Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
“Jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 33:13.
1, 2. (a) Kí nìdí tí Mósè fi ṣe ohun tó ṣe nígbà tó rí i pé ọmọ Íjíbítì kan ń fìyà jẹ Hébérù kan? (b) Kí Mósè tó lè ṣe iṣẹ́ Jèhófà, kí ló yẹ kó mọ̀?
AGBOOLÉ Fáráò ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà. Ọgbọ́n Íjíbítì tó jọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú ibẹ̀ lójú gan-an ni wọ́n sì fi kọ́ ọ. Àmọ́, Mósè mọ̀ pé òun kì í ṣe ọmọ Íjíbítì nítorí pé Hébérù làwọn òbí rẹ̀. Nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogójì ọdún, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tó rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń fìyà jẹ Hébérù kan, kò ṣe bíi pé kò kan òun. Ó lu ọmọ Íjíbítì náà pa. Mósè fara mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì rò pé Ọlọ́run ló ń lo òun láti gba àwọn arákùnrin òun sílẹ̀. (Ìṣe 7:21-25; Hébérù 11:24, 25) Nígbà táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Íjíbítì gbọ́ ohun tí Mósè ṣe yìí, wọ́n kà á sí ọlọ̀tẹ̀, ló bá sá fún ẹ̀mí rẹ̀. (Ẹ́kísódù 2:11-15) Kí Mósè tó lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yóò rán an, ó ní láti túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. Àmọ́, ṣé Mósè á lè kọ́ àwọn ọ̀nà Jèhófà?—Sáàmù 25:9.
2 Ibi tí Mósè sá lọ ló ń gbé ní gbogbo ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló sì ń ṣe níbẹ̀. Dípò kó máa banú jẹ́ nítorí pé àwọn Hébérù bíi tirẹ̀ ò mọyì rẹ̀, ó fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run fàyè gbà pé kó ṣẹlẹ̀ sí òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Mósè fi wà lẹ́yìn odi tí kò sì sẹ́ni tó kà á sí, ó gbà kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn èyí, ó sọ pé: “Ọkùnrin náà Mósè . . . fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Kì í ṣe pé Mósè kàn fẹ́ gbé ara rẹ̀ ga ló ṣe sọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló darí rẹ̀. Àwọn ọ̀nà tó kàmàmà ni Jèhófà gbà lo Mósè. Nítorí náà, bí àwa náà bá sapá láti jẹ́ ọlọ́kàn-tútù, Jèhófà yóò bù kún wa.—Sefanáyà 2:3.
Ọlọ́run Gbéṣẹ́ fún Mósè
3, 4. (a) Iṣẹ́ wo ni Jèhófà rán Mósè? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ran Mósè lọ́wọ́ kó bàa lè ṣe iṣẹ́ tó rán an?
3 Lọ́jọ́ kan, áńgẹ́lì kan tó ń ṣojú fún Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ nítòsí Òkè Hórébù nílẹ̀ Sínáì. Ó sọ fún un pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú. Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kí n sì mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ yẹn sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:2, 7, 8) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ rán Mósè níṣẹ́, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ ṣe é bí Jèhófà bá ṣe sọ fún un.
4 Áńgẹ́lì Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wá nísinsìnyí, jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, kí o sì mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.” Àmọ́ Mósè ò fẹ́ lọ. Ó ronú pé irú òun kọ́ ni wọ́n ń gbéṣẹ́ yẹn fún, ó sì ti gbà pé òun ò ní lè ṣe é. Ṣùgbọ́n Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ.” (Ẹ́kísódù 3:10-12) Jèhófà fún Mósè lágbára kó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó máa jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló rán an lóòótọ́. Áárónì arákùnrin rẹ̀ yóò sì tẹ̀ lé e kó lè máa ṣe agbẹnusọ fún un. Síwájú sí i, Jèhófà yóò kọ́ wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n á sọ àti ohun tí wọ́n á ṣe. (Ẹ́kísódù 4:1-17) Ǹjẹ́ Mósè á lè jíṣẹ́ yìí bí Ọlọ́run ṣe rán an?
