Fifi Ẹmi Ifara-ẹni-rubọ Ṣiṣẹsin Jehofa
“Bi ẹnikan bá ń fẹ́ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o sì gbé [òpó-igi ìdálóró, “NW”] rẹ̀, ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin.”—MATTEU 16:24.
1. Bawo ni Jesu ṣe fi iku rẹ̀ ti o rọdẹdẹ tó awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti?
NI SÀKÁÁNÍ Oke Hermoni tí òjò-dídì mọ odi sí lórí, Jesu Kristi dé ori kókó pataki kan ninu igbesi-aye rẹ̀. Ó ní ohun ti ó dín sí ọdun kan lati fi walaaye. Oun mọ̀ bẹẹ; ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò mọ̀. Akoko naa ti wá dé wàyí fun wọn lati mọ̀. Loootọ, Jesu ti sọrọ bá iku rẹ̀ ti ó rọ̀dẹ̀dẹ̀ ni iṣaaju, ṣugbọn eyi ni ìgbà akọkọ ti ó sọrọ ni kedere nipa rẹ̀. (Matteu 9:15; 12:40) Akọsilẹ Matteu kà pe: “Lati ìgbà naa lọ ni Jesu ti bẹrẹ sii fihan awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi oun kò ti lè ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọpọ ìyà lọwọ awọn agbaagba ati awọn olori alufaa, ati awọn akọwe, ki a sì pa oun, ati ni ijọ kẹta, ki o sì jinde.”—Matteu 16:21; Marku 8:31, 32.
2. Ki ni idahunpada Peteru si awọn ọ̀rọ̀ Jesu nipa ijiya Rẹ̀ ọjọ-iwaju, bawo sì ni Jesu ṣe dahunpada?
2 Ó kù rébété fun Jesu lati kú. Peteru, bi o ti wu ki o ri, fi ìrunú hàn si ohun ti o farajọ èrò buruku bẹẹ nipa iku. Oun kò lè gbà pe Messia ni a o pa niti gidi. Nitori naa, Peteru gbójúgbóyà lati bá Ọ̀gá rẹ̀ wí. Bi awọn èrò-ọkàn didara julọ ti sún un, ó fi inúfùfù rọ̀ ọ́ pe: “Ki a má ri i, Oluwa, kì yoo rí bẹẹ fun ọ.” Ṣugbọn Jesu kọ inurere àṣìní Peteru yii loju-ẹsẹ, ni pàtó bi ẹnikan yoo ti tẹ ori ejo aṣekupani fọ́. “Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ ni iwọ jẹ́ fun mi: iwọ kò ro ohun tii ṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi tii ṣe ti eniyan.”—Matteu 16:22, 23.
3. (a) Bawo ni Peteru ṣe fi aimọọmọ sọ araarẹ di aṣoju Satani? (b) Bawo ni Peteru ṣe jẹ́ okuta idigbolu si ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ?
3 Peteru ti sọ araarẹ di aṣoju Satani laimọọmọ. Idahun Jesu lọna mimuna ti jẹ́ tipinnutipinnu gẹgẹ bi ìgbà ti ó dá Satani lohun ninu aginju. Nibẹ ni Eṣu ti gbiyanju lati dán Jesu wò pẹlu igbesi-aye pẹ̀lẹ́tùù, ipo-ọba laisi ijiya. (Matteu 4:1-10) Nisinsinyi Peteru ń fun un niṣiiri lati maṣe lekoko mọ́ araarẹ. Jesu mọ pe eyi kìí ṣe ifẹ-inu Baba oun. Igbesi-aye rẹ̀ gbọdọ jẹ́ ọ̀kan ti o jẹ́ ti ifara-ẹni-rubọ, kìí ṣe ti onítẹ̀ẹ́ra-ẹni-lọ́rùn. (Matteu 20:28) Peteru di okuta idigbolu si iru ipa-ọna kan bẹẹ; ìbánikẹ́dùn ọlọkanrere rẹ̀ wá di pańpẹ́.a Jesu, bi o ti wu ki o ri, ríran kedere pe bi oun bá fààyè gba èrò eyikeyii nipa igbesi-aye ti o bọ́ lọwọ ifirubọ, oun yoo kuna ojurere Ọlọrun nipa didi ẹni ti ọwọ́ ṣìnkún pańpẹ́ Satani mú.
