Ẹ Fi Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run Kún Ìfaradà Yín
‘Ẹ fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfaradà kún ìgbàgbọ́.’—2 PETERU 1:5, 6, NW.
1, 2. (a) Bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ìdarí Nazi, èésìtiṣe? (b) Báwo ni nǹkan ṣe rí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jehofa lábẹ́ ìbánilò lọ́nà lílekoko yìí?
ÀKÓKÒ ṣíṣú dùdù kan ni ó jẹ́ nínú ìtàn ọ̀rúndún lọ́nà ogún. Bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ìdarí Nazi ni a fi àṣẹ-ọba mú lọ́nà tí kò bá ìdájọ́-òdodo mu tí a sì gbé sọ sínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Èéṣe? Nítorí pé wọ́n gbójúgbóyà láti wà ní àìdásí tọ̀tún-tòsì tí wọ́n sì kọ̀ láti pe Hitler ní olùgbàlà. Ọwọ́ wo ni a fi mú wọn? “Kò sí àwùjọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn . . . tí a jọ̀wọ́ wọn fún ìwà-ìkà rírorò ti àwọn ọmọ-ogun-SS ní irú ọ̀nà kan bẹ́ẹ̀ bí a ti ṣe sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli [àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa]. Ó jẹ́ ìwà-ìkà rírorò tí ìdálóró ti ara-ìyára àti ti èrò-orí tí ń báa lọ láìdáwọ́dúró láti orí ọ̀kan bọ́ sí òmíràn sàmì sí, irú èyí tí kò sí èdè tí ó lè ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ayé.”—Karl Wittig, òṣìṣẹ́-olóyè ìjọba Germany tẹ́lẹ̀rí kan.
2 Báwo ni ọ̀ràn ti rí pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí náà? Nínú ìwé rẹ̀ The Nazi State and the New Religions: Five Case Studies in Non-Conformity, Dókítà nínú ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀-ìtàn Christine E. King sọ pé: “Lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkan [ní ìyàtọ̀ gédégédé sí àwọn àwùjọ ìsìn mìíràn] ni ìjọba ti kùnà láti kẹ́sẹjárí.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lódindi mú ìdúró wọn, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn, èyí túmọ̀sí fífaradà dé ojú ikú.
3. Kí ni ó ti mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti farada àwọn àdánwò mímúná?
3 Kí ni ó ti mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti farada irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ní Nazi Germany nìkan ṣùgbọ́n ní gbogbo ayé? Baba wọn ọ̀run ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti faradà nítorí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run wọn. “Jehofa mọ bí a ṣeé dá àwọn olùfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò,” ni aposteli Peteru ṣàlàyé. (2 Peteru 2:9, NW) Ṣáájú nínú lẹ́tà kan-náà, Peteru ti gba àwọn Kristian nímọ̀ràn pé: ‘Ẹ fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfaradà kún ìgbàgbọ́.’ (2 Peteru 1:5, 6, NW) Nítorí náà ìfaradà tan pẹ́kípẹ́kí mọ́ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run. Ní tòótọ́, láti faradà dé òpin, a gbọ́dọ̀ ‘lépa ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run’ kí á sì fi í hàn. (1 Timoteu 6:11) Ṣùgbọ́n kí ni ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run gan-an ní pàtó?
Ohun ti Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run Jẹ́
4, 5. Kí ni ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
4 Ọ̀rọ̀ orúkọ Griki náà fún “ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run” (eu·seʹbei·a) ni a lè túmọ̀ lóréfèé sí “bíbọ̀wọ̀-ńlá tí ó yẹ fún.”a (2 Peteru 1:6, Kingdom Interlinear) Ó dúró fún ìmọ̀lára ọlọ́yàyà látọkànwá síhà ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí W. E. Vine ti wí, arọ́pò ọ̀rọ̀ orúkọ náà eu·se·besʹ, tí ó túmọ̀ lóréfèé sí “ọ̀wọ̀-ńlá tí ó yẹ,” dúró fún “okun náà, tí ó jẹ́ pé bí a bá darí rẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun, yóò ní ìfisílò rẹ̀ nínú ìgbòkègbodò onífọkànsìn.”—2 Peteru 2:9, Int.