5. Kí nìdí tí ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jẹ́ ìṣòro fún Mósè?
5 Àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì kọ́kọ́ gba ọ̀rọ̀ Mósè àti Áárónì gbọ́. (Ẹ́kísódù 4:29-31) Àmọ́ láìpẹ́, “àwọn onípò àṣẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” fẹ̀sùn kan Mósè àti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé àwọn ló jẹ́ káwọn máa run “òórùn burúkú” níwájú Fáráò àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Ẹ́kísódù 5:19-21; 6:9) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an bí wọ́n ṣe rí i tí àwọn jagunjagun Íjíbítì ń fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin lé wọn bọ̀. Wọ́n ti gbà pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan fáwọn nítorí Òkun Pupa wà níwájú wọn, kẹ̀kẹ́ ẹṣin sì ń bọ̀ lẹ́yìn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí dá Mósè lẹ́bi. Ká ní pé ìwọ ni Mósè, kí lò bá ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n lè lò, Mósè ṣe ohun tí Jèhófà wí, ó ní kí wọ́n palẹ̀ ẹrù wọn mọ́, kí wọ́n sì múra láti lọ. Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run pín Òkun Pupa sí méjì, omi òkun náà sì dúró bí ògiri lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gba àárín òkun náà kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.—Ẹ́kísódù 14:1-22.
Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Ju Ìdáǹdè Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Lọ
6. Kí ni Jèhófà jẹ́ kí Mósè mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì nígbà tó ń gbéṣẹ́ fún un?
6 Jèhófà jẹ́ kí Mósè mọ̀ pé orúkọ òun ṣe pàtàkì nígbà tó ń gbéṣẹ́ fún un. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí gbogbo ẹ̀dá alààyè bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà àti Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà. Nígbà tí Mósè béèrè orúkọ Jèhófà, Jèhófà fèsì pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” Síwájú sí i, ó ní kí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù, ni ó rán mi sí yín.” Jèhófà tún sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:13-15) Jèhófà ṣì ni orúkọ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ Ọlọ́run sí jákèjádò ayé.—Aísáyà 12:4, 5; 43:10-12.
7. Kí ni Ọlọ́run sọ pé kí Mósè ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé onígbèéraga ẹ̀dá ni Fáráò?
7 Nígbà tí Mósè àti Áárónì dé iwájú Fáráò, wọ́n jíṣẹ́ tí Jèhófà rán wọn fún un. Àmọ́, nígbà tí Fáráò agbéraga máa dáhùn, ó ní: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀ láti rán Ísírẹ́lì lọ? Èmi kò mọ Jèhófà rárá àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi kì yóò rán Ísírẹ́lì lọ.” (Ẹ́kísódù 5:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun àti ẹlẹ́tàn ni Fáráò, síbẹ̀ Jèhófà ní kí Mósè lọ máa jíṣẹ́ òun fún un léraléra. (Ẹ́kísódù 7:14-16, 20-23; 8:1, 2, 20) Mósè mọ̀ pé inú ń bí Fáráò bí òun ṣe ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ Fáráò máa gbọ́ tiwọn tí òun àti Áárónì bá tún lọ bá a? Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fẹ́ òmìnira lójú méjèèjì, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ rèé Fáráò fàáké kọ́rí. Ká ní ìwọ ni Mósè, kí lò bá ṣe ná?
8. Àǹfààní wo ló wà nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà yanjú ọ̀rọ̀ Fáráò, ẹ̀kọ́ wo ló sì yẹ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ wa?
