Jehofa, Igbekẹle Mi Lati Ìgbà Èwe Wá
GẸGẸ BÍ BASIL TSATOS TI SỌ Ọ́
Ọdun naa jẹ́ 1920; ibi ti o ti ṣẹlẹ, oke Arcadia ni Peloponnisos lilẹwa, Greece. Mo wà lori ibusun, àrùn Gágá ti ń dẹrubani naa, eyi ti ń lọ kaakiri ayé ń mú mi ṣaisan lọna ti o lewu.
NIGBA kọọkan ti agogo ṣọọṣi bá ti dun, mo mọ̀ pe o ń sefilọ iku ojiya-ipalara miiran ni. Emi ni yoo ha tẹlee bi? Lọna ti o ṣe kongẹ ire, mo bọ́ ninu aisan naa, ṣugbọn araadọta-ọkẹ eniyan baa lọ. Bi o tilẹ jẹ pe mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdun mẹjọ nigba naa, o hàn gbangba pe iriri adẹrubani yii ṣì wà ninu iranti mi.
Awọn Aniyan Tẹmi Ni Ibẹrẹ
Ní akoko diẹ lẹhin naa, Baba mi àgbà kú. Lẹhin isinku rẹ̀, mo ranti pe Mama mi darapọ mọ́ emi ati aburo mi obinrin lori oke pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ile wa. Laisi aniani o ń gbiyanju lati mú ibanujẹ wa dinku, o sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pe: “Wayi o, ẹyin ọmọ, gbogbo wa gbọdọ darugbo ki a sì kú.”
Bi o tilẹ jẹ pe ó fi pẹlẹpẹlẹ sọ ọ́, awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ daamu mi. ‘Ẹ wo bi o ti banininujẹ tó! Ẹ wo bi kò ti dara tó!’ ni mo ronu. Ṣugbọn awa mejeeji ṣe ara giri nigba ti Mama fikun un pe: “Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Oluwa bá tun pada wá, oun yoo jí awọn oku dide, a kì yoo sì kú mọ́!” Áà, iyẹn ma ń tuni ninu o!
Lati ìgbà naa lọ mo ní ọkàn-ìfẹ́ jijinlẹ ninu wiwadii ìgbà naa gan-an ti akoko alayọ yẹn lè dé. Mo bi ọpọlọpọ eniyan léèrè, ṣugbọn kò si ẹnikẹni ti o lè sọ fun mi, bẹẹ ni kò dabi ẹni pe ẹnikẹni tilẹ ní ọkàn-ìfẹ́ ninu jijiroro ọ̀ràn naa, laika bi o ti jẹ sí.
Ní ọjọ kan nigba ti mo jẹ́ nǹkan bi ọmọ ọdun 12, baba mi rí iwe kan gbà lati ọwọ́ ẹgbọn rẹ̀ ọkunrin ti ń gbé ní United States. Ó ni akọle naa Duru Ọlọrun, ti a tẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society. Mo wo itolẹsẹẹsẹ awọn akori inu iwe naa, oju mi rẹrin-in ayọ nigba ti mo ri akori naa “Ipadabọ Oluwa Wa.” Mo kà á pẹlu ọkàn-ìfẹ́ nla, ṣugbọn mo ni ijakulẹ pe a kò funni ni ọdun kankan fun ipadabọ naa. Bi o ti wu ki o ri, iwe naa tọka pe kò jìnnà mọ́.
Laipẹ mo bẹrẹ sii lọ si ile-ẹkọ giga, iwe mi sì ń gbà mi lọ́kàn. Ṣugbọn, lati ìgbà de ìgbà ni aburo baba mi ti o wà ni America ń fi awọn ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà ranṣẹ si mi, eyi ti mo gbadun lati maa kà. Bakan-naa, ni gbogbo ọjọ Sunday, mo maa ń lọ si ile-ẹkọ Ọjọ-Isinmi, nibi ti biṣọọbu ti sábà maa ń wá bá wa sọrọ.
Ní ọjọ Sunday kan ni pato, inu biṣọọbu naa ru soke gan-an ti o sì wi pe: “Awọn alejo ń fi awọn itẹjade aládàámọ̀ kun ilu wa.” Lẹhin naa ni ó wá na ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan soke ti o sì pariwo pe: “Bi ẹnikẹni ninu yin bá rí itẹjade bi iru eyi ni ile yin, ẹ mu wọn wá si ṣọọṣi, emi yoo sì sun wọn.”