5 Ọ̀rọ̀ náà “ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run” nígbà náà tọ́ka sí ọ̀wọ̀ tàbí ìfọkànsìn fún Jehofa tí ń sún wa láti ṣe ohun tí ń tẹ́ ẹ lọ́rùn. Èyí ni a ṣe àní ní ojú àwọn àdánwò tí ó ṣòro pàápàá nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun láti inú ọkàn-àyà wá. Ó jẹ́ ìsopọ̀ onídùúróṣinṣin, ti ara-ẹni pẹ̀lú Jehofa tí a fihàn nínú ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbésí-ayé wa. Àwọn Kristian tòótọ́ ni a rọ̀ láti gbàdúrà pé kí wọn máa gbé “ìgbésí-ayé píparọ́rọ́ àti onídàákẹ́jẹ́ pẹ̀lú ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kíkún.” (1 Timoteu 2:1, 2, NW) Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùtúmọ̀-èdè J. P. Louw àti E. A. Nida ti wí, “nínú iye àwọn èdè kan [eu·seʹbei·a] ní 1 Tm 2.2 ni a lè túmọ̀ lọ́nà tí ó yẹ wẹ́kú sí ‘láti gbé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun yóò ti fẹ́ kí á gbé’ tàbí ‘láti gbé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ fún wa pé kí á gbé.’”
6. Kí ni ìsopọ̀ tí ó wà láàárín ìfaradà àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
6 Àwa lè mọrírì ìsopọ̀ tí ó wà láàárín ìfaradà àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dáradára nísinsìnyí. Nítorí pé a ń gbé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun yóò ti fẹ́ kí á gbé—pẹ̀lú ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run—èyí ń mú kí ayé kórìíra wa, èyí tí ń mú àdánwò ìgbàgbọ́ wá nígbà gbogbo ṣáá. (2 Timoteu 3:12) Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀nà tí a lè gbà sún wa láti farada irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ bí kìí bá ṣe nítorí ìsopọ̀ ti ara-ẹni pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jehofa ń dáhùnpadà sí irú ìfọkànsìn àtọkànwá bẹ́ẹ̀. Ṣá ro bí ó ti gbọ́dọ̀ mú un nímọ̀lára tó láti bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì rí àwọn wọnnì, tí wọ́n ń làkàkà láti tẹ́ ẹ lọ́rùn láìka gbogbo irú àtakò sí, nítorí ìfọkànsìn wọn sí i. Abájọ tí òun fi ní ìtẹ̀sí láti “dá àwọn olùfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò”!
7. Èéṣe tí a fi gbọ́dọ̀ mú ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàgbà?
7 Bí ó ti wù kí ó rí, a kò bí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run mọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì gbà á láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run láìṣiṣẹ́ fún un. (Genesisi 8:21) Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mú un dàgbà. (1 Timoteu 4:7, 10) A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ láti fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà àti ìgbàgbọ́ wa. Èyí, ni Peteru sọ pé, ó gba “ìsapá onífọkànsí.” (2 Peteru 1:5, NW) Báwo, nígbà náà, ni a ṣe lè sapájèrè ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
Báwo ni A Ṣe Lè Sapájèrè Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run?
8. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Peteru ti wí, kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí sísapájèrè ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
8 Aposteli Peteru ṣàlàyé kọ́kọ́rọ́ náà sí sísapájèrè ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ kí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlááfíà bí síi fún yín nípa ìmọ̀ pípéye níti Ọlọrun àti Jesu Oluwa wa, níwọ̀n bí agbára àtọ̀runwá rẹ̀ ti fún wa ni ohun gbogbo tí ó kan ọ̀ràn ìyè àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìmọ̀ pípéye ẹni náà tí ó pè wá nípa ògo àti ìwàfunfun.” (2 Peteru 1:2, 3, NW) Nítorí náà láti fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìgbàgbọ́ àti ìfaradà wa, a gbọ́dọ̀ dàgbà nínú ìmọ̀ pípéye, ìyẹn ni pé, ìmọ̀ kíkún, tàbí èyí tí ó pé pérépéré, nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi.
9. Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé rẹ̀ pé níní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun àti Kristi wémọ́ ohun púpọ̀ ju wíwulẹ̀ mọ ẹni tí wọ́n jẹ́ lọ?
9 Kí ni ó túmọ̀sí láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun àti Kristi? Ní kedere, ó ní ohun púpọ̀ nínú ju wíwulẹ̀ mọ ẹni tí wọ́n jẹ́ lọ. Láti ṣàkàwé: Ìwọ lè mọ ẹni tí aládùúgbò tí ó múlé gbè ọ́ jẹ́ o sì tilẹ̀ lè máa fi orúkọ rẹ̀ kí i pàápàá. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ha yá a ní owó ńlá kan bí? Àyàfi bí o bá mọ irú ẹni tí ó jẹ́ níti gidi. (Fiwé Owe 11:15.) Bákan náà, mímọ Jehofa ati Jesu lọ́nà pípéye, tàbí ní kíkún, túmọ̀sí ohun púpọ̀ ju wíwulẹ̀ gbàgbọ́ pé wọ́n wà àti mímọ orúkọ wọn. Láti múratán láti farada àwọn àdánwò nítìtorí wọn àní dé ojú ikú pàápàá, a gbọ́dọ̀ mọ̀ wọ́n tímọ́tímọ́ níti gidi. (Johannu 17:3) Kí ni èyí ní nínú?
10. Níní ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa àti Jesu wémọ́ ohun méjì wo, èésìtiṣe?
10 Níní ìmọ̀ pípéye, tàbí ìmọ̀ pípé pérépéré nípa Jehofa àti Jesu wémọ́ ohun méjì: (1) mímọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni gidi kan—àwọn ànímọ́, ìmọ̀lára, àti ọ̀nà wọn—àti (2) ṣíṣàfarawé àpẹẹrẹ wọn. Ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run wémọ́ ìsopọ̀ tọkàntọkàn, ti ara-ẹni pẹ̀lú Jehofa a sì ń mú un ṣe kedere nípa ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbésí-ayé wa. Nítorí náà, láti gbà á a gbọ́dọ̀ mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan kí á sì dojúlùmọ̀ dáadáa pẹ̀lú ìfẹ́-inú àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ bí èyí bá ti lè ṣeéṣe níti ẹ̀dá tó. Lóòótọ́ láti mọ Jehofa, ẹni tí a dá wa ní àwòrán rẹ̀, a gbọ́dọ̀ lo irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kí á sì làkàkà láti dàbí rẹ̀. (Genesisi 1:26-28; Kolosse 3:10) Níwọ̀n bí Jesu sì ti ṣàfarawé Jehofa lọ́nà pípé nínú àwọn ohun tí ó sọ tí ó sì ṣe, mímọ Jesu lọ́nà tí ó péye jẹ́ àrànṣe ṣíṣeyebíye nínú mímú ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàgbà.—Heberu 1:3.
11. (a) Báwo ni a ṣe lè jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun àti Kristi? (b) Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ṣàṣàrò lórí ohun tí a kà?