4. Eeṣe ti igbesi-aye itura onikẹẹra-ẹni bajẹ kìí fií ṣe ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀?
4 Ironu Peteru, nitori naa, nilo itunṣebọsipo. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ si Jesu duro fun èrò eniyan, kìí ṣe ti Ọlọrun. Ti Jesu kọ ni igbesi-aye oníkẹ̀ẹ́ra-ẹni bajẹ, ọ̀nà rirọrun lati bọ́ kuro lọwọ ijiya; bẹẹ ni kò sì yẹ ki irú igbesi-aye bẹẹ wà fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀, nitori pe Jesu sọ tẹlee fun Peteru ati awọn ọmọ-ẹhin yooku pe: “Bi ẹnikan bá ń fẹ́ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o sì gbé [òpó-igi ìdálóró, NW] rẹ̀, ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin.”—Matteu 16:24.
5. (a) Ki ni ipenija gbigbe igbesi-aye Kristian? (b) Fun awọn nǹkan pipọndandan mẹta wo ni Kristian kan gbọdọ wà ní imurasilẹ fun?
5 Leralera, Jesu ń pada si ẹṣin-ọrọ pataki yii: ipenija gbigbe igbesi-aye Kristian. Lati lè di ọmọlẹhin Jesu, awọn Kristian, bi Aṣaaju wọn, gbọdọ fi ẹmi ifara-ẹni-rubọ ṣiṣẹsin Jehofa. (Matteu 10:37-39) Nipa bayii, ó to awọn ohun mẹta ṣiṣe pataki tí Kristian kan gbọdọ muratan lati ṣe lẹsẹẹsẹ: (1) sẹ́ araarẹ̀, (2) gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀, kí ó sì (3) maa tọ̀ Ọ́ lẹhin.
“Bi Ẹnikan Bá Ń Fẹ́ Lati Tọ̀ Mi Lẹhin”
6. (a) Bawo ni ẹnikan ṣe ń sẹ́ araarẹ̀? (b) Ta ni a gbọdọ tẹlọrun ju araawa lọ?
6 Ki ni ó tumọsi lati sẹ́ ara-ẹni? Ó tumọsi pe ẹnikan nilati sẹ́ araarẹ̀ patapata, bi ẹni pa ara-ẹni. Itumọ ipilẹṣẹ tí ọ̀rọ̀ Griki ti a tumọsi “sẹ́” ni “lati sọ pe rara”; ó tumọsi “lati sẹ́ patapata-porogodo.” Nitori naa, bi o bá tẹwọgba ipenija igbesi-aye Kristian, iwọ fi imuratan fi awọn ìfẹ́-ọkàn lilagbara, igbadun, ìfẹ́-ọkàn, ayọ, adun, tirẹ silẹ. Ni pataki julọ, iwọ ń fi gbogbo igbesi-aye rẹ ati ohun gbogbo ti ó ní ninu fun Jehofa Ọlọrun fun gbogbo ìgbà. Lati sẹ́ ara-ẹni tumọsi ohun pupọ ju fifi awọn fàájì kan du ara-ẹni lati ìgbà dé ìgbà lọ. Kaka bẹẹ, ó tumọsi pe ẹnikan gbọdọ kọ níni ara rẹ̀ silẹ fun Jehofa. (1 Korinti 6:19, 20) Ẹnikan ti o ti sẹ́ araarẹ ń gbé lati tẹ́, kìí ṣe ara rẹ̀, bikoṣe Ọlọrun lọ́rùn. (Romu 14:8; 15:3) Ó tumọsi pe ni gbogbo akoko igbesi-aye rẹ̀, ó ń sọ pe rárá fun awọn ìfẹ́-ọkàn imọtara-ẹni-nikan ati bẹẹni si Jehofa.