Ìró ohùn rẹ̀ dà mi laamu, ṣugbọn ẹmi igbẹsan rẹ̀ dà mi laamu ju ohùn rẹ̀ lọ. Fun idi eyi, n kò ṣegbọran si ibeere rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, mo kọwe si aburo baba mi mo sì sọ fun un pe ki ó má fi awọn itẹjade Watch Tower ranṣẹ si mi mọ́. Sibẹ, mo ṣì ń ro ọ̀ràn nipa ipadabọ Kristi naa.
Ebi Tẹmi Ń Ga Sii
Nigba ti isinmi opin ọdun de, mo gbé apo aṣọ mi jade lati palẹ awọn aṣọ mi mọ́. Awọn iwe pẹlẹbẹ mẹta tí Watch Tower Society tẹjade wà nibẹ ni isalẹ rẹ̀. Ní ọ̀nà kan ṣa, n kò ṣakiyesi wọn tẹlẹ. A pe ọ̀kan ni Nibo Ni Awọn Oku Wà?
‘Iyẹn dabi eyi ti ń ru ọkàn-ìfẹ́ soke,’ ni mo ronu. Bi o tilẹ jẹ pe mo ranti ikilọ biṣọọbu naa, mo pinnu lati ka awọn iwe pẹlẹbẹ naa pẹlu iṣọra lati lè rí awọn aṣiṣe ti mo lero pe wọn ní. Mo mu lẹ́ẹ̀dì ikọwe kan mo sì fi iṣọra bẹrẹ sii ṣe iwadii mi. Si iyalẹnu mi, gbogbo ohun ti o wà ninu iwe pẹlẹbẹ naa dabi eyi ti o bọgbọn mu, gbolohun ọ̀rọ̀ kọọkan sì ni awọn ẹsẹ iwe mimọ ti a tọka si ki onkawe naa baa le yẹ Bibeli naa wò.
Niwọn bi a kò ti ni Bibeli kan, mo ronu boya awọn ẹsẹ iwe mimọ ti a tọka si ni a ti ṣì lò lati lè bá ète awọn onkọwe naa mu. Nitori naa mo kọwe si aburo baba mi mo sì beere lọwọ rẹ̀ lati fi ẹ̀dà odindi Bibeli kan ranṣẹ si mi. Ó ṣe bẹẹ lọ́gán. Kia ni mo kà á lati Genesisi de Ìfihàn lẹẹmeji, bi o sì tilẹ jẹ pe ohun pupọ ni o wà ninu rẹ̀ ti n kò lè loye, iwe Danieli ati Ìfihàn ru ọkàn-ìfẹ́ mi soke. Mo fẹ́ lati loye awọn ohun ti wọn sọtẹlẹ, ṣugbọn kò si ẹnikẹni larọọwọto ti o lè ràn mi lọ́wọ́.
Mo jade ile-ẹkọ ni 1929, kò sì pẹ́ pupọ lẹhinwa ìgbà naa ti aburo baba mi ti o wa ni America tun fi awọn ẹ̀dà iwe Ilé-Ìṣọ́nà ranṣẹ si mi. Mo bẹrẹ sii gbadun wọn siwaju ati siwaju sii ti mo sì ni ki ó maa fi wọn ranṣẹ si mi lati ìgbà de igba. Mo tun bẹrẹ sii bá awọn ẹlomiran sọrọ nipa ireti fun ọjọ-ọla eyi ti mo ń kẹkọọ rẹ̀ lati inu awọn iwe-irohin naa. Ṣugbọn nigba naa ni igbesi-aye mi yipada lọna àrà.
Itẹsiwaju Nipa Tẹmi ní Burma
Awọn aburo iya mi ti ṣí lọ si Burma (Myanmar nisinsinyi), idile wa sì pinnu pe ti mo bá darapọ mọ wọn, yoo mú iriri mi gbooro sii ati boya ki o sì tun ṣínà anfaani òwò ṣiṣe silẹ fun mi. Iha ila-oorun ti maa ń figba gbogbo wù mi, nitori naa inu mi dun si ifojusọna lilọ sibẹ. Ní Burma, mo ń baa lọ lati maa gba Ilé-Iṣọ́nà lati ọ̀dọ̀ aburo baba mi, ṣugbọn emi funraami kò tii fẹẹkan ri pade ọ̀kan lara awọn Akẹkọọ Bibeli naa, bi a ti ń pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa.