8 Mósè tún lọ jíṣẹ́ mìíràn fún Fáráò, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù wí: ‘Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.’” Ọlọ́run tún sọ pé: “Nísinsìnyí, èmi ì bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn kọlu ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, ní ti tòótọ́, fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó, nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ẹ́kísódù 9:13-16) Jèhófà yóò lo ìdájọ́ tó fẹ́ ṣe fún Fáráò olóríkunkun láti fi agbára rẹ̀ hàn kí èyí lè jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n fún gbogbo àwọn tó bá ń ṣàfojúdi sí i. Lára àwọn tó ń ṣàfojúdi tí Jèhófà máa pa run ni Sátánì Èṣù, ẹni tí Jésù Kristi pè ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30; Róòmù 9:17-24) Orúkọ Jèhófà di ohun táwọn èèyàn polongo jákèjádò ayé gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀. Ìpamọ́ra rẹ̀ ló sì jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata tí wọ́n wá ń jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú wọn rí ìgbàlà. (Ẹ́kísódù 9:20, 21; 12:37, 38) Látìgbà yẹn, orúkọ Jèhófà tó ti di mímọ̀ kárí ayé ti ṣe ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí wọ́n ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ láǹfààní.
Bí Mósè Ṣe Bá Àwọn Olóríkunkun Lò
9. Kí làwọn èèyàn Mósè ṣe tó fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà?
9 Àwọn Hébérù mọ orúkọ Ọlọ́run. Mósè máa ń lo orúkọ yẹn tó bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í bọ̀wọ̀ fún Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Láìpẹ́ sígbà tí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì lọ́nà ìyanu, wọ́n ṣe ohun kan nígbà tí wọn ò tètè rí omi tó dára mu. Kí lohun náà? Ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn nípa oúnjẹ. Mósè wá sọ fún wọn pé kì í ṣe òun àti Áárónì ni wọ́n ń ráhùn sí, pé Jèhófà gan-an ni wọ́n ń ráhùn sí. (Ẹ́kísódù 15:22-24; 16:2-12) Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè lórí Òkè Sínáì, ó sì fi àwọn àmì àgbàyanu hàn wọ́n níbẹ̀. Àmọ́, àwọn èèyàn náà ṣàìgbọràn, wọ́n lọ fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù tí wọ́n ń jọ́sìn, wọ́n ní “àjọyọ̀ fún Jèhófà” làwọn ń ṣe—Ẹ́kísódù 32:1-9.
10. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni lónìí máa gba irú àdúrà tí Mósè gbà nínú Ẹ́kísódù 33:13?
10 Báwo ni Mósè ṣe máa bá àwọn èèyàn yìí tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pè ní ọlọ́rùn líle lò? Mósè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, ó ní: “Jọ̀wọ́, bí mo bá rí ojú rere lójú rẹ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́, kí n lè rí ojú rere lójú rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:13) Àwọn èèyàn tí àwọn alábòójútó nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ń bójú tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Síbẹ̀, àdúrà tó yẹ káwọn alábòójútó wọ̀nyí máa gbà ni pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Táwọn alábòójútó bá mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà, wọ́n á lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe nínú ipò yòówù tó bá yọjú, èyí á sì jẹ́ lọ́nà tó bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ànímọ́ Ọlọ́run mu.
Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Káwọn Èèyàn Rẹ̀ Ṣe
11. Àwọn ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún Mósè, kí nìdí tó sì fi yẹ ká mọ̀ nípa wọn?