7. Ki ni òpó-igi ìdálóró Kristian, bawo ni ó sì ṣe ń gbé e?
7 Lati gbé òpó-igi ìdálóró rẹ, nitori naa, ní iyọrisi wiwuwo. Gbigbe òpó-igi ìdálóró kan jẹ́ ẹrù-ìnira kan ati àmì iṣapẹẹrẹ iku. Kristian naa wà ni imuratan lati jiya bi ó bá pọndandan, tabi ki a dojuti i tabi dá a lóró tabi tilẹ ṣekupa a paapaa nitori jíjẹ́ ọmọlẹhin Jesu Kristi. Jesu sọ pe: “Ẹni ti kò bá sì gbé [òpó-igi ìdálóró, NW] rẹ̀, ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi.” (Matteu 10:38) Kìí ṣe gbogbo ẹni ti ń jiya ni ń gbé òpó-igi ìdálóró. Awọn ẹni buburu ní ọpọlọpọ “irora” ṣugbọn wọn kò ní òpó-igi ìdálóró kankan. (Orin Dafidi 32:10, NW) Bi o ti wu ki o ri, igbesi-aye Kristian jẹ́ igbesi-aye gbigbe òpó-igi ìdálóró ti iṣẹ-isin ifara-ẹni-rubọ si Jehofa.
8. Apẹẹrẹ igbesi-aye wo ni Jesu fi lelẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀?
8 Ipo ti o kẹhin ti Jesu mẹnukan ni pe ki a maa tẹle oun lẹhin. Jesu beere kìí ṣe kìkì pe ki a tẹwọgba ki a sì nigbagbọ ninu ohun ti oun fi kọni nikan ni ṣugbọn pẹlu pe fun gbogbo igbesi-aye wa, a ń baa lọ lati tẹle apẹẹrẹ ti oun fi lélẹ̀. Ki sì ni diẹ lara awọn apa-iha ti o hàn gbangba julọ ninu apẹẹrẹ igbesi-aye rẹ̀? Nigba ti ó fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni iṣẹ-aṣẹ wọn ti o gbẹhin, ó sọ pe: ‘Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa sọni di ọmọ-ẹhin . . . , ẹ maa kọ́ wọn lati kiyesi ohun gbogbo ti mo ti pa ni aṣẹ fun yin.’ (Matteu 28:19, 20) Jesu waasu ó sì kọni ni ihinrere nipa Ijọba naa. Bẹẹ ni awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gan-an ati, nitootọ, gbogbo ijọ Kristian ijimiji ti ṣe. Igbokegbodo onitara yii ní afikun si ṣiṣe ti wọn kìí ṣe apakan ayé mú ikoriira ati atako ayé wá sori wọn, eyi ti ó yọrisi mímú ki òpó-igi ìdálóró wọn tubọ jẹ eyi ti o wuwo sii lati gbé.—Johannu 15:19, 20; Iṣe 8:4.
9. Bawo ni Jesu ṣe bá awọn eniyan miiran lò?
9 Apẹẹrẹ miiran ti o yọri-ọla ninu igbesi-aye Jesu ni ọ̀nà ti ó gbà bá awọn ẹlomiran lò. Oun jẹ́ oninuure ati “oninututu ati onirẹlẹ ọkàn.” Nipa bẹẹ, awọn olutẹtisilẹ sii nimọlara isọdi titun ninu ẹmi a sì fun wọn niṣiiri nipa wíwà nibẹ rẹ̀. (Matteu 11:29) Oun kò fojú tabi ọ̀rọ̀ nà wọn ni patiyẹ lati tẹle e tabi fi awọn ofin kan lélẹ̀ tẹle omiran nipa ọ̀nà ti wọn nilati gbà ṣe bẹẹ; bẹẹ ni oun kò ṣokunfa awọn imọlara ẹ̀bi lati fipa mu wọn lati jẹ́ ọmọ-ẹhin rẹ̀. Laika igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ wọn si, wọn ń fi ojulowo ayọ hàn. Ẹ wo iru iyatọ gédégédé ti eyi jẹ́ si ti awọn wọnni ti wọn ní ẹmi ayé ti oníkẹ̀ẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ ti o sami si “ikẹhin ọjọ”!—2 Timoteu 3:1-4.
Mú Ẹmi Ifara-Ẹni-Rubọ Jesu Dagba Ki O Sì Pa Á Mọ́
10. (a) Gẹgẹ bi Filippi 2:5-8 ṣe sọ, bawo ni Kristi ṣe sẹ́ araarẹ̀? (b) Bi a bá jẹ́ ọmọlẹhin Kristi, iṣarasihuwa ero-ori wo ni a gbọdọ fihàn?