Ní ọjọ kan inu mi dun lati rí ifilọ kan ninu Ilé-Ìṣọ́nà nipa awọn iwe naa Imọlẹ, idipọ meji ti o ṣalaye iwe Ìfihàn ti inu Bibeli. Ni afikun sii, mo kẹkọọ pe igbokegbodo awọn Akẹkọọ Bibeli ní Burma ni a ń bojuto lati ọwọ́ ẹ̀ka Watch Tower Soceity ti India, eyi ti o wà ní Bombay. Mo kọwe ni kiakia lati beere fun awọn iwe Imọlẹ naa, ati lati beere pe ki a rán awọn Akẹkọọ Bibeli ní India lati wa waasu ni Burma.
Awọn iwe naa de lọ́gán nipasẹ ifiweranṣẹ, ní nǹkan bi ọsẹ kan lẹhin naa, awọn Akẹkọọ Bibeli adugbo ọmọ ilẹ Burma bẹ̀ mi wo. Inu mi dun lati mọ̀ pe awujọ kekere kan ninu wọn wà ni ibi ti mo ń gbé ní Rangoon (Yangon nisinsinyi), olu-ilu Burma. Wọn késí mi lati wá si kilaasi ikẹkọọ Bibeli deedee wọn ati lati ṣajọpin pẹlu wọn ninu wiwaasu lati ile de ile. Mo lọra diẹ lakọọkọ ṣugbọn laipẹ mo bẹrẹ sii gbadun ṣiṣajọpin imọ Bibeli pẹlu awọn onisin Buddha, Hindu, ati Musulumi, ati pẹlu awọn ti wọn jẹ́ Kristian ajórúkọ lásán.
Ẹ̀ka ti India wá rán awọn ojiṣẹ alakooko kikun (ti a ń pe ni aṣaaju-ọna) meji, Ewart Francis ati Randall Hopley si Rangoon. Awọn mejeeji pilẹ wá lati England ṣugbọn wọn ti ń ṣiṣẹsin ní India fun ọdun melookan. Wọn fun mi ni iṣiri gan-an ni, nigba ti o sì di 1934, mo ṣe iribọmi gẹgẹ bi ami iṣapẹẹrẹ iyasimimọ mi si Jehofa.
Ìjẹ́rìí Onigboya Kan
Bi akoko ti ń lọ ẹ̀ka ti India fi awọn aṣaaju-ọna pupọ sii ranṣẹ si Burma. Meji ninu wọn, Claude Goodman ati Ron Tippin, ṣe ikesini si ìdíkọ̀ reluwee wọn si bá Sydney Coote, alaboojuto ibudokọ naa sọrọ. Ó gba awọn iwe naa, ó kà wọn tán, ó sì bẹrẹ sii kọwe si ẹgbọn rẹ̀ obinrin ti o wà ni ile-ọkọ, Daisy D’Souza, ni Mandalay. Oun pẹlu gbadun awọn iwe naa ó sì beere fun pupọ sii.
Daisy, ẹni ti o ti ń ṣe isin Katoliki, jẹ́ ẹni ti o ni igboya ara-ọtọ. Ó bẹrẹ sii bẹ awọn aladuugbo rẹ̀ wò ó sì ń sọ fun wọn nipa awọn ohun ti ó ń kẹkọọ rẹ̀. Nigba ti alufaa ṣọọṣi agbegbe naa, ẹni ti o beere idi ti kò fi wá si ṣọọṣi mọ́ lọwọ rẹ̀, sì bẹ̀ ẹ́ wò, ó fi hàn án pe Bibeli kò ti awọn ohun ti ó fi ń kọni lẹhin, iru bi ọ̀run apaadi kan ti ń jó.
Nikẹhin, ó beere lọwọ rẹ̀ pe: “Lẹhin gbogbo awọn ọdun wọnyi ti mo ti ń sọ fun wọn nipa ọ̀run apaadi kan ti ń jó, bawo ni mo ṣe lè sọ fun wọn nisinsinyi pe kò si iru ibikan bẹẹ mọ? Kò si ẹnikankan ti yoo fẹ lati wá si ṣọọṣi.”
“Bi iwọ bá jẹ́ Kristian alailabosi,” ni Daisy dahunpada, “iwọ yoo kọ́ wọn ní otitọ, laika iyọrisi rẹ̀ sí.” Lẹhin naa, o fikun un pe: “Bi iwọ kò bá sọ, nigba naa emi yoo sọ!” Ó sì ṣe bẹẹ.