11 Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni a ṣe lè jèrè irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ nípa Ọlọrun àti Kristi? Nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli ni.b Bí ó ti wù kí ó rí, bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa bá níláti yọrísí jíjèrè ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run fún wa, ó ṣe kókó pé kí a lo àkókò láti ṣàṣàrò, ìyẹn ni pé, kí á ronú síwá-sẹ́yìn, tàbí sìnmẹ̀dọ̀ronú, lórí ohun tí a kà. (Fiwé Joṣua 1:8.) Èéṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì? Rántí pé ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run jẹ́ ìmọ̀lára ọ̀yàyà, àtọkànwá síhà Ọlọrun. Nínú Ìwé Mímọ́, àṣàrò ni a sopọ̀ léraléra pẹ̀lú ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ—ẹni ti inú. (Orin Dafidi 19:14; 49:3; Owe 15:28) Nígbà tí a bá ronú síwá-sẹ́yìn pẹ̀lú ìmọrírì lórí ohun tí a kà, yóò máa kọjá lọ sí inú wa lọ́hùn-ún, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ru ìmọ̀lára wa sókè, ní gbígbún èrò-ìmọ̀lára wa ní kẹ́ṣẹ́, tí yóò sì nípa lórí ìrònú wa. Kìkì nígbà náà ni ìkẹ́kọ̀ọ́ tó lè fún ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ tí a ní pẹ̀lú Jehofa lókun kí ó sì sún wa láti gbé ìgbésí-ayé ní ọ̀nà kan tí ó tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn àní ní ojú àwọn ipò-àyíká tí ń peniníjà tàbí àwọn àdánwò tí ó ṣòro.
Sísọ Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run Dàṣà Nínú Ilé
12. (a) Gẹ́gẹ́ bí Paulu ti wí, báwo ni Kristian kan ṣe lè sọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà nínú ilé? (b) Èéṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ fi ń tọ́jú àwọn òbí arúgbó?
12 Ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ni a níláti kọ́kọ́ sọ dàṣà nínú ilé. Aposteli Paulu sọ pé: “Bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti sọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà nínú agbo-ilé tiwọn fúnraawọn kí wọ́n sì máa san ìsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ojú Ọlọrun.” (1 Timoteu 5:4, NW) Títọ́jú àwọn òbí tí wọ́n ti darúgbó jẹ́, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti sọ, fífí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn. Àwọn Kristian tòótọ́ ń pèsè irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ kìí ṣe kìkì nítorí ìmọ̀lára ojúṣe bíkòṣe nítorí ìfẹ́ fún àwọn òbí wọn. Ju ìyẹn lọ, bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n mọ ìjẹ́pàtàkì tí Jehofa gbékarí títọ́jú ìdílé ẹni. Wọ́n mọ̀ dáradára pé láti kọ̀ láti ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́ ní àkókò àìní yóò báradọ́gba pẹ̀lú ‘sísẹ́ ìgbàgbọ́ Kristian.’—1 Timoteu 5:8.
13. Èéṣe tí sísọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà nínú ilé fi jẹ́ ìpèníjà gidi kan, ṣùgbọ́n ìtẹ́lọ́rùn wo ni ó ń jẹ jáde láti inú títọ́jú àwọn òbí ẹni?
13 A gbà pé, kìí fìgbà gbogbo rọrùn láti sọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà nínú ilé. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ni a lè yàsọ́tọ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà jíjìn síra. Àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà lè máa gbé ìdílé tiwọn ró wọ́n sì lè máa wọ̀dìmú pẹ̀lú ìṣúnná-owó. Irú tàbí ìwọ̀n ìtọ́jú tí òbí kan nílò lè fi dandan béèrè ohun tí ó pọ̀ jù níti ìlera ara-ìyára, èrò-orí, àti ti èrò-ìmọ̀lára lọ́wọ́ àwọn tí ó ń pèsè ìtọ́jú náà. Síbẹ̀, ìtẹ́lọ́rùn gidi lè wà nínú mímọ̀ pé títọ́jú àwọn òbí ẹ̀ni kò jásí “ìsanfidípòpadà yíyẹ” nìkan ṣùgbọ́n ó tún tẹ́ Ẹni náà ‘tí a ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé’ lọ́rùn.—Efesu 3:14, 15.
14, 15. Sọ àpẹẹrẹ ìtọ́jú oníwà-bí-Ọlọ́run ní ìhà ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ fún òbí kan.
14 Gbé àpẹẹrẹ kan tí ó gbún èrò-ìmọ́lára ní kẹ́ṣẹ́ nítòótọ́ yẹ̀wò. Ellis àti márùn-ún nínú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ dojúkọ ìpèníjà gidi kan níti títọ́jú baba wọn nínú ilé. “Ní 1986 àrùn rọpá-rọsẹ̀ kọlu baba mi, èyí tí ó jẹ́ kí ó di arọlápá-rọlẹ́sẹ̀ pátápátá,” ni Ellis ṣàlàyé. Àwọn ọmọ mẹ́fà náà ṣàjọpín nínú bíbójútó àìní baba wọn, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti orí wíwẹ̀ ẹ́ dórí rírí i dájú pé a yí i níhà pada kí ó má baà di ẹni tí ibùsùn dápàá sí lára. “A ń kàwé fún un, bá a sọ̀rọ̀, lu ohùn orin fún un. Kò dá wa lójú yálà ó mọ ohun tí ń lọ ní àyíká rẹ̀, ṣùgbọ́n a bá a lò gẹ́gẹ́ bí ẹni pé ó mọ ohun gbogbo lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”
15 Èéṣe tí àwọn ọmọ náà fi tọ́jú baba wọn bí wọ́n ti ṣe? Ellis ń báa lọ pé: “Lẹ́yìn ikú ìyá wa ní 1964, bàbá wa ni ó dánìkan tọ́ wa dàgbà. Ní àkókò yẹn, ọjọ́-orí wa wà láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́rìnlá. Ó wà fún wa nígbà náà; àwa náà sì wà fún un nísinsìnyí.” Ní kedere, kò rọrùn láti pèsè irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì a sì máa mú àwọn ọmọ náà nígbà mìíràn. “Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ipò baba wa jẹ́ ìṣòro onígbà kúkúrú kan,” ni Ellis sọ. “A ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí a ó mú baba wa padà sí ìlera dídára àwa yóò sì tún lè padà wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìyá wa.” (Isaiah 33:24; Johannu 5:28, 29) Dájúdájú, irú ìtọ́jú onífọkànsìn bẹ́ẹ̀ fún òbí kan gbọ́dọ̀ mú ọkàn-àyà Ẹni náà tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ láti bọlá fún àwọn òbí wọn yọ̀!c—Efesu 6:1, 2.
Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run àti Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Náà
16. Kí ni ó níláti jẹ́ ìdí àkọ́kọ́ fún ohun tí a bá ṣe nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà?
16 Nígbà tí a tẹ́wọ́gba ìkésíni Jesu láti ‘máa tẹ̀lé e lẹ́yìn nígbà gbogbo,’ a wá sábẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá kan láti wàásù ìhìnrere nípa Ìjọba náà àti láti sọni di ọmọ-ẹ̀yìn. (Matteu 16:24; 24:14; 28:19, 20) Ní kedere, níní ìpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́-àìgbọdọ̀máṣe Kristian ní ‘àwọn ìkẹyìn ọjọ́’ wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1) Bí ó ti wù kí ó rí, ìsúnniṣe wa fún wíwàásù àti kíkọ́ni gbọ́dọ̀ lọ rékọjá ìmọ̀lára ojúṣe tàbí iṣẹ́-àìgbọdọ̀máṣe lásán. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jehofa gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdí àkọ́kọ́ fún ohun tí a ṣe àti bí a ṣe ṣe tó nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà. “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun inú ni ẹnu í sọ,” ni Jesu wí. (Matteu 12:34) Bẹ́ẹ̀ni, nígbà tí ọkàn-àyà wa bá kún àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ fún Jehofa, a ń sún wa láti jẹ́rìí nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí ìfẹ́ fún Ọlọrun bá jẹ́ ìsúnniṣe wa, iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa jẹ́ fífi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọrun wa hàn lọ́nà tí ó nítumọ̀.
