu ohun gbogbo ti Jehofa beere lọwọ wọn. Yatọ si mimu ipo ibatan obi-si-ọmọ lagbara sii, awọn obi ati ọmọ yoo fẹ́ lati mu ipo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun lagbara sii.—Owe 6:23.
Wo Igbọran Lọna Títọ́
Ẹ wo bi a ti kun fun ọpẹ́ tó pe Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pese iru imọran gbigbeṣẹ bẹẹ nipa títọ́ awọn ọmọ! (Wo apoti.) Awọn ọmọ ti wọn kọ́ igbọran lati ọ̀dọ̀ awọn obi ti wọn bá wọn wi ninu òdodo jẹ́ orisun ayọ tootọ fun gbogbo ẹgbẹ́ awọn Kristian ara.
Niwọn bi igbọran si Ọlọrun ti tumọsi ìyè, a gbọdọ yẹra fun rironu nipa ero ti siso ikalọwọko ti ofin Ọlọrun gbekarii ominira ara-ẹni rọ̀—ani fun ìgbà kukuru gan-an. Fun apẹẹrẹ, ronuwoye pe a lè da ofin òòfà duro fun ìgbà kukuru. Bawo ni ayọ wa yoo ti pọ̀ to si idunnu ti fífò lati tente ori oke kan lọ soju sanmọ laisi ohun kan lati dí ominira wa lọwọ! Ṣugbọn ki ni yoo ṣẹlẹ gbàrà ti nǹkan ba pada si bi o ti wà tẹlẹ? Ronu nipa iṣubu ti yoo duro de wa!
Kikẹkọọ igbọran nipa titẹwọgba ibawi ń fikun mimu akopọ-animọ ti o wàdeede ti o si ń ràn wá lọwọ dàgbà lati mọ aala wa. Ó ń ràn wá lọwọ lati yẹra fun fifi dandangbọn beere ati jíjẹ́ alainimọlara si awọn ẹ̀tọ́ ati aini awọn ẹlomiran. Ó ń ràn wá lọwọ lati yẹra fun aidaniloju onigba kukuru. Ni ṣoki, o ń yọrisi ayọ.
Nitori naa, boya iwọ jẹ agbalagba tabi ọmọde, kọ́ igbọran nipa titẹwọgba ibawi “ki o lè dara fun ọ” ati pe “ki iwọ ki o le wà pẹ́ ni ayé.” (Efesu 6:1-3) Ta ni o fẹ́ lati fi ifojusọna rẹ̀ fun wiwalaaye titilae sinu ewu nipa kikuna lati kọ́ igbọran nipa ṣiṣaitẹwọgba ibawi?—Johannu 11:26.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
ẸYIN OBI, Ẹ KỌNI NI IGBỌRAN NIPA BIBANIWI NINU ÒDODO
1. Baniwi lori ipilẹ awọn ofin ati ilana Iwe Mimọ.
2. Baniwi kìí wulẹ ṣe nipa fifi dandangbọn beere igbọran ṣugbọn nipa ṣiṣalaye idi ti igbọran fi jẹ́ ipa-ọna ọgbọ́n—Matteu 11:19b
3. Baniwi kìí ṣe ninu ibinu bẹẹ ni kìí ṣe pẹlu jíjágbemọ́ni.—Efesu 4:31, 32.
4. Baniwi ninu ọ̀yàyà ipo ibatan ti onífẹ̀ẹ́ ati onígẹ̀.—Kolosse 3:21; 1 Tessalonika 2:7, 8; Heberu 12:5-8.
5. Bá awọn ọmọ wi lati ìgbà ọmọ-ọwọ.—2 Timoteu 3:14, 15.
6. Baniwi leralera ati pẹlu iṣedeede.—Deuteronomi 6:6-9; 1 Tessalonika 2:11, 12.
7. Bá araarẹ wí lakọọkọ ki o si tipa bẹẹ kọni nipa apẹẹrẹ.—Johannu 13:15; fiwe Matteu 23:2, 3.
8. Baniwi pẹlu igbọkanle kikun ninu Jehofa, ni bibẹbẹ fun iranlọwọ rẹ̀ ninu adura.—Onidajọ 13:8-10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ibawi ẹ̀kọ́ ni ọ̀nà ìyè”