Dick ati Daisy ati awọn ọmọbinrin wọn agba meji ṣe iribọmi ní Rangoon nigba kan-naa ti mo ṣe tèmi. Ní ọdun mẹta lẹhin naa, ní 1937, mo gbé ọmọbinrin wọn keji, Phyllis, niyawo.
Mo Sálà Lọ si India
Ikọ ogun Japan yawọ Burma nigba Ogun Agbaye II, Rangoon sì ṣubu ni March 8, 1942. Awọn ará ilu ti wọn jẹ́ alejo ni a fipa mu lati sá jade kiakia lọ si India. Ọgọrọọrun gbiyanju lati salọ gba inu awọn igbó nla, ṣugbọn pupọ kú loju ọ̀nà. Ó ṣẹlẹ pe mo mọ oṣiṣẹ ijọba ti ń bojuto ìjáde kuro ni ilu naa gẹgẹ bi ẹnikan, nitori naa o ṣeeṣe fun mi lati rí awọn tikẹẹti gba lori ọ̀kan ninu ọkọ̀ ẹrù ti o kẹhin ti yoo fi Rangoon silẹ lọ si Calcutta. Fifi ile ati pupọ ninu awọn ohun-ìní wa silẹ ninu iru ikanju bẹẹ jẹ́ akoko bibanininujẹ fun gbogbo wa. Awọn ara Japan gba Burma lati 1942 si 1945.
Iṣunna-owo wa rẹlẹ nigba ti a dé India, wíwá iṣẹ rí kò sì rọrun. Eyi yọrisi idanwo igbagbọ. Mo pade oṣiṣẹ ijọba ilẹ Britain kan ti o fun mi ni iṣẹ olówó gọbọi kan ti kìí ṣe ti oníjà ogun, ṣugbọn o ni ninu ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi apakan eto-idasilẹ ológun. Pẹlu iranlọwọ Jehofa, o ṣeeṣe fun mi lati kọ iṣẹ naa ti mo sì tipa bayii pa ẹri-ọkan jijagaara ti Kristian mọ́. (Isaiah 2:2-4) Ní awọn ọ̀nà miiran pẹlu, a nimọlara ọwọ́ onifẹẹ Jehofa.
A fidikalẹ si New Delhi, olu-ilu India, nibi ti ile gbigbe ti fẹrẹ ma ṣeeṣe lati rí. Bi eyi tilẹ ri bẹẹ, a ri ile kan ti o ni ààyè ni aarin ilu-nla naa gan-an. Ó ni iyàrá ìrọ̀gbọ̀kú nla kan pẹlu ẹnu ọ̀nà abawọle kan ti o dá wà, iyàrá yii sì ṣiṣẹ fun iwọnba ọdun diẹ ti o tẹlee gẹgẹ bi Gbọngan Ijọba fun Ijọ Delhi ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, nitori ikaleewọ ti a gbekari gbogbo awọn itẹjade Watch Tower Society ní India ni 1941, a kò le gba awọn iwe-ikẹkọọ Bibeli.
Bi A Ṣe Kadii Ikaleewọ naa Kuro
Ní ọjọ Sunday kan ní 1943, awọn ti wọn ń lọ fun isin ni awọn ṣọọṣi Delhi gba iwe-ilewọ kan ti awọn alufaa ṣọọṣi ọtọọtọ 13 fi ọwọ́ sí. O kilọ pe: “ẸYIN ỌMỌ ILẸ DELHI Ẹ ṢỌRA FUN AWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA.” Ẹsun ti wọn fi kàn wa ni pe a ti ka iṣẹ wa leewọ ní India nitori ọ̀ràn iṣelu.
Pẹlu ifọwọsi ẹ̀ka ilẹ-iṣẹ ti o wà ní Bombay, a yara tẹ̀ iwe-ilewọ kan ti o tu aṣiri awọn alufaa a sì pín in kiri. Niwọn bi mo ti jẹ́ alaboojuto oluṣalaga, orukọ ati adirẹsi mi ni a tẹ̀ si isalẹ iwe-ilewọ ti a kọ ọ̀rọ̀ lile si naa. Laipẹ lẹhin naa, nigba ti awọn ọlọpaa rí emi ati Margrit Hoffman ti a ń pín awọn ẹ̀dà iwe-ilewọ naa, wọn fi aṣẹ-ọba mú wa wọn sì fi wa si ẹwọn. Bi o ti wu ki o ri, wọn tú wa silẹ laipẹ lẹhin ti wọn gba béèlì wa.
