Ṣe Iribọmi! Ṣe Iribọmi! Ṣe Iribọmi!—Ṣugbọn Eeṣe?
“LAAARIN iwọnba oṣu diẹ mo ti baptisi iye ti ó ju ẹgbẹrun mẹwaa awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde.” Bẹẹ ni ojihin-iṣẹ-Ọlọrun onisin Jesuit Francis Xavier kọwe nipa iṣẹ rẹ̀ ninu ijọba Travancore, India. “Mo lọ lati abule de abule mo sì sọ wọn di Kristian. Gbogbo ibi ti mo bá lọ mo ń fi ẹ̀dà kan awọn adura ati ofin wa silẹ ni èdè ibilẹ.”
Bi a ti fà á lọ́kàn mọra lọna giga pẹlu awọn lẹta Francis Xavier, Ọba John ti Portugal paṣẹ pe ki a kà wọn soke ketekete lori gbogbo aga iwaasu jakejado ijọba rẹ̀. Lẹta ti January 1545 ti a ṣẹṣẹ fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tán paapaa ni a tẹwọgba fun itẹjade. Ki ni iyọrisi rẹ̀? “Laipẹ laijinna ìlàjì awọn akẹkọọ ni Europe, ‘ni kikunlẹ lori orukun wọn ati dida omije gbigbona janjan jade,’ fi dandangbọn beere fun lilọ si India ki wọn sì yí awọn abọgibọ̀pẹ̀ lọ́kàn pada,” ni Manfred Barthel kọ ninu iwe rẹ̀ The Jesuits—History & Legend of the Society of Jesus. Ó fikun un pe: “Èrò naa pe ó lè gbà ju awọn olùwọ́n omi-mimọ diẹ ati ẹkúnwọ́ àpò iwe pelebe kan lati yi odidi ijọba lọ́kàn pada kò jọ bi ohun ti ó ti ṣẹlẹ si ọpọlọpọ nigba naa.”
Ki ni ohun ti a ṣaṣepari rẹ̀ niti gidi nipa iru iyilọkan pada gbogbogboo bẹẹ? Onisin Jesuit Nicolas Lancilloto rohin lọna ti ó bá ọgbọn mu fun Romu pe: “Ọpọ julọ ninu awọn wọnni ti a baptisi ní isunniṣe abẹnu diẹ. Ẹrú awọn Larubawa ati awọn Hindu nireti lati jere ominira wọn nipasẹ rẹ̀ tabi lati jere idaabobo kuro lọwọ ọ̀gá atẹniloriba kan tabi lati wulẹ ni ẹ̀wù gbárìyẹ̀ titun tabi láwàní kan. Ọpọ ṣe bẹẹ lati yèbọ́ ninu awọn ijiya kan. . . . Awọn ẹni yoowu ti a bá sún nipasẹ igbagbọ tiwọn funraawọn lati wá igbala ninu awọn ẹkọ wa ni a kà sí ayírí. Ọpọlọpọ di apẹhinda ti wọn sì pada si iṣe ibọriṣa wọn ti tẹlẹ laipẹ si akoko ti a baptisi wọn.”
Ìfẹ́-ọkàn naa lati yí abọgibọ̀pẹ̀ lọ́kàn pada ki a sì baptisi wọn ni awọn olùwádìíyẹ̀wò ará Europe ti sanmani ìgbà naa ṣajọpin pẹlu. A sọ pe Christopher Columbus baptisi “awọn India” akọkọ ti ó bá pade ni Caribbean. “Ilana-eto ọla-aṣẹ ti Ijọba awọn ará Spain fi iyilọkanpada awọn eniyan ibilẹ si ipo akọkọ,” ni The Oxford Illustrated History of Christianity sọ. “Nigba ti ó fi maa di opin ọrundun kẹrindinlogun, 7,000,000 awọn India ti ilẹ-ọba Spain ti di Kristian, ó keretan ni orukọ lasan. Ni ibi ti a ti ní iṣiro awọn iyilọkanpada lọwọ (Pedro de Gante, ibatan Olu-ọba Charles V, ti ó ti darapọ mọ́ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa, sọ nipa bibaptisi 14,000 pẹlu iranlọwọ ẹnikanṣoṣo ni ọjọ kan), ó ṣe kedere pe isọfunni ipilẹ ti ó jamọ pataki ni kò ti ṣeeṣe.” Iru iyilọkanpada eléréfèé bẹẹ ni ibalo onroro, oniwa-ipa, atẹniloriba pẹlu awọn ọmọ ibilẹ naa sábà maa ń tẹle.
Ijẹpataki ti a gbekari iribọmi ru awọn olùwádìíwò ati ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wọnyi lọkan soke siwaju. Ni 1439, Pope Eugenius IV gbé ofin kan jade ni Igbimọ Florence ti ó sọ pe: “Iribọmi mímọ́ mú ipo akọkọ ninu sakramẹnti, nitori pe ó jẹ́ ẹnu-ọna igbesi-aye nipa tẹmi; nitori pe nipa rẹ̀ ni a ń sọ wa di mẹmba Kristi ti a sì ń ní ibatan pẹlu Ṣọọṣi naa. Ati niwọn bi o ti jẹ pe nipasẹ ọkunrin akọkọ iku wọ inu gbogbo eniyan, ayafi ti a bá di atunbi nipa omi ati Ẹmi Mimọ, a kò lè wọnu ijọba Ọrun.”
Ìjà bẹ́ silẹ, bi o ti wu ki o ri, nipa iribọmi ta ni ó tilẹ bá ofin mu. “Nitori pe ó tun jẹ́ lajori ààtò àbáwọnú ẹgbẹ awujọ ṣọọṣi, iribọmi ni a tete gbà gẹgẹ bi ẹ̀tọ́ kan nipa oniruuru awọn ṣọọṣi afigagbaga, eyi ti ọkọọkan ninu wọn pe araarẹ̀ ni onigbagbọ gbogbogboo ti ó sì fẹsun adamọ ati iyapa kan awọn yooku. Awọn iyipada ninu ààtò iribọmi lati ọwọ́ oniruuru ẹ̀yà-ìsìn ni kò ṣeeyẹsilẹ,” ni The Encyclopedia of Religion kọwe.
Bi o ti wu ki o ri, aṣa iribọmi ti wà ṣaaju igbagbọ Kristian. A lò ó ni Babilonia ati ni Egipti igbaani, nibi ti a ti rò pe awọn omi tutu Nile ń funnilokun sii ti ó sì ń funni ni aileeku. Awọn Griki pẹlu gbagbọ pe iribọmi lè mú atunda wá tabi pe ó lè fi isapa mú aileeku wá fun ẹni ti ó nimọ nipa rẹ̀. Ẹ̀ya-ìsìn Ju ní Qumran ń ṣe iribọmi fun itẹwọgbani sinu ẹgbẹ́ awujọ wọn. A bere pe ki a kọ Keferi ti o yipada si isin Ju nílà ki a sì baptisi rẹ̀ ni ọjọ meje lẹhin naa nipa iribọmi niwaju awọn ẹlẹrii.
Lọna ti o ṣe kedere, ijẹpataki pupọ ni a ti gbekari iribọmi la gbogbo ìran já. Ṣugbọn ki ni nipa ti ode-oni? Ó ha ṣe pataki ni akoko ode-oni wọnyi bi? Bi ó bá rí bẹẹ, eeṣe? Niti gidi, a ha nilati baptisi rẹ bi?