11 Ní Òkè Sínáì, Jèhófà fẹnu sọ ohun tó fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn èyí, Mósè gba àwọn wàláà òkúta méjì tí Ọlọ́run kọ àwọn Òfin Mẹ́wàá sí. Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ látorí òkè náà, ó rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jọ́sìn ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe. Ó wá fi ìbínú fọ́ àwọn wàláà náà mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ yángá. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà tún Òfin Mẹ́wàá náà kọ sórí wàláà òkúta tí Mósè gbẹ́. (Ẹ́kísódù 32:19; 34:1) Àwọn òfin wọ̀nyí ò sì tíì yí padà látìgbà tí Ọlọ́run ti ṣe wọ́n. Àwọn òfin yẹn náà ṣì ni Mósè ní láti pa mọ́. Síwájú sí i, Ọlọ́run jẹ́ kí Mósè túbọ̀ mọ irú ẹni tí òun jẹ́, èyí sì jẹ́ kí Mósè mọ irú ìwà tó yẹ kóun máa hù bó ṣe ń ṣojú fún Jèhófà. Òótọ́ ni pé Òfin Mósè ò de àwa Kristẹni, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà pàtàkì tó wà nínú òfin náà kò yí padà títí di ìsinsìnyí, àwọn ìlànà yẹn ṣì ni gbogbo ẹni tó bá ń jọ́sìn Jèhófà ní láti máa tẹ̀ lé. (Róòmù 6:14; 13:8-10) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò ná.
12. Níwọ̀n bí Jèhófà ti sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa sin òun tọkàntọkàn, kí ló yẹ kí wọ́n máa ṣe?
12 Ó yẹ ká máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà níbẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé òun nìkan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa sìn. (Ẹ́kísódù 20:2-5) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́. (Diutarónómì 4:33-35) Jèhófà jẹ́ kó yé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ohun yòówù káwọn orílẹ̀-èdè yòókù máa ṣe, òun ò ní fàyè gba ìbọ̀rìṣà tàbí ìbẹ́mìílò láàárín àwọn èèyàn òun. Ìjọsìn wọn sí i gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkànwá, kì í ṣe tójú ayé lásán. Gbogbo wọn gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo okunra wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diutarónómì 6:5, 6) Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa kíyè sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti ìwà wọn, kí wọ́n rí i pé ìfẹ́ Jèhófà làwọn fi ṣáájú nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Léfítíkù 20:27; 24:15, 16; 26:1) Jésù Kristi náà tún ṣàlàyé pé a gbọ́dọ̀ máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Máàkù 12:28-30; Lúùkù 4:8.
13. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi gbọ́dọ̀ ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí Jèhófà, kí ló sì yẹ kó mú káwa náà máa ṣègbọràn sí i? (Oníwàásù 12:13)
13 Máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ délẹ̀délẹ̀. Ó yẹ káwọn èèyàn Ísírẹ́lì rántí pé nígbà tí Jèhófà bá àwọn dá májẹ̀mú, àwọn jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á ṣègbọràn sí i délẹ̀délẹ̀. Wọ́n lómìnira láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó bá wù wọ́n, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn pa òfin Jèhófà mọ́ délẹ̀délẹ̀ tó bá kan àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe òfin lé lórí. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á sì ṣe àwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn láǹfààní torí pé gbogbo àṣẹ Jèhófà ló ń ṣeni láǹfààní.—Ẹ́kísódù 19:5-8; Diutarónómì 5:27-33; 11:22, 23.
14. Báwo ni Ọlọ́run ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa fi nǹkan tẹ̀mí ṣáájú?
14 Máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ohun tara ṣèdíwọ́ fáwọn ohun tẹ̀mí. Wọn kò gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lépa nǹkan tara ṣáá. Jèhófà ya ọjọ́ kan tó kà sí mímọ́ sọ́tọ̀ ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kìkì àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbọ́dọ̀ máa ṣe lọ́jọ́ náà. (Ẹ́kísódù 35:1-3; Númérì 15:32-36) Lọ́dọọdún, wọ́n tún gbọ́dọ̀ fi àyè sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe àwọn àpéjọ mímọ́ kan tó jẹ́ àkànṣe. (Léfítíkù 23:4-44) Ìwọ̀nyí á jẹ́ kí wọ́n lè ráyè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ribiribi tí Jèhófà ti ṣe, wọ́n á tún rántí àwọn ọ̀nà rẹ̀, wọ́n á sì lè fi ìmoore hàn nítorí gbogbo oore rẹ̀. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe ohun wọ̀nyí nínú ìjọsìn wọn, wọ́n á túbọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un á jinlẹ̀ sí i, wọ́n á sì túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè máa rìn láwọn ọ̀nà rẹ̀. (Diutarónómì 10:12, 13) Àwọn ìlànà dáradára tó wà nínú àwọn ìtọ́ni wọ̀nyẹn ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní láǹfààní gan-an.—Hébérù 10:24, 25.