Lẹhin naa, lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, Margrit ṣe ibẹwo si ile Ọgbẹni Srivastava, ojiṣẹ kan ti a mọ̀ dunju ninu igbimọ adelé ijọba India. Ọgbẹni Srivastava fi ọyaya gbà á, ó sì sọ fun un ni akoko ijiroro naa, pe awọn iwe-ikẹkọọ wa ni a ti kaleewọ laitọ ní India. Ní ọjọ yẹn o ṣẹlẹ pẹlu pe Margrit pade pẹlu mẹmba ile igbimọ ijọba kan lati ipinlẹ Madras. Oun wà ni ilu-nla naa lati lọ si ipade ile igbimọ ijọba kan. Ó sọ fun un bi ikaleewọ ti a gbekari awọn iwe-ikẹkọọ wa ṣe jẹ eyi ti kò dara rara, o sì ṣeleri lati gbe ibeere naa dide ni ibi ipade kan ti ń bọ̀.
Ni akoko naa, mo ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluṣetọju iṣegun lailo egboogi ní ile-iwosan adugbo kan. Ó dara, o ṣẹlẹ pe Ọgbẹni Srivastava fi ara pa, ile-iwosan naa sì ran mi lọ lati wò ó boya itọju iṣegun lailo egboogi lè ran an lọwọ. Mo ríi pe Ọgbẹni Srivastava ṣọmọlúàbí, bi a sì ti ń dapaara, mo mẹnukan an ṣakala pe a ti fi owó gba béèlì emi ati Omidan Hoffman kuro lẹ́wọ̀n. Mo ṣalaye pe o jẹ́ nitori idaamu awọn alufaa ni a ṣe ka awọn iwe-ikẹkọọ wa leewọ nitori ọ̀ràn iṣelu ṣugbọn pe awa kìí ṣe oṣelu rara. Mo ń baa lọ pe, aṣoju ẹ̀ka wa, Edwin Skinner, ti beere fun ifọrọwanilẹnuwo kan lati ṣalaye ipo wa, ṣugbọn a ti já a kulẹ.
Ní ọjọ bii melookan lẹhin naa, Ọgbẹni Srivastava wi fun mi pe: “Ọgbẹni Jenkins [oṣiṣẹ ijọba naa ti kò nifẹẹ si iṣẹ wa] yoo fẹhinti lẹhin iwọnba ọjọ diẹ sii, ti Ọgbẹni Francis Mudie yoo sì gba ipo rẹ̀. Sọ fun Ọgbẹni Skinner lati yọju si mi, emi yoo si fi í han Ọgbẹni Francis.”
Ọgbẹni Srivastava ṣeto ipade naa gẹgẹ bi ó ti ṣeleri. Nigba ti o ń lọ lọwọ, Ọgbẹni Francis Mudie wi fun Arakunrin Skinner pe: “Emi kò lè ṣeleri ohunkohun fun ọ, ṣugbọn emi yoo gbé ọ̀ràn naa yẹwo.” Niwọn bi o ti jẹ pe ile igbimọ ijọba yoo bẹrẹ iṣẹ ni ọjọ diẹ sii, Arakunrin Skinner duro lati ri abajade rẹ̀. Lotiitọ gẹgẹ bi o ti sọ, mẹmba ile igbimọ ijọba naa lati Madras dide o sì beere pe: “O ha jẹ́ otitọ pe a ka awọn itẹjade Watch Tower Bible and Tract Society leewọ nitori ọ̀ràn iṣelu bi?”
“Bẹẹkọ, a ṣe ikaleewọ naa nitori awọn idi ti o jẹmọ iṣoratẹlẹ,” ni Ọgbẹni Francis Mudie dahunpada, “ṣugbọn ijọba ti pinnu nisinsinyi lati mú ikaleewọ naa kuro.”
Ẹ wo bi akoko naa ti jẹ amuniloriya tó fun wa nigba ti a gbọ irohin yẹn! Ní ọsẹ kan lẹhin naa ẹ̀ka ile-iṣẹ ní Bombay gba lẹta kan ti o fidi opin ikaleewọ naa mulẹ.