10 Jesu fi apẹẹrẹ lélẹ̀ ninu sísẹ́ra-ẹni. Ó gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀ ó sì ń baa lọ lati maa gbé e nipa ṣiṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀. Paulu kọwe si awọn Kristian ni Filippi pe: “Ẹ pa ẹmi-ironu ero-ori yii mọ́ ninu yin eyi ti ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu, ẹni ti, bi o tilẹ wà ni aworan-irisi Ọlọrun, kò fi ironu fun fifi ipá gba nǹkan, eyiini ni, pe oun nilati bá Ọlọrun dọgba. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó sọ ara rẹ̀ dòfo ó sì mú aworan-irisi ẹrú, ó sì wá wà ni jíjọ awọn eniyan. Ju eyiini lọ, nigba ti o rí ara rẹ̀ ni àwọ̀ ẹ̀dá eniyan, ó rẹ ara rẹ̀ silẹ ó sì di onigbọran titi de oju iku, bẹẹni, iku lori òpó-igi ìdálóró.” (Filippi 2:5-8, NW) Ta ni ó lè tubọ sẹ́ ara rẹ̀ latokedelẹ ju iyẹn lọ? Bi iwọ bá jẹ́ ti Kristi Jesu ti o sì jẹ́ ọ̀kan ninu awọn ọmọlẹhin rẹ̀, iwọ gbọdọ pa ẹmi-ironu ero-ori kan-naa yii mọ́.
11. Gbigbe igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ tumọsi gbigbe fun ifẹ-inu ta ni?
11 Aposteli miiran, Peteru, sọ fun wa pe niwọn bi Jesu ti jiya ti ó sì kú fun wa, awọn Kristian nilati fi ẹmi kan-naa ti Kristi ní, dihamọra, bi awọn ọmọ-ogun ti o ti murasilẹ daradara. Ó kọwe pe: “Ǹjẹ́ bi Kristi ti jiya fun wa nipa ti ara, iru inu kan-naa ni ki ẹyin fi hamọra: nitori ẹni ti o bá ti jiya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹṣẹ; Ki ẹyin ki o maṣe fi ìgbà ayé yin iyooku wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹẹ eniyan, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun.” (1 Peteru 3:18; 4:1, 2) Ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ Jesu ni kedere fi bi ohun ti nimọlara nipa ifẹ-inu Ọlọrun hàn. Ó jẹ́ ẹni ti ọkàn rẹ̀ papọ sójúkan ninu ifọkansin rẹ̀, ti ó ń fi ìgbà gbogbo fi ifẹ-inu Baba rẹ̀ leke tirẹ̀, àní titi de ojú iku aláìgbayì paapaa.—Matteu 6:10; Luku 22:42.
12. Igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ ha jẹ́ eyi ti kò gbadun mọ́ Jesu bi? Ṣalaye.
12 Bi o tilẹ jẹ pe igbesi-aye onifara-ẹni-rubọ Jesu jẹ́ ipa-ọna ninira onipenija fun un lati tẹle, oun kò rí i bi alaigbadunmọni. Kaka bẹẹ, Jesu ri igbadun ninu titẹri araarẹ̀ ba fun ifẹ-inu atọrunwa. Fun un, ṣiṣe iṣẹ Baba rẹ̀ dabi ounjẹ. Ó ri itẹlọrun gidi gbà ninu rẹ̀, gan-an gẹgẹ bi ẹnikan yoo ti rí i gbà lati inu ounjẹ ti o dọ́ṣọ̀. (Matteu 4:4; Johannu 4:34) Nipa bayii, bi o bá fẹ́ nimọlara aṣeyọri tootọ ninu igbesi-aye rẹ, kò si ohun tí ó sàn ti o lè ṣe ju ki o tẹle apẹẹrẹ Jesu nipa mimu itẹsi ero-ori rẹ̀ dagba.