Ó Yẹ Ká Mọyì Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
15. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé tí Mósè bá mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, yóò ṣe é láǹfààní? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló lè jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ Jèhófà?
15 Bí Mósè bá mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, yóò túbọ̀ mọ bó ṣe lè bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì lò. Ẹ́kísódù orí kẹrìnlélọ́gbọ̀n ẹsẹ karùn-ún sí ìkeje sọ pé Ọlọ́run kọjá níwájú Mósè, ó ń polongo pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà, ó ń mú ìyà wá sórí àwọn ọmọ àti sórí àwọn ọmọ-ọmọ, sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin nítorí ìṣìnà àwọn baba.” Wá àyè láti ṣàṣàrò lórí ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ànímọ́ kọ̀ọ̀kan túmọ̀ sí? Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn ànímọ́ náà hàn? Báwo làwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni ṣe lè fi àwọn ànímọ́ yìí hàn? Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ànímọ́ náà hàn nínú ìwà kálukú wa?’ Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
16. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọyì àánú Ọlọ́run, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì pé ká ṣe bẹ́ẹ̀?
16 Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” Bó o bá ní ìwé Insight on the Scriptures, o ò ṣe ka àlàyé tó wà lábẹ́ àkọlé yìí “Mercy” [Àánú]? O sì lè ṣèwádìí lórí kókó yẹn tó o bá ní ìwé Watch Tower Publications Index tàbí Watchtower Library (CD-ROM) [Àkójọ Ìwé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tá A Ṣe Sínú Àwo Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò].a Lo ìwé atọ́ka Concordance láti fi wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa àánú. Wàá rí i pé àánú Jèhófà máa ń jẹ́ kó dín ìyà tí ì bá fi jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kù nígbà míì, àánú rẹ̀ sì tún máa ń jẹ́ kó fi ìyọ́nú hàn. Àánú ló ń jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe ohun tó máa mú ìtura wá fáwọn èèyàn rẹ̀. Òun ló jẹ́ kó pèsè àwọn ohun tara àti tẹ̀mí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílò nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Diutarónómì 1:30-33; 8:4) Àánú Jèhófà ń mú kó dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀. Ó fi àánú bá àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un lò. Ẹ ò rí i pé ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní máa fi ìyọ́nú bá ara wọn lò!—Mátíù 9:13; 18:21-35.
17. Tá a bá mọ ohun tí oore ọ̀fẹ́ Jèhófà túmọ̀ sí, báwo nìyẹn yóò ṣe mú kí ìjọsìn tòótọ́ túbọ̀ gbilẹ̀?
17 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú náà ló tún jẹ́ olóore ọ̀fẹ́. Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí oore ọ̀fẹ́ túmọ̀ sí? Fi ohun tó o gbà pé ó túmọ̀ sí yìí wé ohun tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ olóore ọ̀fẹ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kan lára ohun tó fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí olóore ọ̀fẹ́ ni pé ó máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ tí nǹkan ò bá rọgbọ fún lọ́wọ́. (Ẹ́kísódù 22:26, 27) Nǹkan lè má rọrùn fáwọn àjèjì àtàwọn míì lórílẹ̀-èdè tí wọ́n bá lọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ àti pé kí wọ́n máa fi inú rere bá wọn lò, ó rán wọn létí pé àwọn náà ti jẹ́ àjèjì nígbà kan rí, ìyẹn ni ìgbà tí wọ́n wà nílẹ̀ Íjíbítì. (Diutarónómì 24:17-22) Àwa èèyàn Ọlọ́run ńkọ́ lóde òní? Tá a bá jẹ́ olóore ọ̀fẹ́, a ó wà níṣọ̀kan, àwọn ẹlòmíràn á sì lè wá sin Jèhófà.—Ìṣe 10:34, 35; Ìṣípayá 7:9, 10.
18. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe fara wé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè mìíràn?
18 Àmọ́ o, ìgbatẹnirò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ní sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè mìíràn ò gbọ́dọ̀ borí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà àtàwọn ìlànà tó fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà. Ìyẹn ni Jèhófà fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn kò gbọ́dọ̀ fara wé àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, bóyá kí wọ́n máa ṣe irú ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe tàbí kí wọ́n máa hùwà pálapàla bíi tiwọn. (Ẹ́kísódù 34:11-16; Diutarónómì 7:1-4) Èyí kan àwa náà lónìí. A gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe jẹ́ mímọ́.—1 Pétérù 1:15, 16.
19. Báwọn èèyàn Ọlọ́run bá mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà àìtọ́, báwo lèyí ò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n kó sí ìṣòro?
19 Kí Jèhófà lè rí i dájú pé àwọn ọ̀nà òun yé Mósè dáadáa, ó ṣàlàyé fún un pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ dídá, síbẹ̀ òun ń lọ́ra láti bínú. Jèhófà máa ń fàyè sílẹ̀ káwọn èèyàn lè mọ àwọn òfin rẹ̀ kí wọ́n sì lè fi wọ́n sílò. Jèhófà máa ń dárí ji ẹni tó bá ronú pìwà dà, àmọ́ kì í jẹ́ kí ẹni tó bá dẹ́sẹ̀ tó burú gan-an tó yẹ fún ìjìyà lọ láìjìyà. Ó kìlọ̀ fún Mósè pé ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe yóò kan àwọn ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, yálà kó ṣe wọ́n láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún wọn. Báwọn èèyàn Ọlọ́run bá mọyì àwọn ọ̀nà Jèhófà, èyí ò ní jẹ́ kí wọ́n máa dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí ìṣòro tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn fà tàbí kí wọ́n máa rò pé ó ń fi nǹkan falẹ̀.
20. Kí ló lè jẹ́ ká máa hùwà tó tọ́ sáwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run àtàwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí? (Sáàmù 86:11)
20 Bó o bá fẹ́ kí ìmọ̀ tó o ní nípa Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ jinlẹ̀ sí i, máa ṣèwádìí, kó o sì máa ṣàṣàrò tó o bá ń ka Bíbélì. Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò onírúurú ohun tó mú káwọn ànímọ́ Jèhófà wuni. Máa ronú nípa bó o ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run àti bó o ṣe lè túbọ̀ máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kó o sì máa fi ọ̀rọ̀ yìí sí àdúrà. Èyí kò ní jẹ́ kó o jìn sí ọ̀fìn nípa tẹ̀mí, á jẹ́ kó o lè máa hùwà tó tọ́ sáwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Ọlọ́run, á sì jẹ́ kó o lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run ológo wa, kí wọ́n sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé wọ̀nyí.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí nìdí tó fi yẹ kí Mósè jẹ́ ọlọ́kàntútù, kí nìdí tó sì fi yẹ káwa náà jẹ́ ọlọ́kàntútù?
• Àǹfààní wo ló jẹ yọ látinú sísọ tí Mósè ń sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún Fáráò lásọtúnsọ?
• Àwọn ìlànà tó ṣe pàtàkì gan-an wo ni Ọlọ́run kọ́ Mósè tó kan àwa náà lónìí?
• Báwo la ṣe lè túbọ̀ mú kí òye wa nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà jinlẹ̀ sí i?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Mósè jíṣẹ́ fún Fáráò bí Jèhófà ṣe rán an gẹ́lẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jèhófà fún Mósè ní àwọn òfin rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Máa ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà