Awọn Irisi Iran Lati Ilẹ Ileri
Sinai Oke Mose ati Àánú
NIGBA ti o bá ronu nipa Oke Sinai, o ṣeeṣe ki o ní Mose lọkan. Eeṣe? Nitori pe Mose gba Ofin Ọlọrun lori oke kan ni Ilẹ Sinai tí omi yika. Oke wo? O ṣeeṣe ki o jẹ́ ọ̀kan ti a fihàn loke yii.a
Ni apa iha guusu ilẹ tí omi yika naa, ní nǹkan bi idaji ọ̀nà ibi ti omi ń gbà wọnú Okun Pupa, ni oke téńté kan ti o ni ori ṣonṣo meji wà. Gbogbo awọn aaye agbegbe yii bá awọn iṣẹlẹ Bibeli ti o niiṣe pẹlu Mose mu. Oke ṣonṣo kan ni a ń pe ni Jebel Musa, ti o tumọsi “Oke Mose.”
Oniruuru awọn irohin iṣẹlẹ Bibeli mu ki orukọ yẹn jẹ eyi ti o baa mu wẹku. Iwọ ha ranti pe Mose ń ṣe oluṣọ agutan agbo-ẹran Jetro nigba ti angẹli kan farahan ninu igbó jíjó kan bi? Nibo niyẹn? Bibeli sọ pe o jẹ́ ni ‘oke Ọlọrun, Horebu,’ eyi ti a tun pe ni Oke Sinai. (Eksodu 3:1-10; 1 Ọba 19:8) Lẹhin ti Mose ṣamọna awọn eniyan Ọlọrun jade kuro ni Egipti, o mu wọn wa sihin in. Eksodu 19:2, 3 so pe “nibẹ ni Israeli si dó si niwaju oke naa. Mose si goke tọ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke naa wá.”
Iyẹn jẹ́ ìgbà akọkọ ti Mose gun Oke Sinai, o sì ṣe ju wiwulẹ gun oke naa lọ niwọnba diẹ. A kà pe: “Oluwa si sọkalẹ wa si Oke Sinai, lori oke naa: OLUWA si pe Mose lori oke naa.”—Eksodu 19:20.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn arinrin-ajo ibẹwo ni ọjọ wa yii ti tiraka gun oke kọja awọn ipa-ọna ti a sami si lálẹ́ lati dé otente naa, ni fifẹsẹpalẹ lati wo yíyọ oorun, lẹhin naa ti wọn si ń sọkalẹ nigba ounjẹ ọ̀sán. Kò ri bẹẹ pẹlu Mose. Ọlọrun sọ fun un pe: “Goke tọ mi wá sori oke, ki o si duro nibẹ; emi o sì fi walaa okuta fun ọ, ati àṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ.” Nigba iṣẹlẹ yẹn “Mose sì wà lori oke ni ogoji ọ̀sán ati ogoji òru.”—Eksodu 24:12-18.
Nitori naa ó lè yeni pe orukọ Mose ni a sopọ mọ oke yii, ṣugbọn eeṣe ti o fi jẹ́ pẹlu “aanu”? O dara, bi Mose ti wà loke nibẹ ti o ń gba Ofin naa, awọn eniyan ti o wà ni pẹtẹlẹ nisalẹ (boya ni Pẹtẹlẹ er-Raha ninu aworan naa) gbé igbesẹ omugọ kan. Wọn fipa mu arakunrin Mose lati ṣe ọlọrun kan. Aaroni sọ pe: “Ẹ kán oruka wura ti o wà ni eti . . . ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá.” Nipa bayii wọn ṣe ọmọ maluu oniwura kan fun ijọsin. Eyi bí Ọlọrun otitọ naa ninu ó sì jálẹ̀ si ikú ẹgbẹẹgbẹrun. (Eksodu 32:1-35) Ṣugbọn Aaroni ni a fi àánú hàn si ti a si dariji. Eeṣe?
Alaye Ọlọrun ninu Eksodu 32:10 fihàn pe oun kò wo Aaroni gẹgẹ bi ẹni ti o da iwa aitọ Israeli. Nigba ti akoko iyanju ọ̀rọ̀ si de, “gbogbo awọn ọmọ Lefi” yan iha Ọlọrun, eyi ti o ni Aaroni ninu laiṣiyemeji. (Eksodu 32:26) Nitori naa loju otitọ naa pe Aaroni jẹbi, o rí àánú Ọlọrun gbà ni isalẹ Oke Sinai.
Lẹhin naa, Mose sọ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati mọ Jehofa siwaju sii ati lati ri ogo Rẹ̀ jade. (Eksodu 33:13, 18) Nigba ti o jẹ ohun ti kò ṣeeṣe fun Mose lati rí oju Ọlọrun, Jehofa fi diẹ ninu ògo Rẹ̀ hàn án, ni titẹnumọ ọn pe Oun “ó sì ṣe aanu fun ẹni ti [Oun] o ṣe aanu fun.” (Eksodu 33:17–34:7) Ó jẹ́ ohun ti o baa mu julọ fun Ọlọrun lati tẹnumọ aanu rẹ̀, nitori pe Bibeli lo “aanu” lemọlemọ lọpọ ìgbà ni isopọ pẹlu ibalo Ọlọrun pẹlu Israeli, awọn ti oun mu wa sinu majẹmu ni Sinai.—Orin Dafidi 103:7-13, 18.
Awọn oluṣebẹwo si Oke Sinai lonii rí ile awọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe ni isalẹ rẹ̀, eyi ti o jẹ́ pe agbarakaka ni o fi lè ran wa leti ọ̀kan ninu ijọsin tootọ ti Mose kẹkọọ nipa rẹ̀ lori oke naa. Kaka bẹẹ, isin ninu ile awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe dá lori awọn awọn ère isin. Eyi ti a fihàn nihin-in yii jẹ́ “Àkàbà si Paradise.” A gbe e kari iwe kan lati ọwọ́ ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe ara Byzantine kan John Climacus. Lẹhin lilo nǹkan bii 40 ọdun ninu àhámọ́ ile awọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe, o di mọgaji ile awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe naa ti o si kọwe nipa àkàbà ifiṣapẹẹrẹ kan si ọrun. Ṣugbọn ṣakiyesi pe awọn alufaa-ojiṣẹ melookan ni a yaworan wọn gẹgẹ bi ẹni ti awọn ẹmi eṣu ń fà lọ si ibi idaloro ayeraye ninu iná ọrun-apaadi. O ṣe kedere, ṣugbọn kò bá iwe mimọ mu!—Oniwasu 9:5, 10; Jeremiah 7:31.
Ni ifiwera pẹlu ẹkọ èké yẹn, otitọ naa ni pe Olodumare jẹ́ “Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ.” (Eksodu 34:6) Mose sunmọ Ọlọrun alaaanu yii timọtimọ lori Oke Sinai.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun aworan ti o tubọ tobi sii, wo 1993 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.