17. Báwo ni a ṣe lè mú ìsúnniṣe títọ̀nà dàgbà fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà?
17 Báwo ni a ṣe lè mú ìsúnniṣe títọ̀nà dàgbà fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà? Fi ìmọrírì ronú síwá-sẹ́yìn lórí ìdí mẹ́ta tí Jehofa ti fifún wa fún nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1) A nífẹ̀ẹ́ Jehofa nítorí àwọn ohun tí ó ti ṣe fun wa. Kò sí ìfẹ́ títóbi tí òun ti lè fihàn sí wa ju bí òun ti ṣe nínú pípèsè ìràpadà náà. (Matteu 20:28; Johannu 15:13) (2) A nífẹ̀ẹ́ Jehofa nítorí ohun tí ó ń ṣe fún wa nísinsìnyí. A ní òmìnira ọ̀rọ̀-sísọ pẹ̀lú Jehofa, ẹni tí ń dáhùn àwọn àdúrà wa. (Orin Dafidi 65:2; Heberu 4:14-16) Bí a ti ń fi àwọn ire Ìjọba sí ipò àkọ́kọ́, a ń gbádùn àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé. (Matteu 6:25-33) A ń gba ìpèsè tí kò dáwọ́ dúró ti oúnjẹ tẹ̀mí tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí a ń dojúkọ. (Matteu 24:45) A sì ní ìbùkún jíjẹ́ apákan ẹgbẹ́-ará Kristian kárí-ayé tí ó yà wá sọ́tọ̀ nítòótọ́ kùrò lára àwọn ènìyàn yòókù nínú ayé. (1 Peteru 2:17) (3) A tún nífẹ̀ẹ́ Jehofa nítorí àwọn ohun tí ó fẹ́ láti ṣe fún wa síbẹ̀. Nítorí ìfẹ́ rẹ̀, a “di ìyè tòótọ́ mú”—ìyè àìnípẹ̀kun ní ọjọ́-ọ̀la. (1 Timoteu 6:12, 19) Nígbà tí a bá gbé ìfẹ́ Jehofa nítìtorí wa yẹ̀wò, dájúdájú ọkàn-àyà wa yóò sún wa láti ní ìpín onífọkànsìn nínú sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀ àti àwọn ète ṣíṣeyebíye rẹ̀! Àwọn ẹlòmíràn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní sọ ohun tí a ó ṣe fún wa tàbí bí a ṣe níláti ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà tó. Ọkàn-àyà wa yóò sún wa láti ṣe ohun tí a lè ṣe.
18, 19. Ìdènà wo ni arábìnrin kan ṣẹ́pá kí ó baà lè ṣàjọpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà?
18 Àní lójú àwọn ipò-àyíká tí ń peniníjà pàápàá, ọkàn-àyà tí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ru sókè ni a ó sún láti sọ̀rọ̀. (Fiwé Jeremiah 20:9.) Èyí ni a fihàn nípa ọ̀ràn Stella, obìnrin Kristian onítìjú akika kan yẹ̀wò. Nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ síi kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó ronú pé, ‘Èmi kò lè lọ láti ilé dé ilé láé!’ Ó ṣàlàyé pé: “Mo sábà máa ń dákẹ́jẹ́ẹ́. Èmi kò lè tọ àwọn ẹlòmíràn lọ láé láti bẹ̀rẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀.” Bí ó ti ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ìfẹ́ rẹ̀ fún Jehofa ròkè, ó sì mú ìfẹ́-ọkàn gbígbóná láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dàgbà. “Mo rántí sísọ fún olùkọ́ Bibeli mi pé, ‘Mo fẹ́ gidigidi láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò ṣáà lè ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì ń dà mí láàmú níti gidi.’ Èmi kò jẹ́ gbàgbé ohun tí ó sọ fún mi láé: ‘Stella, kún fún ìmoore pé ìwọ fẹ́ láti sọ̀rọ̀.’”
19 Láìpẹ́ láìjìnnà, Stella bá araarẹ̀ tí ó ń jẹ́rìí fún aládùúgbò tí ó múlé tì í. Lẹ́yìn náà ó gbé ohun tí ó jẹ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀ ṣíṣe pàtàkì gidi—ó ṣàjọpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé fún ìgbà àkọ́kọ́. (Iṣe 20:20, 21) Ó padà rántí pé: “Mo kọ ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà mi débi pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní iwájú mi, ojora ti mú mi jù láti wo àwọn àkọsílẹ̀ mi!” Nísinsìnyí, ní ọdún márùndínlógójì lẹ́yìn náà, Stella ṣì ń tijú lọ́nà àdánidá. Síbẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá ó sì ń báa lọ láti ní ìpín tí ó ṣe gúnmọ́ nínú rẹ̀.
