Èéṣe tí Olè Jíjà Fi Ń Pọ̀ Síi?
RIO DE JANEIRO—ọjọ́ Sunday, October 18, 1992. Etíkun Copacabana àti Ipanema gbígbajúmọ̀ ni àwọn èrò pé pitimọ sí. Lójijì, àjọ ìpàǹpá àwọn èwe yabo etíkun náà, ní fífìjà pẹẹ́ta láàárín araawọn àti ní jíjí ohunkóhun tí ó níyelórí gbé lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní etíkun náà. Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kéré níye sí wọn dúró síbẹ̀—láìlè ṣe ohunkóhun. Ó jẹ́ àlá búburú ní ọ̀sángangan fún àwọn olùgbé Rio de Janeiro àti àwọn arìnrìn-àjò ìbẹ̀wò.
Níti tòótọ́, ìwà-ọ̀daràn tí ó ní ohun-ìní nínú ti di ohun tí ó wọ́pọ̀. Ní àwọn ìlú ńlá, àwọn olè ti fipá ja àwọn èwe lólè—tí wọ́n sì tilẹ̀ ń pa wọ́n nígbà mìíràn pàápàá—láti gba bàtà tẹníìsì wọn. Àwọn olè ń wọlé yálà àwọn ènìyàn wà ní ilé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ alábòsí, lẹ́yìn ìgbà tí ojú wọn bá ti dá sí inú ilé tán, ń jí ohun-ọ̀ṣọ́ àti owó, tí wọ́n sì ń fẹsẹ̀ fẹ lẹ́yìn náà. Àgbájọ ènìyàn ń kó ilé-ìtajà. Àwọn àwùjọ tí a ṣètò dáradára tilẹ̀ ń jí àwọn ènìyàn gbé pàápàá, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ìpeléke ìye àwọn ìjínigbé ní Brazil. Ó sì ṣeéṣe kí o fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ mìíràn láti inú ìrírí araàrẹ tàbí láti inú ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ rẹ. Ṣùgbọ́n èéṣe tí olè jíjà fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀?
Èéṣe tí Àwọn Ènìyàn Fi Ń Jalè?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpeléke ipò-òṣì àti lílo àwọn oògùn olóró jẹ́ ìdí pàtàkì méjì, ìdáhùn náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. The New Encyclopædia Britannica ṣàkíyèsí pé: “Ìwákiri fún okùnfà kanṣoṣo fún ìwà-ọ̀daràn ni a ti kọ̀ sílẹ̀ pátápátá gẹ́gẹ́ bí aláìméso jáde.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé kan-náà dámọ̀ràn pé irú ìṣòro bíi ti olè jíjà bẹ́ẹ̀ ní tààràtà “kò ṣẹ̀yìn ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkan àti ìbínú àwọn èwe sí jíjẹ́ ẹni tí àṣeyọrí níti ohun èèlò ti ara àti àǹfààní wíwọ́pọ̀ nínú ìgbésí-ayé di àléèbá fún.” Bẹ́ẹ̀ni, nítorí ìkìmọ́lẹ̀ ńláǹlà ti èrò pé ríra ọ̀pọ̀ ọjà bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó jẹ́ ohun yíyẹ, ọ̀pọ̀ ní kò mọ ọ̀nà mìíràn láti ní àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí, bí kìí bá ṣe nípa olè jíjà.
Lọ́nà tí ó fanilọ́kàn mọ́ra, bí ó ti wù kí ó rí, The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Iye ìwà-ọ̀daràn kò yípadà ní ìfiwéra láàárín ẹgbẹ́-àwùjọ ènìyàn ìbílẹ̀ níbi tí àwọn ènìyàn ti gbàgbọ́ pé ọ̀nà ìgbésí-ayé àwọn yóò máa báa lọ. Iye ìwà-ọ̀daràn dàbí èyí tí ó lọ sókè láàárín àwọn ẹgbẹ́-àwùjọ ènìyàn níbi tí ìyípadà léraléra ti ń wáyé nípa ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé àti ohun tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà—àti nínú ìrètí wọn fún ire-àlàáfíà ọjọ́-ọ̀la wọn.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà fikún un pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kò ní àǹfààní iṣẹ́ tí ó pọ̀ tó. Àwọn iṣẹ́ tí a kò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó dàbí èyí tí kò runisókè nígbà tí a bá fiwé èrè kíákíá tí ń runisókè èyí tí ń wọlé wá láti inú ìwà olè-jíjà. Àwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ wà ní ìmúratán láti dágbálé ewu ìfàṣẹ-ọba-múni nítorí pé wọn kò ní púpọ̀ láti pàdánù.”
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ní iṣẹ́ tí kò mówó púpọ̀ wọlé kìí jalè, nígbà tí ọ̀pọ̀ iye àwọn òṣìṣẹ́ onígègé àti àwọn lébìrà ń ṣàfọwọ́rá àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ bí ẹni pé ó jẹ́ apákan owó-iṣẹ́ wọn. Ní tòótọ́, fún àwọn àṣà jìbìtì kan, ipò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kan báyìí ni a béèrè fún. Ìwọ kò ha ti gbọ́ nípa àwọn ìwà-atinilójú tí ó ní ọ̀pọ̀ owó ribiribi nínú lára èyí tí àwọn wọnnì tí a pín ẹ̀bi fún ti jẹ́ àwọn òṣèlú, òṣìṣẹ́ ìlú, àti àwọn oníṣòwò bí? Kò sí iyèméjì kankan nípa rẹ̀, olè jíjà kò mọ sọ́dọ̀ àwọn òtòṣì nìkan.
Tún rántí, pẹ̀lú, pé àwọn àwòrán ara ògiri àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń fi olè jíjà ṣàwàdà (òṣèré tí ó ṣe pàtàkì jùlọ náà tilẹ̀ lè jẹ́ olè), èyí tí ó jọbí ẹni pé ó ń mú ìwà olè-jíjà túbọ̀ ní ìtẹ́wọ́gbà. Kí á gbà pé, wíwo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni a lè kà sí eré-ìnàjú, ṣùgbọ́n ní àkókò kan-náà, àwùjọ ni a fi bí a ti ń jalè hàn. A kò ha fi ọgbọ́n gbé èrò náà jáde pé àfàìmọ̀ ni kí ìwà-ọ̀daràn má pé bí? Láìṣiyèméjì, ìwọra, ìmẹ́lẹ́, àti ìrònú náà pé gbogbo ènìyàn ní ń ṣe é láṣegbé parapọ̀ dákún ìbísí nínú olè jíjà. Lọ́nà tí kò ṣeésẹ́, a ń gbé ní “ìgbà ewu” ti a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ìfẹ́ fún ara-ẹni àti ìfẹ́ owó mókè.—2 Timoteu 3:1-5.
Ìwọ Kò Gbọ́dọ̀ Jalè
Láìka àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàrere ayé tí a ti gbé gbòdì sí, ó ṣekókó láti ṣègbọràn sí òfin náà pé: “Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́.” (Efesu 4:28) Ẹnìkan tí ó gbé ìníyelórí gíga jù karí àwọn ohun-ìní tàbí ìgbádùn lè fi ìtànjẹ mú araarẹ̀ gbàgbọ́ pé ìwà olè-jíjà yẹ ní ohun à-á-farawewu fún. Ṣùgbọ́n olè jíjà wúwo ní ojú Ọlọrun ó sì fi àìní ìfẹ́ fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́-ẹni hàn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àní ìwà olè-jíjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ pàápàá lè ṣamọ̀nà sí mímú ọkàn ẹni gíràn-án. Kí sì ni nípa dídi ẹni tí a ń wò gẹ́gẹ́ bí alábòsí? Ta ni yóò fọkàn tán olè? Lọ́nà tí ó mọ́gbọ́ndání, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín kí ó jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe-búburú.”—1 Peteru 4:15.
Dájúdájú ìwọ dẹ́bi fún ìpeléke nínú olè jíjà, ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ènìyàn ní agbègbè tí ìwà-ọ̀daràn ti pọ̀ ṣe ń kojú rẹ̀? Báwo ni àwọn olè tẹ́lẹ̀rí kan ti ṣe yí ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn padà? Olè jíjà yóò ha dópin kárí-ayé láé bí? A rọ̀ ọ́ láti ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e, “Ayé kan Láìsí Àwọn Olè.”