Pada Si Burma ti Ogun Ti Ṣe Lọ́ṣẹ́
Iṣakoso orilẹ-ede Britain pada si Burma lẹhin Ogun Agbaye II, mẹwaa ninu wa ti a jẹ́ Ẹlẹ́rìí sì pada si Rangoon ni iwọnba oṣu diẹ lẹhin naa. Inu wa dun lati ri awọn Ẹlẹ́rìí adugbo ti o ṣẹku lẹẹkan sii. Orilẹ-ede naa wà ni ipo ibanujẹ. Awọn ipese fun gbogbo ilu, titikan iná manamana ati ọkọ̀ akérò ti gbogbo ilu, ni kò si. Nitori naa a ra ọkọ jeep kan lọdọ awọn ológun a sì lò ó lọna rere lati kó awọn eniyan lọ si ipade ti a ti ṣeto laipẹ lẹhin ipadabọ wa.
Olufifẹhan kan fun wa ni ilẹ̀, a sì kọ́ Gbọngan Ijọba kan ti o mọníwọ̀n, pẹlu iranlọwọ awọn oninuure eniyan ni agbegbe naa. Awọn igi ọparun ti o tobi, awọn ọparun ti a hun pọ̀ lati fi ṣe ogiri, ati òrùlé koriko ni a fi kọ́ ọ. Níhìn-ín, ni April 1947, Nathan H. Knorr, aarẹ Watch Tower Society nigba naa, ati akọwe rẹ̀, Milton G. Henschel, sọ awọn asọye nigba ibẹwo wọn si Rangoon. Ní akoko naa, a ní awọn Ẹlẹ́rìí 19 ní gbogbo Burma. Ṣugbọn asọye Arakunrin Knorr, ti o sọ ní Gbọngan Iṣere New Excelsior, ni 287 awọn eniyan pesẹ si!
A Fìdíkalẹ̀ ni Australia
Ni January 4, 1948, Burma ni a yọnda ominira kuro labẹ Great Britain fun, ọpọ julọ awọn ọmọ Europe sì kà á si ohun ti o dara julọ lati fi orilẹ-ede naa silẹ. Lẹhin igbeyẹwo tadura-tadura, emi ati Phyllis pinnu lati mú ọmọbinrin wa ki a sì ṣí lọ si Australia. A fìdíkalẹ̀ si Perth, olu-ilu iha Iwọ-oorun Australia.
Ni fifi Burma silẹ lẹẹkan sii, ati ni akoko yii fun ìgbà wíwà pẹ́ titi, jẹ́ akoko ibanujẹ gan-an fun wa. Lati ìgbà de ìgbà, a ń gbọ́ irohin lati ọ̀dọ̀ awọn ẹni ọ̀wọ́n ti wọn wà nibẹ, a sì layọ lati mọ pe iṣẹ Ijọba naa ń tẹsiwaju laisọsẹ ni orilẹ-ede yẹn.
Bẹrẹ ni 1978, fun ọdun mẹrin ó jẹ́ idunnu wa lati ṣiṣẹsin gbogbo awọn ijọ ti ń sọ èdè Griki ninu awọn ilu-nla pataki-pataki ni Australia. Eyi tumọsi irin-ajo gbigbooro, niwọn bi o ti ju 4,200 kilomita (ibusọ 2,600) lọ lati etikun iwọ-oorun si etikun ila-oorun orilẹ-ede ńlá yii. Lẹhin ìgbà diẹ, ipo oju-ọjọ, eyi ti o yatọ gidigidi lati ipinlẹ kan si omiran, pakun ilọsilẹ ninu ilera wa. Nitori naa a tun pada fìdíkalẹ̀ si Perth, nibi ti mo ti ń baa lọ lati maa ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba ninu ọ̀kan lara awọn ijọ 44 ti o wà ni ilu naa.
Bi awọn ọdun ti kọja lọ, ojú mi ti di bàìbàì sii, kíkàwé sì ti di iṣoro. Sibẹ, laika awọn iṣoro ilera sí, ọkan-aya wa ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ sibẹ. Awa mejeeji ń fi igbọkanle duro de ọjọ alayọ naa nigba ti gbogbo eniyan ti o bá bẹru Jehofa yoo rí oòrùn ojurere rẹ̀ ‘ti yoo là, ti oun ti imularada ni ìyẹ́-apá rẹ̀, [awa] ó sì jade lọ, a o sì maa dagba bi awọn ẹgbọrọ maluu inu agbo.’—Malaki 4:2.a
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni December 13, 1992, nigba ti a ń pari ìtàn igbesi-aye yii, Arakunrin Tsatos sun ninu orun ikú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Idile mi pẹlu Arakunrin Henschel ati Knorr ni Burma (Myanmar) ni 1947
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Basil Tsatos ati aya rẹ̀, Phyllis, ni Australia