13. Bawo ni ifẹ ṣe jẹ ipá asunniṣiṣẹ ti o wà lẹhin ẹmi ifara-ẹni-rubọ?
13 Niti gidi, ki ni ipá asunniṣiṣẹ ti o wà lẹhin ẹmi ifara-ẹni-rubọ? Ni ọ̀rọ̀ kan, ifẹ ni. Jesu sọ pe: “Ki iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. Eyi ni ekinni ati ofin ńlá. Ekeji sì dabi rẹ̀, iwọ fẹ́ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.” (Matteu 22:37-39) Kristian kan kò lè jẹ́ ẹni ti ń wá ti ara rẹ̀ nikan ati, ni akoko kan-naa, ki o ṣegbọran si awọn ọ̀rọ̀ wọnni. Ayọ ati ọkàn-ìfẹ́ tirẹ̀ ni a gbọdọ kọ́kọ́ ṣakoso ni pataki julọ nipa ifẹ rẹ̀ fun Jehofa ati lẹhin naa nipa ifẹ rẹ̀ fun awọn aladuugbo. Bi Jesu ṣe gbé igbesi-aye rẹ̀ niyẹn, ohun ti o sì reti lọdọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ niyẹn.
14. (a) Awọn ẹrù-iṣẹ́ wo ni a ṣalaye ni Heberu 13:15, 16? (b) Ki ni ó ń fun wa niṣiiri lati fi ìtara waasu ihinrere naa?
14 Aposteli Paulu loye ofin ifẹ yii. Ó kọwe pe: “Ǹjẹ́ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigba gbogbo, eyiini ni eso ète wa, ti ń jẹwọ orukọ rẹ̀. Ṣugbọn ati maa ṣoore oun ati maa pinfunni ẹ maṣe gbagbe: nitori iru ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.” (Heberu 13:15, 16) Awọn Kristian kìí rú ẹbọ ẹran tabi iru wọnni si Jehofa; fun idi eyi, wọn kò nilo alufaa eniyan ninu tẹmpili gidi kan lati ṣaboojuto ninu ijọsin wọn. Nipasẹ Kristi Jesu ni a ń rú ẹbọ iyin wa. Ni pataki julọ ó sì jẹ́ nipasẹ ẹbọ iyin yẹn, ijẹwọ ni gbangba si orukọ rẹ̀ yẹn, ni a ń fi ifẹ wa fun Ọlọrun hàn. Ni pataki ẹmi aimọtara-ẹni-nikan wa ti o jẹ jade lati inú ifẹ wá ń fun wa niṣiiri lati fi ìtara waasu ihinrere naa, ni lilakaka lati wà ni ìháragàgà nigba gbogbo lati fi eso ètè wa rubọ si Ọlọrun. Ni ọ̀nà yii a ń fi ifẹ aladuugbo hàn pẹlu.
Ifara-Ẹni-Rubọ Ń Mú Awọn Ibukun Jìngbìnnì Wá
15. Awọn ibeere tí ń tọpinpin wo nipa ifara-ẹni-rubọ ni a lè beere lọwọ araawa?
15 Sinmi fun ìgbà diẹ ná ki o sì ronu siwa-sẹhin lori awọn ibeere ti o tẹlee yii: Ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye mi isinsinyi ha fi ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ kan hàn bi? Awọn gongo ilepa mi ha tọka si iru igbesi-aye kan bẹẹ bi? Awọn mẹmba idile mi ha ń kárúgbìn èrè tẹmi lati inu apẹẹrẹ mi bi? (Fiwe 1 Timoteu 5:8.) Awọn ọmọ alainibaba ati opó ń kọ́? Awọn pẹlu ha ń janfaani lati inu ẹmi ifara-ẹni-rubọ mi bi? (Jakọbu 1:27) Mo ha lè mú akoko ti mo ń lò ninu ẹbọ iyin itagbangba gbooro si bi? Ó ha ṣeeṣe fun mi lati nàgà fun anfaani iṣẹ-isin aṣaaju-ọna, Beteli, tabi ti ijihin-iṣẹ-Ọlọrun, tabi mo ha lè ṣilọ lati lọ ṣiṣẹsin ni agbegbe kan ti aini gbé pọju fun awọn olupokiki Ijọba bi?
