A Fi “Adé Ìyè” San Èrè fun Un
SI ANGẸLI ijọ ti o wà ni Smirna, ni a sọ fun aposteli Johannu pe ki o kọwe pe: “Ṣe oloootọ de oju ikú, emi ó sì fi adé ìyè fun ọ.” (Ìfihàn 2:8, 10) Nitori naa, ikede naa ti a ń ṣe nihin-in pe Frederick William Franz, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ati Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ati iye awọn ẹgbẹ́ iṣakoso Ọlọrun miiran, pari ipa-ọna igbesi-aye rẹ̀ ti ori ilẹ̀-ayé ni owurọ December 22, 1992, jẹ́ eyi ti o banininujẹ ati eyi ti o kun fun ayọ.
Ó jẹ́ ikede ti o banininujẹ niti pe ó sọ fun wa nipa kikuro loju ìran ilẹ̀-ayé ti iranṣẹ Jehofa ti o jẹ́ ààyò-olùfẹ́ gidigidi ati oluṣotitọ lọna titayọ. Sibẹ, ó tun jẹ́ ikede ti ó kun fun ayọ nitori pe fun Arakunrin Franz wa ọwọn ni awọn ọ̀rọ̀ Ìfihàn 14:13 ṣe fisilo nisinsinyi pe: “[Ayọ ni fun, NW] awọn òkú ti o kú nipa ti Oluwa lati ihin lọ: Bẹẹni, ni ẹmi wí, ki wọn ki o lè sinmi kuro ninu làálàá wọn, nitori iṣẹ wọn ń tọ̀ wọn lẹhin.” Arakunrin Franz jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ati onirẹlẹ, ojiṣẹ alaapọn ati amesojade gan-an ẹni ti Jehofa Ọlọrun lò lọna pupọ jaburata gẹgẹ bi mẹmba “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” lati ṣetilẹhin ninu pipese ounjẹ tẹmi fun “awọn ará-ilé” ati ẹlẹgbẹ wọn.—Matteu 24:45-47, NW.
A bí Arakunrin Franz ni September 12, 1893, ni Covington, Kentucky. Ó bá otitọ pade nipasẹ ẹgbọn rẹ̀ ọkunrin. Ni akoko yẹn ó ń lọ si ile-ẹkọ University of Cincinnati, ni mimurasilẹ lati di ojiṣẹ Ṣọọṣi Presbyterian kan. Dipo eyi, ó yasọtọ kuro lara Ṣọọṣi Presbyterian ó sì darapọ mọ́ awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti ń pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa. Oun ni a baptisi ni November 30, 1913, ati ni ọdun ti o tẹle e ó kuro ni yunifasiti ó sì kowọnu iṣẹ olùpín-ìwé-ìsìn-kiri (aṣaaju-ọna). Ni June 1, 1920, ó di mẹmba idile Beteli ni Brooklyn. Laipẹ-laijinna, oun ni a fi sidii ṣiṣe kòkáárí iwe kíkọ ati awọn akọsilẹ nipa igbokegbodo awọn olùpín-ìwé-ìsìn-kiri, ati ni 1926 a gbé e lọ si ẹ̀ka onkọwe alatun-unṣe, nibi ti o ti ṣiṣẹ lọna ti o mesojade julọ. Ni 1945 ó di igbakeji ààrẹ Watch Tower Society ati awọn ẹgbẹ miiran ti o tanmọ ọn. Bi ààrẹ ìgbà naa Nathan H. Knorr ti kú ni 1977, ó di ààrẹ Watch Tower Society. Ó ṣiṣẹ ni ipo yẹn titi di ìgbà ikú rẹ̀. Lakooko igbesi-aye rẹ̀, Arakunrin Franz rí i ti iye awọn Ẹlẹ́rìí ti Jehofa pọ sii lati ori iwọnba ẹgbẹrun diẹ si iye ti o sunmọ million mẹrin ati ààbọ̀. Ó gbadun ọpọ awọn anfaani iṣẹ-isin, ti o ní ninu sisọrọ ni awọn apejọpọ agbaye ati bibẹ awọn ẹ̀ka ati ile awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wò ni apá ibi pupọ ni ayé. Ìtàn igbesi-aye rẹ̀ farahan ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ti May 1, 1987.
Ni irọlẹ ọjọ Monday, December 28, 1992, ipade-ijọsin iṣe-iranti kan ni a ṣe ninu Gbọngan Ijọba ti Beteli Brooklyn. Ọrọ-asọye ọlọ́yàyà kan ti ó sì gbeniro nipa tẹmi ni Arakunrin Albert D. Schroeder ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọ. Awọn idile Beteli ni Watchtower Farms, Patterson, Mountain Farm, ati Kingdom Farm, ati idile Beteli ti o wà ni ẹ̀ka ti Canada bakan naa ni a sopọ nipasẹ tẹlifoonu.
Gbogbo eniyan, ni pataki awọn wọnni ti wọn ti ṣiṣẹ ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu rẹ̀, yoo ṣàárò Arakunrin Franz gidigidi. Ó jẹ́ olóye, afunniniṣiiri, ati onisuuru si gbogbo awọn ti o bá ṣiṣẹ ti o sì bá rinrin-ajo. Loootọ, awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ huwapada si i ni ibamu pẹlu ọ̀rọ̀ Heberu 13:7 pe: “Ẹ maa ranti awọn ti wọn jẹ́ olori yin, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun yin; ki ẹ maa ro opin ìwà-ayé wọn, ki ẹ sì maa ṣe afarawe igbagbọ wọn.”
Ni December 30, 1992, Arakunrin Milton G. Henschel ni a yàn gẹgẹ bi ààrẹ Society karun-un, lati gbapò Arakunrin Franz.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31, 32]
Frederick W. Franz ni 1913
Ni ile-iṣẹ ẹ̀rọ ti Society ni Myrtle Avenue ni 1920
Pẹlu Nathan H. Knorr ni Yankee Stadium ni 1953