20. Àpẹẹrẹ wo ni ó fihàn pé kìí tilẹ̀ ṣe inúnibíni tàbí ìfinisẹ́wọ̀n ni ó lè pa àwọn Ẹlẹ́rìí olùfọkànsìn ti Jehofa lẹ́nu mọ́?
20 Kìí tilẹ̀ ṣe inúnibíni tàbí ìfinisẹ́wọ̀n ni ó lè pa ẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí onífọkànsìn tí Jehofa mọ́. Gbé àpẹẹrẹ Ernst àti Hildegard Seliger ti Germany yẹ̀wò. Nítorí ìgbàgbọ́ wọn, àwọn méjèèjì papọ̀ lo àròpọ̀ iye tí ó ju ogójì ọdún lọ nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi àti àwọn ọgbà-ẹ̀wọ̀n Kọmunisti. Àní nínú ẹ̀wọ̀n pàápàá, wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn. Hildegard padà rántí pé: “Àwọn òṣìṣẹ́-olóyè ọgbà-ẹ̀wọ̀n kà mí sí ẹni tí ó léwu ní pàtàkì, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí obìnrin ẹ̀ṣọ́ kan ti wí, mo ń sọ̀rọ̀ nípa Bibeli látàárọ̀-ṣúlẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi mí sí àjàalẹ̀.” Lẹ́yìn tí a fún wọn ní òmìnira wọn, Arákùnrin àti Arábìnrin Seliger lo àkókò kíkún wọn fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian. Àwọn méjèèjì ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú ìṣòtítọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, Arákùnrin Seliger ni 1985 àti aya rẹ̀ ni 1992.
21. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà wa?
21 Nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti lílo àkókò láti fi ìmọrírì ṣàṣàrò lóri ohun tí a kọ́, àwa yóò dàgbà nínú ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Èyí, nípa bẹ́ẹ̀, yóò yọrísí gbígba ìwọ̀n tí ó túbọ̀ kún síi nínú ànímọ́ ṣíṣeyebíye yẹn—ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run. Láìsí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kò sí ọ̀nà tí a lè gbà farada àwọn onírúurú àdánwò tí ń dé bá wa gẹ́gẹ́ bíi Kristian. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á tẹ̀lé ìmọ̀ràn aposteli Peteru, ní bíbáa lọ láti ‘fi ìfaradà kún ìgbàgbọ́ wa àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà.’—2 Peteru 1:5, 6. NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nípa eu·seʹbei·a, William Barclay sọ pé: “Seb- ara [gbòǹgbò] ọ̀rọ̀ náà ni ó túmọ̀sí ọ̀wọ̀ tàbí ìjọsìn. Eu ni ọ̀rọ̀ Griki náà fún gidigidi; nítorí náà, eusebeia jẹ́ ìjọsìn, ọ̀wọ̀ gidigidi tí a sì fifúnni lọ́nà ẹ̀tọ́.”—New Testament Words.
b Fún ìjíròrò nípa bí a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ láti mú ìmọ̀ wa nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jinlẹ̀ síi, wo Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1993, oju-ìwé 12 sí 17.
c Fún ìjíròrò kíkún nípa bí a ṣe lè sọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà fún àwọn òbí àgbàlagbà, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti June 1, 1987, oju-ìwé 13 si 18.
Kí ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Kí ni ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
◻ Kí ni ìsopọ̀ tí ó wà láàárín ìfaradà àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
◻ Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí sísapájèrè ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?
◻ Báwo ni Kristian kan ṣe lè sọ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run dàṣà nínú ilé?
◻ Kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdí àkọ́kọ́ fún ohun tí a ṣe nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìfaradà àti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a fi sẹ́wọ̀n nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi ní Ravensbrück fihàn