16. Bawo ni ọgbọ́n ṣe lè ràn wá lọwọ lati gbé igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ?
16 Nigba miiran ó wulẹ gba ọgbọ́n diẹ lati dé ẹkunrẹrẹ agbara wa ninu fifi ẹmi ifara-ẹni-rubọ ṣiṣẹsin Jehofa. Fun apẹẹrẹ, Janet, aṣaaju-ọna deedee kan ni Ecuador, ṣiṣẹ ounjẹ oojọ alakooko kikun. Laipẹ laijinna, itolẹsẹẹsẹ rẹ̀ mú ki o ṣoro lati doju wakati ti a beere fun lọwọ aṣaaju-ọna deedee pẹlu ẹmi ọ̀yàyà. Ó pinnu lati ṣalaye iṣoro rẹ̀ fun olugbanisiṣẹ rẹ̀ ó sì beere fun didin awọn wakati iṣẹ rẹ kù. Niwọn bi olugbanisiṣẹ rẹ̀ kò ti muratan lati dín akoko iṣẹ rẹ̀ kù, ó mú Maria, ẹni ti ń wá iṣẹ abọọṣẹ wa sibẹ ki o baa lè ṣe aṣaaju-ọna. Ikọọkan wọn gbà lati ṣiṣẹ ilaji ọjọ, ni pinpin iṣẹ oojọ kan ṣe. Olugbanisiṣẹ naa tẹwọgba idamọran naa. Nisinsinyi awọn arabinrin mejeeji jẹ́ aṣaaju-ọna deedee. Nigba ti ó rí abajade yiyanilẹnu yii, Kaffa, ẹni ti ṣiṣiṣẹ alakooko kikun fun ile-iṣẹ yii kan-naa ti dálágara tí ó sì ń jijakadi lati maa ṣe deedee pẹlu akoko aṣaaju-ọna, mú Magali lọ sibẹ o sì ṣe ifilọni kan-naa. A tẹwọgba oun naa pẹlu. Nipa bayii, ó ṣeeṣe fun awọn arabinrin mẹrin lati ṣe aṣaaju-ọna, dipo awọn meji ti wọn ti dori koko fifi iṣẹ-isin alakooko kikun silẹ. Ọgbọ́n ati idanuṣe ní iyọrisi ti o ṣanfaani.
17-21. Bawo ni tọkọtaya kan ṣe tun ète wọn ninu igbesi-aye gbeyẹwo, pẹlu iyọrisi wo sì ni?
17 Siwaju sii, gbé ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ tí Evonne tẹle ni ọdun mẹwaa ti o ti kọja yẹwo. Ó kọwe ohun ti o tẹle e yii si Watch Tower Society ni May 1991:
18 “Ni October 1982, emi ati idile mi rìn yika Beteli ti o wà ni Brooklyn. Rírí i mú ki n fẹ́ lati yọnda ara mi lati ṣiṣẹ nibẹ. Mo ka iwe ìwọṣẹ́ kan, ibeere ti o yẹ fun afiyesi kan sì wà nibẹ, ‘Ki ni ipindọgba wakati iṣẹ-isin pápá rẹ fun oṣu mẹfa ti o kọja? Bi ipindọgba wakati bá kéré si mẹwaa, ṣalaye idi.’ Emi kò lè ronu idi ti o fẹsẹmulẹ, nitori naa mo gbé gongo-ilepa kan kalẹ mo sì lebá ni oṣu marun-un.
19 “Bi o tilẹ jẹ pe mo lè ronu nipa awọn àwáwí melookan fun ṣiṣaiṣe aṣaaju-ọna, nigba ti mo ka iwe 1983 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ó dá mi loju pe awọn ẹlomiran ti bori awọn idiwọ ti o tubọ tobi ju temi lọ ki wọn baa lè ṣe aṣaaju-ọna. Nitori naa, ni April 1, 1983, mo kuro lẹnu iṣẹ alakooko kikun mi ti ń mowo jaburata wọle mo sì di aṣaaju-ọna oluranlọwọ, mo sì wọnu agbo awọn aṣaaju-ọna deedee ni September 1, 1983.
20 “Ó jẹ́ idunnu mi lati fẹ́ iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ rere kan ni April 1985. Ní ọdun mẹta lẹhin naa, ọrọ-asọye apejọpọ agbegbe kan nipa ṣiṣe aṣaaju-ọna sún ọkọ mi lati fẹnu kò mi leti ti o sì beere pe, ‘Iwọ ha mọ idi kankan ti emi kò fi nilati bẹrẹ ṣiṣe aṣaaju-ọna ní September 1 bí?’ Ó darapọ mọ́ mi ninu iṣẹ yii fun ọdun meji ti o tẹlee.
21 “Ọkọ mi tun yọnda lati ṣe iṣẹ ikọle ni Beteli ti o wà ni Brooklyn fun ọsẹ meji ó sì kọwe beere fun Eto Ikọle Jakejado Awọn Orilẹ-Ede. Nitori naa ni May 1989 a lọ si Nigeria fun oṣu kan lati ṣeranwọ ninu kíkọ́ ẹ̀ka. Ni ọ̀la awa yoo rinrin-ajo lọ si Germany, nibi ti a o ti ṣeto iwe-irinna fun wa lati wọ Poland. Ó dun mọ́ wa lati lọwọ ninu iru idawọle ikọle ṣiṣe pataki ati manigbagbe bẹẹ ati lati jẹ́ apakan iru iṣẹ-isin alakooko kikun titun yii.”
22. (a) Bawo ni awa, bí Peteru, ṣe lè di okuta idigbolu laimọọmọ? (b) Fifi ẹmi ifara-ẹni-rubọ ṣiṣẹsin Jehofa kò sinmi lori ki ni?
22 Bi kò bá ṣeeṣe fun iwọ funraarẹ lati ṣe aṣaaju-ọna, iwọ ha lè fun awọn wọnni ti wọn wà ninu iṣẹ-isin alakooko kikun niṣiiri lati dìrọ̀ mọ anfaani wọn ati boya ki o tilẹ ràn wọn lọwọ lati ṣe bẹẹ bi? Tabi iwọ yoo ha dabi awọn mẹmba idile tabi awọn ọ̀rẹ́ diẹ ti wọn lọkan rere ti, bí Peteru, wọn lè sọ fun iranṣẹ alakooko kikun kan lati tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, lati ṣaanu araarẹ̀, laimọ bi iyẹn ṣe lè jẹ́ okuta idigbolu bi? Loootọ, bi ilera aṣaaju-ọna kan bá wà ninu ewu gidigidi tabi ti ó bá ń ṣainaani awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe Kristian, oun lè nilati fi iṣẹ-isin alakooko kikun silẹ fun ìgbà diẹ. Fifi ẹmi ifara-ẹni-rubọ ṣiṣẹsin Jehofa kò sinmi lé orukọ idanimọ kan, bíi aṣaaju-ọna, oṣiṣẹ ni Beteli, tabi awọn miiran. Kaka bẹẹ, ó sinmi lori ohun ti a jẹ́ gẹgẹ bi ẹnikọọkan—bi a ṣe ń ronu, ohun ti a ń ṣe, bi a ṣe ń bá awọn ẹlomiran lò, bi a ṣe ń gbé igbesi-aye wa.
23. (a) Bawo ni a ṣe lè maa baa lọ lati ní ayọ jíjẹ́ alabaaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun? (b) Idaniloju wo ni a rí ninu Heberu 6:10-12?
23 Bi a bá ni ẹmi ifara-ẹni-rubọ nitootọ, awa yoo ní ayọ jíjẹ́ alabaaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun. (1 Korinti 3:9) Awa yoo ni itẹlọrun ti mímọ̀ pe awa ń mú ọkàn Jehofa yọ̀. (Owe 27:11) A sì ni idaniloju naa pe Jehofa kò ni gbagbe wa tabi pa wá tì niwọn bi a bá ti wà gẹgẹ bi oloootọ si i.—Heberu 6:10-12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni èdè Griki, “okuta ìdìgbòlù” (σκάνδαλον, skanʹda·lon) ni “orukọ apakan pańpẹ́ ti a ń so ìjẹ mọ, ni ipilẹṣẹ, fun idi yii, ó jẹ́ pańpẹ́ tabi ikẹkun funraarẹ.”—Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words.
Ki Ni Èrò Rẹ?
◻ Bawo ni Peteru ṣe di okuta idigbolu laimọọmọ si ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ?
◻ Ki ni o tumọsi lati sẹ́ ara-ẹni?
◻ Bawo ni Kristian kan ṣe ń gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀?
◻ Bawo ni a ṣe ń mú ẹmi ifara-ẹni-rubọ dagba ti a sì ń pa á mọ?
◻ Ki ni ipá asunniṣiṣẹ ti o wà lẹhin ẹmi ifara-ẹni-rubọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Iwọ ha muratan lati sẹ́ araarẹ, ki o gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀, ki o sì maa tẹle Jesu nigba gbogbo bi?